Bí wọ́n ṣe fẹ ìfẹ̀hónúhàn àgbẹ̀ kan ní Bucharest lójú lórí ayélujára, tí wọ́n sì tún wá fi ọgbọ́n gbà á mọ́ ọn lọ́wọ́

Thumbnail image of the <a href="https://www.youtube.com/watch?v=FEAY-LK9FWA">Youtube video</a> on September 15 protests in Bucharest by Digi24HD. Fair use.

Àwòrán kékeré ti àwòrán-olóhùn YouTube náà, “Violențe la protestul oierilor din Piața Victoriei”, lórí ìfẹ̀hónúhàn ọjọ́ 15 oṣù Kẹ̀sán ọdún 2006 ní Bucharest, orílẹ̀-èdè Romania, látọwọ́ Digi24HD. Ìtumọ̀ àkọ́lé nì ní èdè Gẹ̀ẹ́sì: “Ìwà ipá níbi ìfẹ̀hónúhàn ní Gbágede Victoriei. Ìkọlù pẹ̀lú àwọn ọlọ́pàá gendarmes, wọ́n sì lo gáàsì tajútajú.” Ìlò lọ́nà tó bófin mu.

Àtẹ̀jáde yìí láti ọwọ́ Matei Vrabie àti Calin Georgia ti Funky Citizens, àjọ tí kìí ṣe ti ìjọba kan ní Romania tí ó ń ṣiṣẹ́ ní ìkóríta ìṣàkóso ìjọba rere àti ìkópa ọmọ ìlú, jẹ́ ara kan nínú àwọn ìròyìn alákọlẹ́sẹẹsẹ Ìfihàn (Spotlight) ti oṣù Kẹsàn-án 2026 ti Global Voices, “Ìfẹ̀hónúhàn nínú Ìjọba tiwa-n-tiwa.” Pẹ̀lú ìfihàn yìí, a fẹ́ ṣe àwárí onírúurú àwọn ọ̀nà ìfẹ̀hónúhan, àwọn ọgbọ́n tí àwọn ìjọba ń lò láti sọ wọ́n di aláìbófinmu, fi ipá tẹrí wọn bọlẹ̀, àti ìbáṣepọ̀ onípọ́n-ọ́n-na tí ó wà láàárín ìfẹ̀hónúhàn àti ìjọba tiwa-n-tiwa. O lè ṣe àtìlẹyín fún iṣẹ́ ìròyìn yìí nípa ṣíṣe ìtọrẹ owó níbí.

Ní ọjọ́ 15 oṣù Kẹsàn-án, ọgọọgọ́rùn-ún sí ẹgbẹ̀rún àwọn olùṣọ́ àgùntàn, àwọn olùṣìn ẹran àti àwọn àgbẹ̀ mìíràn ni wọ́n parojọ sí Gbàgede ìlú Victoriei, ní iwájú olú ilé-iṣẹ́ ìjọba Romania ní Bucharest, láti fi ẹ̀hónú wọn hàn lórí ìfòfindè kíkó àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́ alààyè jáde lọ sí òkè òkun jákèjádò Àjọ Ìṣọ̀kan Yúróòpù (EU), èyí tí a ti fà gùn titi di òpin ọdún 2026 lẹ́yìn àwọn ìbẹ́sílẹ̀ àjàkálẹ̀ àrùn àwọn ẹran aṣàpọ̀jẹ kéékèèké àti àrùn ọgbẹ́ àgùntàn.

Wọ́n béèrè owó gbà-má-bínú fún àwọn ẹran tí wọ́n pa nítorí àrùn àti fún àwọn èso oko tí wọ́n bàjẹ́ látàrí ọ̀gbẹlẹ̀. Àwọn olùgbékalẹ̀ ti ké sí àwọn olùfẹ̀hónúhàn láti mú àgùntàn, ọkọ̀ katakata àti àwọn ìdì koríko gbígbẹ wá sí gbàgede ìlú náà, ṣùgbọ́n àwọn ìhámọ́ ṣe ìdènà fún àwọn ẹran alààyè àti àwọn ẹ̀rọ ńláńlá láti wọ inú agbègbè ìfẹ̀hónúhan náà.

