
Minority Africa ni ó yàwòrán ìṣàpẹẹrẹ, a gba àṣẹ kí a tó ó lò ó.
Patricia Namutebi ni ó kọ ìtàn yìí tí Minority Africa sì tẹ̀ ẹ́ jáde ní ọjọ́ 16, oṣù Beelu, ọdún 2024. Ẹ̀dà àtúnkọ yìí ni a ṣe àtúntẹ̀jáde nísàlẹ̀ yìí gẹ́gẹ́ bí ìfẹnukò lórí àjùmọ̀ṣe ìròyìn gbígbéjáde. Gbogbo orúkọ ni a ti yí padà láti dáàbò bo àwọn ẹni tí ọ̀rọ̀ náà kàn.
Jane Francis ò fìgbà kan mọ bàbá tó bí i. Ní ìgbà tí ó wà ní ọmọ ọdún 15, ó bá ìyá rẹ̀ jáde lọ sí àárín ìgboro fún ọjọ́ tí ó lárinrin. Níbẹ̀ ni wọ́n ti pàdé ọkàn lára àwọn ọ̀rẹ́ ìyá rẹ̀ tó ní “Ó jọ ẹ́ gidi gan-an ni o!”
Ìyá rẹ̀ sì fèsì pé, “àbúrò mi nìyí”.
“Ọkàn mi bàjẹ́,” Francis Rántí. “Nígbà tí ó ṣe díẹ̀, ìyá mi ní kí n tẹ̀ ẹ́ mọ́ra nítorí òun ò mọ bí òun yóò ṣe ṣàlàyé fún àwọn ènìyàn wí pé ọmọ òun ni mo jẹ́.”
Èyí ya Francis lẹ́nu púpọ́, ṣùgbọ́n kò lọ́ ìyá rẹ̀ nífun lorí ọ̀rọ̀ náà, nítorí òun nìkan ni ẹni tí ó mọ̀ ní ẹbí. Ìyá rẹ̀ kò sọ òtítọ́ fún-un àyàfi ìgbà tí ó pé ọmọ ọdún 17 ni ó jẹ́ kí ó mọ àtiwáyé rẹ̀: Wọ́n fi ipá bá a lò pọ̀ nínú ìyárá rẹ̀ ní ilé ìgbé àwọn akẹ́kọ̀ọ́. Ìyá Francis fura sí ọkùnrin tí ó mú iyàrá gbè é, ṣùgbọ́n kò jẹ́wọ́ rí wí pé òun ni. Ẹni ọmọ ọdún 18 ni ìyá Francis nígbà náà.
Francis ṣàlàyé pé, “ìyá mi ṣì nírètí wí pé ọjọ́ kan ń bọ̀ tí òun yóò fi ọwọ́ òfin mú ọkùnrin náà, tí àyẹ̀wò DNA yóò sì jẹ́ ṣíṣe”. “Inú ìgbé ayé ẹ̀kọ̀ ni ó ṣì ń gbé.”
Ìfipábánilòpọ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìwà-ọ̀daràn tí ó wọ́pọ̀ jùlọ ní ilẹ̀ Áfíríkà. Àṣẹ̀ṣẹ̀ṣe ìwádìí tí Equality Now ṣe ṣàfihàn ònírúurú àwọn ìdojùkọ̀ tí àwọn tí wọ́n fipá bá lò pọ̀ máa ń kojú bí wọ́n ń bá ń wá ìdájọ́ òdodo, lára wọn ni àisí òfin tó fẹsẹ̀ múlẹ̀, ètò ìgbófinró tí ó mẹ́hẹ, àwọn ìtàn àrọ̀sọ nípa Ìfipábánilòpọ̀ láwùjọ, àti dídá ẹni tí a bá lò pọ̀ lẹ́bi. Àwọn nǹkan báwọ̀yìí ń ṣe ìdènà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn arúfin láti fojú ba ilé ẹjọ́, àwọn tí ilé ẹjọ́ dá lẹ́bi ò pọ̀, èyí tí ó sì fà á kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀daràn ó lọ láì jìyà ẹṣẹ̀. Nítorí èyí, ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n fipá bá lò pọ̀ yìí ní wọ́n ṣì wá nínú ewu, tí wọn kò rí ìdájọ́ òdodo àti àtìlẹyìn tí ó gúnmọ́ tí wọ́n nílò.
