
ACC. H. O. Idoko, aṣojú àjọ Nigeria Security and Civil Defense Corps (NSCDC), ń sọ̀rọ̀ níbi àpéjọ àtúnyẹ̀wò Ìlànà-òfin Ìfararọ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní Abuja, 4-6 August, 2026. Àwòrán láti ọwọ́ Triple Peace Africa. A gba àyè láti lò ó.
Owó púpọ̀ ni àwọn oríẹ̀-èdè àgbáyé lápapọ̀ ń ná sórí ogun àti ètò ààbò ju ti àtẹ̀yìnwá lọ. Ìnáwó àgbáyé lápapọ̀ ti tó tírílíọ̀nù 2.7 owó orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ní ọdún 2024, gẹ́gẹ́ bí Stockholm International Peace Research Institute (SIPRI) ti ṣe sọ, bí àwọn ìjọba ṣe fi kún owó níná nínú rògbòdìyàn ogun tí ó ń wáyé ní Yúróòpù àti ìwọ̀ oòrùn Éṣíà àti àwọn ìkọlura tí ó ń gbèrú sí i tí ó dínà ààbò níbòmíràn.
Áfríkà wà lára àwọn ìṣesí yẹn. Ìnáwó àwọn ológun ní kọ́ńtínẹ́ǹtì náà ti fò fẹ̀rẹ̀ sí ìdá 8.5 nínú ọgọ́rùn-ún ní ọdún 2025 sí bílíọ̀nù 58.2 billion. Ìnáwó orílẹ̀-èdè Nàìjíríà pàápàá lọ sókè jù ti àtẹ̀yìnwá lọ pẹ̀lú ìdá 55 nínú ọgọ́rùn-ún sí bílílọ̀nù 2.1 owó orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà gẹ́gẹ́ bí àfihàn SIPRI.
Ṣùgbọ́n fún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, owó ìṣúná rọ̀gùrọ́gú fún ètò-ààbò kò ì tí ì yanjú ìṣòro tí ó ti ó ń gbèrú sí i. Orílẹ̀-èdè ń dojú kọ ìrúkèrúdò àwọn agbésùnmọ̀mí, ìwà ìgárá-jíjà, ìjínigbé ọlọ́pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, ìjà ẹlẹ́yàmẹ̀yà, àti ìwà ọ̀daràn ẹlẹ́nipúpọ̀, pẹ̀lú àwọn ìrísí tó yàtọ̀ gedegbe láti agbègbè kan sí òmíràn. Láti oṣù Kẹfà ọdún 2025 sí Oṣù Keje ọdún 2026, okééré jù àwọn ènìyàn tí ó tó 7,825 ni wọ́n jí gbé nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ 1,713 tí ó jọ ìjínigbé káàkiri orílẹ̀-èdè, tí ó sì jẹ́ wí pé àwọn ènìyàn tí ó tó 1,142 ni wọ́n pa. Ní Oṣù-keje, Ààrẹ Bọ́la Tinubu fọwọ́sí ìgbésẹ̀ láti gba àwọn ọmọ-ogun 28,000 kún àwọn tí ó ti wà nílẹ̀ àti ìṣẹ̀dá àwọn ẹ̀ka ikọ̀ ọmọ-ogun tuntun, èyí ni tuntun nínú ọ̀wọ́ àwọn ìgbésẹ̀ láti mú kí àwọn ọmọ-ogun àti àwọn àjọ ààbò orílẹ̀-èdè náà gbòòrò sí i.
Ipò yìí ló ń fa àtúnyẹ̀wò Ìlànà-òfin Ìfararọ Orílẹ̀-èdè náà, èyí jẹ́ ìlànà tí a ṣètò láti mú kí ìṣètò tó dára jù dé bá ìdènà ìkọlura àti ọ̀nà ìlàjà, nígbà tí ó tún ń yanjú àwọn okùnfà tí ó ń jẹ́ kí làásígbò ta gbòǹgbò kí ó sì tún máa ṣẹlẹ̀ léraléra.