Ìfẹ̀hónúhàn náà bẹ̀rẹ̀ ní ìrọwọ́rọsẹ̀ ṣáájú aago 10 òwúrọ̀. Nígbà tí yóò fi di ọ̀sán, àwọn olùfẹ̀hónúhàn kan ti rọ́ kọjá àwọn ìdènà ọlọ́pàá, wọ́n sì ń sọ òkúta, ìgò àti àwọn òkúta ẹgbẹ́ ojú ọ̀nà; àwọn ọlọ́pàá-ológun Gendarmerie sì fi afẹ́fẹ́ gáàsì tajútajú dá wọn lóhùn. Ọlọ́pàá-ológun gẹ́ndámù ìlú Bucharest sọ pé àwọn ènìyàn 24 nílò ìtọ́jú ìlera ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn, lára wọn ni ọlọ́pàá-ológun gẹ́ndámù 10, mẹ́rin nínú wọn sì wà ilé ìwòsàn, wọ́n sì mú àwọn èèyàn 47 lọ sí àwọn àgọ̀ ọlọ́pàá. Ààrẹ Nicușor Dan àti Adelé Aṣàkòóso Ìjọba Ilie Bolojan ni wọ́n jọ bu ẹnu àtẹ́ lu ìwà ipá náà. Àwọn ẹgbẹ́ àwọn ẹlẹ́ran ọ̀sìn sọ pé àwọn ènìyàn tí kì í ṣe àgbẹ̀ ti darapọ̀ mọ́ àwọn ọ̀mítímitì èrò náà, Alákòóso Ìpínlẹ̀ Bucharest sì sọ pé “àwọn àgbẹ̀ àgùntàn kì í kó ara wọn jọ báyìí.”

Ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní òpópónà nìyẹn. Ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lórí ayélujára, ṣẹlẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀ àti ṣáájú rẹ̀, ni kókó ìròyìn tuntun kan láti ọwọ́ Funky Citizens, àjọ ọmọ-ìlú ní Bucharest, níbi tí mo ti ń ṣe ìwádìí lórí ìfẹ̀tànyínilọ́kànpadà àti ìròyìn èké lórí ayélujára. Pẹ̀lú àwọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀ mi, a ṣe àyẹ̀wò àwọn àtẹ̀jáde gbangba lórí Facebook 1,186 àti àwọn àwòránhùn orí TikTok 100 tí wọ́n tẹ̀ jáde ní èdè Romanian ní ọjọ́ 14 àti 15 oṣù Kẹsàn-án, a sì tọpa àwọn ìtàn tí ó tàn káàkiri nípa ìfẹ̀hónúhan náà, bí ọ̀rọ̀ kan náà tàbi èyí tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jọra ṣe ń yí láti ojú-ewé kan sí òmìíràn láàárín ìṣẹ́jú-àáyá síra, àti irú èdè tí ó bá àwọn ìpè fún ìkóra-ẹni-jọ rìn.

Ìwádìí tí ó hàn kedere jùlọ kò kan ìwà ipá náà. Ó kan alẹ́ ọjọ́ kan ṣáájú. Láàárín aago 7:00 sí 7:15 alẹ́ ní ọjọ́ 14 oṣù Kẹsàn-án, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ojú-ewé Facebook tún àtẹ̀jáde tẹ̀, tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jọ ọ̀rọ̀ kan náà, àtẹ̀jíṣẹ́ kan tí ó sọ pé à ń retí “àwọn àgbẹ̀ tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 200,000” ní Gbàgede Victoriei ní ọjọ́ kejì. Ní ọjọ́ kejì, gẹ́gẹ́ bí àwọn ìròyìn ti ṣe sọ, àwọn èèyàn tí wọ́n lé ní 3,000 ni wọ́n jáde síta. Nípa lílo àkókò ìṣẹ́jú-àáyá 300 láti ṣàmì sí ọ̀rọ̀ kan náà tàbi ọ̀rọ̀ tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jọra tí àwọn ojú-ewé ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tẹ̀ jáde, a ya àwòrán àwọn ìbáṣiṣẹ́pọ̀ tí ó yọrí sí. Ó lé ní nǹkan bí ìdá 90 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ìṣàmúlò 2,253 nínú ìsopọ̀ orí ayélujára ìkẹyìn, tí ó ti wà nílẹ̀ láàárín ọjọ́ méji gbáko, ti gbaradì láàárín àwọn ìṣẹ́jú 15 wọ̀nyẹn ní ìrọ̀lẹ́ ṣáájú kí ìfẹ̀hónúhàn náà ó tó bẹ̀rẹ̀.

Distribution of posts and public attention. Graph by Funky Citizens, used with permission.

Pínpín kárí àwọn àtẹ̀jáde àti àkíyèsí aráàlú. Àwòrán láti ọwọ́ Funky Citizens, tí a lò pẹ̀lú àṣẹ wọn.