Láti ìgbà tí Francis ti mọ bí wọ́n ṣe lóyún òun ni ó ti ń tiraka láti mọ bí òun ti ṣe ṣẹ̀. Ó ní, “N kò mọ bàbá mi débi tí n ó mọ ìdílé tí mo ti wá”.
Mi ò ní ìbátan tí mo lè fi yangan. Ìyá mi sọ pé nínú àṣà wa, ohun ìtìjú ni láti bí ọmọ tí a kò mọ ìdílé rẹ̀. O tún sọ sí i wí pé, mo ní láti máa díbọ́n bíi ẹni wí pé àbúrò rẹ̀ ni mo jẹ́ ní gbogbo ìgbà.
Ó rántí ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí ó wáyé nílé ìwé nígbà tí wọ́n béèrè orúkọ àpèlé rẹ̀, orúkọ tí ó ṣẹ̀ wá láti inú ìdílé:
Ní gbogbo ìgbà tí mo bá dárúkọ mi ni mo máa ń di ẹni yẹ̀yẹ̀, tí àwọn ènìyàn yóò máa ṣẹnu ṣùtì sí mi gẹ́gẹ́ bí ẹni tí kò ní ará. Kílódé tí ń kò le è ní orúkọ tèmi nígbàtí mi ò ní ìdílé tàbí ẹbí kankan?
Kéèyàn mọ orísun rẹ̀ kì í ṣé ohun tó ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀ nígbà kan ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ó wà ní apá ìlà oòrùn Afíríkà sí bí ó ti ṣe wà nísinsìnyí. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn àṣà Uganda ni orúkọ àpèlé ti jẹ ti bàbá, tí ó ń sọ nípa ìdílé bàbá. Ó máa ń ṣàfihàn ẹ̀yà, ìran àti gbogbo ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú ìdánimọ̀ ìdílé. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹ̀yà ni ó ní bí wọ́n ṣe ń sọ ara wọn ní orúkọ, orúkọ àpèlé sì ń tọ́ka sí ìran, ìtilẹ̀ǹde, àti ìpo ní àwùjọ, èyí tí ó ṣe pàtàkì fún ìkẹ́gbẹ́ àti ìbáṣepọ̀ ní àwùjọ.
Orúkọ àpèlé tún ní ipa pàtàkì tí ó ń kó lórí ìdánimọ̀ lábẹ́ òfin, èyí tí ó ṣe pàtàkì fún ṣíṣe ìforúkọsílẹ̀ bíi gbígba ìwé-ẹ̀rí ọjọ́ ìbí, káàdì ìdánimọ̀ gbogboogbò, àti ìwé ẹ̀rí ilẹ̀.
Èròńgbà Francis ni láti pọ̀ sókè rajà, kí òun lọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn, pẹ̀lú ìrètí ìbẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé tuntun, kí òun sì ní ẹbí ti òun.
Ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn tí mo gbìyànjú láti gba ìwé ìrìnnà ní ọ́fíìsì níbí ní Uganda, wọ́n ní kí ìyá mi lọ mú àwọn àkọsílẹ́ nípa bàbá mi wá, pàápàá bí ó bá jẹ́wọ́ wí pé òun ò mọ ibi tí bàbá mi wà.
