
Ọ̀mọ̀wé Jakob Lesage àti díẹ̀ lára àwọn ikọ̀ iṣẹ́ ìwádìí àkópamọ́. Obidah Amos ló ní àwòrán. A gba àṣẹ kí a tó lò ó.
Àpilẹ̀kọ yìí jẹ́ ọ̀kan lára àpilẹ̀kọ oníṣísẹ̀ntẹ̀lé “Ẹ̀tọ́ àwọn Ènìyàn Ìbílẹ̀,” Ohùn Àgbáyé oṣù Kẹ́jọ ọdún 2026. Àfojúsùn àwọn àpilẹ̀kọ oníṣísẹ̀ntẹ̀lé náà ni láti fúnni ní òye nípa ìgbé ayé àti ìrírí àwọn ará ìlú, láti ṣàfihan àwọn ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ láwùjọ, láti jẹ́ kí àwọn ènìyàn Ìbílẹ̀ sọ ìrírí wọn fúnra wọn, àti láti sọ ìtàn nípa àwọn olórí, ajàfẹ́tọ̀ọ́ àti àwọn ará ìlú, àti àwọn nǹkan mìíràn. Ó lè ṣe àtìlẹ́yìn fún ìtẹ̀síwájú ìjábọ̀ ìròyìn yìí nípa fífowósílẹ̀ níbí.
Bí ó bá ṣe pé ìdojúkọ àkúnrùn èdè nípasẹ̀ ṣíṣètò ìrónilágbára fún àwọn ará ìlú láti lè ṣe àkópamọ́ èdè wọn ni ọ̀nà kan tí ó ní agbára jùlọ ńkọ́ ? Iṣẹ́-àkànṣe Àkópamọ́ Èdè Kam jẹ́ àpẹẹrẹ bí akitiyan àwọn ará ìlú ṣe le ṣèrànwọ́ fún ìpamọ́ àwọn èdè tó wà nínú ewu àkúrun.
Èdè Kam (tí àwọn ènìyàn tún ń pè ní Nyingwom) jẹ́ èdè tí wọ́n ń sọ ní àwọn ìletò 29 ní ìjọba Ìbílẹ̀ Bálì ní ìpínlè Tárábà ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Yóò fẹ́rẹ̀ẹ́ tó nǹkan bí i 8,000 sí 11,000 ìye ènìyàn ló ń sọ èdè Kam lónìí. Gẹ́gẹ́ bí àwọn èdè ìbílẹ̀ mìíràn ní apá àríwá-ìlà-oòrùn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, kò sí olùṣèwádìí tí ó kọbi ara sí èdè náà ṣáájú ọdún 2016. Ìdí nìyẹn tí kò fi sí ìwé, ìwé atúmọ̀ ọ̀rọ̀, àkọtọ́ èdè, kò sì sí àkásílẹ̀ olóhùn-àti-àwòrán kankan tí ó dá lórí èdè ọ̀hún tí ẹnikẹ́ni le lò láti fi ṣe ìkópamọ́.
Kí èdè yìí má ba à á run, Ọ̀mọ̀wé Jakob Lesage, ẹni tí ó jẹ́ onímọ̀ ẹ̀dá èdè àti olúkọ́ni ní Ilé-ẹ̀kọ́ Èdè Ilẹ̀ Adúláwọ̀ áti Áṣíà, ní fáṣítì Humboldt-Universität zu Berlin, bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣiṣẹ́ àkànṣe Kam lọ́dún-un 2016. Fún ọdún mẹ́wàá gbáko, ó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí wọ́n ń sọ èdè náà nípa ṣíṣe àmúlò ìlànà tí ó ń pè ní “ìlànà ìtànkálẹ̀”: Dípò kí ó wá láti òkèrè ṣiṣẹ́ bí i àgbà ọ̀jẹ̀ nínú ìwádìí, ó ró àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Kam 14 ní agbára láti ní ìmọ̀ nípa ṣíṣe àkópamọ̀ èdè. Ní ìgbà tí iṣẹ́ àkànṣe ọlọ́dún mẹ́wàá náà wá sí òpin ní oṣù Kẹta ọdún 2026, ikọ̀ náà ti ṣe àmúwá àwọn ìwé àtọ́ka fún gírámà èdè Kam, ìwé atúmọ̀ èdè orí ẹ̀rọ-ayélujára, wọ́n ti gbà 307 ohùn àti àwòránolóhùn sílẹ̀, wọ́n sì ti ṣẹ̀dá ìbùdó-ìtàkùn kan fún èdè Kam.
