Orílẹ̀-èdè Colombia léwájú nínú àwọn orílẹ̀-èdè tí kì í fọ èdè Gẹ̀ẹ́sì nílẹ̀ Amẹ́ríkà tó kọ́kọ́ fòfin de abẹ́ dídá fún àwọn ọmọbìnrin

Òǹkọ̀ròyìn ló ni àwòrán tí ó yà lórí Canva Pro.

Ó ku ọjọ́ mẹ́sàn-án — ọjọ́ mẹ́sàn-án kí gbèdéke ó tó ó pé, tí ìwé àbádòfin náà ò le è di òfin mọ́, tí a ní láti tún iṣẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún bẹ̀rẹ̀. Sùgbọ́n ní ọjọ́ 10, oṣù Okúdù, ọdún 2026, Ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà orílẹ̀-èdè Colombia dìbò wọ́n sì fọwọ́ síi, èyí tí ó mú kí orílẹ̀-èdè Colombia jẹ́ àkọ́kọ́ nínú àwọn orílẹ̀-èdè tí kì í sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì nílẹ̀ Amẹ́ríkà (Latin America) tí ó dáwọ́ ìdábẹ́ ọmọbìnrin dúró. Ìwé àbádòfin 440 ti 2025, tí a mọ̀ sí “Niñas sin Ablación” (“Àwọn ọmọbìnrin tí a kòì dábẹ́ fún”), jẹ́ òfin tí a kò ṣe ní ilé ìṣòfin, ṣùgbọ́n, láàárín àwùjọ́ àwọn ènìyàn tí ó nílò rẹ̀ jùlọ.

Ní ọjọ́ 22, oṣù Ẹrẹ́nà, ọdún 2007, àwọn ọmọdébìnrin mẹ́ta tí wọ́n sẹ̀sẹ̀ bí ní ìlú Emberá Chamí kú látàrí àkóràn ojú ara tí wọ́n kó lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n dábẹ́ fún wọn tán. Èyí ni ìsẹ̀lẹ̀ àkọ́kọ́ tí ó wọ inú àwọn ìwé àkọsílẹ̀ ìjọba, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n gbàgbọ́ pé kì í se àkọ́kọ́ irú ẹ̀ tí ó ti wáyé.

Láti ìgbà náà, orílẹ̀-èdè Colombia ti di orílẹ̀-èdè ní Latin America tí ó gbà pé àwọn èèyàn ṣì ń dàbẹ́ fún àwọn ọmọbìnrin nínú orílẹ̀-èdè wọn. Dípò kí èyí jẹ́ orísun ìtìjú, ó ta orílẹ̀-èdè náà jí láti gbé ìgbésẹ̀ àti ṣe ìrànlọ́wọ́ láti gbé ètò ìkásẹ̀ abẹ́ dídá nílẹ̀ wọ inú ètò  Ìlépa Ìdàgbàsókè Àgbáyé Tó Dúró Ṣinṣin — ṣùgbọ́n lẹ́yìn ogún ọdún, láìsí òfin tí ó ti àwọn akitiyan wọ̀nyẹn lẹ́yìn, ìfídí múlẹ̀ ètò yìí nìkan ò tó láti dáàbò bo ẹnikẹ́ni.

Abẹ́ dídá (tí àwọn àwùjọ kan ń pè ní ‘ìwòsàn’, ‘àtúnṣe’ tàbí ‘iṣẹ́ abẹ’) jẹ́ gíge apá kan tàbí gbogbo ẹran ojú ara ọmọbìnrin láì ní ohunkóhun í ṣe pẹ̀lú ìwòsàn ara. Ní orílẹ̀-èdè Colombia, wọ́n máa ń dá abẹ́ fún àwọn ọmọdébìnrin láti ọmọ ìtàdógún títí dé ọmọ ọdún 12. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí àwọn àjọ ètò ìlera àgbáyé sọ, àwọn àtubọ̀tán rẹ̀ kìí ṣe é yí padà: ìṣàn ẹ̀jẹ̀ gbuuru, àkóràn ọlọ́jọ́ pípẹ́ tí kìí lọ bọ̀rọ̀, àwọn ìsòrò lásìkò ìrọbí, ìdámú ọpọlọ, híhu ìwà ségesège, àìbalẹ̀ ọkàn, ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn, tí ó sì lè já sí ikú, bí ó bá dé ojú ẹ̀.

