Jíjẹ́ akọ kọ́ ni ọkọ̀ òfuurufú fi ń fò: Ohun tí ó fà á tí àwùjọ fi ń wo àwọn awakọ̀ obìnrin níwò àìbáṣàmu

Black woman driving a car

Obìnrin tí ó ń wa ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́. Gustavo Fring ló ni àwòrán láti orí Pexels. Ìwé àṣẹ ìlò: Fún lílò lọ́fẹ̀ẹ́.

Láti ọwọ́ Langalihle Mhlanga

Ọkọ̀ òfuurufú náà ṣẹ̀ṣẹ̀ gbéra nílẹ̀ ti ohun gbogbo fi bẹ̀rẹ̀ sí í dojú rú.

Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún àwọn adarí ìgbókègbodò ojú òfuurufú nígbà tí ariwo ìbẹ́ gbàámù ńlá kan ró tí èéfín dúdú bítákun gba ọ̀gangan ibi tí ọkọ̀ òfuurufú Air Algerie Flight 6289 fò gbà ní ìṣẹ́jú díẹ̀ ṣáájú ìgbà náà.

Nínú ọ̀kan lára àwọn ètò orí amóhùnmáwòrán tí mo fẹ́ràn jù lọ, Mayday Air Disaster, (Àkópapọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ 26, Ìṣẹ̀lẹ̀ 7) tí àkọ́lée rẹ̀ ń jẹ́ “Divided in Crisis”, tí ó jáde ní ọjọ́ 16, oṣù Kejì, ọdún 2025. Àwọn olùwádìí tún ṣàtúnyẹ̀wò ìṣẹ̀lẹ̀ búburú tó ṣẹlẹ̀ sí Air Algerie Flight 6289, tí ó jẹ́ ẹ̀yà ọkọ̀ òfuurufú Boeing 737-200 tí ó já lulẹ̀ lẹ́yìn ìṣẹ́jú díẹ̀ tí ó gbéra ní pápá òfuurufú Tamanrasset ní gúúsù orílẹ̀-èdè Algeria ní ìparí orí ọ̀nà ìsáré ọkọ̀ òfuurufú ní ọjọ́ 6, oṣù kẹta, ọdún 2003.

Ìgbéranílẹ̀ ọkọ̀ tí ó bẹ̀rẹ̀ láláì ní wàhálà pẹ̀lú ojú-ọjọ́ tí ó dára ni ó yíra padà di àjálù nígbà tí ẹ̀njíìnì ọkọ̀ náà dáṣẹ́ sílẹ̀ ní àsìkò tí ó ń gbéra tí èyí sì mú kí àwọn ikọ̀ awakọ̀ ó mú àwọn ìpinnu pàjàwìrì ṣe, èyí tí ó padà já sí àdánù ọkọ̀ òfuurufú náà. Awakọ̀ méjì ló wà nínú agódo ìtukọ̀ ọkọ̀ òfuurufú ní ọjọ́ yẹn: obìnrin awakọ̀ tí ó jẹ́ olùṣàkóso ọkọ̀ náà, àti àgbàlagbà ọkùnrin kan tí ó jẹ́ alábòójútó.

Wíwo ìṣẹ̀lẹ̀ náà lórí ètò mú kí ọkàn mi pòruru, ṣùgbọ́n èyí kìí ṣe nítorí àwọn ìdí kan tí ó hàn gbangba. Ó bani lẹ́rù bí àwọn ìpinnu ojoojúmọ́ àti àwọn ìṣe ojoojúmọ́ ṣe lè di ìṣẹ̀lẹ̀ aburú tí a kò lè fa ọwọ́ aago rẹ̀ sẹ́yìn. Ìṣẹ̀lẹ̀ ètò yẹn ló mú mi bẹ̀rẹ̀ ìtọpinpin ohun tí ó fà á tí àwùjọ fi ń wo àwọn awakọ̀ obìnrin níwò àìbáṣàmu.

