Ọjọ́ tí ó tẹ̀lé ìkún-omi tí ó ṣẹlẹ̀ ní àárín gbùngbùn Nepal

Map by Google Earth via Nepali Times. Used with permission.

Àwòrán Google Earth láti orí Nepali Times. A gba àṣẹ kí a tóó lò ó.

Ìròyìn yìí, tí Kunda Dixit kọ, ni àkọ́kọ́ tẹ̀ jáde rẹ̀ wà nínú ìwé ìròyìn Nepali Times. Ẹ̀dà rẹ̀ tí a ṣe àtúnṣe ráńpẹ́ sí ni a tún tẹ̀ jáde lórí Global Voices lábẹ́ àdéhùn àjọpín-ìròyìn.

Òkè Langtang Lirung, ìyẹn òkè ńlá tí ó ga ní ìwọ̀n 7,245 mítà ju ìpele òkun lọ, tí ó sì wà ní kìlómítà 45 ní ìhà àríwá ìlú Kathmandu, ní ìtàn ládojúdé kan.

Ìṣẹ́lẹ̀ ńlá tó rinlẹ̀ tí ìwọ̀n rẹ̀ tó 7.8 mi àárín gbùngbùn Nepal tìtì ní oṣù kẹrin ọdún 2015, ó sì mú kí òkìtì yìnyín ńlá kan yalulẹ̀ ní apá gúúsù rẹ̀, èyí tí ó jábọ́ sínú òkìtì yìnyín tó wà ní ìsàlẹ̀, tí ó sì bò abúlé Langtang ní àbòmọ́lẹ̀, àwọn ènìyàn tí ó tó 300 sì jẹ́ Ọlọ́run nípè.

Ní ọjọ́ 26 Oṣù Kẹjọ ọdún 2026, ìṣẹ́lẹ̀ ńlá kan tí ó rinlẹ̀ tó ìwọ̀n 4.4 wáyé nítòsí ààlà ibodè pẹ̀lú orílẹ̀-èdè China ní déédéé aago 8:37 òwúrọ̀ ní àkókò aago orílẹ̀-èdè Nepal (2:52 òru ní àkókò aago UTC). Lọ́tẹ̀ yìí, ó mú kí òkìtì yìnyín ńlá kan dà wìì silẹ̀ ní ìhà àríwá Langtang.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé inú Nepal ni Langtang Lirung wà, àwọn pàǹtírí tí ó ṣàn láti ara òkìtì yìnyín tí ó ń ya lulẹ̀ náà ti dí odò Lhende Khola tí òjò-oníjì tí mú kí ó kún, èyí tí ó pààlà pẹ̀lú orílẹ̀-èdè China. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni omi tí ó dárogún náà ya, tí ó sì mú kí àpapọ̀ òbítíbitì ẹrẹ̀, omi, àti àwọn àfọ́kù àpáta wọ́ gba inú Odò Trisuli sínú orílẹ̀-èdè Nepal.

Ohun tí àwọn amòye tí ó ti wo àwòrán tí wọ́n fi ẹ̀rọ ayí-ayé-ká yà láti ilé iṣẹ́ Planet Labs gbà pé ó ṣẹlẹ̀ nìyẹn. Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ṣì ń jiyàn lórí bóyá ìṣẹ́lẹ̀ náà ló mú kí òkìtì yìnyín ara òkè náà ó wó lulẹ̀ ní apá àríwá, tàbí bóyá òkìtì yìnyín tí ó ń ṣàn lulẹ̀ náà ní agbára tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí ìṣẹ̀lẹ̀ ìṣẹ́lẹ̀ náà fi ṣẹlẹ̀.