Nígbà tí Lesage ń bá akọ̀rọ̀yìn Global Voices, Abdulrosheed Fadipe, sọ̀rọ̀ lórí WhatsApp, ó ṣàlàyé bí iṣu ṣe kú àti tí ọ̀bẹ ṣe bẹ ẹ́ lórí iṣẹ́ àkànṣe náà.

Olóògbé Isa Sarkin Sawa, ọba àwọn ẹ̀yà Kam (ẹni tí ó wo aṣọ funfun), pẹ̀lú àwọn àlejò lọ́balọ́ba tí wọ́n wà ṣíbí ayẹyẹ àṣeparí Iṣẹ́-àkànṣe Àkópamọ́ Kam. Obidah Amos ló ní àwòrán. A gba àṣẹ kí a tó lò ó.
GV: Kí ló kọ́kọ sún un yín débi ṣíṣe iṣẹ́ lórí àwọn èdè Nàìjíríà?
JL: Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní àwọn àkójọpọ̀ èdè tí ó yàtọ̀ sí ara wọn, tí wọn kò sì sí àkópamọ́ fún wọn, tí ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn agbègbè tí wọ́n ń pònhùngbẹ pé kí èdè wọn ó jẹyọ nínú iṣẹ́ ìwádìí, tí àwọn náà yóò sì bá ẹgbẹ́ èdè pé. Yóò fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdajì nínú àwọn èdè tí ó lé ní 500 tí wọn kò ì tíì ṣe iṣẹ́ ìwádìí ìjìnlẹ̀ tó ní ìtumọ̀ lórí wọn – tí Nàìjíríà sì jẹ́ orílẹ̀-èdè tí ó ní èdè tí ó pọ̀ ti kò sí ní àkópamọ́ ju ibikíbi ní orílẹ̀ Áfíríkà lọ.
Fún onímọ̀ ẹ̀dá èdè, iṣẹ́ yìí jẹ́ ohun tí ó yáni lórí, a ò gbọdọ̀ jáfara láti ṣe é. Ṣíṣe ìwádìí nípa èdè kan ṣoṣo tí a kò ṣàkópamọ́ rẹ̀ dáadáa lè yí ohun tí a rò pé a mọ̀ nípa ẹ̀ka èdè, ìtàn, àti ìmọ̀ èdè lápapọ̀ pàápàá padà. Kam jẹ́ irú àwọn èdè bẹ́ẹ̀ — ó wà lára àwọn èdè tí a kà sí ẹ̀ka èdè Niger-Congo, ṣùgbọ́n kò sí ẹ̀yà èdè kéékèèké kankan tí a lè kà á sí nítorí ó yàtọ̀, tí èyí sì ti fa oríṣiríṣi ìbéèrè lórí bí ó ti se rí bí ó ṣe rí. Èdè yìí ní àwọn àbùdá kọ̀ọ̀kan tí ó tan iná ìmọ́lẹ̀ sí àwọn ìjiyàn lórí èdè ní àpapọ̀.
Yàtọ̀ sí pé èyí jẹ́ iṣẹ́ ìwádìí ìjìnlẹ̀, iṣẹ́ náà ṣe pàtàkì fún àwọn tó ń sọ àwọn èdè náà, tí wọ́n ń fẹ́ kí ìtàn wọn wà lákọọ́lẹ̀ kí èdè wọn sì má kú àkúnrun. Nàìjíríà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn agbègbè tí ò wọ́pọ̀ níbi tí ìmọ̀ ẹ̀dá èdè ti ṣe pàtàkì fún ìwádìí ìjìnlẹ̀, tí ó sì ní ìtumọ̀ tóòtọ́ sí àwọn ènìyàn tí ó ń sọ èdè náà — àwọn ènìyàn nífẹ̀ẹ́ láti ṣàkópamọ́ àwọn èdè wọn.
GV: Níbo ni Kam wà lórí òṣùwọ̀n èdè tó wà ní ojúnà àkúrun — ǹjẹ́ èdè náà wà nínú ewu bí?
