Bí ó ṣe rí fún àwọn obìnrin orílẹ-èdè Afghanistan tó ń dá oko-òwò lábẹ́ ìjọba Taliban

Women in Afghanistan.

Àwọn obìnrin ní Afghanistan. Àwòrán tí a yọ láti inú fídíò Women’s rights being rolled back in Afghanistan – BBC News’ lórí ikànnì YouTube BBC News. A lò ó lọ́nà òdodo.

Arezo ló kọ àpilẹ̀kọ yìí ní ọdún 2025. Ó fún wa ní àṣẹ láti tẹ̀ ẹ́ jáde gẹ́gẹ́ bí ara iṣẹ́ àkànṣe lórí àkójọpọ̀ ìtàn tí ó ń ṣe àfihàn ìrírí àwọn ọ̀dọ́bìnrin àti ọmọdébìnrin ní Afghanistan, lẹ́yìn tí Taliban gba ìjọba ní oṣù Ògún, ọdún 2021.

Láti ìgbà tí àwọn Taliban ti jẹ gàba lé Orílẹ̀-èdè Afghanistan lórí ní oṣù Ògún, ọdún 2021, ni àwọ́n Taliban ti ń fi oju ẹ̀tọ́ àwọn ará orílẹ̀-èdè náà gbolẹ̀, tí wọ́n sì ń sọ àwọn ètò tó ń dáàbò bo ẹ̀tọ́ wọ̀nyí di yẹpẹrẹ. Àwọn obìnrin àti ọmọdébìnrin ni èyí kàn jùlọ látárí bí àwọn Taliban yìí ṣe ṣe àgbékalẹ̀ àwọn òfin máṣu-mátọ̀ tí ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ mú ìparun bá àwọn ẹ̀tọ́ àti òmìnira wọn.

Lára àwọn òfin máṣu-mátọ̀ wọnyìí ni àtìpa àwọn ilé ẹ̀kọ́, Ifásítì àti àwọn àyè ìkẹ́kọ̀ọ́ tí àwọn obìnrin àti ọmọdébìnrin tí ń kẹ́kọ̀ọ́. Ohun mìíràn tí wọ́n tún ṣe ni fìfi òfin de àwọn obìnrin tí ó n ṣiṣẹ́ ní àwọn ẹ̀ka ìjọba àti àwọn ilé iṣẹ́ aládani. Yíyọ ọwọ́ àwọn obìnrin kúrò nínú ètò ọrọ̀ ajé àti ètò tí ó ní ṣe pẹ̀lú bíbéèyàn ṣe ní gbangba jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìwà àìtọ́ àti ìninilára tó burú jùlọ tí Taliban ti hù sí àwọn obìnrin orílẹ̀-èdè Afghanistan.

Pẹ̀lú ìdánilójú àkọ́kọ́ ní ọdún 2021 pé àwọn yóò “dáàbò bo ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin”, gbogbo àwọn òfin tí àwọn Taliban ni ó tùbọ́ fi àwọn ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn àti ẹ̀tọ́ áwùjọ àwọn obìnrin dùn wọ́n. Láì sí àní-àní, wọ́n ti sọ orílẹ̀-èdè Afghanistan di túbú fún àwọn obìnrin.

Àwọn òfin yìí wà lóríṣìiríṣìi láti oríi sísọ ìbòrí (hijab) di kànánpágbígbẹ́sẹ̀ lé ìjáde obìnrin láì jẹ́ wí pé ọkùnrin alábòójútó tẹ̀ lé e. Gbogbo àwọn òfin wọ̀nyí ni wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ gbé kalẹ̀ láti fi sé àwọn obìnrin mọ́ ilé. Lónìí, ó ṣòro láti rí àwọn obìnrin àti ọmọdébìnrin ní òde tàbí ní àwọn ibi ìpéjọpọ̀ láwùjọ.

Ní àkótán, àwọn òfin Taliban ń gbìyànjú láti rí i dájú pé kò sí ìlọsíwájú àti ìdàgbàsókè fún àwọn obìnrin orílẹ̀-èdè Afghanistan.

Ìgbésí ayé mi gẹ́gẹ́ bi obìnrin oníṣòwò

Pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó ń rùn nílẹ̀ yìí, èmi, gẹ́gẹ́ bí obìnrin orílẹ̀-èdè Afghanistan, tí mo ti gbé, tí mo sì ti ṣiṣẹ́ nínú irú àyíká tí ó léwu bẹ́ẹ̀ tí kò sì fi àyè gba obìnrin, mo sì pinnu láti di oníṣòwò ní Afghanistan.

