Ìfojú ọ̀tun wo àjùmọ̀gbépọ̀: láti àìlórílẹ̀-èdè sí ìdúrólóṣùṣù-ọwọ̀

Zahra Marwan, oníṣẹ́-ọnà àti òǹkọ̀wé ní Amẹ́ríkà ni ẹni tí ó ni iṣẹ́ ọnà, tí ó sì kọ àkọsílẹ̀ pé, ‘Èyí ni àwòrán ìyá mi pẹ̀lú àwọn alábàágbé rẹ̀ nígbà tí ó wà ní ọ̀gọ̀ṣọ́. Ó máa ń sọ fún mi ní nígbà kan pé, ‘Mi ò bá má ti kó ó yín lọ sí ọ̀hún kí àjọṣepọ̀ àárín wa ó lè rí gẹ́gẹ́ bí isan sí ọrùn.’ Kí ló dé tí ó ṣe ní látí mú ọ̀kan nínú kí a ní àǹfààní sí ẹ̀tọ́ wa gẹ́gẹ́ bí i ọmọnìyàn tàbí kí á gbé papọ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹbí tí kin ní kan ò le è pín níyà?’. A tọrọ àṣẹ ìyọ̀nda kí a tó lo ọ̀rọ̀ àti àwọ̀rán yìí.

Láti ọwọ́ Christy Chitengu

Ben Okri, òǹkọ̀wé ilẹ̀ aláwọ̀ fúnfun tó jẹ́ ọmọ orilẹ̀-èdè Nàíjíríà kọ àkọsílẹ̀ nígbà kan rí pé: “Ohun kan tó jẹ́ àkó nípa wa ni ipa láti ṣẹ̀dá, láti ṣẹ́gun, láti nífaradà, láti àyídá, láti nífẹẹ́, àti láti tayọ ìsọro wa.” Òye irú ọ̀rọ̀ báyìí yé àwa tí a mọ bí ó ṣe ń rí lára bí a kò bá ní àwọn tí a lè bá kẹ́gbẹ́ — tí ẹnìkan ó rí wa, alẹ́nu sùgbọ́n tí kò sí ohùn, tí kò sí ẹni tí ó mọ Òkòló wa lỌ́yọ̀ọ́. Irú ọ̀rọ̀ báyìí jẹ́ èyí tó ń fún wa ní ìwúrí láti má sọ ìrètí nù, ìrètí pé ó ṣe é ṣe kí àyípadà rere ó dé bá wa.

Àjùmọ̀gbépọ̀ tayọ ohun tí ó wà lábẹ́ òfin lásán lọ; ìrírí tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìtẹ́wọ́gbà láwùjọ ẹni àti ìkánisí láti ọ̀dọ̀ ìjọba. A tún lè rí i níbí àjọṣepọ̀ ọlọ́rẹ̀ẹ́-dọ́rẹ̀ẹ́, sísọ àwọn èdè abínibí, àti fífi ìdí múlẹ̀ níbi tí eèyàn pè ní ibùgbé. Sùgbọ́n fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ eèyàn, irúfẹ́ àwọn ìkẹ́gbẹ́ méjì wọ̀nyìí — èyí tó níi ṣe pẹ̀lú ìrírí àti èyí tó jẹyọ lábẹ́ òfin- kì í pàdé. Bí wọ́n ṣe ń bí wọn báyìí ni ètò yìí ti máa ń yapa.

Irú ìyapa yìí ye mí yékéyéké. Emí fún àpẹẹrẹ, wọ́n bí mi sí South Africa, wọn ò sì tẹ́wọ́gbà mi gẹ́gẹ́ bi ojúlówó ọmọ orílẹ̀ èdè náà — yálà gẹ́gẹ́ bí i pé ó jẹ́ orílẹ̀-èdè tí a bí mi sí tàbí orílẹ̀-èdè tí àwọn òbí mi ti wá — èyí jẹ́ ohun tó rújú sí mi àti sí àwùjọ mi pẹ̀lú. Báwo ni mó ṣe máa máa gbé pọ̀ ní ibìkan — tí mo sì ń sọ èdè ibẹ̀, gbígba àṣà ìbẹ̀, tí mó sì tún ń gbé gbogbo ìgbé ayé mi níbẹ̀ — síbẹ̀, orílẹ̀-èdè náà ò rí mi gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìlú?. Gbogbo ìgbà tí mo bá ń ṣàlàyé ìdí tí mi ò ṣe ja mọ́ nǹkankan níbìkan ṣoṣo tí mo mọ̀ ní ilé àti ìbùgbé tí àwọn òbí mi ti ṣẹ̀ wá, ìrújú náà tún máa ń túbọ̀ peléke ni. Dídákẹ́ ní àwọn àkókò náà ń rán mi létí ààlà tó wà láàárìn èmi àti òye ìtẹ́wọ́gbà. Èyí jẹ́ ìrírí kan ní ti ìtẹ̀síwájú nínú ipò àìní-orílẹ̀-èdè. Níbi tí ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn ìtàn yìí ti jẹyọ — ọ̀kọ̀ọ̀kan ìrírí tí okùnfà rẹ̀ yàtọ̀ gedegbe, tí ó ní ọwọ́ àwọn ìtàn ìṣẹ̀lẹ̀ àtẹ̀yìnwá nínú, tí ìṣojúṣàájù sì ń mú kí ó túbọ̀ le koko sí i bí ojú ẹja.