JL: Àwọn èèyàn ṣì ń fọ Kam dáadáa, fún ìdí èyí kò sí nínú ewu báyìí — ṣùgbọ́n bíi ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdè ní àgbègbè náà, ó ń dójú kọ ìṣòro ńlá.
Ìkúrun èdè kìí ṣe nípa àdánù èdè nìkan. Ọ̀gangan ìpò ibi tí a gbé ti ń lò ó ni èdè máa ń gbé. Bí àwọn ọ̀gangan ìpò lílo èdè náà bá ti wọ òòkùn lọ, bẹ́ẹ̀ náà ni èdè náà yóò máa wọlẹ̀ díẹ̀díẹ̀. Ẹ jẹ́ ká ti ibi iṣẹ́ àgbẹ̀ wò ó: iṣẹ́ àgbẹ̀ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ará abúlé Kam ń ṣe. Wọ́n máa ń lo èdè wọn nígbà tí wọ́n bá ń palẹ̀ oko, bí wọ́n bá ń ṣọ̀gbìn, àti bí wọ́n bá ń ṣòwò pẹ̀lú aládùúgbò wọn. Ṣùgbọ́n bí àwọn ènìyàn bá ṣí lọ sí ìlú ńlá — níbi tí Ajé gúnlẹ̀ sí tàbí nítorí pé ìṣòro àyípadà ojú ọjọ́ mú kí iṣẹ́ àgbẹ̀ nira — ọ̀gangan ìpò náà yóò pòòrá. Àwọn èdè mìíràn yóò gba ìpò wọn, tí àwọn ọ̀gangan ìpò tuntun wọ̀nyìí sì fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ lórí àwọn èdè mìíràn. Bí o bá ṣí lọ sí Jalingo, olú-ìlú Ìpínlẹ̀ náà, èdè Haúsá ni wàá máa sọ kùrà nítorí èdè tí àwọn yẹn ń sọ ní ojoojúmọ́ nìyẹn. Bí ọ̀nà tí àwọn èèyàn ń gba gbé ìgbé ayé ṣe ń yípadà, bẹ́ẹ̀ náà ni èdè tí wọ́n sọ ń yí padà. Pẹ̀lú bí àwọn òpópónà ṣe ti ń já àwọn abúlé Kam pọ̀ mọ́ àwọn ìlú ọlọ́rọ̀ Ajé ńláńlá, kò sí ṣíṣe kò sí àìse, irú ìyípadà bẹ́ẹ̀ lè wáyé ní ẹyẹ-ò-ṣọkà.
Nítorí náà, màá sọ pé àwọn èèyàn ń sọ Kam ṣùgbọ́n ó lè má bọ̀ nínú ewu. Ohun tó ṣe kókó jù ni pé a ń ṣàkópamọ́ rẹ̀ nígbà tí àwọn èèyàn ṣì ń lò ó dáadáa, tí wọ́n sì ń sọ ọ́ lójoojúmọ́ — iṣẹ́ tí a ti ń fi ọdún mẹ́wàá tó kọjá ṣe nìyẹn.
GV: Báwo ni ó ṣe rọrùn láti ṣe iṣẹ́ àkópamọ́ èdè tí kì í ṣe tiyín lọ́nà tó bá ìlànà mú? Ipa wo sì làwọn ọmọ ìbílẹ̀ tó ń sọ èdè náà kó nínú iṣẹ́ àkópamọ́ náà?
JL: Ní tèmi, ó ṣe kókó pé àwọn ọmọ ìlú kò kópa nìkan, ṣùgbọ́n nítorí wí pé àwọn ni aláṣẹ ohun tí wọ́n fẹ́ kó wà ní ìpamọ́ àti ọ̀nà tí wọ́n fẹ́ gbà kó o pamọ́. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tí mo ti ń ṣiṣẹ́ yìí, mo ti ń lọ ìlànà iṣẹ́ tí mò ń pè ní ìlànà ìtànkálẹ̀ iṣẹ́-ìwádìí: Olùṣewádìí nìkan kọ́ ni ọ̀mọyún-ìgbín-nínú-ìkarahun tàbí apaṣẹ wàá tí ó ń dá gbogbo ìpinnu ṣe. Oníkálukú ni ó ní ojúse, àpínkárí ìmọ̀ọ̀ṣe, ohun-èlò àti àṣẹ lórí iṣẹ́ ní àárín àwọn olùṣọ́ èdè ni wọ́n fi ṣe. Àtìlẹ́yìn ni onímọ̀ ẹ̀dá èdè ṣe.