Àmọ́ nísìnyìí, kò sí irúfẹ́ àwọn àmúyẹ báyìí mọ́: ẹni tí kò ní bàbà ò nílò láti lọ wá àkọsílẹ̀ nípa bàbá rẹ̀ wá bí kò bá sí ní àrọ́wọ́tó. Ìdásílẹ̀ ẹ̀ka tí ó ń mójútó fíforúkọsílẹ̀ àwọn ọmọ Uganda, National Identification and Registration Authority (NIRA) ní ọdún 2015, ti jẹ́ kí ètò náà di ìrọrùn fún tonílé tẹlẹ́mù.
Michael Muganga, Alukoro Àjọ NIRA, ṣàlàyé pé, ọmọ aláìní-òbí ni wọ́n ń pè àwọn ọmọ tí wọ́n lóyún wọn látàrí ìfipábánilòpọ̀ tàbí àwọn oyún tí a kò mọ ẹni tí ó ní í. Ó ní “Ní NIRA, a mọ̀ pé àwọn ọmọ aláìní òbí wà, a sì gbà wọ́n gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe wà”. Ìtúmọ̀ “Ọmọ aláìní òbí” ni ọmọ tí kò rí ẹni ṣe òbí fún-un, a sì ń lò irúfẹ́ orúkọ yìí nínú àwọn àkọsílẹ̀ fún àwọn ọmọ tí ò lóbìí, àwọn ọmọ tí wọ́n gbà tọ́, tàbí láti gbá káàdí ìdánimọ̀ ti ò ń fi ni hàn gẹ́gẹ́ bí ọmọ orílẹ-èdè níbi tí òbí ọmọ kò ti jẹ́ mímọ̀.
Muganga gba àwọn olùforúkọsílẹ̀ ní ìyànjú láti ka ìwé ìgbọ̀rọ̀sílẹ̀ náà ní àkàyé. Ó ṣàlàyé pé “Ó ní abala kan tí ó ní ‘mi ò mọ bàbá mi’. Èyí ni kí ẹni tí a bí látàrí ìfipábánilòpọ̀ tàbí ẹni tí a kò rẹ́nì gba oyún rẹ̀ ó fa àmì ẹ̀yàn lé lóró.
Síbẹ̀, nígbà tí a ṣe àyẹ̀wò ìwé ìgbọ̀rọ̀sílẹ̀ náà, a rí i wí pé, bí ó ti lẹ̀ jẹ́ wí pé àṣàyán wà láti yan “mi ò ní bàbá,“ tí ó jẹ́ kí a ènìyàn parí ìwé ìgbọ̀rọ̀sílẹ̀ náà, kò sí àṣàyàn fún “mi ò ní ìyá,“ èyí tí ó dà bí ìyànjẹ́ fún àwọn ọmọ aláìní ìyá.
Jù bẹ́ẹ̀ lọ, àwọn tí ó ti lọ fún ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò olójúkojú ní NIRA sọ àwọn ìrírí tí ó yàtọ̀. Bí wọ́n bá ń fi ọ̀rọ̀ sílẹ̀ fún ìwé-ẹ̀rí ìdanimọ̀ ọmọ-orílẹ̀-èdè ní orí ẹ̀rọ-ayélujára, àwọn ohun tí àwọn tí ó ń fi orúkọ sílẹ̀ ní láti fi ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ọ̀rọ̀ sílẹ̀, gẹ́gẹ́ bíi orúkọ ìdílé, orúkọ ìyá ní omidan, àti àwọn ìwífún nípa ibi tí wọ́n ti bí áwọn òbí wọn, títi kan abúlé, ẹkùn, àti agbègbè ẹkùn.
Ní ọ̀nà àti ṣe àrídájú wí pé ọmọ ìbílẹ̀ Uganda ni ènìyàn ń ṣe, bí wọ́n bá ní kí àwọn ènìyàn ó wà fún ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò olójúkorojú, níbi tí wọ́n á ti ya àwòrán ojú àti gbígba òntẹ̀ ìka sílẹ̀, wọ́n tún máa ń béèrè àwọn ìbéèrè mìíràn bíi èyí tó ní í ṣe pẹ̀lú èdè abínibí wọn. Àwọn kan sọ pé wọ́n máa ní kí ẹni tí kò bà lè sọ èdè abínibí rẹ̀ dáadáa tàbí tí kì í sọ ọ́ rárá torí ìdí kan tàbí òmíràn ó pé ọ̀kan nínú àwọn ẹbí rẹ̀ wá fún àrídájú pé ọmọ orilẹ̀-èdè ni.
