
Àgékù àwòrán ìwò-ojú-ẹ̀rọ láti ìjábọ̀ ìròyìn láti ọwọ́ Gazete Duvar. Àwọn obìnrin ń wọ́de ní ẹ̀ka Van. Canva ni a fi tún àwòrán náà ṣe.
“Orílẹ̀ èdè Turkey ń fẹ́ àyípadà,” èyí ni àkóónú atẹ̀jáde kan tí ó wà lórí ìkànnì ìbánidọ́rẹ̀ tí ó gbajúgbajà-n-nì tí ó ń jẹ́ Instagram Turkishdictionary, nígbà tí ó ń ṣe àfihàn ìròyìn kan wí pé àwọn obìnrin méje ni wọ́n ti di pípa láàárín ọjọ́ mẹ́ta. “Ẹ jẹ́ ká sọ òótọ́. Orílẹ̀-èdè Turkey ní ìṣòro ìwà ipá,” ka àtẹ̀jáde mìíràn tí wọ́n fi si orí Instagram.
Ní àwọn ọ̀sẹ̀ tí ó kọjá, àwọn ẹgbẹ́ ajàfẹ́tọ̀ ọmọnìyàn ní Turkey tí ń sa gbogbo ipá wọn láti pe àkíyèsí si àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ní ṣe pẹ̀lú àwọn ìwà ipá ní orílẹ̀-èdè náà. Ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù yìí, àwọn obìnrin méjì ni wọ́n pa ní Istanbul. Ọmọdékùnrin ẹni ọdún 19 tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Semih Çelik ni ó ṣe ikú pa İkbal Uzuner and Ayşenur Halil, lẹ́yìn tí ó ṣe iṣẹ́ láabi yìí tán ni ó sì gba ẹ̀mí ara rẹ̀. Çelik ni ìròyìn fi hàn pé ilé ẹjọ́ ti dá ní àwọn ẹbì tẹ́lẹ̀ rí tí ó sì ní ìpèníjà pẹ̀lú ìlera ọpọlọ. Ó tún ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹgbẹ́ tí wọ́n ní ìséra tí kò ti ọkàn wọn wá ní orílẹ̀ èdè Turkey, tí wọ́n máa ń pè fun kí àwọn ọkùnrin máa fi ipá bá obìnrin lòpọ̀, kí wọ́n máa kó ìnira bá wọn, àti pàápàá kí wọ́n máa pa àwọn obìnrin, lórí àwọn ìkànnì ìbánidọ́rẹ̀. Obìnrin tí wọ́n rí òkú rẹ̀ ní kòpẹ́ kòpẹ́ yìí ni Rojin Kabaiş, ẹni ọdún 21 akẹ́kọ̀ọ́ Fásitì tí o sọnù fún ọjọ́ 18.
Àwọn obìnrin àti ọmọdé tí wọ́n ti di òkú
Uzuner àti Halil nìkan kọ́ ni àwọn obìnrin tí orúkọ wọ́n jáde nínú àwọn kókó ìròyìn ní Turkey ní ọ̀sẹ̀ tí ó kọjá. Àwọn ọkùnrin méjì tí wọ́n fi ipá bá obìnrin mìíràn lò pọ̀ ní Istanbul ni wọ́n ti di títún gbé lẹ́yìn tí wọ́n ti kọ́kọ́ dá wọn sílẹ̀ lẹ́yìn tí fọ́nrán ìwà ìbàjẹ́ náà dé orí àwọn ìkànnì ìbánidọ́rẹ̀ tí ó sì fa fífi igbe ta àwọn ará ìlú.
Akọ̀ròyìn kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Melisa Gulbas, nínú àgbéjáde rẹ̀ tí ó fi síta lẹ́nu lọ́ọ́lọ́ yìí ni ó ti ṣe àfihàn pé ìwà ipá tí ó ń dójú kọ àwọn obìnrin àti ọmọdé ni ó tí ń dé ìpele tí kò sí irú rẹ̀ ní Turkey. Nípa ṣíṣe àfiwé àkọsílẹ̀ láti 2021 àti 2022, Gulbas kọ wípé àlékún tí ó jẹ́ ìdá ọgọ́ta ni ó ti dé bá àwọn ẹjọ́ ìfipábánilò tí àwọn obìnrin ń kojú ní 2023.