Òfin tí a fi lélẹ̀ látàrí iye àwọn ènìyàn tí orí kó yọ 

Iye tí ó wà nínú àkọsílẹ̀ ìjọba kò sàfihan gbogbo ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀. Ìjọba máa ń mọ̀ nípa àwọn ìṣẹlẹ̀ wọ̀nyí nígbà tí àwọn ọmọdébìnrin wọ̀nyí bá dé ilé ìwòsàn nítorí ìrora ìṣoro ìdábẹ́, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ agbègbè tí èyí ti máa ń ṣẹlẹ̀ ni wọ́n jìnná sí ilé ìwòsàn tí ó sún mọ́ wọn. Fún ìdí èyí, àkọsílẹ̀ kéré sí ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ gan-an.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àkọsílẹ̀ tí ó wà tó láti ṣàfihàn bí ìṣòro náà ti ṣe gbalẹ̀ bí ẹní tó. Ẹ̀ka Ìlera orílẹ̀-èdè Colombia ṣàkọsílẹ̀ ìsẹ̀lẹ̀ 91 ní ọdún 2023 àti 54 ní ọdún 2024, síbẹ̀, kò sí àkọsílẹ̀ kan tó kájú gbogbo ìṣẹlẹ̀ náà nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìsẹ̀lẹ̀ náà máa ń wáyé ní àwọn agbègbè tí kò ní ànfààní sí ìtọ́jú lábẹ́ ètò ìlera. Láàárín ọdún 2020 sí 2025, Àjọ gbogboogbo tó ń mójútó Ìlera ṣe àkọsílẹ̀ ìsẹ̀lè 204, tí 177 nínú àwọn ti ó fara gbá ìṣẹ́lẹ̀ yìí jẹ́ àwọn ọmọbìnrin tí ó ń gbé nílùú, pàápàá jùlọ àwọn ẹ̀ka Risaralda àti Chocó.

Ní ìlú Pueblo Rico nìkan, wọ́n ṣe àkọsílẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ 46 láàárín ọdún 2013 sí 2014: 32 nínú wọn jẹ mọ́ àwọn ọmọ ọwọ́ tí kò tíì pé ọdún kan, 11 sì jẹ́ àwọn ọmọdé tí ọjọ́ orí wọn tó ọdún kan sí méjì. Àkọsílẹ̀ Àjọ Aṣojú Ọmọ abínibí ti Orílẹ̀-èdè Colombia, pẹ̀lú àjọṣepọ̀ Àjọ Tí Ń Ṣojú Ọ̀rọ̀ Ìlera Ìbálòpọ̀ àti Ìbímọ (UNFPA) jẹ́rìí síi pé eni méjì nínú mẹ́ta àwọn obìnrin Emberá ni wọ́n ti dá ábẹ́ fún. Àwọn aláṣẹ tún ti rí irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́è  láàárín àwọn Afro-Colombian, Raizal, Palenquero, àti láàárín àwọn àtọ̀húnrìnwá tí ó ṣí wá láti ìlú mìíràn.

A kò sọ̀rọ̀ nípa àwọn àgbàlagbà. Àwọn ọmọ ọwọ́ tí ó pọ̀ jọjọ ni à ń sọ̀rọ̀ nípa wọn.

Òtítọ́ yìí pàtó ló mú kí àwọn obìnrin Emberá  — ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn tí ó la ìṣẹ̀lẹ̀ náà já — ò dúró dé ìjọba, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní í wá ojútùú ní àwọn agbègbè wọn. Ìwé àbádófin náà ti ara ìjíròrò ọlọ́dún pípẹ́ pẹ̀lú àwọn agbègbè tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà kàn, tí wọ́n sì ń wá àwọn ọ̀nà àbáyọ láti dáàbò bo àwọn ọmọdébìnrin wọn.

