
Ajgul Serikova, olùgbé ẹkùn Uzunkol ti agbègbè Kostanai ní apá àríwá Kazakhstan, ń pọn gbogbo omi tí ó lè rí pọn kí omi ó tó ó lọ. Àwòrán láti orí Central Asian Bureau for Analytical Reporting (CABAR.asia). A fi òdodo lò ó.
Nazgul Aidabossynova láti Kazakhstan ló ṣe àgbéjáde àpilẹ̀kọ yìí pẹ̀lú ètò owó ìrànwọ́ Digital Spark, gẹ́gẹ́ bí ara Ètò Ìrànwọ́ Agbègbè iṣẹ́-àkànṣe EECA, tí àjọ Metamorphosis Foundation àti TechSoup ṣé àgbékalẹ̀ rẹ̀, ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú CIVICUS àti lábẹ́ Digital Democracy Initiative (DDI) tó ń ṣe kòkárí apá ibi tí àwọn ènìyán pọ̀ sí jùlọ ní Àgbáyé. A ṣe àtẹ̀jáde rẹ̀ lórí Global Voices lábẹ́ àdéhùn àjọpín-ìròyìn.
Ní abúlé Qyzylsay, ní apá Gúúsù Kazakhstan, omi máa ń lọ ní ọ̀sọ̀ọ̀sán. Kì í ṣe àpèjúwe lásán. Bí yóò bá fi di ọ̀sán, gbogbo ọ̀pá omi ló máa ti gbẹ.
Àfẹ̀mọ́júmọ́ ni àwọn obìnrin tí máa ń jí pọnmi sí inú gbogbo agbomisí tí wọ́n ní. Lẹ́yìn náà wọ́n yóò dúró kí omi padà dé. Ní àwọn àkókò tí wọ́n fi ń dúró yìí, wọn a máa kó àwón garawa lọ sínú ọgbà, wọ́n á fún àwọn nǹkan ọ̀sìn ní oúnjẹ, wọ́n á mú àwọn ọmọ lọ sí ilé ìwé, wọn a sì tún máa ṣe onírúurú iṣẹ́ ilé tí ẹnikẹ́ni kò kà sí, tí ẹnikẹ́ni kò sanwó fún àti tí ẹnikẹ́ni kò rí. Àwọn obìnrin mẹ́wàá pinnu láti yí ìyẹn padà.
Ìṣòro tí ẹnikẹ́ni ò kà
Qyzylsay jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ibi tó gbóná ju ní Kazakhstan. Àkókò ẹ̀rùn tó ń wáyé nísìnyí jẹ́ ohun tí àwọn tó ti pẹ́ níbẹ̀ sọ pé kì í wáyé ní 20 ọdún sẹ́yìn. Gẹ́gẹ́ bí àkójọpọ̀ ìwífún-alálàyé Kazakhstan, ìdá 20–60 nínú ọgọ́rùn-ún omi ni kì í dé àwọn ìgbèríko. Ọ̀pọ̀ àwọn abúlé ìgbèríko ni wọ́n ò ní àwọ́n ohun amáyédẹrùn fún ìṣèmọ́tótó gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́-ìwádìí Borgen, kódà bí omi bá wà, kì í ṣe mu ní gbogbo ìgbà. Fún àwọn obìnrin Qyzylsay, èyí kì í ṣe nípa ìṣirògún. Ìdákẹ́ rọrọ ẹ̀ro-omi tí omi kò jáde nínú rẹ̀ ní ọ̀sán ni.
Ní oṣù kẹfà ọdún 2026, àwọn obìnrin àjọ UN ṣe àgbéjáde ìjábọ̀ aṣinilétí rẹ̀ “Ìlọsíwájú Àwọn Obìnrin Àgbáyé 2026: Dídọ́gba Takọtabo ní Àkókò Ìṣòro Ojú-ọjọ́ Àgbáyé.” Ó sọ àwọn obìnrin Qyzylsay ti mọ̀ dáadáa. Ètò ọ̀gbìn ọlọ́jọ́ pípẹ́, tàbí ọjọ́ iwájú tí ó dúró ṣinṣin ò ṣe é ṣe láì ṣe àfikún “owó-àìsan ìtọ́jú ilé” sínú ètò ìsòro àyípadà ojú-ọjọ́ àti ètò ọ̀gbìn.
Àwọn obìnrin ìgbèríko yìí ní wọ́n máa ń gbé èyí tí ó wúwo jù lọ nínú àì ṣe déédéé iná mànàmáná, iṣẹ́ àṣekára, àti ìtọ́jú àwọn ẹran-ọ̀sìn. Àbájáde náà sì ni pé wọn kì í ráyè láti kẹ́kọ̀ọ́, pawó, tàbí láti ṣètò ohunkóhun.