Bí ó bá jẹ́ wí pé ìmìtìtì ilẹ̀ náà ló ṣokùnfa ìṣẹ̀lẹ̀ náà, á jẹ́ pé ó fa ìgbọ̀nrìrì òkè kan níbi tí ìrì dídì àti yìnyín rẹ̀ ti ń yòrò nítorí ìlọ́wọ́rọ́ àgbá-ńlá-ayé. Ìyẹn nìkan kọ́, ó tún ṣẹlẹ̀ ní àkókò tí òjò-oníjì ń kásẹ̀ nílẹ̀, nígbà tí ìrì dídì ara òkè náà máa ń pọ̀ gan-an, tí omi sì ti kún inú àwọn òkìtì òkúta àti pàǹtírí tí ó kù lẹ́yìn tí òkìtì yìnyín ńlá tí ń yọ́ fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó dàbí ẹni pé orí òkìtì oníyìnyín kan ní orílẹ̀-èdè Nepal ni àjálù yìí ti bẹ̀rẹ̀, ó ṣàfihàn bí adágún odò oníyìnyín tó fa àkúnya (GLOFs), yíyọ́ tí òkìtì yìnyín ń yọ́, àti bí ìfọ́yángá àwọn òkìtì òkúta àti pàǹtírí tí ó ń fa àjálù tí ó kọjá ààlà láti Òkè olórí pẹrẹsẹ Tibetan ṣe máa fa ewu gidi lọ́jọ́ iwájú. adágún odò oníyìnyín tó fa àkúnya

Pàápàá jù lọ láì sí ìṣẹ́lẹ̀, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìkún-omi ní ṣísẹ̀ntẹ̀lé ti wáyé láìpẹ́ yìí ni àwọn agbègbè tí ó wà láyìíká àwọn òkè Himalaya tí ó jẹ́ okùnfà àpapọ̀ àwọn nǹkan wọ̀nyí: ìṣẹ̀lẹ̀ Chamoli lọ́dún 2021, ìṣẹ̀lẹ̀ Melamchi lọ́dún 2021, ìṣẹ̀lẹ̀ Sikkim lọ́dún 2023, ìṣẹ̀lẹ̀ Thame lọ́dún 2024, ìṣẹ̀lẹ̀ Bhote Kosi lọ́dún 2025, àti èyí tí ó ṣẹlẹ̀ nínú ọdún 2026 tí a wà yìí. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ìgbà òjò-oníjì ni gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣẹlẹ̀.

Ìṣẹ̀lẹ̀ àkúnya omi tí ó ṣẹlẹ̀ ní Rasuwagadhi lọ́jọ́ 8 oṣù kéje ọ́dún tó kọjá (tí a ṣàpèjúwe rẹ nínú àwòrán ilẹ̀-ayé tó wà nísàlẹ̀ yìí) pa ènìyàn 18, ó sì wọ́ ibùdó ìgbàṣẹ-láti-wọ̀lú tó ṣe pàtàkì jùlọ fún òwò àti ìrìn-àjò afẹ́ ní ẹnubodè tí ó wà láàárín orílẹ̀-èdè Nepal àti orílẹ̀-èdè China lọ. Bákan náà ni ó ba àwọn òpópónà márosẹ̀, àwọn àgọ́ ìpèsè iná mànàmáná, àti àwọn òpó apínáká tó wà ní Nepal jẹ́, èyí tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń tún ṣe lẹ́yìn àwọn àjálù àdánidá tí ó ti wáyé tẹ́lẹ̀.

Image by Google Earth via Nepali Times. Used with permission.

Àwòrán Google Earth láti orí Nepali Times gbé jáde láti orí . A gbà àṣẹ kí a tó lò ó.

Àwọn onímọ̀ tọ orísun àkúnya omi náà wọ́n sì sọ wí pé àwọn adágún omi tó wà lórí òkìtì yìnyín ńlá tí wọ́n kóra jọ sórí àwọn òkè, ló yẹ̀, tí èyí sì jẹ́ kí òbítíbitì omi tó kún fún pàǹtírí yalulẹ̀ sí ìsàlẹ̀ odò. Ní ọdún tó kọjá, àwọn ará ìlú tó ń gbé lápá ibi tó bọ́ sí ilẹ̀ orílẹ̀-èdè China ti ṣí àwọn adarí ìjọba ìbílẹ̀ tí ó wà ní Nepal létí nípa ewu náà. Kò sí ìṣínilétí ní ọdún yìí rárá.

Bákan náà, ibi tí ìyalulẹ̀ òkìtì yìnyín ńlá náà àti ibi tí àkúnya omi náà ti bẹ̀rẹ̀ sún mọ́ ẹnubodè; kò le gbà òbítíbitì omi tó kún fún pàǹtírí náà jù ìṣẹ́jú díẹ̀ lọ kí ó tó ṣàn dé ìbùdó ìgbàṣẹ-láti-wọ̀lú ti Rasuwa.