Àwọn ojú òdì tí àwùjọ fi ń wo àwọn awakọ̀ obìnrin ní ilẹ̀ Áfíríkà

Ọmọ obìnrin ilẹ̀ Áfíríkà, ẹni ọdún 23 ni mí, mo sì ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún nínú ìgbésí ayé mi ṣàkíyèsí bí àwùjọ ṣe ń wo ìmọ̀ọ́ṣẹ́ ṣe gẹ́gẹ́ bí àbùdá ajẹmọ́-akọ. Ọ̀nà tí àwùjọ ń gbà láti fojú tẹ́mbẹ́lú abo lóde òní kò hànde. Dípò bẹ́ẹ̀, àwọn ojú ìwòye yìí farasin sínú àwọn ìṣeṣí, àwọn ìròrí, àwọn ìfara sọ̀rọ̀, àwọn àwàdà, àti àwọn ìyàlẹ́nu tí ó máa ń wáyé nígbà tí àwọn ènìyàn-án bá rí obìnrin ní àwọn ipò tí ó ní í ṣe pẹ̀lú dídarí. Papàá jùlọ bí wọ́n bá ń wa ọkọ̀, tàbí bí wọ́n bá wà nínú agódo ìtukọ̀ ọkọ̀ òfuurufú.

Di ìsìnsìn yìí, ó ní àwọn ènìyàn tí kìí lè pa àìbalẹ̀ ọkàn wọn mọ́ra nígbà tí wọ́n bá rí i pé obìnrin ni awakọ̀ Uber wọn. Kì í pẹ́ àwọn ẹlòmíràn láti fagilé wíwọ ọkọ̀ náà. Àwọn tí ò fagilé wíwọ ọkọ̀ náà máa ń fi ojú sí gbogbo ìṣẹ́wọ́, gbogbo ìkójàánu, gbogbo ìbọ́sí ìlà ọkọ̀ mìíràn ní ojú pópó, àti gbogbo bí obìnrin náà ṣe ń pẹ́ ọ̀nà gbà, àfi bí ẹni pé wọ́n ń wá ẹ̀rí kan láti fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn obìnrin ò mọ ọkọ̀ọ́ wà bí i ọkùnrin.

Mo ṣàkíyèsí pé káríayé ni ìròrí yìí. Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè Áfíríkà, àwùjọ ṣì ń rí iṣẹ́ ọkọ̀ wíwà gẹ́gẹ́ bí i iṣẹ́ ọkùnrin. Àwọn ọkùnrin ní wọ́n pọ̀ jùlọ ní ibùdó tasín, ọkọ̀ akérò, ọkọ̀ ẹrù àti ọkọ̀ òfuurufú. Ó ṣì tún máa ń ya àwọn ènìyàn lẹ́nu bí wọ́n bá rí i wí pé obìnrin ń wa ọkọ̀ akérò, tí irúfẹ́ ìyàlẹ́nú báyìí kìí sì í wáyé bí ó bá jẹ́ ọkùnrin. Bákan náà, ìyàlẹ́nu ni ó máa ń jẹ́ fún àwọn èrò kan nínú ọkọ̀ òfuurufú bí wọ́n bá gbọ́ ohùn obìnrin lórí ẹ̀rọ agbagbe. Àwọn kan tún máa ń gbẹ́kẹ̀ lé awakọ̀ ọkùnrin ju obìnrin lọ láì ṣe iyèméjì, kódà bí wọ́n bá jọ ní ìwé ẹ̀rí  kan náà lọ́wọ́.

Ohun tí ó ṣe mí ní kàyèéfì ni bí àwùjọ ṣe ṣọ àwọn ojú ìwòyé yìí di ohun tí ó tọ́. Àwọn ènìyàn máa ń fi àwọn awakọ̀ obìnrin ṣe yẹ̀yẹ́ láì fi ìgbà kan bi ara wọn léèrè ohun tí ó ń pa ẹ̀rẹ̀kẹ́ẹ wọn lẹ́rìn-ín. Àbí kí ni àwùjọ gbà lérò gan-an? Bóyá wọ́n rò pé jíjẹ́ akọ ni a fí ń wa ọkọ̀ òfuurufú ni? Tàbí bóyá iṣẹ́ ẹ̀njíìnì inú ọkọ̀ akérò máa ń yàtọ̀ bí obìnrin bá ń wà á? Mo lérò wí pé láti inú ìgbàgbọ́ pé àwọn àbùdá ọkùnrin ni dídarí, mímọ ẹ̀rọọ́ lò àti pé ìfarabalẹ̀ nínú ìṣòro jẹ́ àbùdá tí ó jẹ́ ti ọkùnrin nìkan.

Ọ̀rọ̀ tí kò ṣe é gbọ́ sétí ni.