Gẹ́gẹ́ bi Okri ti ṣe rán wa letí, ipa wa láti ṣẹ́gun ìjìyà wa ni àkó wa ní tòótọ́. Àìlórílẹ̀-èdè yìí fẹ́rẹ̀ẹ́ fi mí sípò tí kò wù mí nítorí ohun tí mi ò ní, àmọ́ àìní ìwé ẹ̀rí ọmọ orílẹ̀-èdè kò ní agbára lórí ẹ̀mí ọmọnìyàn tí ó ń múni ní ìforítì, ìfẹ́ sí ọmọlàkejì, àti àyídà. Òtítọ́ yìí ni ó sì fún mi ní àǹfààní láti lè kojú àwọn ètò àti òfin àlàkalẹ̀ tó ń fa kí àìní orílẹ̀-èdè yìí ó máa wọ́lẹ̀. Ìpinnu láti ṣẹ̀dá ayé kan níbi tí ibi tí a ti bíni kò ní dí ẹni lọ́wọ́ sí rírí àǹfààní sí ètò-ẹ̀kọ́, ètò-ìlera, ààbò ní àwùjọ àti ìgbanisísẹ. Àwọn ẹ̀tọ́ tó ń róni lágbára láti dá gbé pẹ̀lú ìbuyì fúnni gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ọmọnìyàn.

Irú ayé tí ọmọ mi ọkùnrin kò ti ní máa bẹ̀rù ìyọnisẹ́yìn látàrí ibi tí ìyá tàbí bàbá rẹ̀ ti ṣẹ̀ wá — irú ọjọ́ ọ̀la tí mò ń jà fún nìyẹn.  Síbẹ̀, ìlàkàkà láti wó ìyọnisẹ́yìn tí ó ti wọ àwọn ètò lẹ́wù lulẹ̀ jẹ́ ohun tí ó ń fa ìrẹ̀wẹ̀sì ọ̀kan, èyí tí ó ḿaa ń sábà dánìkan wà tí ó sì jẹ́ ìpèníjà pàápàá jùlọ ní ojú àwọn ìlànà iṣẹ́ tí ó díjú láti là kọjá àti àwọn orílẹ̀-èdè tí ó lágbárá.

Pẹ̀lú gbogbo àdojúkọ wọ̀nyìí, mo rí ìwúrí nínú àjùmọ̀ṣe. Àjọ Global Movement Against Statelessness ni ibi ìkẹ́gbẹ́ tí ó jẹ́ ẹ̀rí ìforítì àjùmọ̀ṣe. Pẹ̀lú ìṣọ̀kan, à ń tún ojúwòye ọ̀rọ̀ náà tò, à ń kojú àìṣòdodo, a sì ń fi hàn pé àwọn ìbode tàbí àwọn ìwé ẹ̀rí orílẹ̀-èdè tó láti fi iyì wa gbolẹ̀. Ní ọjọ́ 27, oṣù Kejì ọdún 2024 ni a ṣe ìfiọ́lẹ̀ Àjọ Global Movement Against Statelessness tí àwọn tí àìní-orílẹ̀-èdè ti pa lára, tí a fi ẹ̀tọ́  sí àǹfààní láti jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè dùn àti àwọn tí òfin ìyọnisẹ́yìn orílẹ̀-èdè. Ìdarí tí wọ́n ń ṣàmúlò jẹ́ àmúpapọ̀ ìgbé ayé àti ìrírí ẹni, èyí tó ń fi àyè sílẹ̀ fún ìkanikún, ìwàlọ́gbaagba, àti àjùmọ̀ṣe tí kò sì yọ ẹnìkan sílẹ̀. Nípasẹ̀ ìṣàmúlò irúfẹ́ àkàkún wọ̀nyìí, a kò ṣe ìmúgbòòrò àfojúsun wa nìkan, à ń pe àwọn ọ̀nà ìdarí àtijọ́ níjà. Orí odó yìí ni Ṣàngó wa dúró lé lórí, a sì tún ń ṣe àrídájú wí pé gbogbo àríwísí ló wúlò, a sì ń ṣe ìdarí létòlétò, lódodo, láì sí hùwà ìmọtara-ẹni níkan.

Bí àjọ náà ṣe ń sààmì ayẹyẹ ọdún kan àkọ́kọ́, a tún ṣe àgbéyẹ̀wò nípa ọjọ́ iwájú. Ohun àmúṣe lọ́dún tó ń bọ̀ ni títúbọ̀ fìdi àjọ wa àti àwọn ipa tí à ń kó múlẹ̀, kí a sì túbọ̀ tẹpẹlẹ mọ́ ìdágbàsókè àjọ tí ó gbilẹ̀ nínú ìbáṣepọ̀, ìṣọ̀kan àti àfojúsùn tó àjùmọ̀pínhùn. Àsìkò tó wuyì jùlọ láti ìgbà tí a ti dá àjọ yìí sílẹ̀ ni ìpè fún àpéjọpọ̀ ọmọ àjọ tó wáyé ní Ọjọ́rú, ọjọ́ 5 oṣù Ẹrẹ́nà, ọdún 2025, níbi tí a ti ní àǹfààní lati ṣàpérò lórí ibi tí a bá iṣẹ́ dé àti bí a ṣe lè túbọ̀ tẹ́síwájú.

Bí o bá fẹ́ túbọ̀ nímọ̀ nípa Global Movement Against Statelessness, lọ sí orí ìtàkùn àgbáye.

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.