Ǹjẹ́ Ìwé-àbádòfin Ìya-àyè-ìjókòó-sọ́tọ̀ fáwọn obìnrin lè mú kí ìdọ́gba akọ-àti-abo tí Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nílò wá sáyé?

Nigeria's Parliament building

Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Àwòrán láti ọwọ́ Kabusa16  nípasẹ̀ Wikimedia Commons. Ìwé-àṣẹ: CC BY-SA 4.0 Deed.

Ọgọọgọ́rùn-ún àwọn obìnrin ní wọ́n ṣèwọ́de káàkiri ní olú ìlú orílẹ́-edè Nàìjíríà, Àbújá, ní Ọjọ́ 11, Oṣù Okúdù, tí wọ́n ń rọ àwọn aṣòfin lati gbé Ìwé-àbádòfin Ìya-àyè-ìjókòó-sọ́tọ̀ fún àwọn obìnrin (tí a tún mọ̀ sí Ìwé-àbádòfin Àyè Ìjókòó tí a Fi sílẹ̀ fún àwọn obìnrin), àtúnṣe kan sí ìwé òfin láti fòpin sí àìpọ̀ tó àwọn obìnrin nípò aṣojú ní àwọn ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn obìnrin kó ìda 50 nínú ọgọ́rùn-ún nínú iye ènìyàn ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ìdá 4.5 nínú ọgọ́rùn-ún obìnrin ló wà ní Ilé-Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Àpapọ̀. Ipò ìsàlẹ̀ pátápátá ni orílẹ̀-èdè Nàìjíríà wà lórí ọ̀rọ̀ àwọn obìnrin nípò aṣojú ní àwọn ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ní àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé àti ilẹ̀ Adúláwọ̀.

Àfojúsùn ìwé-àbádòfin yìí ni láti ṣẹ̀dá àfikún àyè 37 tí a máa yà sọ́tọ̀ fún àwọn obìnrin nìkan ní Ilé-Ìgbìmọ̀ Àgbà àti Ilé-Ìgbìmọ̀ Aṣojú Kékeré (ọ̀kan fún ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan àti Olú-ìlú Orílẹ̀-èdè Àbújá), pẹ̀lú àyè mẹ́ta ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan. Àwọn àyè tuntun wọ̀nyí tí ó wà fún ìdíje du ipò àwọn obìnrin nìkan nínú ètò ìdìbò àpapọ̀, jẹ́ àgbékalẹ̀ ìgbà díẹ̀ lati mú ìtẹ̀síwájú bá ìdọ́gba láàárín ẹ̀yà ìbí akọ àti abo àti ìṣèjọba tí ó ka gbogbo ènìyàn kún.

Ìdí ti àwọn agbẹnusọ kan fi ń ṣúgbàá àbá náà kí ó dòfin

Ifebuchechukwu Francisca Edeh, agbẹnusọ lórí ọ̀rọ̀ àwọn obìnrin àti ọ̀dọ́, tí ó tún jẹ́ olùdásílẹ̀ àjọ Touch to Heal, sọ fún Global Voices wí pé àwọn ìdínà ajẹmọ́ètò ti ṣe ìdíwọ́ fún àwọn obìnrin láti rọ́wọ́ mú gẹ́gẹ́ bí aṣojú nínú àwọn ètò òṣèlú sáà tí a wà lọ́wọ́lọ́wọ́.

Ní ti ìwé-ìtàn òde òní orílẹ̀-èdè náà, ìráàyè sí ìṣojú nípò òṣèlú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà jẹ́ èyí tí ó yọ àwọn obìnrin sẹ́yìn. Àwọn ìdínà ajẹmọ́ètò nìwọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí i àwọn òfin olójúṣàájú, àṣà àbínibí, ìgbéyàwó, àti ìpèníjà àìní àǹfààní. Láìsí àwọn ìgbésẹ̀ gidi, òbíríkítí àìkanikún yìí yóò túbọ̀ tẹ̀síwájú. Àwọn àyè ìjókòó tí a yà sọ́tọ̀ fún àwọn obìnrin yìí kì í ṣe ọ̀nà-àbáyọ tí ó dúró pẹ́ títí; wọ́n jẹ́ ètò ìṣíkúrònípò kan sí òmíràn láti wó àwọn ìdínà ètò ìṣèlú lulẹ̀. Lọ́gán tí ìṣedéédé bá ti bọ́ sí i, ìnílò irú àwọn ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ yóò dínkù.

Ìwé àbá náà kò jábọ́ láti sánmọ̀. Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, àwọn ẹgbẹ́ obìnrin, àwọn iléèṣẹ́ tí kì í ṣe ti ìjọba, àti àwọn aṣòfin kọ̀ọ̀kan ti ṣe kòòkárí ìpè fún àwọn àtúnṣe sí àlékún ìkópa àwọn obìnrin nínú òṣèlú. Àwọn ìgbésẹ̀ ìṣáájú, tí àwọn àtúnṣe ìwé-òfin tí ó jẹmọ́ ọ̀rọ̀ akọ-àti-abo àti àwọn ohun àtiṣe ẹgbẹ́ òṣèlú wà lára ẹ̀, kò so èso tó jọjú.