Ìgbésẹ̀ yìí kì í ṣe láti fi ìyà jẹ ẹnikẹni, àdìídì ṣe ni. Fífi ẹ̀sùn ọ̀daràn kan àwọn ìyá ńlá àti àwọn agbẹ̀bí ìbílẹ̀ yóò kàn mú kí àwọn ìdílé láti má lè gbé àwọn ọmọbìnrin wọn lọ sí ilé-ìwòsàn nígbà tí ìṣòro ìdábẹ́ bá dé. Èyí máa mú kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọdé ó kú síi dípò kí ó dín kù.

Òfin náà ṣe ìdásílẹ̀ ìgbìmọ̀ alàjọṣepọ̀ kan fún àwọn iléèṣẹ́ tí ó ń ṣojú ìjọba, Àjọ tí ó ń dáàbò bo àwọn ọmọdé ti orílẹ̀-èdè Colombia (ICBF), àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ìlú, àti àwọn aṣojú láti àwọn agbègbè tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti ń wáyé. Ó ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ìtọ́jú, àwọn ìlànà ìtọ́jú ìlera ní túláàsì, ètò ṣíṣe àkọsílẹ̀ tí ó lágbára, àti ọ̀nà tí ó gbé onírúurú àṣà yẹ̀wò láti sàfihan bí ìsòrò náà ṣe le tó, lọ́nà tí èyí ò ní lè jẹ́ àwáwí fún àìṣe nǹkan kan.

Alejandrina Guasorna: Ẹ̀rí ẹni tí ó mórí bọ́ kan

Nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ kan pẹ̀lú El Pais, Alejandrina Guasorna rántí ìgbà tí òun jẹ́ ẹni ọdún 74, tí ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin sì jẹ́rìí sí awuyewuye tí ó ń lọ: ní ọjọ́ tí a bí i, ẹnìkan gé idọ ojú ara rẹ̀ kúrò. Abẹ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́, ìṣó tí a mú raná, iyàrá tí a sé pa, lẹ́yìn náà, ìdákẹ́rọ́rọ́.

Kò sí ẹni tí ó sọ fún-un rí. Yálà ìyá rẹ̀ tàbí èyíkéyìí nínú àwọn obìnrin ní agbègbè Emberá ní Pueblo Rico, Risaralda. Ó dàgbà láì mọ̀, ó gbé ìgbé ayé rẹ̀ láì mọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó tún di agbẹ̀bí láì mọ̀, tí ó sì ń gbẹ̀bí àwọn ọmọdébìnrin mìíràn tí wọ́n ń wá sí ayé, tí irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ sì tí ṣẹlẹ̀ sí wọn.

Ohun tí ó múni lọ́kàn jù nínú ìtàn rẹ̀ kì í ṣe ti àkókò tí kò lè rántí, bí kò ṣe gbogbo ohun tí ó rántí: àwọn ọmọdébìnrin tí ó kú, ìṣàn ẹ̀jẹ̀ gbuuru, àwọn àkóràn ojú ara àti àwọn ọmọ ìkókó tí kò yè é.

Lẹ́yìn náà ni a gbọ́ gbólóhùn tí ó bani nínú jẹ́ jù lọ: “Gbogbo ìgbà ni wọ́n máa ń gbé òkú àwọn ọmọdébìnrin wá. A kò kà á sí nǹkan kan.” Kì í ṣe àìmọ̀kan. Ó jẹ́ àṣà ìran-dé-ìran tí ó bò wá lójú, tí kò jẹ́ kí á rí ìṣẹ̀lẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí àìda tí a ò sì lè fọhùn nípa rẹ̀; ju kí a sin òkú àwọn ọmọdébìnrin tí ó bá kú, kí wọ́n sì tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìgbé ayé wọn”.

Guasorna takò ọ̀kan nínú àwọn àròyé tí ó wọ́pọ̀ jùlọ tí à ń lò fi mú àìtọ́ dà bí ohun tí ó tọ́: èyí kì í ṣe àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àtijọ́ tí kò ṣe é yí padà. Ó yàtọ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè kan ní Áfíríkà níbí tí àwọn agbẹ̀bí ìbílẹ̀ tí ń ṣe é. Ó jẹ́ àṣà àti ìrandíran, láàárín àwọn agbègbè tí kò ní ànfààní sí ètò ẹ̀kọ́, tí ọwọ́jà ìjọba kó dé, tí wọ́n ò rí ẹni sọ fún wọn wí pé ohun tí wọ́n ń ṣe sí ara àwọn kì í ṣe ohun tí ó wúlò tàbí pọn dandan.

