Ìfarahàn lórí ayélujára di owó fún àwọn ọ̀dọ́ ní orílẹ-èdè Cameroon

A content creator making a video. Image from CanvaPro.

Oní-ìwìfún alálàyè kan tí ó ń ya fídíò. Àwòrán láti orí CanvaPro.

Láti ọwọ́ Julienne Honba

Ní orílẹ̀-èdè Cameroon, ìfarahàn lórí ayélujára ti di àǹfààní ọrọ̀ ajé gidi fún ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́. Bí wọ́n ṣe n kẹ́kọ̀ọ́ ní yunifásítì, tí wọ́n ṣe àwọn iṣẹ́ oní-àkókò péréte, tí wọ́n sì ń ṣe àwọn ìwífún alálàyé sí orí ẹ̀rọ ayélujára, wọ́n ń ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan tí ó lè mú owò wọlé fún wọn ní àṣeyọrí.

A screenshot of Emily’s videos.

Awòrán ọ̀kan nínú àwọn fídíò Emily Boughem

 

Láràárọ̀, Emily Bougem, 25, máa ń kọ́kọ́ ṣe àyẹ̀wò gbogbo ohun èlò iṣẹ́ rẹ̀. Ó máa ń ṣàyẹ̀wò bóyá ẹ̀rọ atánná (ring light) ti ṣe é lò, bóyá ẹ̀rọ gbohungbohun (microphone) wà nípò tó yẹ, àti bóyá ẹ̀rọ ayàwòrán ti wà ṣeé lò fún yíya fídíò. Báyìí ni ó ṣe maá n ṣe lójoojúmọ̀ láti bí ọdún mẹ́rin sẹ́yìn. Ṣùgbọ́n, Emily kì í ṣe Oní-ìwífún alálàyé nìkan. Ó tún jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ yunifásítì tí ó ní láti dé ilé-ẹ̀kọ́ ní aago 7:30 àárọ̀. Síbẹ̀, iṣẹ́ rẹ̀ ti máa ń bẹ̀rẹ̀ ṣáajú àkókò yìí.

Ó máa ń jí ní déedé aago 3:30 àárọ̀ nígbà tí agogo ìtanijí rẹ̀ bá dún. Ó máa ń pe àkókò yìí ní  “kíláàsì ṣáájú kíláàsì.”. Nínú yàrá kékeré rẹ̀ ní agbègbè Damas ní ìlú Yaoundé, ó máa ń ṣe àtúnyẹ̀wò àwọn fídíò tí ó yà ní ọjọ́ tó kọjá, lẹ́yìn náà, ó tún máa ṣàtúnṣe sí àwọn fìdíò náà. Ó máa ń lo ojú òpó rẹ̀ lórí ẹ̀rọ ayèlujára tí a mọ̀ sí EmiBougs Services, láti kọ́ àwọn eèyàn lẹ́kọ̀ọ́ lórí bí a ṣe ń lo àwọn ètò Microsoft Office, ìmọ̀ nípa iṣẹ́ ìṣètò ọjà lórí ẹ̀rọ ayélujára, àti bí a ṣe ń fi ohùn sí orí fídíò

Ṣíṣe ìwífún alálàyé kọjá ohun tí à ń ṣe nítorí ìfẹ́ inú lọ́dọ̀ Boughem. Ó sọ fún Global Voices pé:

“Kò rọrùn láti rí iṣẹ́. Bí mo bá fẹ́ ànfaani si iṣẹ́ ti yoó fí mí lọ́kànbalẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, mo gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àwọn ènìyàn mọ̀ mí. Mo nílò kí n mọ àwọn eèyàn pẹ̀lú. Pàtàkì jùlọ, mo nílò owó. Nítorí naa, ọ̀nà wo ni mo tún lè gbà bí mi ò bá lo àwọn ojú-òpó bí LinkedIn, Facebook àti Instagram? Kò ní ná mí ju data àti ìgboyà díẹ̀ lọ.”