Ìlànà náà túmọ̀ sí wí pé, àwọn olùṣọ́ èdè Kam ní kó ipa tí ó pọ̀ jù lọ ní gbogbo ìpele — àwọn ni yóò ṣe àkásílẹ̀ ohùn àti àwòràn-olóhùn, ìdàkọ, ìtumọ̀, àti ní pàápàá jù lọ, ṣíṣe ìpinnu àwọn ohun tí ó yẹ kí a ṣe àkọsílẹ̀ rẹ: yálà ìtàn àtẹnudẹ́nu ni o, ìmọ̀ ìbílẹ̀, àwọn ìtàn ajẹmáṣà tó ṣe pàtàkì. Àkópamọ́ náà jẹ́ àwọn ohun tí àwọn ikọ̀ olùṣọ èdè náà kà kún.
Kí n má paró, ètò iṣẹ́ ìwádìí alákadá kò kì ń mú u rọrùn. Ètò yìí rọ̀gbọ̀kú lé ṣíṣe iṣẹ́ ìwádìí onígbà díẹ̀ àti àbájáde tí ó tọ àlàkalẹ̀ lẹ́yìn. Èyí tí ó pọ̀ jù lọ nínú iṣẹ́ ìwádìí lẹ́ka ìmọ̀ ẹ̀dá èdè ká ìbéèrè ìwádìí tí yóò ràn iṣẹ́ onímọ̀ ẹ̀dá èdè lọ́wọ́ sí ju ohun tí ó wúlò fún àwọn àwùjọ tí wọ́n ti ń sọ àwọn èdè tí wọ́n ṣe ìwádìí lé lórí lọ. Àmọ́ nǹkan ti ń yípadà, àwọn iṣẹ́-ìwádìí tí wọ́n ń ṣe lóde òní fi ti ìwádìí ìjìnlẹ̀ tó péye ṣe, tí kò tako ohun tí àwọn àwùjọ tí ó ni èdé fẹ́.
Àfojúsùn mi ni láti ṣe àwòṣe iṣẹ́ ní èyí tí yóò fi àkóso sí ọwọ́ àwọn elédè, tí wọn yóò sì ka iṣẹ́ náà kún lẹ́yìn ìgbà tí iṣẹ́ àkànṣe náà bá dópin. Mo máa sọ wí pé iṣẹ́ atẹ̀lé àlàkalẹ̀ náà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àǹfààní látàrí àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn tí ó ní èdè tí iṣẹ́-ìwádìí dá lé lórí. Olúkúlùkù ló máa jẹ èrè bí àjọṣepọ̀ bá dán mọ́rán.

Ayẹyẹ àṣeparí Iṣẹ́-àkànṣe Àkópamọ́ Èdè Kam. Ijó tí wọ́n ń jó yìí ni wọ́n ń pè ní Ǹsúróng. Obidah Amos and Rev. Saul Samuel ni wọ́n ni àwòrán. A gba àṣẹ kí a tó ó lò ó.
Ará ìlú tí ó ṣe kòkárí iṣẹ́ àkópamọ́ èdè náà, Babangida Audu, sọ bí iṣẹ́ náà ṣe bẹ̀rẹ̀:
Ní ìgbà tí òyìnbó aláwọ̀ funfun [ìyẹn Lesage] dé sí Sarkin Dawa lọ́dún 2016, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní í lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn àgbàlagbà ìlú, tí bàbá mi sì jẹ́ ọ̀kan lára wọn. Ó bèrè lọ́wọ́ bàbá mi bóyá ó ní ọmọ tí ó kàwé tí àwọn sí le jọ ṣíṣe papọ̀, bí bàbá mi ṣe pè mí kí ń máa bọ̀ nílé nìyẹn nítorí Abuja ni mo wà nígbà yẹn. A ṣe ìpàdé pẹ̀lú òyìnbó náà nígbà tí mo dé, tí mo sì ràn án lọ́wọ́ pẹ̀lú ṣíṣe aáyán ògbùfọ̀ àti àdàkọ. Mo darapọ̀ mọ́ iṣẹ́-àkànṣe náà nítorí mo fẹ́ kí èdè mi ó gòkè àgbà. Nígbà tó yá, wọ́n ní kí n máa ṣe kòkárí iṣẹ́ àkópamọ́ èdè náà. Lẹ́yìn náà ni a gba àwọn ènìyàn mìíìn mọ́ra, a sì kó ikọ̀ ẹlẹ́ni-méjì lọ́nà mẹ́fa jọ tí gbogbo wa sì jẹ́ ènìyàn 12.