Muganga ṣàlàyé pé, kí àwọn àjọ tó ń rí sí àwọn ọmọ tí kò ní òbí máa mú àwọn ìwé ẹrí tí wọ́n gbà lọ́dọ́ ìjọba dání bíi ìwé láti ọ̀dọ̀ àwọn ọlọ́pàá nígbà tí wọ́n bá ń ṣe àyẹ̀wò ìdánimọ̀ fún àwọn ọmọ tí kò lóbìí. Èyí yóò mú ìrọ̀rùn bá gbígba àwọn ìwé kan tó jẹ́ ti ìjọba.
Stella Anam, olùdarí War Victims and Children Networking (WVCN) ní Àríwá Uganda, dá àjọ tirẹ̀ sílẹ̀ láti fi wá ibùgbé fún àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé tí ìkọlù Lord’s Resistance Army (LRA) pa lára, èyí tó jẹ́ rògbòdìyàn láti kojù ìjọba Uganda tó ń lọ́ lọ́wọ́lọ́wọ́, tí ó sì ti ṣọ àwọn èèyàn tó ju ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ kan di aláìnílé lórí, tí ó sì tún ṣokùnfa ikú àwọn èèyàn tó ju 100,000 lọ, gẹ́gẹ́ bí ìṣirò àjọ United Nations. Ogun yìí ti sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ di ọmọ òrukàn. WVCN ń ran àwọn ọmọ yìí lọ́wọ́, pàápàa àwọn tí kò tilẹ̀ mọ bàbá tó bi wọn mọ́, láti fi orùkọ sílẹ̀ àti láti gba àwọn ìwé ìdánimọ̀.
Àdojúkọ̀ kan tí àjọ yìí ní ni pé, lẹ́yìn tí wọ́n bá ti pèsè àwọn ìwé tó yẹ̀, àwọn aṣojú NIRA ṣì tún máa ń ṣe ìbéèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọ yìí nípa bàbá wọn àti ìdílé tí wọ́n ti wá. Anam jẹ́ kí ó di mímọ̀ pè, ìpàdé pẹ̀lú àwọn aṣojú NIRA ní ọdún 2023 ṣokùnfà àwọn ìyàtọ̀ kọ̀ọ̀kan àmọ́ ìṣoró náà kòì tíì lójútùú tán.
Ọmọ ọdun mẹ́rin ni Aciro Sandra nígbà tí o mọ̀ wí pé South Sudan ni wọ́n bí òun sí, níbi tí àwọn obi rẹ̀ ti wà nínú ìgbèkùn LRA, lábẹ́ àkóso Joseph Kony. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún, nígbà tí ó fẹ́ gba ìwé ìdánìmọ̀ gbogboogbò rẹ̀, ó kọ̀ láti pèsè àwọn ìwífún nípa bàbá rẹ̀.
Ó ní, “Àyà mi já láti ló orúkọ rẹ̀ tórí ibi tí ó ti wá”. Bàbá rẹ́ tí kúrò nínú ìgbèkùn ó sì ti dí aláṣẹ ní LRA. Wọ́n dá ẹbí rẹ̀ sílẹ̀ ní ọdún 2004, wọ́n sì fi ìlú Gulu ní Àríwá Uganda ṣe ibùgbé. Lónìí, orúkọ bàbá rẹ̀ ló wà nínú àwọn ìwé rẹ̀ àmọ́ ìlú tuntun kan tí àwọn èèyàn kò ti mọ́ ohunkóhun nípa àná bàbá rẹ̀ ni ó ń gbé.