Ọ̀mọ̀wé Sanda Julie, Olùdarí Àgbà ti Àjọ Onílàjà ní Ìpínlẹ̀ Plateau (Plateau State Peacebuilding Agency), ń sọ̀rọ̀ níbi àpèjọ ìpàdé àtúnyẹ̀wò Ìlànà-òfin Ìfararọ Orílẹ̀-èdè, tí ó wáyé ní Abuja, orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, láti ọjọ́ 4-6 oṣù Kẹjọ ọdún 2026. Àwòrán láti ọwọ́ Triple Peace Africa. A gba àyè láti lò ó.
Àtúnrò ọ̀nà tí Nàìjíríà ń gbà ṣètò ìfararọ ìlú
Ìgbìyànjú àkọ́kọ́ tí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ṣe láti ní Ìlànà-òfin Ìfararọ Orílẹ̀-èdè ni ọdún 2012, nígbà tí Àjọ tí ó ń rí sí ètò Ìfararọ àti Ìlàjà Rògbòdìyàn, ìyẹn Institute for Peace and Conflict Resolution (IPCR) darí ètò náà tí ó sì ṣe àkọsílẹ̀ ìlànà-òfin àkọ́kọ́. Àkọsílẹ̀ ìlànà-òfin náà kò jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún lílò. Pẹ̀lú iye àwọn ènìyàn tí ó lé ní mílíọ̀nù 240 àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀yà àti èdè, orílẹ̀-èdè Nàìjíríà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn orílẹ̀-èdè ní àgbáyé tí ó ní àwùjọ tí ó kún fún onírúurú ẹ̀yà. Níní onírúurú ẹ̀yà àti àṣà kì í ṣe ohun tó ń fa ìjà. Ṣùgbọ́n ìfigagbága òṣèlú, ìkùnsínú lórí ilẹ̀ àti ohun àlùmọ́ọ́nì, ìrúkèrúdò láàárín àwọn aládùúgbò, àwọn àjọ àìlágbára àti èrò pé a ti ya wá sọ́tọ̀ máa ń fi oríkorí ní orílẹ̀-èdè náà, má a ń sọ ẹ̀dùn ọkàn àdúgbò di ìwá ipá.
Ní gbogbo Oṣù-kẹjọ, àwọn àjọ ìjọba, àwọn ẹgbẹ́ tí ó ń rí sí ètò ìfararọ, àwọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀ ìdàgbàsókè àti àwọn ọ̀mọ̀ràn nípa ẹ̀rọ àti ọgbọ́n ìmọ̀ pàtó pàdé ní Abuja àti ní ẹ̀kùn ìṣèlú mẹ́ta — Kano, Enugu àti Èkó — láti ṣe àtúnyẹ̀wò ìlànà-òfin àtijọ́ àti láti ṣe ìlànà tuntun kan tí yóò so àwọn aláṣẹ ìjọba àpapọ̀, ti ìpínlẹ̀ àti ti ìjọba ìbílẹ̀ pọ̀.
Chris Ngwodo, adarí àgbà fún Ọ́fíìsì Nàìjíríà fún Ìmúrasílẹ̀ Ọgbọ́n-Ìdáàbòbò àti Ìfarada, ìyẹn Strategic Preparedness and Resilience (OSPRE), ó ń bá Global Voices sọ̀rọ̀ ní Abuja, Nàìjíríà, sọ wí pé ìdí tí a fi ń ṣe é ni láti mú ìdènà ìjà wọnú ètò ààbò orílẹ̀-èdè tó gbòòrò jù, àti láti ṣàyẹ̀wò ré kọjá ìwà ipá tí a lè fojú rí nínú ìkọlura ogun sí àwọn ohun tí ó ń ṣe okùnfà rẹ̀.
“Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwà ipá ló wà tí kì í ṣe ìwà ipá tí a lè fojú rí gbangba,” ni ó sọ, bí ó ti ṣe ń tọ́ka sí àìdọ́gba tó wá nínú ètò, àìṣe déédéé nínú ètò ìdájọ́, àìbìkítà láti ọ̀dọ̀ ìjọba àti àìsí àǹfààní gẹ́gẹ́ bí àwọn ìjà tí kò fojú hàn gbagba ṣùgbọ́n tí okùnfà rẹ̀ kò kéré ní ipa ìbàjẹ́ .
Ngwodo gbé ìlànà-òfin náà kalẹ̀ lórí èrò tí a mọ̀ dáadáa wí pé ìfararọ kì í ṣe ti àìsí ìjà lásán, bí kò ṣe ti wíwà ìdájọ́ òdodo.
Ó ṣàlàyé wí pé “Ìwà ipá tó wà nínú ètò àwùjọ kò hàn gbangba. Kò sí ẹnì tí ó lè rí í, ṣùgbọ́n ó wà.” “Íwà ìpáǹle oníṣẹ̀lẹ̀ ni ohun tí ó máa ń wáyé nígbà tí àwọn ènìyàn bá ń jà.” Ìlànà tuntun náà, bí ó ṣàlàyé, wà láti yanjú méjèèjì nípa gbígbé ara lé orí ìdájọ́ òdodo ìmúpadàbọ̀sípò, ìdájọ́ òdodo ìjẹníyà, àti ìdájọ́ òdodo ìpín-déédéé, àti lórí ìmúdọ́gba àǹfààní fún gbogbo ènìyàn.
Nígbà tí a béèrè bóyá ìlànà-òfin tuntun yóò yanjú àwọn ìṣòro ààbò orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Ngwodo kò ṣiyèméjì: “Kò ní yanjú wọn.” Ohun tí ìwé àkọsílẹ̀ náà lè ṣe, bí ó ṣe jiyàn, ni láti yí ipò orílẹ̀-èdè náà padà láti ìhùwàsí kíjokíjo lẹ́yìn tí ìṣẹ̀lẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ sí ètò ìmúrasílẹ̀, tí ó ju ọ̀nà tí a lè gbá dojúkọ ìwà ipá nìkan, ṣùgbọ́n ṣíṣe àwárí ìdí tí ìwà àwọn náà ṣe wọ́pọ̀ ní àwọn ibìkan àti ìdí tó fi ń fi ìgbàgbogbo wáyé.
Ó sọ wí pé “Kì í ṣe wí pé àwọn ènìyàn ń jà nítorí pé ìwà jàgídíjàgan jọba lọ́kàn wọn.” Gẹ́gẹ́ bí ó àlàyé rẹ̀, àwọn okùnfà gan-an jẹ́ ìkùnà ìṣàkóso, àìṣe déédéé nínú ìṣàkóso ìdájọ́, àwọn ẹ̀dùn ọkàn àtìgbà-dégbà, àìbíkítà, àti àìpọ̀ tó àǹfààní.
Láti ìgbà ìgbìyànjú ìlànà-òfin tó kẹ́yìn, ipò ìgbékalẹ̀ ìfararọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti gbòòrò gan-an. OSPRE fúnra rẹ̀ kò sí ní ọdún 2012, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ìgbìmọ̀ ìfararọ ìpínlẹ̀ tó ń ṣiṣẹ́ jákèjádò orílẹ̀-èdè báyìí kò sí. ni Ngwodo wí pé, iṣẹ́ tó wà níwájú báyìí, ni láti mú ìpìlẹ̀-ètò yìí bára mu àti láti mú un gbòòrò sí i.