Ìrìnàjò tí ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ parí kí ó tóó bẹ̀rẹ̀

Fífọwọ́ sí òfin náà kò rọrùn rárá. Ìjíròrò lórí ìwé àbádòfin náà wáyé lẹ́ẹ̀mejì ní Ilé-Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ní ọdún 2025, tí àwọn Aṣojú Ìgbìmọ̀ Àkọ́kọ́ sì tún gbà á wọlẹ́ láìsí olùtakò kankan. Ṣíbẹ̀, fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀sẹ̀, ìjíròrò tí ó kẹ́yìn, ìgbésẹ̀ kan ṣoṣo tí ó kù, forí ṣánpọ́n sí ipò 12 tàbí 13, nínú ètò ìpàdé àwọn aṣòfin, tí ó wà lẹ́yìn àwọn ọ̀rọ̀ bí ìwé ẹ̀rí ìrànwọ́ owó ilé-ìwé àti owó ìrànwọ́ ọkọ̀.

Gbèdékè akókò jẹ́ ọjọ́ 20, oṣù Òkúdù. Ìdìbò ẹlẹ́ẹ̀kejì fún ààrẹ ṣì máa wáyé ní ọjọ́ 21 oṣù Òkúdù. Díẹ̀ nínú àwọn olóṣèlú náà tún fẹ́ mú ọ̀rọ̀ náà le koko sí i.

Ohun tí ó dára ni ti wí pé ìdìbò náà wáyé, nítorí ọ̀rọ̀ ìṣèlú Colombia, kọjá ohun tí a lè fẹnu sọ. Èyí jẹ́ àbálọbábọ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún àìgbẹ́nudákẹ́ àwọn obìnrin tí kò ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú lílọ́wọ́ sí ìṣèlú, ṣùgbọ́n fún àǹfààní ti ara wọn.

Abẹ́ dídá ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọbìnrin tí ó lé ní mílíọ̀nù 230 jákèjádò àgbáyé ní orílẹ̀-èdè 94. Nínú àwọn orílẹ̀-èdè 94 tí a ti ṣe àkọsílẹ̀ àṣà náà, 59 péré ni ó ní òfin tí ó dè é, tí ọ̀pọ̀ nínú àwọn òfin wọ̀nyí sì fìdímúlẹ̀ ní Áfíríkà, Yúróòpù, àti Apá Àríwá ilẹ̀ Amẹ́ríkà.

Kí ó tó di wí pé ìwé àbádòfin yìí di òfin, Latin America kò ní òfin kankan.

Leandra Becerra, agbẹjọ́rò Equality Now fún Latin America, ṣe ìsọni-ṣókí pàtàkì àkókò náà lẹ́yìn tí wọ́n fọwọ́ sí ìwé òfin náà. Ó ní pé: “Àṣeyọrí yìí jẹ́ àbájáde iṣẹ́ takuntakun ọlọ́pọ̀lọpọ̀ ọdún tí àwọn tí ó ti mórí bọ́, àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́, àti àwọn aṣòfin ṣe. Ìpèníjà tí ó kù ní í ṣe pẹ̀lú rírí i dájú pé òfin náà dí àmúlò, pẹ̀lú ìfẹ́ ìṣèlú tí ó rẹ́sẹ̀ mulẹ̀ àti àwọn ohun tí ó péye, kí dídábẹ́ fún ọmọdébìnrin má ba wáyé ní Colombia mọ́.”

Ààrẹ Gustavo Petro ṣì ní láti bu ọwọ́ lu ìwé òfin náà kí ó sì di òfin, ṣùgbọ́n èyí tí ó le jù nínú ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀. Colombia ti ṣe ìpinnu wí pé ìdábẹ́ ọmọbìnrin ti di àfìṣẹ́yìn tí eégún fi aṣọ.

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.