
Ibùgbé, pẹ̀lú ibalùwẹ̀ tí a kọ́ fún ìgbà díẹ̀ láàárín àwọn àgọ́. Àwòrán láti ọwọ́ òǹkọ̀wé. A gba àṣẹ láti lò ó.
Láti ọwọ́ Marwa Rommaneh
Ní àwọn wákàtí òwúrọ̀, nígbà tí ó yẹ kí àwọn ilé-ìwé ó bẹ̀rẹ̀ láti máa gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sí iyàrá ìkẹ́kọ̀ọ́, àgbàlá náà kún fún àwọn ọkùnrin tí wọ́n ń sùn sórí ilẹ̀ẹ́lẹ̀. Ìrìn kiri bẹ̀rẹ̀ kí ọjọ́ ó tó yọ, àwọn ènìyàn sì ń dúró sórí ilà níwáju balùwẹ̀. Àwọn ilé-ìwé Gaza kò sí mọ́ fún ẹ̀kọ́, ṣùgbọ́n wọ́n ti yí wọ́n padà sí àwọn ibùgbé àwọn tí ogun ṣí kúrò nílùú, ibi tí àwọn ìdílé tí ọgọọgọ́rùn-ún ẹbí ń gbé.
Ní ọ̀sẹ̀ àkọ́kọ́ ogun Gaza ní Oṣù Kẹ̀wá 2023, United Nations Relief and Works Agency (UNRWA) sọ pé nǹkan bíi 218,600 ènìyàn tí ogun ṣí kúrò nílé ni wọ́n ń fi ilé-ìwé 92 ṣe ibùgbé káàkiri Gaza, nígbà tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ fi àwọn ilé-ìwé ìjọba àti àwọn ilé mìíràn ṣe ibi ìsádì. Bí ọjọ́ ṣe ń lọ, iye wọn ń pọ̀ sí i, tí àpọ̀jù àwọn ènìyàn sì di ohun tí ó wáyé lójoojúmọ́.
Ní irú àwọn àyíká báwọ̀nyí, kò gba ìgbà pípẹ́ kí a tó mọ̀ pé ohun kan pàtàkì ti pòórá: ìdáwà pẹ̀lú ìpàṣìírímọ́ kò sí mọ́ ní ìgbésí ayé.
Ìran àjọṣepọ̀ onítẹ̀síwájú
Ohun gbogbo tí ó máa ń jẹ́ ṣíṣe lẹ́yìn ògiri ilé nígbà kan rí ti wá di ohun tí a ń ṣe ní gbangba. Iná dídá, aṣọ fífọ̀, rírẹjú, àti àwọn ìṣe ojoojúmọ́ di ohun tí ó ń wáyé ní ojú kan ṣoṣo, ní iwájú gbogbo ènìyàn. Kò sí iyàrá, kò sí ilẹ̀kùn, kò sì sí igun tí ó lè fún ènìyàn ní ìṣẹ́jú kan láti dá wà. Ìgbé ayé níbí kì í ṣe àgbélọ́tọ̀, ṣùgbọ́n èyí tí ó fí ara kọ́ ara, níbi tí gbogbo nǹkan nípa ìdílé kọ̀ọ̀kan di ìran àjọṣepọ̀ onítẹ̀síwájú.
Ìfarakọ́ra yìí kì í ṣe nípa àìní àyè nìkan — ó tún jẹ́ nípa ìpàdánù dídá wà, kódà fún ìṣẹ́jú díẹ̀. Ìdákẹ́jẹ́ ṣọ̀wọ́n, rírẹjú sì di ohun tí ènìyàn gbọdọ̀ ṣe pẹ̀lú ìkíyèsára, bí ẹni pé ó wà fún ìgbà díẹ̀ ní ibi tí kò ti sí àyè fún un fún ìdúróṣinṣin.