Láti òsì sí ọ̀tún: Olùdarí Àgbà, Ilé-Ẹ̀kọ́ Ìfararọ àti Ìyanjú Ìjà; Institute of Peace and Conflict Resolution (IPCR), Dókítà Joseph Ochogwu; Alága, Ìgbìmọ̀ Ilé Aṣòfin lórí ìgbékalẹ̀ ìfararọ àti ìṣọ̀kan àwùjọ, Sadiq Tafida; Olùdámọ̀ràn Pàtàkì fún Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lórí Ààbò Orílẹ̀-èdè, Maj Gen Adéyínká Famadewa (Rt); àti Olùdarí Àgbà Ọ́fíìsì fún Ìmúrasílẹ̀ Ọgbọ́n-Ìdáàbòbò àti Ìfarada (OSPRE), Chris Ngwodo, níbi ìpàdé àwọn olùkópa lórí àtúnyẹ̀wò Ìlànà-òfin Ìfararọ Orílẹ̀-èdè ní Abuja, Nàìjíríà. Àwòrán láti ọwọ́ Triple Peace Africa. A lò ó pẹ̀lú àṣẹ.
Ohun tí ó ré kọjá ìgbésẹ̀ ológun
Ọjọ́ Nàìjíríà ti pẹ́ ní kíkópa nínú ìdáàbòbò ìfararọ àgbègbè nípasẹ̀ Àjọ Ìṣọ̀kan Ọrọ̀ Ajé Àwọn Orílẹ̀-èdè Ìwọ̀-Oòrùn Áfíríkà (ECOWAS) àti nípasẹ̀ àwọn ọmọ ogun àti àwọn aṣojú ìjọba tí a rán lọ sí Liberia, Sierra Leone, Guinea-Bissau, Sudan àti Côte d’Ivoire. Àmọ́ ṣá, ní inú orílẹ̀-èdè, ìgbésẹ̀ ìjọba sí ìṣòro ààbò ti gbé ẹrù rẹ̀ lé àwọn ọmọ ogun lórí.
Ní ìpàdé Àbújá, olùdámọ̀ràn Ààrẹ Lori ààbò ìlú, Maj General Adeyinka Famadewa (Rt), sọ wí pé Nàìjíríà kò lè “yọ ara rẹ̀ kúrò” nínú ìṣòro ààbò rẹ̀. Ó ṣe àfikún wí pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìgbésẹ̀ ológun lè dí àwọn ẹgbẹ́ ológun tí kì í ṣe ti ìjọba lọ́wọ́ kí wọ́n sì gba ilẹ̀ padà, wọn kò dára fún yíyanjú àwọn ohun ìṣèlú, ọrọ̀ ajé àti àwùjọ tó ń jẹ́ kí ìwà ipá padà wá lẹ́yìn tí ìgbésẹ̀ náà bá dópin.
Aṣojú kan láti àjọ ìdàgbàsókè orílẹ̀-èdè Jámánì, GIZ African Union Office, Chijioke Iwuamadi, jẹ́rìí sí irú èrò kan náà nípa ìdènà, ó ń jiyàn pé fífi owó sínú ìdènà àti ìgbékalẹ̀ ètò ìlàjà ìgbà pípẹ́ lè ní ìwúlò tí ó nípá púpọ̀, tí kò sì fi bẹ́ẹ̀ náni lówó ju fífèsì lemọ́lemọ́ sí àwọn rògbòdìyàn lẹ́yìn tí wọ́n bá ti bẹ́ sílẹ̀.
Ǹjẹ́ Nàìjíríà ní owó láti ná lé ìdènà ìwà ipá bí?
Nàìjíríà kò ní ìkọlura kan ṣoṣo. Ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìkọlura tí wọ́n ń dà pọ̀ mọ́ ara wọn tí wọ́n sì yàtọ̀ láti agbègbè sí agbègbè. Ìdìtẹ̀ ọmọ ogun tí kì í ṣe tìjọba ní àríwá ìlà-oòrùn ti wà fún ohun tó ju ọdún mẹ́wàá lọ, nígbà tí ìwà ìgárá àti ìjínigbé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sì ti mú ìdàrú bá àwọn ìletò ní àríwá ìwọ̀-oòrùn àti àwọn ibòmíràn. Ìjà láàárín àwọn àlájùmọ̀jọgbé àti ìwà ọ̀daràn ọlọ́pọ̀ ènìyàn ń tẹ̀lé ìlànà tiwọn.