Nígbà tí yóò fi di August 27, 2026, iye àwọn tí wọ́n ti kú ti lé ní 160, tí ó sì ṣe é ṣe kí iye ẹ̀mí tí ó sọnù ó ọgọ́rùn-ún ní ìlọ́po. Títí tí ilẹ̀ ọjọ́ kejì fi mọ́, àwọn ènìyàn ń rí òkú àwọn ènìyàn, òkú ẹranko àti pàǹtí tí wọ́n léfòó lórí Odò Narayani ní kìlómítà 200 ní ìsàlẹ odò ní agbègbè Nawalparasi.

Image via Nepali Times. Used with permission.

Nepali Times ló ni àwòrán. A gbà àṣẹ kí a tó ó lò ó.

Àjálù yìí jẹ́ ká mọ ìdí pàtàkì tí orílẹ̀-èdè Nepal ti fi ń béèrè fún owó ìrànwọ́ Òfò níbi àwọn ìpàdé àpérò tí àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé ń ṣe lórí ipa tí ìṣòro àyípadà ojú-ọjọ́ ń kó lórí ètò ọrọ̀-ajé, pàápàá jù lọ ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ó wà lágbègbè àwọn òkè ńláńlá. Iye owó àwọn ohun amáyédẹrùn àti dúkìá tí ó bàjẹ́ yóò tó ẹgbẹẹgbẹ̀rún-lọ́nà-ẹgbẹ̀rún owó dọ́là ni ìlọ́po-ìlọ́po, tí àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ ìdáàbòbò àyíká sì gbà pé àwọn orílẹ̀-èdè tó ń ba àyíká jẹ́ jùlọ, tí wọ́n sì jẹ́ olórí àwọn tó ń ṣe àwọn ohun tí ó ń fa ìṣòro ojú-ọjọ́, bíi orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àti China, ló yẹ kí wọ́n faragbá sísan owó náà.

Láàárín ìṣẹ́jú péréte, yóò fẹ́ẹ̀ẹ́ tó nǹkan bíi àgọ́ ìpèsè iná mànàmáná ńláńlá mẹ́fà, àwọn òpó apínáká àti àwọn ẹ̀ka apíná káàkiri ní agbègbè Bhote Kosi àti Trisuli ni wọ́n ṣègbé tàbí tí wọ́n bàjẹ́ kọjá àtúnṣe. Ibi tí orílẹ̀-èdè Nepal kọ́ àwọn ẹ̀rọ afagbára-oòrùn-pèsè-iná tí ó ní ìpín-agbára Wáàtì 25 sí ní Nuwakot ni gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ bò mọ́lẹ̀.

Àwọn iṣẹ́ àkànṣe mìíràn tí wọ́n ń ṣe lọ́wọ́ náà bàjẹ́ gidi gan-an. Nǹkan bíi afárá méjìlá tí ó gba orí odò Bhote Kosi àti Trisuli, tí àwọn kan lára wọn wà ní nǹkan bí 70 kìlómítà ní ìsàlẹ̀ odò, ni omi ti gbẹ́ lọ, tí kò sì sì bí ènìyàn yóò ṣe rí àwọn òpópónà márosẹ̀ tó lọ sí àríwá gbà kọjá.

Image via Nepali Times. Used with permission.

Nepali Times ló ni àwòrán. A gbà àṣẹ kí a tó ó lò ó.

Àjálù náà kọlu orílẹ̀-èdè Nepal lẹ́yìn ọdún kan tí ìfẹ̀hónúhàn àwọn ẹni tí a bí lẹ́yìn ọdún 1997 tí ó wáyé ní oṣù Kẹsán ọdún 2025 tí ó mú kí ètò ìdìbò ó tètè wáyé, èyí tí ó sọ Balendra Shah ní abẹ́ àsíá Ẹgbẹ́ Ọ̀ṣèlú Rastriya Swatantra (RSP) di Olórí Ìjọba. Kòì tíì tó oṣù mẹ́fà tí ó gba ìjọba, ó sì ti ń dojú kọ ìpèníjà ṣíṣe àwárí àti ìdóòlà ẹ̀mí oníwàràwéré, àti àtúnṣe ní agbègbè Àfonífojì Trisul tí ó ti parun.

Bó pẹ́ bó yá, Nepal yóò nílò àwọn ètò tó múnádóko láti lè kojú àwọn àjálù tí ìṣẹ́lẹ̀ àti àyípadà ojú-ọjọ́ ń fà tí ó dájú pé ó túbọ̀ máa sẹlẹ̀ sí i lọ́jọ́ iwájú.

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.