Ní àkókò tí mo dara pọ̀ mọ́ ìpolongo abẹ́rẹ́ ajẹsára àrùn rọmọlápá-rọmọlẹ́sẹ̀ ní Gaza, tí mo sì ṣiṣẹ́ ìkọsílẹ̀ ìwífún àti ìranlọ́wọ́ ní oko-ìwádìí, ìrírí náà tayọ iṣẹ́ àkóso nìkan. Ó jẹ́ ìfojúrinjú pẹ̀lú òtítọ́ yìí lójoojúmọ́. Láti tọ́ àwọn ọmọdé lọ a ní láti wọ ibi tí ó kún fún ènìyàn àti ṣíṣe iṣẹ́ ní ibi tí kò sí ìtura tàbí àṣìírí. Kò sí ibi pàtó fún ìbáraẹnisọ̀rọ̀ tàbí ìtọ́jú; gbogbo ìgbésẹ̀ tí a gbé ni ó wáyé ní àárín èrò ní ibi tí ohun tí à ń ṣe ti fi ara kọ́ ìgbé-ayé ojoojúmọ́ àwọn ènìyàn.
Bí ọjọ́ ṣe ń lọ, àìní àyè fún ara ẹni kò já mọ́ nǹkan kan mọ́; ó di ọ̀kan lára ìrírí ìgbé-ayé fúnra rẹ̀. Gbogbo nǹkan hàn gbangba, ó jẹ́ pínpín, ó ṣe é fi ojú rí nígbà gbogbo, níbi tí kò sí àyè “àdáwà” bí wọ́n ti ní òye rẹ̀ tẹ́lẹ̀.
Àwọn ìṣòro ìgbé-ayé ojoojúmọ́
Àjọ Ètò Ìlera Àgbáyé; The World Health Organization (WHO) àti UNICEF ti dárúkọ àwọn ìṣòro ìlera tí ó ń pọ̀ sí i tí àwọn ọmọdé ní Gaza ń dojú kọ, pàápàá jùlọ ìnira láti ṣètò ìrànlọ́wọ̀ ìlera àti fífún àwọn ènìyàn ní abẹ́rẹ́ ajẹsára ní àwọn ibi tí ó kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tí àwọn ohun-èlò kò sì tó nǹkan.
Ní àdúgbò yìí, àpọ̀jù àwọn ènìyàn tayọ àpèjúwe nìkan; ó di ohun tí ó ń darí gbogbo nǹkan: àyè láti rìn kiri, ìbáraẹnisọ̀rọ̀, àti ìpèsè ìtọ́jú gan-an. Ohun gbogbo ni àìsí àyè tó péye ní ipa lé lórí àti bí àwọn ènìyàn ṣe pọ̀ sí, tí ó sì ń mú kí iṣẹ́ tó rọrùn di líle.

Àwọn àgọ́ àti ibùgbé fún àwọn ìdílé tí ogun lé kúrò ní Gaza. Àwòrán láti ọwọ́ onkọ̀wé. A gba àṣẹ láti lò ó.
Àwọn ọmọdé ń gbé nínú òtítọ́ yìí lójoojúmọ́, láì ní òye tí ó kún ojú òṣùwọ̀n tàbí kí ó mọ́ wọn lára. Kò sí àyè fún eré-ṣíṣe, kò sì sí ayíká tí ó ń pèsè ààbò tàbí ìtura. Fún àwọn ọmọdé tí wọ́n ní ìpènìjá ara, ìṣòro wọn tún peléke sí i, nítorí wọ́n ń gbé nínú ipò tí kò bá àwọn àìní tó kéré jù lọ wọn mu.
Save the Children ṣe ìṣirò pé ní ọdún 2024, ó tó bíi àwọn ọmọdé 475 lóṣooṣù ní Gaza ni ó fi ara gbọgbẹ́ tí ó lè sọ wọ́n di abarapá fún gbogbo ọjọ́ ayé wọn, pẹ̀lú pípàdánù apa1 tàbí ẹsẹ̀, etí dídi, àti ìpalára ojú tí ó kọjá sísọ. Ní àwọn ibi tí ó kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àwọn ohun bí èyí ń mú kí ìṣòro ojoojúmọ́ pọ̀ sí i, níbi tí kò sí àwọn ohun tó kéré jù lọ fún ààbò àti àṣírí kò sí rara.