Bákan náà ní oṣù ọ̀wàwà, ọmọ kékeré ẹni ọdún méjì ni ó kú sí ipò àìkú-àìyè lẹ́yìn tí wọ́n fi ipá bá a lò ní agbègbè Tekirdağ. Nígbà tí ó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀, olórí ẹgbẹ́ àwọn agbẹjọ́rò ní Tekirdağ, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Egemen Gürcün sọ wípé àlékún tí bá ìwà ìlo ọmọ ní ìlòkulò ní agbègbè náà, “nípa ṣíṣe atọ́ka sí ìpè fún àwọn agbẹjọ́rò fún àwọn ẹjọ́ tí ó ní ṣe pẹ̀lú ìlòkulò ọmọdé tí iye rẹ̀ jẹ́ 283 lọ́wọ́ ẹgbẹ́ agbẹjọ́rò náà ní ọdún 2023 nìkan, pẹ̀lú ìpè tí iye rẹ̀ jẹ́ 172 ní ọdún 2024,” Bianet ló jábọ̀ ìròyìn náà Bianet.
Ní oṣù ọwẹ́wẹ̀, obìnrin agbófinró kan ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ni ọ̀daràn tí wọ́n fí ẹ̀sùn tí iye rẹ̀ jẹ́ mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n pa.
Ní oṣù ọwẹ́wẹ̀ náà bákan náà, ìròyìn tí ó báni lọ́kàn jẹ́ kọ lu orílẹ̀ èdè náà pé òkú ẹni ọdún mẹ́jọ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Narin Güran ni wọ́n rí ní tòsí abúlé tí ó ń gbé pẹ̀lú àwọn ẹbí rẹ̀. Ikú ọmọdébìnrin náà ló ṣe òkùnfà àwọn ìfẹhónúhàn tí ó kárí gbogbo orílẹ̀ èdè náà tí ó sì pè fún àlàyé ìjọba. Àwọn olóye sọ wípé àwọn òfin ìlú tí ó ní ṣe pẹ̀lú ìwà ipá ni kò pé ye tí ó sì ní àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn àti àwọn ìṣe tí kò bá ìgbà mu tí wọ́n fi ààyè gba ìwà ìbàjẹ́ àti àwọn oníbàjẹ́ nínú.
Ní ọdún 2022, lẹ́yìn tí àgbéjáde ẹgbẹ́ a-jà-f'ẹ́tọ̀ ọmọnìyàn Human Rights Watch (HRW) tí ó lágbára kan jáde, Emma Sinclair-Webb, ẹni tí ó jẹ́ olùdarí ìpín Yúróòpù àti ààrin gbùngbùn Asia ní HRW, ṣàlàyé ìdí tí ó ṣe nira láti dojú ìjà kọ ìwà ipá tí ó ń dójú kọ àwọn obìnrin ní ilẹ̀ Turkey:
Ọ̀nà tí ìjọba ń gbà dojú ìjà kọ ìwà ipá tí àwọn obìnrin ń kojú ní wọ́n fí àwọn ọ̀rọ̀ a-fẹ́-á-jẹ-má-fẹ́-á-yó ṣe àpèjúwe rẹ̀. Àwọn aláṣẹ rí i gẹ́gẹ́ bí apá kan lára ojúṣe ìjọba àpapọ̀ láti dáàbò bo àwọn obìnrin, tí wọ́n rí bí ohun ẹlẹgẹ́, àti láti ṣe àtìlẹ́yìn fún àgbékalẹ̀ ẹbí. Ó wà ní àkọsílẹ̀ pé ààrẹ orílẹ̀ èdè Turkey ń tako ìdọ́gba akọ àti abo tí ó sì ti di píparẹ́ nínú òfin ìjọba. Nígbà tí à ń rí ipa tí ìjọba ń kó láti dojú ìjà kọ ìwà ipá tí ó ń kojú àwọn obìnrin. Nígbà tí à ń rí akitiyan ìjọba láti wa egbò dẹ́kun fún ìwà ipá tí ó ń kojú àwọn obìnrin, ìjọba yìí bákan náà ló ń mú ìfàsẹ́yìn bá akitiyan ara rẹ̀ nípa yíye rí ìdojú ìjà kọ ìwà ipá gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà láti mú ìtẹ̀síwájú bá ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin tàbí rírí ìdọ́gba akọ àti abo dájú.