Ní ọdún 2023, mo bẹ̀rẹ̀ sí í dá oko-òwò ní ẹ̀ka ilé-iṣẹ́ tí ó n ṣe ọṣẹ-àbùfọ̀ àti ike, mo sì pèsè iṣẹ́ fún àwọn obìnrin mẹ́fà àti àwọn ọkùnrin mẹ́jọ.

Ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, mo kojú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdènà àti ìṣòro.

Nígbàkígbà tí mo lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ìjọba àti àwọn ilé-iṣẹ́ aládàáni láti fi orúkọ sílẹ̀ àti láti parí ètò lórí iṣẹ́ mi, àwọn ènìyàn máa ń fi ojú àìda wo mi, wọ́n sì máa ń bi mí ní àwọn ìbéèrè tí kò tọ́. Nígbà tí mo bá lọ sí àwọn ilé ìtajà láti ṣàyẹ̀wò ọjà àti láti rí bí mo ṣe lè tẹ́ àwọn oníbàárà mi lọ́rùn, wọ́n máa fi ojú ẹ̀gàn àti àbùkù wò mí.

Ṣùgbọ́n mi ò jẹ́ kí ó sú mi. Láì fi ti gbogbo àwọn ìdíwọ̀ wọ̀nyí ṣe, mo tẹ̀síwájú nínú ìdojúkọ ìfojútẹ́mbẹ́lú abo.

Lójoojúmọ́, tìbẹ̀rù-tojo ni mo fi ń lọ sí ibi iṣẹ́. Nígbàkigbà, àwọn ọmọ ogun Taliban lè wọ ibi-iṣẹ́ mi, kí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í bi mí ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbéèrè nípa ìborí tí mo wọ̀ sórí tàbí àwọn nǹkan mìíràn.

Nígbà tí mò ń ṣàkóso ibi iṣẹ́ mi, wọ́n máa wí fún mi pé kí n lé gbogbo àwọn òṣìṣẹ́bìnrin lọ, kí àwọn ọkùnrin nìkan máa ṣe iṣẹ́. Kódà nígbà tí mo gbìyànjú láti sọ̀rọ̀ tùtù fún wọ́n pé mo máa pèsè àyè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ fún àwọn obìnrin àti àwọn ọkùnrin, wọ́n tún máa wá àwáwí mìíràn láti rí i dájú pé kò sí àyè fún àwọn obìnrin láti ṣe iṣẹ́.

Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, wọ́n fi ṣìkún òfin mú mi, wọ́n sì gbé mi lọ sí ẹ̀ka ìtìmọ́lé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ńlá. Wọ́n dá mi dúró síbẹ̀ fún ìgbà pípẹ́, wọn ò sì fi ọ̀wọ̀ kankan wọ̀ mí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá-ọmọ-ènìyàn, obìnrin tàbí oníṣòwòbìnrin.

Ohun tí wọ́n fi mú mi ò ju ti ìgbìyànjú mi láti wá ọ̀nà ìjẹ fún ara mi àti láti dá iṣẹ́ sílẹ̀ fún àwọn ènìyàn.

Lẹ́yìn-ò-rẹyìn, wọ́n dá mi sílẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí àwọn ẹbí mi ṣe onídùro fún mi, ìwà àìbọ̀wọ̀fúnni àti ìrẹnisílẹ̀ èyí tí mi ò sì lè gbàgbé láeláé yìí rú mi nínú.

Àwọn ìdíwọ́ tí kò lópin àti ìrètí tí ó ti wọmi

Ìgbésí ayé lábẹ́ ìjọba Taliban ni ìdíwọ́ àìlópin fún àwọn obìnrin Afghanistan, pàápàá jù lọ fún àwọn obìnrin tí wọ́n ní ìrètí òmìnira àti kíkópa láwùjọ jẹ lógún ń dojú kọ àwọn ìdíwọ́ tí kò lópin. Ní sáà yìí, a kò ní ìrètí pé ọjọ́ ọ̀la yóò dára.

Wọ́n ti gba ẹ̀tọ́ sí ẹ̀kọ́, iṣẹ́, òmìnira láti jáde lọ́wọ́ wa, pàápàá jùlọ, òfin líle ti de yíyan aṣọ wíwọ̀.

Ọjọ́ ọ̀la Afghanistan ń fi ojoojúmọ́ ṣókùnkùn sí i, pàápàá jùlọ fún àwọn obìnrin.

Ìgbésí ayé ọmọniyàn lábẹ́ ìjọba Taliban jẹ́ kìkì ìrora, ìjìyà àti àwọn onírúurú ìdíwọ́.

Fún àwọn obìnrin Afghanistan, ó dà bí i ìyani sọ́tọ̀ láwùjọ, èyí tí ó jẹ́ pé wọ́n ti gba ìrètí ọjọ́ ọ̀la àti òmìnira ara-ẹni ní ọwọ́ wa.

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.