Ìròrí rẹ̀ yìí ń ṣàfihàn iyipada tí o n wáyé laaarin àwọn ọ̀dọ́ orílẹ-èdè Cameroon. Ní orílẹ̀ èdè tí iṣẹ́ tí ẹni tó kàwé lè ṣe jẹ́ péréte, àwọn ọ̀dọ́ ti bẹ̀rẹ̀ sí í rí ẹ̀rọ ayélujára gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ìdókòwò dípò ibi eré ṣíṣe. Àwọn olùlò ayélujára tí ó ju mílíọ̀nù 12 lọ ní orílẹ̀ èdè náà, àti àwọn ti ó fẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù 6 ti wọ́n ń lo àwọn ojú-òpó àjọlò lórí ayélujára ń sàfihàn bí ẹ̀rọ ayélujára ṣe ṣe pàtàkì nínú ìgbésí ayé àwọn eèyàn.

Fún ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ orílẹ̀ èdè Cameroon, ìfarahàn lórí ayélujára ti di ọrọ̀ ajé tí ó ń mú owó wọlé. Ọ̀kan nínú wọn ni Florent Marius Ngah, ọmọ ọdún 28, ẹni tí ọ̀pọ̀ ènìyàn mọ̀ lórí ayélujára sí Dylan Comedy. Ó jẹ́ Oní-ìwífún alálàyé àti apanilẹ́rìn-ín. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í fi fídíò sí orí ẹ̀rọ ayélujára ní ọdún 2020 fún ìdánilárayá nìkan. Ó sàlàyé fún Global Voices pé:

Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀, mi ò mú gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rárá. Mo kan ń ṣe àwọn ìwífún alálàyé fún eré ni. Ṣùgbọ́n ní ọdún 2022 tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í rí owó nínú rẹ̀ ni orin yí padà. Tí mo sì rì í pé mo ní làti mú-un ní òkúnkúndùn.

Lónìí, Marius Ngah ka ojú òpò ayélujára sí ọ̀kan pàtàkì nínú iṣẹ́ òòjọ́ rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́pé, ó jẹ́ kí ó di mímọ̀ pé ṣíṣe ìwífún alálàyè níkàn kò ṣée gbáralé gẹ́gẹ bí ọ̀rọ̀ ajé ní orílẹ̀ èdè Cameroon, ṣùgbọ́n ìfarahàn lórí ayélujára ti la ọ́nà sílẹ̀ fún àwọn àǹfààní tí ó ṣeé ṣe kí ó má tó wọ́n lọwọ́. Ó ṣàlàyé pé:

Ohun tí ó máa ń mú owó wọlé ni dída iṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ilé iṣẹ́ àti ìpolówó ọjà. Bí o kò bá farahàn lóri ayélujára, wọn ò ní rí ohun ti ó ń ṣe, àwọn àǹfààní wọ̀nyí náà kò ní yọjú fún ọ.

Ní èrò rẹ̀, ìfarahàn lórí ayélujára ṣe ju kí eèyàn jẹ́ gbajúmọ̀ lọ. Ìfarahàn yìí tí fún-ún ní àńfààní làti pàdé awọ̀n eèyàn tí ó làmìlaka, láti bá awọn eèyàn da isẹ́ pọ̀ àti láti dé àwọn àyè kan tí kò léro pé oun lè wọ̀.

Mo ti pàdé àwọn ènìyàn kan tí mi ò lérò pé mo màá jókòó tì wọ́n rí. Díẹ̀ lára wọn sì ti di ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́.

A screenshot of one of Dylan comedy’s videos.