Àtẹ̀jáde mìíràn tí ó jáde ní ọdún 2023 láti ọwọ́ àpapọ̀ ẹgbẹ́ àwọn obìnrin ilẹ̀ Turkey Turkish Women's Associations Federation (TKDF) àti àjọ àpapọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè tí ó ń rí sí ìlera àwọn obìnrin (UNFPA) tí orílẹ̀ èdè Turkey, ni ó rí pé èèyàn 8 nínú mẹ́wàá tí wọ́n fi ìwà ipá kàn jẹ́ obìnrin, tí ìdá mẹ́tàléláàdọ́rin nínú àwọn obìnrin tí wọ́n fi ìwà ipá kan yìí jẹ́ ìyàwó ilé àti pé àwọn ọkùnrin ní wọ́n ń hùwà ìbàjẹ́ yìí nínú ìdá àádọ́rùn àwọn ẹjọ́ tí wọ́n di gbígbà sílẹ̀ tí a bá pín-in láàárín àwọn ọkọ àti aya (ìdá 36), àti àwọn mọ̀lẹ́bí (ìdá 21).
Ní ìbámu pẹ̀lú ìkànnì tí ó ń jẹ́ A Máa Mú Òpin Dé Bá Pípa Àwọn Obìnrin, obìnrin tí iye wọn jẹ́ 315 ni àwọn ọkùnrin ti pa, tí òkú àwọn obìnrin tí iye wọ́n jẹ́ 248 jẹ́ rírí ní àwọn àyè tí ó mú ìfura lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ìkànnì náà ní 2023. Nínú ọdún yìí nìkan, àwọn obìnrin tí iye wọ́n jẹ 319 ni wọ́n ti pa, ní ìbámu pẹ̀lú àkọsílẹ̀ mìíràn láti ọwọ́ ìkànnì aṣàkópamọ́ mìíràn.
Ọ̀nà àbáyọ tí orílẹ̀ èdè náà là kalẹ̀ fún àwọn ikú wọ̀nyí ni láti dí ọ̀nà ìfi ààyè gba ìjà, nítorí, gẹ́gẹ́ bí ohun tí mínísítà fún ètò ìdájọ́ Yilmaz Tunc sọ, ìkànnì náà jẹ́ orísun ìwà ipá náà, èyí tí ó bí àwọn ìwà ọ̀daràn“ fífi ipá bá ọmọdé lò pọ̀ àti ìwà àbùkù.”
Ìpadà sí ìpéjọ Istanbul nígbẹ̀yìn?
Ní 2021, Turkey yọ ara rẹ̀ kúrò nínú ìpéjọ Istanbul, ìgbìmọ̀ ìpéjọ ilẹ̀ Yúróòpù tí ó wà fún dídènà àti didojú ìjà kọ ìwà ipá tí ó ń kojú àwọn obìnrin. Láti ìgbà tí ìyọkúrò náà ti wáyé, àwọn ẹgbẹ́ a-jà-fún-ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin ti pè fún kí orílẹ̀ èdè Turkey padà wọ inú ìpéjọ náà, bíótilẹ̀jẹ́pé ààrẹ orílẹ̀ èdè Turkey ní èròńgbà mìíràn. Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ níbi ìpàdé ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀ ní ọjọ́ kẹsàn-án oṣù ọ̀wàwà, ààrẹ náà sọ wípé, “ìyọkúrò wa nínú ìpéjọ Istanbul kò ní ipa tí kò dára bí ò ti lè wù kó kéré tó lórí ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin.” Ààrẹ náà tún pinnu láti fi kélé òfin gbé àwọn tí wọ́n ní àkọsílẹ̀ ìwà ọ̀daràn tí wọ́n yóò sì fi ojú bá ilé ẹjọ́ tí kò sì ní jẹ́ kí àwọn ọ̀daràn máa rìn ní ọ̀fẹ́ ní orílẹ̀ èdè náà.
“Àṣegbé náà ni,” òun ni ìdí gbòógì fún ṣíṣe ikú pa àwọn obìnrin, ọmọdé, àti àwọn ẹranko tí wọ́n nù , gẹ́gẹ́ bí Sera Kadigil ṣe sọ, tí ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ àti ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin, nínú fọ́nrán ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò.
Ní àkókò kan náà, gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó wà nínú àwọn àbọ̀ ìròyìn, àwọn ọlọ́pàá náà ti bẹ̀rẹ̀ sí ni ṣe àmójútó àwọn ẹgbẹ́ tí wọ́n mọ̀ sí “incel” nígbà tí títa tajú tajú sì lọ sókè si ní orílẹ̀ èdè lẹ́yìn onírúurú ìṣẹ̀lẹ̀ ìpànìyàn tí ó ṣẹlẹ̀ ní oṣù méjì sẹ́yìn. Àwọn à-jà-fún-ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin àti ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn obìnrin ti jáde sí ìgboro káàkiri orílẹ̀ èdè náà, tí wọ́n sì ń pè fún àyípadà nínú àwọn òfin.