Ọgbọ́n ìmọ̀ọ́ṣe kò fi ìgbà kan jẹ́ ti akọ tàbí abo

Ọkọ̀ wíwà kò ní ohunkóhun í ṣe pẹ̀lú ìjẹ́ akọ tàbí abo. Ó ní í ṣe pẹ̀lú ẹ̀kọ́, ìbánisọ̀rọ̀, ìkóra-ẹni- níjanu, àwọn ètò àti ìlànà, ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àti ọgbọ́n ìmọ̀ọ́ṣe. Ọkọ̀ òfuurufú Boeing 737 kò ní ṣiṣẹ́ yàtọ̀ nítorí pé obìnrin ló wà nínú agódo ìtukọ̀, bákan náà ló rí fún ọkọ̀ akérò tàbí ọkọ̀ akẹ́rù.

Síbẹ̀síbẹ̀, ojú òpè ni àwùjọ ṣì fi ń wo àwọn obìnrin tó ń ṣe iṣẹ́ awakọ̀ dípòo kí wọ́n rí wọ́n gẹ́gẹ́ bí akọ́ṣẹ́mọṣẹ́. Ohun tí ó ń jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yìí túbọ̀ bí mi nínú ni bí àwùjọ ti ṣe fi ẹ̀rí hán wí pé àwọn ojú ìwòyè yìí lè di àfìsẹ́yìn tí eégún aláré ń fiṣọ nígbà tí wọ́n bá fẹ́.

Fún ọ̀pọ̀ ọdún, ojú àìtọ́ ni àwùjọ fi ń wo àwọn ọkùnrin tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí akọ̀wé owó ní àwọn ilé ìtajà nítorí pé wọ́n rí iṣẹ́ olùṣèrànwọ́fóníbàárà àti akọ̀wé owó gẹ́gẹ́ bíi “iṣẹ́ àwọn obìnrin”. Ní ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, bí aláìmọ-ohun-tí-ó-ń-ṣe ni yóò rí bí ọ̀kunrin bá ń ṣe iṣẹ́ akọ̀wé. Ṣùgbọ́n bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ó padà dí ohun tí àwùjọ fara mọ́. Lónìí, ọ̀pọ̀ ènìyàn kìí ṣe iyèméjì nígbá tí wọ́n bá rí ọkùnrin tó ń ṣiṣẹ́ akọ̀wé owó.

Èyí fi hàn gbagba pé àwọn èrò tó so mọ́ jíjẹ́ akọ tàbí aboó lè yí padà. Síbẹ̀, nígbà tí ọ̀rọ̀ di ọ̀rọ̀ àwọn obìnrin nínú iṣẹ́ ọkọ̀ wíwà, àwùjọ ṣì ń fi ojú ìwòyè àtijọ́ wò ó.

Àwùjọ ṣì ń fẹ́ kí obìnrin fi mímọ̀ọ́ṣe wọn hàn kí wọ́n tó lè ní ìgbàgbọ́ nínú wọn. Ní ìdàkejì ẹ̀ẹ̀wẹ̀, àwùjọ sábà máa ń kọ́kọ́ gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ọkùnrin kí wọ́n ó tó ó wo ìpójú òṣùwọ̀n-ọn mímọ̀ọ́ṣe wọn.

Ìfúngunmọ́ tí ó ń ti ibi ojú ìwòyè yìí wá ń fa ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn tí ó pọ̀. 

Àwọn ojúṣàájú sí àwọn obìnrin

Gẹ́gẹ́ bí obìnrin, pàápàá jùlọ obìnrin ilẹ̀ Áfíríkà, ohun tí a gbọ́njú mọ̀ ni pé àwùjọ kìí sábà wo àṣìṣe obìnrin kan gẹ́gẹ́ bí àṣìṣe ti ara ẹni. Bí obìnrin kan bá ní ìṣòro ní ibi iṣẹ́ tí àwọn ọkùnrin pọ̀ sí, àwùjọ lè di ẹ̀bi àṣìṣe yìí lé orí gbogbo obìnrin. Ṣùgbọ́n èyí kò rí bẹ́ẹ̀ fún àwọn ọkùnrin, àṣìṣe ẹnìkan, ti ẹni náà ni. Ọkùnrin awakọ̀ tí kò mọ ọkọ̀ọ́ wà kò mọ̀ ọ́ wà ni. Ṣùgbọ́n gbogbo obìnrin ni kò mọ̀ ọ́ wà bí obìnrin kan kò bá mọ ọkọ̀ọ́ wà.