Àwòrán ọ̀kan nínu àwọn fídíò Dylan Comedy

Ìgbénde àwọn Oní-ìwífún alálàyé, àwọn olù-fi-ẹ̀rọ ayélujára yí ojú ìwoye ẹni padà (influencers), àti àwọn oníṣòwò orí ẹ̀̀rọ ayélujára (digital entrepreneurs) ń ṣàfihàn ìyípadà ti ó bá ọ̀nà tí àwọn ọ̀dọ́ orílẹ̀ èdè Cameroon ń gbà rí iṣẹ́. Wọ́n ń mú ọ̀nà míràn mọ́ ọ̀nà àtijọ́ tí wọ́n ń lò láti wá iṣẹ́, nígbà míràn, wọ́n ń lo ayélujára dípò ọ̀nà àtijọ yìí, látàrí lílò ó láti bá àwọn eèyàn da iṣẹ́ pọ̀̀, ṣe ìpolongo ara wọn àti láti ṣọ àwọn ìwífún alálàyé di owó.

Facebook jẹ́ ojú-òpó àjọlò tó gbajúmọ̀ jù lọ ní orílẹ̀ èdè Cameroon. Ní oṣù Kẹrin ọdún 2026, ó kó ìdá 86 nínú 100 àwọn olùṣàmúlò ẹ̀rọ ayélujára. Èyí sì fi hàn gẹ́gẹ́ bi ojú-òpó pàtàkì fún ìbánisọ̀rọ̀, ìdánilárayá, gbígbé ìròyìn jáde àti fún ìpolówó ọjà ní orílẹ̀-èdè náà. Àmọ́̀, ṣíṣe àmúlò ojú òpo Facebook jùlọ kò túmọ̀ sí pé ó ń jẹ́ wọ́n ń lò fún iṣẹ́. Bi o tilẹ̀ jẹ́ pé kòṣemáni ni Facebook jẹ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ eèyàn, ojú òpó bíi LinkedIn ń lé iwájú nípasẹ̀ lílò tí àwọn ọ̀dọ́ ń lò ó fún wíwá ìkẹ́kọ̀ọ́, iṣẹ́, àti ìfira-ẹni hàn fún iṣẹ́.

Ìwádìí kan tó wáyé lóri ojú òpó ìbánidọ́rẹ̀ẹ́ Whatsapp tí wọ́n ṣe ní oṣù Èbìbí, ọdún 2026 láàárín àwọn akẹ́kọ̀ọ́ 30 ní Yunifásítì Yaounde I, ní orílẹ̀ èdè Cameroon ni o fi idi èyí múlẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwádìí náà kò kájú èrò gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ orílẹ̀ èdè Cameroon, ó ṣàfihàn bí  àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé-iwé náà ṣe ń ṣàmúlo ẹ̀rọ ayélujára fún iṣẹ́. Nínú àwọn abẹ́nàmọ̀ náà, àwọn 27 sọ pé LinkedIn ni ojú-òpó tí wọ́n fẹ́ràn jùlọ fún wíwá ètò ìkọ́ṣẹ́-ajẹmákadá, iṣẹ́ ṣíṣe àti àńfààní sí iṣẹ́, àwọn mẹ́tà yan WhatsApp láàyọ̀. Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó yan Facebook, Instagram tàbí X gẹ́gẹ́ bí ojú-òpó tí ó ṣe pàtàkì fún àńfàání sí iṣẹ́. Àbájáde ìwádìí yìí fi hàn pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Facebook ṣì jẹ́ ojú-òpó tí ọ̀pọ̀ ènìyàn ń lò jùlọ ní orílẹ̀ èdè Cameroon, ó ṣee ṣe kí ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yunifásítì máa rí LinkedIn gẹ́gẹ́ bí àyè pàtàkì fún iṣẹ́ wíwa àti ìdàgbàsókè iṣẹ́.

Ìbẹ̀rẹ̀ ìdúnkokò-mọ́ni àti jìbìtì órí ayélujára

Ojú òpó kànnáà tí ó n ṣí àyè sílẹ̀ fún àǹfààní iṣẹ́ tún lè mú ewu dání. Àwọn ewu yìí lọ́pọ̀ ìgbà máa ń wáye láti ibi fífi ìwífún ara ẹni sí órí ayélujára. Dylan Comedy sọ pé:

Kò sí ohun tí ó rọrún làti ṣe láyé yìí ṣùgbọ́n ẹni ti yòó lá oyin inú àpata, kò ní wo ẹnu àáké.