Natalia Solntseva ń pọn omi sí inú garawa kan láti bomirin ọgbà ìyá-ìyá rẹ̀ ní Koksai, ẹkùn Almaty. Central Asian Bureau for Analytical Reporting. (CABAR.asia). A fi òdodo lò ó.
Àwọn obìnrin ìgbèríko Kazakhstan máa ń ṣiṣẹ́ fún wákàtí 10 sí 15 lójúmọ́, púpọ̀ nínú ẹ̀ kì í jẹ́ kíkà sí àti tí wọn ò sì kí ń gba owó fún. Ní Qyzylsay, iṣẹ́ náà gba kí wọ́n máa jí ní aago mẹ́rin òwúrọ̀ ní àwọn ọjọ́ tí wọ́n bá fẹ́ bú omi rin àwọn ohun ọ̀gbìn tí wọn yóò dúró lórí pápá kan fún wákàtí márùn-ún tí wọ́n wo bí omi ṣe ń ṣàn gba àwọn ibi tí a là fún un kọjá. Bí àkókò fún ọ láti bu omi rin ohun ọ̀gbìn bá fò ọ́ rú, ọgbà ohun ọ̀gbìn rẹ̀ yóò rá mọ́lẹ̀. Wákàtí márùn-ún, ní ẹ̀èmẹta lọ́sẹ̀: wákàtí ogójì sí 60 lóṣù, ni wọn fi ń ṣe ọ̀kan nínú àwọn iṣẹ́ tí kò lówó lórí rárá.
Ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ tí ó ń ṣe ju Wásapù lọ
Orúkọ mi ni Nazgul, láti oṣù karùn-ún sí oṣù kẹfà 2026, Mo ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ mẹ́rin fún àwọn obìnrin ní Qyzylsay lábẹ́ iṣẹ́-àkánṣe tí ó ń jẹ́ “Digital Voice of Qyzylsay Women.” Ohun ti1 ètò náà dá lé lórí ò le: Ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin ní agbègbè yìí ni wọ́n ní ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ ajáfáfá. Ìṣòro wọn ní pé wọn ò ní ìmọ̀ wí pé àwọn ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn lè ṣe ju fífi àtẹ̀jíṣẹ́ ránṣé nìkan lọ.
A bẹ̀rẹ̀ láti ibi àwọn ohun tí ó rọrùn: Ìránnilétí fún ìtọ́jú àwọn ẹran-ọ̀sìn, àkọsílẹ̀ oko ojoojúmọ́ pẹ̀lú àwọn àwòrán, àti ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí ohun-àmúlò eGov, èyí tí ó máa ń fún ni ní àǹfààní láti rí ọwọ́tó àwọn àkọsílẹ̀ ìjọba láì rin ìrìnàjò lọ sí ìgboro.
Fún àwọn obìnrin tí wọ́n tí tò fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí ní àwọn ilé-iṣẹ́ ìjọba láti gba ìwé ẹ̀rí ọjọ́ ìbí lásán, èyí kì í ṣe ohun ìrọrùn. Ìfihàn ni.
Lẹ́yìn náà a mẹ́nu lọ ibi omi.
Ẹ̀rí tí kò ṣe é kájú fún

Ẹ̀rọ omi kan ní ìgbèríko Kazakhstan ń yọ ẹrẹ̀, omi tí ó pọ́n. Àwòràn láti Central Asian Bureau for Analytical Reporting (CABAR.asia). A fi òdodo lò ó.
Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ 2 ni a pè ní “Omi tó já fáfá: Bí ọgbà Rẹ bá sọ fún ẹ pé Òùngbẹ ń gbẹ Ohun.” A kọ́ àwọn akópa bí wọn ó ti ya àwọn ìṣòro omi bí i, odò ohun-ẹ̀gbin lílà gbígbẹ, àwọn òpó agbómi tí ó bẹ́, àti àwọn orísun tó ti kó ẹ̀gbin, tí ó ní àpamọ́ àwọn àkókò àdáṣe. A pé àwọn èyí ní “Àwọn Káàdì Ìṣòro omi.” Èrò lásán ni àwòrán láìsí ajúwe ìwífún-alálàyé. Àwòrán pẹ̀lú GPS máa ń ṣàkóso, ọjọ́, àti pé ẹ̀rí ni àlàyé jẹ́.
A sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹ̀tọ́ omi Kazakhstan lọ́nà tí ó mú òye rọrùn, kì í ṣe ní ọ̀nà èdè-ìperí tí ó le. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn obìnrin náà ni wọ́n ò tí ì gbọ́ ọ rí wí pé ẹ̀tọ́ lábẹ́ òfin ni rírí omi tó mọ́ lò, kì í ṣe ojú rere láti ọ̀dọ̀ ìjọba ìbílẹ̀.