Láti i2gbà ti1 wọ́n ti padà sílé, àwọn tí ó fara-gbàrù-wẹ̀ bí i Sandra máa ń kojú ìtìjú, ìwà ipá sí obi2nrin, ifojútẹ́mbẹ́lú ẹni àti àíkanikún láwùjọ.
Anam ṣe àfikún pé, àwọn tí ó fara-gbàrù-wẹ̀, pàápàá jùlọ àwọn ọmọ kéékèèké ṣì ń gbé pẹ̀lú ọgbẹ́ ọkàn, kódà àwọn ìdílé wọn ò tẹ́wọ́ gbà wọ́n. Èyí tí ó sì ṣokùnfà ìpenìjà gbòógì tó ní í ṣe pẹ̀lú ìdánìmọ̀.
Ọ̀kan nínú àwọn tí ètò Anam ṣe ìrànwọ́ fún sọ ìrírí rẹ̀:
Kódà bí mo bá jẹ́ afarakááṣá, n ò gbọdọ̀ sọ̀rọ̀ nípa ìfipábánilòpọ̀. Èèwọ̀ ni níbí. Èyí lè ṣe ìdìná fún mi láti rí ọkọ fẹ́.
Iriri iya Francis jẹ́ ọgbẹ́ ọkàn tí Francis ṣì ń bá já. Ó sì nírètí pé ètò ìdájọ́ òdodo yóò wáyé ní Uganda níbi tí wọ́n ti máa fìyà jẹ ẹni tí ó ṣẹ̀, tí wọ́n á gbè lẹ́yìn ẹni tí ó fara-gbàrù-wẹ̀ dípò kí wọ́n sọ wọ́n di ẹni yẹ̀yẹ́.
Nígbà mìíràn, tí àwọn obìnrin bá fi ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ sùn, níṣe ni wọ́n tún máa ń dá wọn lẹ̀bi àgbèrè tàbí pé àwọn ni wọ́n fa ìṣẹ̀lẹ̀ ipá náà, èyí tí ó jìnnà sí òótọ́”. Ó ní, èyí gan-an ní ó ń kọ òun lóminú.
Mary Nakiranda, agbẹjọ́rò fún FIDA ní Uganda, ṣàlàyé pé òfin tó de àwọn ọmọ mìíràn náà ló dé àwọn ọmọ aláìlóbìí, òfin wọ́n ò dá yàtọ̀. “Níwọ́n ìgbà tó jẹ́ pé àbájáde ìfipábánilòpọ̀ ni wọ́n fi bí wọn, àwùjọ àti àwọn ẹbí wọn ní láti tẹ́wọ́ gbà wọ́n bí wọ́n ṣe rí”. Ó tún fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé “Bí àwọn afarakááṣá bá mọ àwọn ọ̀daràn tí wọ́n ṣe iṣẹ́ láabi yìí, kí wọ́n fi ẹjọ́ náà tó àwọn ọlọ́pàá tàbí àjọ bíi FIDA Uganda léti, láti ṣe àyẹ̀wò DNA láti lè fìdí ẹni tó loyún múlẹ̀. Kì í ṣe pé àwọn bàbá yìí á máa gbọ́ bùkátà nìkan, wọ́n a tún jìyà ọ̀ràn tí wọ́n dá.”
Francis, meanwhile, keeps her distance from men. “I’m still haunted by my mom’s story. I don’t feel safe around men,” she admits. “My biggest fear is having children. I worry about what life would be like for them (in terms of identity).”
Francis ń yẹra fún ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn ọkùnrin. Ó ní “Ọgbẹ́ ọkàn ni ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ìyá mi jẹ́, ọkàn mi ò balẹ̀ lóri àwọn ọkùnrin”. “Ohun tó bà mí lẹ́rù jùlọ ni ọmọ bíbí. Ẹ̀rú náà jẹ́ irúfẹ́ ìgbé ayé tí wọn yóò gbé (látàrí ìdánimọ̀).