Awọn ewu yìí ṣọ̀tọ̀ọ́tọ̀ bí jíjí ìdánimọ̀ ẹni (identity theft), jíjí àkọọ́lẹ̀ ẹni lórí ayélujára (account hacking), ìdúnkòkò mọ́ni lórí ayélujára (cyberbullying), àti jìbìtì lórí ayélujára. Ndjakomo, ẹni tí ó jẹ́ ọmọ ọdún 23 nísìnyìí rántí ọjọ́ tí wọ́n jí àkọọ́lẹ̀ Instagram rẹ̀ ní ọdún méjì sẹ́yìn.

Ẹni tí ó jí àkọọ́lẹ̀ mi yìí lo orúkọ àti àwòrán mi láti bẹ̀rẹ̀ sí í béèrè owó lọ́wọ́ àwọn tó ń tẹ̀lé mi. Mo ṣì kéré nígbà náà, mi ò tíì mọ bí mo ṣe leè kojú irú ìṣòro bẹ́ẹ̀.

Ẹlòmíràn tó ní irú ìrírí yìí, Bidias, ṣàlàyé bí wọ́n ṣe lù ú ní jìbìtí tí ó jọ àǹfààní iṣẹ́.

Mo gba ímeèlì kan tó dà bí ìdáhùn sí àtẹ̀ránṣẹ́ iṣẹ́ tí mo kọ. Mo tẹ okùn (link) tó wà nínú rẹ̀. Kí n tó mọ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀, gbogbo àwọn àkọọ́lẹ̀ orí ayélujára tí ó so mọ́ ímeèlì mi ni wọ́n ti gba. LinkedIn, Facebook, gbogbo ẹ pátá.

Awọn ìrírí wọ̀nyìí kò ṣeé ta dànù. Ìdúnkokò mọni lórí ayélujára àti jìbìtì ṣíṣe lórí ẹ̀rọ ayélujára jẹ́ ìṣoro kan gbòógí jákè-jádò àgbáyé. Ìwádìí tí UNICEF ṣe láàárín àwọn ọ̀dọ́ ní orílẹ̀-èdè 30, ọ̀kan nínú mẹ́ta àwọn ọ̀dọ́ ní wọ́n ti ní ìrírí ìdúnkokò mọ́ni lórí ayélujára, bákan náà, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdá mẹ́ta nínú mẹ́rin àwọn olùdáhùn tí ó sọ pé àwọn ojú-òpó àjọlò jẹ́ àyè kan tí irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ti máa ń ṣẹlẹ̀ jù lọ.

Àwọn aláṣẹ ní orílẹ̀ èdè Cameroon tí fí oríṣi ọ̀nà lélẹ̀ láti mú ìdàgbàsókè bá aàbò orí ayélujára, àti ìmọ̀ tó yè kooro nípa lílo ayélujára.  Ẹ̀ka ìjọba lóri ìfìwéránṣẹ́ àti ìbánisọ̀rọ̀ ń fi gbogbo ìgbà ń wá ojútùú sí lílo ayélujára láì mú ewu dání látàrí ìpolongo àwọn ètò ìlanilọ́yẹ̀ àti ìfilọ́lẹ̀ àwọn àjọ tí ó ń dánilẹ́kọ̀ọ́ nípa ìlò rẹ̀.

Órílẹ̀-èdè náà tún gbé àwọn ìgbésẹ̀ láti mú kí ààbò lóri ìwífún ara ẹni fẹsẹ̀ rinlẹ̀ nípasẹ̀ Òfin 2024/017, tí wọ́n ṣe ní ọdún 2024. Àwọn aṣòfin fi àwọn òfin de gbígbà, kíkọ àti lílò àwọn ìwífún ara ẹni, wọ́n sì tún ń gbé ìgbésẹ̀ láti pèsè aàbò fún àwọn ará ìlú, èyí tí yóò kojú lílo àwọn ìwífún wọn lórí ayélujára lọ́nà àìtọ́.