Ibi gbogbo ni a ti ń dáná alẹ́ ni ti ojúṣàájú yìí fún àwọn obìnrin. Ó wà ní ibi iṣẹ́, ní iyàrá ìkẹ́kọ̀ọ́, ní àwọn àyè tó jẹ mọ́ ipò adarí, níbi àwọn ìjíròrò nípa ìmọ̀ èrò ìṣẹ̀dá ohun, ìmọ̀ ẹ̀rọ, ìṣèlú àti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀. Agbára àti àṣẹ ni bí ọkùnrin bá ní ìgboyà, ṣùgbọ́n ìwà àrífìn ni ìgboyà obìnrin-ín jẹ́. Àwọn ọkùnrin ní ẹ̀tọ́ láti pàṣẹ. Obìnrin ní láti faramọ́ àṣẹ àwọn ọkunrin kí wọ́n sì máa sa ipáa wọn láti fi hàn pé wọ́n lóye tí ó tó, wọ́n sì ká ojú ẹ̀.

Ó máa ń dáni lágara bí ènìyán bá ń ṣiṣẹ́ dójú àmì ṣùgbọ́n kí akitiyan ẹni ó máà tó lójú aráyé. Bóyá nítorí ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ yìí ṣe tayọ à ń wa ọkọ̀ òfuurufú tàbí ọkọ̀ akẹ́rù lọ. Ẹ̀ka ètò ọkọ̀ọ́ jẹ́ àfihàn ọ̀kan nínú ẹ̀ka ìṣòro tó fẹjú ní àwùjọ wa; àwùjọ kò ì tíì faramọ́ rírí obìnrin ní ipò tó ní í ṣe pẹ̀lú àṣẹ pípa, ìmọ̀ọ́ṣe tó gba ọgbọ́n orí, àti ìdarí — ní ọdún 2026, pàápàá láàárín àwọn ènìyàn tí wọ́n ń pè fún ìlọsíwajú àwùjọ.

Ohun tí ó mú kí ojúṣàájú yìí dun ni jùlọ ni pé, ó ti pẹ́ tí àwọn obìnrin ilẹ̀ Áfíríkà tí ń ṣe ojúṣe tí ó pọ̀. Àwùjọ gbẹ́kẹ̀ lé àwọn obìnrin láti tọ́ ọmọ dàgbà, láti ṣèrànwọ́ fún ìdílé, láti di òpó ìdílé mú ṣinṣin nípa ìmọ̀lára, láti farada ìṣòro ọrọ̀ ajé àti láti ṣàtìlẹyìn fún àwùjọ lásìkò tí nǹkan bá nira. Ṣùgbọ́n láìròtẹ́lẹ́ ni ìbẹ̀rùbojo yóò gba ọkàn àwọn ènìyàn so bí a bá fi obìnrin sí ipò adarí ọkọ̀ òfuurufú. Ìtakora yẹn sọ ohun gbogbo nípa ojúṣàájú.

Bí àwùjọ fẹ́, bí wọ́n kọ̀, ayé ti yí padà. Lójoojúmọ́ ni àwọn obìnrin ń wa ọkọ̀ òfuurufú, wọ́n ń wa ọkọ̀ akérò, wọ́n ń ṣàkóso àwọn ètò ọkọ̀, wọ́n ń lọ káàkiri àwọn ìlú, wọ́n sì ń mú kí ọrọ̀ ajé máa gbèrú sí i. Àwọn ọ̀dọ́bìnrin tí ó ń gòkè àgbà ń rí àwọn obìnrin tí wọ́n ń di àwọn ipò tí wọ́n sọ fún àwọn ìran ìṣàájú pé wọn kò lèe dé mú.

Gbogbo ẹ̀ jù lọ, ìlọsíwájú tòótọ́ kò le è wáyé àyàfi bí àwọn obìnrin tó di onírúurú àwọn ipò yìí mú bá dẹ́kun ìfọjú tẹ́mbẹ́lú ara wọn. Nígbà tí gbígbọ́ ohùn awakọ̀ obìnrin lórí ẹ̀rọ agbagbe nínú ọkọ̀ òfuurufú kò bá jẹ ohun ìyàlẹ́nu sí ẹnikẹ́ni mọ́. Nígbà tí àwùjọ bá dẹ́kun rírí ìmọ̀ọ́ṣe gẹ́gẹ́ bi àbùdá ọkùnrin nìkan. Àti nígbà tí ojú àwùjọ bá là sí òye pé ọgbọ́n àti ìmọ̀ kò fi ìgbà kankan jẹ́ ti akọ tàbí abo.

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.