Nígbà tí yóò fi di aago 3:30 ọ̀sán ní ọjọ́ 15 oṣù Kẹsàn-án, ojú-ìsopọ̀ náà ní àwọn ìṣámúlò 160 àti àwọn ọ̀rọ̀ 12 ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọ́n ti pín káàkiri lórí rẹ̀. Ètò náà kóra jọ gan-an: àwọn ìṣùpọ̀ méjì tí ọ̀kọ̀ọ̀kan ní ìṣámúlò 50, tí ó dá lórí ẹ̀dà méjì “àwọn àgbẹ̀ 200,000″ tí wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ jọra, èyí tí ó jẹ́ 100 nínú àwọn ìṣámúlò 160 náà, tí wọ́n sì ni èyí tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdá 90 nínú ọgọ́rùn-ún gbogbo ìsopọ̀. Àwọn ẹ̀rọ orí ìsopọ̀ tí a lè dárúkọ tó hàn jù lọ, bíi Case de Vis, femina.ro àti ROL.ro, jẹ́ ojú-ewé tó ń kó àkóónú jọ tí wọ́n sì ń pín in káàkiri, wọn kì í ṣe ti òṣèlú ní gbangba. Ṣíṣe ìtúntẹ̀jáde ọ̀rọ̀ kan náà láàárín ìṣẹ́jú-àáyá jẹ́, nípa ìtumọ̀ rẹ̀, pínpín nǹkan káàkiri lọ́nà ìbáṣiṣẹ́pọ̀ ní ìtumọ̀ ìlànà ìmọ̀-ẹ̀rọ. Ṣùgbọ́n kò dá nìkan fúnra rẹ̀, ṣe àfihàn ẹni tó ṣàgbékalẹ̀ rẹ̀ tàbí ìdí tí ó fi ṣe é; àgbàjọ-ìwífún wa kò fi àyè gba ìṣèpinnu nípa ète.

Nínú ìṣàkóso yìí, àwọn ìtàn mẹ́rin kan fara hàn gbangba nínú àkójọ ìròyìn náà. Ìkínní jẹ mọ́ ohun tí àwọn àgbẹ̀ ń béèrè tí wọ́n jẹmọ́ nípa ọrọ̀ ajé ní pàtó: kí dídáwọ́ ẹran pípa dúró, kí ìtajà sí òkèèrè ó bẹ̀rẹ̀ padà, àti kí iye owó ọjà ó má hán gógó. Ìkeji dá lórí ìforígbárí pẹ̀lú àwọn ọlọ́pàá-ológun Gendarmerie, níbi tí àwọn ìròyìn kan ń dá àwọn olùfẹ̀hónúhàn lẹ́bi pé wọ́n fi ipá ré ìdènà àwọn ọlọ́pàá kọjá, tí àwọn ìròyìn mìíràn sì ń dá ẹ̀bi fún àwọn ọlọ́pàá, pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń tẹnumọ́ léraléra pé a ti fi àwọn “adárúgúdùsílẹ̀” sí àárín àwọn èrò náà. Ìkẹ́ta sọ ìfẹ̀hónúhàn náà di ti ọ̀rọ̀ òṣèlú pátápátá, tí ó dá lórí ìpè tí olórí AUR, George Simion, pè fún ìfọkanbalẹ̀ àti pé kí àwọn Gendarmerie kó ara wọn ní ìjánu, àti lórí àwọn àríyànjiyàn nípa bóyá ìdásí rẹ̀ ṣe ìrànwọ́ tàbi ó ṣe àkóbá fún ọ̀ràn àwọn àgbẹ̀ náà. Ìkẹrin, èyí tí kò fi bẹ́ẹ̀ so mọ́ ohun tí ó ṣẹ̀lẹ̀ ní ọjọ́ náà, dá lórí àwọn ìṣòro tí ó wà nínú ìpìlẹ̀ iṣẹ́ àgbẹ̀ ní Romania, láti ìdádúró owó ìrànwọ́ EU fún ẹ̀rọ iṣẹ́ àgbẹ̀ títí dé ìyípadà sí ọ̀nà ìsọ̀gbìn tí kì í tu ilẹ̀.

Chronological 3D dissemination network. Graph by Funky Citizens, used with permission.

Ìtànkálẹ̀ àtẹ̀jáde olójú ìwòye mẹ́ta ní ṣísẹ̀ntẹ̀lé. Àwòrán láti ọwọ́ Funky Citizens, tí a lò pẹ̀lú àṣẹ wọn.

Àwọn ìtọ́kasí sí Àjọ Ìṣọ̀kan Yúróòpù (EU) pín sí èdè àmúlò méjì tó yàtọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Àwọn àtẹ̀jáde mẹ́tàdínláàdọ́ọ́rin dárúkọ Brussels tàbí EU nípa ìfẹ̀hónúhàn náà. Àwọn kan ṣe àpèjúwe ìjíròrò tí ó jọjú lórí ìfòfindè ìkó ẹran jáde sí òkèèrè pẹ̀lú Àjọ Ìgbìmọ̀ Yúróòpù (European Commission); àwọn mìíràn tún sọ EU gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá, pẹ̀lú àwọn àgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ bíi “àfojúsùn Yúróòpù ni láti fi wá sílẹ̀ láìsí ẹran, láìsí àgbẹ̀ ẹran-ọ̀sìn, láìsí iṣẹ́ àgbẹ̀ ní Romania,” tàbí àwọn ẹ̀sùn pé “EU fẹ́ fi ebi pa Romania.”

Ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, a tọpa àwọn ìkànnì orí Telegram méjì tí Ilé-Ẹ̀kọ́ Orílẹ̀-èdè “Elie Wiesel” àti ilé-iṣẹ́ aṣèwádìí nípa ọ̀rọ̀ ààbò GLOBSEC ti ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ tẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ara àwọn àjọ ìpolongo tí ó ń ṣe ègbè lẹ́yìn Kremlin, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ ní Romania àti Moldova. Ìrísí tí wọ́n fi ṣe àgbékalẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn wọn yípadà láàárín wákàtí díẹ̀. Ní aago 11:56 owúrọ̀, ìkànnì kan ṣe àlàyé ìfẹ̀hónúhàn náà, ó sì ṣe àtòjọ àwọn ohun tí àwọn àgbẹ̀ ń béèrè. Ní aago 2:06 ọ̀san, ìkànnì kejì kan ti bẹ̀rẹ̀ ìkìlọ̀ pé “àwọn afipágbàjọba” yóò lo ìfẹ̀hónúhàn náà láti ṣe “ìtọ́níjà, lẹ́yìn náà ìfẹ̀lójú, lẹ́yìn náà ipò pàjáwìrì.” Ní aago 4:03 ọ̀sán, lẹ́yìn ìkọlù náà, ìkànnì kan náà tún yínu padà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í tako bí àwọn ilé-iṣẹ́ móhùmáwòrán ṣe gbé ìròyìn ìforígbárí náà. Irú ìyípadà kan náà, láti ìkẹ́dùn sí ìtọ́níjà-àti-ìfẹ̀lójú sí àìlèfọkàntán àwọn oníròyìn, tún wáyé nínú àwọn àtẹ̀jáde tí ó lo èdè ìkójọpọ̀ ní gbangba wálíà, pẹ̀lú àwọn ìpè pé kí wọ́n “gba Bucharest” àti àwọn ìkéde pé “ÌYÍPADÀ-ÌJỌBA ti bẹ̀rẹ̀.”

Lórí TikTok, níbi tí a ti ṣàyẹ̀wò lórí àwọn àwòránhùn 100 láti orí àwọn ìṣàmúlò 34 lábẹ́ àmì ọ̀rọ̀-atọ́ka #protest, irú ìpínuà kan náà tún sẹ́yọ. Àwọn àwòránhún mọ́kànlélọ́gbọ̀n ló mẹ́nu ba Gendarmerie tààràtà nínú àpèjúwe wọn, àwòránhùn kan ṣoṣo tí a pin kiri jù lọ, èyí tí ó kéde ìforígbárí tuntun àti ìtìmọ́lé ọ̀pọ̀ èèyàn, dá nìkan ní ìfèsì-àwọn-òǹwòran tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 30,000.

Kò sí èyíkéyìí nínú gbogbo èyí tí ó sọ fún wa ẹni tí ó ṣètò ìfẹ̀hónúhàn náà, tàbi ẹni tí ó jèrè láti inú bí wọ́n ti ṣe fẹ ìretí nípa rẹ̀ ní àfẹ̀lójú. Ohun tí àwọn ìwífún-oní-àlàyé náà fi hàn ni bátànì kan tí ó jọra jákèjádò Romania àti agbègbè rẹ̀: ẹ̀dùn ọkàn ọrọ̀ ajé tòótọ́, tí àkójọ àwọn ìṣàmúlò-orí-ayélujára kan tí wọ́n ń ṣe ìtúntẹ̀jáde fẹ́ lójú láàárín wákàtí díẹ̀, tí wọ́n sì wá fi kún àwọn ìtàn tí ó ti wà tẹ́lẹ̀ lórí àwọn ìdìbò tí a jí, ìjọba tí kò bófin mu àti “ètò” kan tí a gbọdọ̀ dojú ìjà kọ.

Ṣíṣe ìyàtọ̀ láàárín ìfẹ̀hónúhan àwọn àgbẹ̀ àti ìfẹ̀lójú tí a fẹ̀ ẹ́ lójú lórí ayélujára, àti ipa ìfẹ̀lójú ìmọ̀ọ́mọ̀ ṣe òṣèlúkóṣèlú láti lo ìfẹ̀hónúhàn náà fún ète òṣèlú, kì í ṣe atọ́ka òye ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní Gbàgede Victoriei. Òun gan-an ni ìtàn náà.

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.