Ṣùgbọ́n síbẹ̀, àwọn tí wọ́n ń ṣagbátẹrù òfin náà kò sọ ìrètí nù. Esther Ogbomo, agbóhùn-àtàwòrán-sórí ẹ̀rọ ayélujára ní ìlú Àbújá, sọ fún Global Voices pé òún ní ìrètí ayọ̀ pé wọn ó fọwọ́sí ìwé-àbádòfin náà tí yóò si di òfin.

Mo nígbàgbọ́ pé Ìwé-àbádòfin Ìya-àyè-ìjókòó-sọ́tọ̀ fún àwọn obìnrin yìí yóò jẹ́ sísọ di òfin nítorí pé ìmọ̀ ìkàsí ìkopa àwọn obìnrin nípò aṣojú nínú òṣèlú ti ń gbèrú sí i. Bí ìgbẹnusọ, àtìlẹ́yìn àwọn ènìyàn, àti ìfarajìn láti ọ̀dọ̀ àwọn aṣòfin bá tẹ̀ síwájú, ó ṣe é ṣe kí ìwé-àbádòfin yìí lè ṣèrànlọ́wọ́ fún àìṣedéédé ẹ̀yà-ìbí akọ àti abo nínú ètò ìṣèlú.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìpèníjà ṣaláì wà, àwọn awuyewuye nípa ìkàsí àti ìṣọgbọọgba aṣojú tó ń gbilẹ̀ ló ń mú mi ní ìrètí ayọ̀ nípa ìsọdòfin rẹ̀.

Àwọn orílẹ̀-èdè Ilẹ̀ Adúláwọ̀ tí wọ́n ti ń lo ètò onípìn-ín tàbí àyè ìjókòó àfisílẹ̀ fún àwọn obìnrin, bí i Orílẹ̀-èdè Rwanda, Senegal, and South Africa, ti mú àlékún bá ipò ìṣojú àwọn obìnrin ní àwọn ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin.

Ìbẹnu-àtẹ́ lu Ìwé-àbádòfin Ìya-àyè-ìjókòó-sọ́tọ̀ fún àwọn obìnrin

Àwọn lámọ̀ọ́mọ́ tilẹ̀ ń béèrè bóyá ìpèsè àyè ìjókòó sílẹ̀ fún àwọn obìnrin nínú ìgbímọ̀ ni ọ̀nà tí yóò tán ìṣòro náà. Christopher Olusa, agbẹnusọ fún àwọn ọ̀dọ́ àti amẹ̀sọ-ọ̀rọ̀ níbi àpéjọ àwọn ènìyàn, nígbàgbọ́ wí pé ìwé-àbádòfin ìya-àyè-ìjókòó-sọ́tọ̀ fún àwọn obìnrin yìí kò ní ìwúlò kankan.

Ó sọ fún Global Voices pé:

Kò yẹ kí ó jẹ́ ọ̀rọ̀ akọ-tàbí-abo bí kò ṣe ohun tí ẹkùn ìdìbò bá nílò. A ní ẹ̀tọ́ nínú ìṣèjọba àwa-ara-wa láti dìbò yan ẹnikẹ́ni tí a bá fẹ́, láì fi ti ẹ̀yà-ìbí akọ tàbí abo ṣe, nítorí náà ìwé-àbádòfin ìya-àyè-ìjókòó-sọ́tọ̀ fún àwọn obìnrin yìí ń sọ fún wa pé  ìjókòó nínú ìgbímọ̀ tọ́ sí àwọn ènìyàn nítorí pé wọ́n jẹ́ obìnrin.

Ìdí mìíràn tí mi ò fi fara mọ́ ìwé-àbádòfin náà ni pé a wà ní àkókọ́ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn, èmi tìkalára mi pẹ̀lú, ń fẹ́ ki a mú àdínkù bá owó tí a ń fi ń ṣàkóso ìlú, pàápàá kí a mú ọ̀kan nínú àwọn ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin kúrò. Ètò ìgbìmọ̀ àṣòfin oníbejì gbówó lórí jù, nítorí náà ṣíṣètò àyè ìjókòó fún àwọn obìnrin nìkan dàbí i gbígbọn ọwọ́ èkuru sáwo ni, mi ò sí nígbàgbọ́ pé yóò so èso tó yanranntí. Mi ò tún nígbàgbọ́ pé nígbà tí a bá ṣì ṣètò àyè ìjókòó nítorí ọ̀rọ̀ ẹ̀yà-ìbí akọ-àti-abo, pé bí tàbí nígbà tí a bá dìbò yan àwọn ènìyàn wọ̀nyí tán, wọn ò ní ká wọ́n kún ọgba pẹ̀lú àwọn olóṣèlú mìíràn tí a dìbò yàn.

Ìwé-àbádòfin Ìya-àyè-ìjókòó-sọ́tọ̀ náà wà ní ìpele ìgbìmọ̀ ní Ilé-Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Àpapọ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́, níbi tí wọn á ti ṣe ìdìbò/àgbéyẹ̀wò alátúpalẹ̀ ní Ọjọ́ 7, Oṣù Agẹmọ, tí àwọn agbẹnusọ sì ń tẹ̀ síwájú láti rí wí pé ó di gbígbàwọlé kí sáà ìṣòfin yìí ó tó pin.

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.