Ó sọ síwájú sí i pé:
Èdè Gẹ̀ẹ́sì la fi ń bára wa sọ̀rọ̀. Ó pẹ́ díẹ̀ kí a tó mọ bó ṣe máa ń sọ̀rọ̀. A máa ń ní láti ṣe àpèjúwe fún un nígbà mìíràn kí nǹkan lè ye é dáadáa. Gbogbo ìgbà ló máa ń fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́. Bí nǹkan kan kò bá yé e, ó máa ń béèrè pé kí á ṣàlàyé rẹ̀ fún òun dáadáa.
Ẹlòmíràn tí ó kópa nínú iṣẹ́ àkànṣe náà, Garba Rahab Precious, gbàgbọ́ wí pé iṣẹ́ àkànṣe náà ti ṣèrànwọ́ fún ìpamọ́ èdè náà fún ìran tí ó ń bọ̀, èyí sì ṣẹlẹ̀ látàrí ṣíṣiṣẹ́ papọ̀ pẹ̀lú àwọn ará ìlú.
Wọ́n kọ́ àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ náà ní ẹ̀kọ́ nípa bí a ti ń lò ẹ̀rọ-ayàwòrán láti fi ká àwòrán-olóhùn kalẹ̀ àti bí àti ń gbà ohùn sílẹ̀, wọ́n sì kọ́ èmi náà ní ẹ̀kọ́ bí a ti ń da ohun tí wọ́n ń sọ nínú àkásílẹ̀ kọ àti bí wọ́n ṣe ń yí ìtúmọ̀ rẹ̀ sí èdè Gẹ̀ẹ́sì. Lọ́jọ́ tí a bá ti fẹ́ ṣe iṣẹ́ àkópamọ́, a máa ń lọ sí àwọn abúlé Kam káàkiri láti ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú àwọn olùṣọ́ èdè nípa oríṣiríṣi orí ọ̀rọ̀. A ó fi àwọn àwòrán-olóhùn tí a bá gbà sílẹ̀ ránṣẹ́ sì Yakub [orúkọ tí ó ń pè Lesage] tí yóò sàyẹ̀wọ̀ rẹ̀, a ó sì ṣe àdàkọsílẹ̀ àti ìtumọ̀ rẹ̀.
GV: Àwọn ìpèníjà wo ni ẹ kọjú nígbà tí ẹ̀ ń ṣe iṣẹ́ yìí, báwo lẹ sì ṣe yanjú wọn?
JL: Èyí tó tóbi jù lọ ni àjàkáyé àrùn ọlọ́jẹ̀ COVID-19. Mo ti gbèrò láti rìnrìn àjò wá sí Nàìjíríà — ṣùgbọ́n ṣàdédé ni èyí kò ṣe é ṣe mọ́.
Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí mú àyípadà bá bí a ti ń ṣe ìwádìí ni ẹ̀ka ìmọ̀ ẹ̀dá èdè aṣàpèjúwe nípa bí a ṣe ń lo èdè. A gbẹ́kẹ̀lé àwọn olùṣewádìí láti ìta tí ó ń ṣe ìrìnàjò sí àwọn agbègbè tí wọ́n ti fẹ́ ṣe ìwádìí. Àjàkáyé àrùn tó gbòde kan nígbà náà fi àìdára tó ìlànà yìí hàn. Ó sì mú mi ní ìdánilójú nípa ìlànà tó dára kan tí mo ti fẹ́ máa lò tẹ́lẹ̀: bí a bá ti fún àwọn ará ìlú tí wọ́n ti ń sọ èdè náà ní ìmọ̀ àti àwọn irinṣẹ́ tí wọ́n nílò láti ṣe àkópamọ́ èdè wọn, iṣẹ́ ìwádìí náà kò ní yẹsẹ̀ bí olùṣewàdìí àtòkèèrè wá kò bá le rí ọkọ̀ bálúù wọ̀ láti rin ìrìnàjò.