Síbẹ̀, àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ṣàlàyé pé àwọn òfin yìí nìkan kò lè kájú àwọn ìṣoro orí ayélujára yìí. Wọ́n ní, bí ìbánisọ̀rọ̀ orí ayélujára ṣe ń gbòòrò sí i, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ewu rẹ̀ náà ń pọ̀ sí i. Nítorí náà, àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ nínú ààbò ayélujára àti àwọn ajàfún-ẹ̀tọ́ lílo ayélujára fẹnukò pé, àwọn òfin yìí ṣe pàtàkí lóòótọ̀, ṣùgbọ́n ìpolongo àti ìdánilẹkọọ àtìgbà-dé-ìgbà ni yóò dín àwọn ewu yìí kù.

Michel Boris Affah Ebengue, ọmọ ọdún 29, jẹ́ onímọ̀ ẹ̀rọ (industrial engineer). Ó tún jẹ́ olùdásílẹ̀ Futura Tutoring, ilé iṣẹ́ kan tí ó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ tí ó wà ní Yaoundé, orilẹ̀ èdè Cameroon.  Futura Tutoring màa ń pèsè ìtọ́sọ́nà ẹ̀kọ́ àti ìmúrasílẹ̀ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n fẹ́ kọ ìdánwò. Gẹ́gẹ́ bí oníṣòwò tí kò tíi dàgbà púpọ̀, tí ó sì máa ń gba àwọn òṣìṣẹ́ lóòrè-kóòrè, ó ní ìgbàgbọ́ pé ayélujára ti di ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà pàtàkì tí àwọn ènìyàn fi ń rí àǹfààní iṣẹ́. Síbẹ̀, ó kilọ̀ pé kò yẹ kí ènìyàn ro pé ìfarahàn lórí ayélujára nìkan tó láti rí iṣẹ́. Ó sọ pé:

Ayélujára lè mú àńfààní wá ṣùgbọ́n ọgbọ́n ìmọ́ọ́ṣe, ìwé ẹ̀rí ẹ̀kọ́ àti bí ènìyàn ṣe wúlò sí ní yóò jẹ́ kí àwọn àǹfààní náà dúró lọ́wọ́ ẹni.

Ní èrò tirẹ̀, ẹ̀rọ ayélujára jẹ́ irinṣẹ́ tí ó lágbára gan-an fún ìmúgbòrò iṣẹ́. Ṣùgbọ́n ó máa n ṣe àfikún si imọọse ni, kò lè rọ́pò ọgbọ́n ìmọ́ọ́ṣe. Ó kádìí ọ̀rọ̀ rẹ nílẹ̀ báyìí:

Àwọn ojú-òpó ayélujára jẹ́ irinṣẹ́ tí ó dára gan-an, ṣùgbọ́n wọn kò lè rọ́pò ìkọ́ṣẹ́ àtí wíwá ìmọ̀ kún ìmọ̀ àtìgbà- dégbà.

LinkedIn, Facebook, Instagram, TikTok àti X ti mú ìyípadà bá ọ̀nà tí àwọn ọ̀dọ́ fi ń bá ara wọn sọ̀rọ̀, ọ̀nà tí wọ́n fi ń wá iṣẹ́ àti fífi ara ẹni hàn fún iṣẹ́. Lóde òní, ìfarahàn lórí ayélujára ti di ọ̀nà okòwò kan. Ó jẹ́ ọ̀nà tí àǹfáàní ń gbà wọlé àti ọrọ̀ ajé. Àmọ́, ìfarahàn yìí tí ó n la ọ̀nà fún àǹfáàní náà tún mú àwọn ewu dáni. Fún àwọn ọ̀dọ́ ní Cameroon, wíwá àǹfáàní níi ṣe pẹlu bi wọn ṣe lè lo ẹrọ ayélujára ní àlòyọrí nìtorí okùn sí òpó ayélujàra kan ti wọ́n bá tẹ̀ lè mú anfaani tàbí ewu dání.

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.