Lẹ́yìn ogún náà: Òtítọ́ tí kòì tíì yí padà
Bí a tilẹ̀ ti sọ nípa “lẹ́yìn ogun,” nǹkan díẹ̀ ni àyípadà ti dé bá nínú àwọn ibùgbé àwọn tí ogun lé kúrò nílé. Pípọ̀ lápọ̀ jù àwọn ènìyàn wà síbẹ̀, àyè há síbẹ̀, ìgbé-ayé ojoojúmọ́ ń tẹ̀síwájú bákan náà láìfi àyè kalẹ́ fún ìdánìkan wà. Kò sí ìpadà sí ilé ní tòótọ́, kò sì sí nǹkan mìíràn tí ó lè fúnni ní ìtura bí ó ti wù kí ó kéré mọ, bí kò ṣe ìtẹ̀síwájú àwọn ipo ìṣòro kan náà, tí ó ti di bárakú láìka ti bí wọ́n ṣe le koko tó sí.
Nínú òtítọ́ yìí, “lẹ́yìn ogun” kò jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ìtẹ̀síwájú ohun tí ó ti wà tẹ́lẹ̀. Títò lóri ilà kan náà, àyè kékeré tí wọ́n ń pín kan náà , àti ìmọ̀lára pé wọ́n ń gbé ìgbésí ayé wọn níwájú gbogbo ènìyàn. Ó dàbí ẹni pé àkókò dúró ní ìgbà tí ogun lé wọn kúrò nílé, láì fún ẹnikẹ́ni ní àǹfàní láti gba apá kankan nínú ìgbésí ayé wọn tẹ́lẹ̀ padà.
Ìtẹ̀síwájú yìí kò túmọ̀ sí pé ipò náà wà bákan náà nìkan, ṣùgbọ́n ó túmọ̀ sí pé ó ti fi gbòǹgbò múlẹ̀. Bí ọjọ́ ṣe ń lọ, ìpàdánù àkókò ìdáwà kò jẹ́ nǹkan tó wà fún ìgbà díẹ̀ mọ́, ṣùgbọ́n ó di ipò tí ó ń yí bí ènìyàn ṣe ń wo àyè àti ara wọn padà fún ìgbà pípẹ́.
Kí ni a pàdánù nígbà tí a kò bá lè ṣe ohunkóhun ní ìkọ̀kọ̀?
Kí ogún lé ènìyàn kúrò nílé kìí ṣe pípàdánù ilé nìkan, ṣùgbọ́n pípàdánù gbogbo ìgbésí ayé ènìyàn, pípàdánù àyè tí ó ti bo àwọn àṣìírí ojoojúmọ́ rí, tí ó sì ti fún àwọn ènìyàn ní ìmọ̀ pé apá kan nínú ìgbésí ayé wọn jẹ́ tiwọn nìkan.
Ní àwọn ìbúgbé àwọn tí ogun ṣí kúrò nílé, àwọn ènìyàn kò kàn gbé ní àwọn ibi kọ̀ọ̀kan fún ìgbà díẹ̀, ṣùgbọ́n nínú òtítọ́ ìgbé-ayé tuntun olọ́pọ̀lọpọ̀ èrò. Bí ọjọ́ ṣe ń lọ, ìpàdánù àkókò ìdáwà kọ̀ jẹ́ nǹkan tó wà fún ìgbà díẹ̀ mọ́, ṣùgbọ́n òtítọ́ tó ti yí ọ̀nà ìbáṣepọ̀ láàárín àwọn ènìyàn, àyè, àti ìgbé-ayé fúnra rẹ̀ padà.
Here, it is not only walls that disappear, but also the boundaries that once gave life its simplest meaning: the ability for a person to have a space of their own, even if it is nothing more than a small corner where no one is watching.
Níbí, kìí ṣe ògiri nìkan ló pòórá, àwọn ààlà tí ó fún ìgbé-ayé ní àwọn ìtumọ̀ tó kéré jùlọ náà dópin: ẹ̀tọ́ ẹni sí àyè ti ẹni, bí ó tilẹ̀ jẹ́ igun kékeré kan nìkan tí kò sí ẹni tí ó ń woni.
Marwa Rommaneh jẹ́ òǹkọ̀wé òmìnira àti akẹ́ẹ̀kọ́ jáde ìmọ̀ Ìṣàkóso Ìṣòwò láti Al-Quds Open University, tí ó ń kọ̀wé láti Palestine.