Nítorí náà, a bèrè sí ní ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ láti ọ̀nà jínjìn. A ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Elisha Yunana — ẹni tíi ó jẹ́ ọmọ ìlú kan tí kò jìnnà sí agbègbè náà tí ó sì ní ìmọ̀ nípa bí a ti ń ṣe àkópamọ́, — a ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́sẹ̀ méjì fún àwọn ará ìlú Kam ikọ̀ ẹlẹ́ní-mẹ́wàá àkọ́kọ́ kan, a sì kọ́ wọn ní bí wọ́n ṣe ń lọ àwọn irinṣẹ́ tí wọ́n fi ká àwòrán àti ohùn sílẹ̀ fúnra wọn. Kò rọrùn láti kó àwọn irinṣẹ́ náà dé ibẹ̀: Fáṣítì tí mo ti ń ṣiṣẹ́ kò ní ètò tí a le fi ra wọ́n ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, nítorí náà mo rà á ní orílẹ̀-èdè Germany, mo sì fi rán àwọn ọ̀rẹ́ mi tí wọ́n ń rìnrìnàjò láti bá mi fi rán ọkọ̀ sí abúlé Kam.
Fífi àwọn àkópamọ́ ṣọwọ́ síra-ẹni kò rọgbọ. Ìwọ̀n àwọn ohùn àti àwòrán-olóhùn tí a kà sílẹ̀ wúwo tó bẹ́ẹ̀ tí ó mú un níra láti kọjá lórí ìṣàsopọ̀ ẹ̀rọ-ayélujára àwọn abúlé náà tí kò ṣe é gbókàn tàn. A ní láti wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdá nípa fifi àwọn àkópamọ́ náà ránṣẹ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn ti wọ́n wà ń gbé ní Jalingo, níbi tí ẹ̀rọ-ayélujára ti já gaara.
Ṣíṣe àdàkọ sílẹ̀ náàb mú ìṣòro tirẹ̀ lọ́wọ́: Kam kò ní ìlànà àkọtọ́ fún kíkọ sílẹ̀. Ọ̀nà tí a gbà tán ìṣòro yìí ni gbígbọ́kàn lé iyè inú àwọn elédè — a bẹ̀rẹ̀ láti orí i bí àwọn elédè ṣe ń lo àwọn ìró ohùn, a sì wá ojútùú sí ìṣòro kíkà bí wọ́n ṣe ń yanjú, dípòo gbígbé ètò wá láti lé wọn lórí.
Ikọ̀ náà díde sí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìpèníjà wọ̀nyí, àṣepé iṣẹ́ tí a ṣe jẹ́ nǹkan àmúyangàn fún mi!
GV: Bí èdè yìí bá wọ òkùnkùn lọ́la, kí ni nǹkan tí ẹ lérò pé ilé-ayé máa pàdánù?
JL: Ayé Kam yóò so ohun tí ó pọ̀ nù: Àwọn àwàdà, ìtàn, bí àwọn ènìyàn ṣe ń ṣàfihàn ìbáṣepọ̀ sí ara wọn, ọ̀nà kan láti fi àwọn nǹkan pamọ́ fún àwọn ènìyàn tí kì í sọ èdè náà
Fún gbogbo àwọn ará ayé tó kù, yóò túmọ̀ sí pípàdánù fèrèsè sí ojú ìwòyè àṣà àti èdè tí a kò ì tíì ṣí wò rárá.
Lesage gbàgbọ́ wí pé ti àwọn ará ìlú Kam ni àkóso àjogúnbá èdè wọn ń ṣe, ó sì tún sọ wí pé àwọn onírúurú àwọn ohun-àmúlò tí àwọn ṣẹ̀dá, yóò túbọ̀ máa jẹ́ lílò fún gbogbo ènìyàn láti máa lò ó.