Àwọn àlàfo ìyapa wọ̀nyí máa ń bá ara wọn ṣiṣẹ́. Ẹ̀sìn máa ń so pọ̀ mọ́ ẹ̀yà. Àríyànjiyàn lórí ilẹ̀ ń di ìjà láàárín àwọn alájùmọ̀jọgbé àdúgbò. Ìfigagbágba ìṣèlú máa ń jẹ́ kí ìkùnsínú tó ti wà tẹ́lẹ̀ jinlẹ̀ sí i, nígbà tí ìṣíkiri, ìyípadà nínú iye àti irú àwọn olùgbé, àti ìkànnì ìbánisọ̀rọ̀ orí ayélujára, tó lè tan irọ́ àti ọ̀rọ̀ tó ń rú ìbínú sókè kálẹ̀, ń fi kún ìṣòro náà. Ìyàtọ̀ láàárín àwọn agbègbè yẹn ni ìdí tí àtúnyẹ̀wò ìlànà-òfin náà fi tẹ̀lé ìfọ̀rọ̀wérọ̀ ní ẹkùn-ẹkùn, láti gbìyànjú láti fi ìyàtọ̀ àwọn àdúgbò hàn, ṣùgbọ́n kí ó tún jẹ́ ohun tó lè ṣiṣẹ́ jákèjádò orílẹ̀-èdè.
Ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Adarí Àgbà Ilé-Ẹ̀kọ́ Àlàáfíà àti Ìyanjú Ìjà (IPCR), Joseph Ochogwu, ìṣọ̀kan tí a fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ nínú ètò àti ọ̀nà ìmúṣẹ tí a fà lélẹ̀ ní kedere fún ìgbékalẹ̀ ìfararọ jákèjádò àwọn ẹkùn ìṣèlú orílẹ̀-èdè yóò ràn án lọ́wọ́ láti yẹra fún ṣíṣe àṣetúnṣe, ìfohunèlò ṣòfò, ìlòdì sí ara wọn láàárín àwọn àjọ, àti kí àwọn ènìyàn àwùjọ má di ẹni tí a gbàgbé.
Ǹjẹ́ Nàìjíríà ní owó láti ná lé ìdènà ìwà ipá bí?
Nàìjíríà ti ń ná owó tó gọntiọ láti wá ojútùú sí àìsí ààbò. Ìnáwó ológun pọ̀ sí i jálẹ̀ ọdún 2025, láìsí ìtakora kankan tó wà nínú rírọ́ ẹgbẹ́ ọmọ-ogun ní agbára àti fífi owó sí ìdènà. Ṣùgbọ́n méjèèjì ń ṣiṣẹ́ ní ibi tó yàtọ̀ nínú ìlànà ìwà ipá. Ọ̀kan ń kojú ewu, èkejì sì ń gbìyànjú láti dín àwọn ohun tí ó ń ṣokùnfa wọn kù, Nàìjíríà sì gbọdọ̀ pinnu bí yóò ṣe pín àfiyèsí àti ohun àmúlò rẹ̀ láàárín wọn.
Ó ti ju ọdún mẹ́wàá lọ láti ìgbà ìgbìyànjú ìlànà-òfin àkọ́kọ́, ipò ààbò orílẹ̀-èdè náà sì ti yípadà. Ó ń kojú àwọn ìrísí àìsí ààbò tó yàtọ̀ síra ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, pẹ̀lú oríṣìíríṣìí ìgbésẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn àjọ ìjọba, àwọn ìgbìmọ̀ ìfararọ àti àwọn ẹgbẹ́ aráàlú. Bóyá ìṣọ̀kan yẹn lè yọrí sí ìkọlura tó dín kù àti dídènà àwọn èyí tí ó ti wà tẹ́lẹ̀ láti padà wá yóò sinmi lé ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí àwọn ìfọ̀rọ̀wérọ̀ náà bá parí.