Ọ̀kan nínú àwọn akópa náà sọ pé: “Mo máa ń rò pé wọn pa wá tì nítorí wọ́n lè ṣe é. Nísìnyí mo ti mọ̀ pé nítorí pé a ò ní ẹ̀rí ni wọ́n fi pa wá tì. Nítorí náà ní báyìí a ó ní ẹ̀rí.”
Òǹkà tó yí ohun gbogbo padà
Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kẹta ló rinlẹ̀ jù. A jókòó papọ̀, a sì jọ ṣe ìṣirò iye jálá wàrà kan gangan — àti iye owó àkókò iṣẹ́ àwọn obìnrin ní iye owó òṣìṣẹ́ tó kéré jùlọ. Yàrá dákẹ́ rọ́rọ́ nígbà tí àwọn obìnrin rí i wí pé àwọn kàn ń ṣiṣẹ́ lásán fún àwọn alágbàsíṣẹ́ àwọn ni. Iṣẹ́ ọ̀fẹ́ ni àwọn ń ṣe, kì í ṣe okoòwò.
A tún ṣe ìṣirò iye owó tí a lè rí lórí ìṣètò ìbomirin ọ̀gbìn pẹ̀lú ẹ̀rọ: Wákàtí 60 lóṣooṣù. Ọgọ́ta wákàtí tí a lè lò fún àwọn ìrìn-àjò ọjà, ẹ̀kọ́ orí ẹ̀rọ-ayélujára, ìsinmi, tàbí kíkópa nínú iṣẹ́ ìlú. Owó KZT 500 (USD 1.09) fún wákàtí kọ̀ọ̀kan, ìyẹn jẹ́ KZT 30,000 (USD 65.17) ó kọjá àkókò ọ̀gbìn kan — ó tó láti san àsanpadà iye owó ètò ẹ̀rọ afami àdáṣiṣẹ́ àjọlò.
Nígbà tí yóò fi di àkókò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kẹrin, ọ̀rọ̀ náà ti yísẹ̀. A ò sọ̀rọ̀ lórí àwọn ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ oníkálukú mọ́. À ń sọ̀rọ̀ nípa agbára àjọṣepọ̀.
Àbájáde tó ṣe pàtàkì jùlọ nínú àwọn oṣù mẹ́rin wọ̀nyìí kì í ṣe ìmọ̀ nípa lílọ ẹ̀rọ-ayélujára. Ìgbáralé ni. Àwọn obìnrin akópa tí wọ́n ti kọ́mọlùbọ́pọ̀ pẹ̀lú ara wọn fún ọdún pípẹ́ pinnu láti dá ẹ̀gbẹ́ àjùmọ̀ṣe sílẹ̀.
Ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdí fún ìdásílẹ̀: láti parapọ̀ wá ojútùú sí ìṣòro àì sí omi ìlú nípasẹ̀ ṣíṣeṣẹ́ àkọsílẹ̀, àgbàwí tó létò, àwọn ẹ̀rọ-amáyédẹrùn ìbomirin ọ̀gbìn àjọpín, àti láti jẹ́ kí iṣẹ́ àwọn obìnrin hàn gbangba-gbàngbà nínú ètò ọrọ̀-ajé àti ní ìlú.
Kí ni ohun tí ó kàn
Àwòṣe ìtànkálẹ̀ ẹ̀kọ́ láti Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Kẹrin ti bẹ̀rẹ̀: Àwọn olùkópa mẹ́ta ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn aládùúgbò wọn ní ohun tí wọ́n kọ́ nínú àwọn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ wa.
Ẹgbẹ́ àjùmọ̀ṣe náà yóò béèrè fún owó ìrànwọ́ àjùmọ̀ní láti ṣe àgbékalẹ̀ ẹ̀rọ kànga ajáfáfá tí gbogbo wọn yóò jọ máa lò.
Àyípadà tí yóò pẹ́ púpọ̀ jù lọ nínú iṣẹ́-àkànṣe náà le láti díwọ̀n. Nígbà tí obìnrin kan bá kọ́ bí a ṣe ń ṣírò iye àkókò rẹ̀, tó sì gbé àwòrán kan sókè, tí ó sì wí pé, “Èyí ni ẹ̀rí, wọ́n sì gbọdọ̀ fèsì,” àyípadà alálòpẹ́ yóò dé bá òun fúnra rẹ̀ àti fún àwùjọ rẹ̀.
Omi ní Qyzylsay ṣì máa ń lọ ní ọ̀sọ̀ọ̀sán. Ṣùgbọ́n àwọn obìnrin tí ń gbé e ti rí ẹnu láti sọ̀rọ̀.





