
Ìbáyíká jẹ́ ní àdúgbò kan ní ìlú Èkó, Nàìjíríà. Boluwatife Oguns ló ní àwòrán tí a yọ lò láti orí Unsplash. Ó wà fún lílò lọ́fẹ̀ẹ́.
Àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ń kojú àpọ̀jù ooru lọ́wọ́lọ́wọ́. Àpọ̀jù ooru yìí ti fa ìnira tí ó pọ̀ dé ibi wí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn lori ẹ̀rọ alátagbà ń sọ bí ó ṣe ní ipa lórí ìlera wọn, àti bí ó ṣe ń dín agbára wọn láti ṣiṣẹ́ dáadáa kù.
Gẹ́gẹ́ bí àjọ tó n ṣe àmojútọ́ Ojú-ọjọ́ ti Nàìjíríà (NiMet) ṣe sọ, ooru yìí ń mú lámùújù nítorí pé oṣù Ẹrẹ́nà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn oṣù àpọ̀jù ooru— lẹ́yìn tí ọyẹ́ máa ń kásẹ̀ nílẹ̀, kí àsìkò òjò ó tó ó bẹ̀rẹ̀. Ooru náà ń mú ayé nira fún àwọn ènìyàn ní àwọn agbègbè káàkiri orílẹ̀-èdè náà, ṣùgbọ́n ó peléke ní àwọn agbègbè tí ó wà ní apá àárín-gbùngbùn àríwá, ìwọ̀-oòrùn àríwá, àti ìlà-oòrùn àríwá, pẹ̀lú àwọn agbègbè tó wà ní àárin-gbungbun àwọn ìpínlẹ̀ tí ó wà ní apá gúúsù.
Ipa àpọ̀jù ooru lórí àwọn ọmọ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà
Global Voices bá ìsọ̀rí àwọn ọmọ Nàìjíríà kan sọ̀rọ̀ láti mọ bí ipa ooru ṣe tó ní agbègbè wọn, lórí iṣẹ́ wọn, àti ìgbé-ayé ojoojúmọ́ wọn.
Onyekachi Ogbu jẹ́ onímọ̀ èdè Igbo àti akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ nínú ìṣàkóso ìwífún-alálàyé fún AI. Ó ń gbé ní Enugu, Nàìjíríà. Ó ṣàlàyé ipa àpọ̀jù ooru náà ní orí iṣẹ́ ẹ rẹ̀:
Ó ń mú kí iṣẹ́ ṣòro púpọ̀ láti ṣe, pàápàá jùlọ fún irú èmi tí mò ń ṣiṣẹ́ láti ilé. A kìí lo iná mànàmáná ọba ní ilée wa. Ẹ̀rọ asòòrùn di iná mànàmáná àti ẹ̀rọ amúnáwá ni à ń lò, a ò sì lè lo ẹ̀rọ asòòrùn di iná mànàmáná yìí fún odidi ọjọ́ kan. A sábà máa ń lò ó nígbà tí òòrùn-ún bá ń ràn dáadáa láti nǹkan bí aago 9 òwúrọ̀ títí di bíi aago 12 tàbí aago 1 ọ̀sán. A tún máa ń lò ó ní alẹ́ lọ́pọ̀ ìgbà, ṣùgbọ́n a ò lè gbé ẹ̀rọ afátẹ́gùn wa le é lórí nítorí agbára rẹ̀ ò ká a. Dípò èyí, a máa ń gbẹ́kẹ̀lé atẹ́gún tí ó ń bá ojú àwọn fèrèsé wọlé. Nígbà tí a bá ń lo ẹ̀rọ amúnáwá ni a máa ń tan àwọn ẹ̀rọ afátẹ́gùn inú àjàa wa. Nítorí ooru, ó ṣòro láti ṣiṣẹ́ nínú ilé. Ní ìgbà mìíràn, mo máa ń gbé ẹ̀rọ ayárabíàṣà alágbèéká mi jáde síta kí n lè gba afẹ́fẹ́ tútù díẹ̀ sí ara bí mo bá ń ṣiṣẹ́.
Ooru náà kì í jẹ́ kí ènìyàn pa ọ̀kàn pọ̀ sóju kan. Báwo ni yóò ṣe rí bí a bá ní ìpàdé orí ẹ̀rọ ayélujára, ti ẹ ní láti wọ aṣọ, ṣùgbọ́n tí ẹ̀ ń làágùn yọ̀bọ̀ nínú ìpàdé. Ọ̀kàn ò lè papọ̀ sójú kan nítorí pé ooru ò jẹ́ kí ara ó balẹ̀, kò sì ṣe é ṣe láti bọ́ aṣọ nínú ìpàdé orí ẹ̀rọ-ayélujára.
Mo máa ń fi abẹ̀bẹ̀ fẹ́ra tàbí kí n jáde síta láti gba atẹ́gùn lọ́pọ̀ ìgbà. Ìgbà mìíràn ẹ̀wẹ̀wẹ̀, mo máa ń ra epo sí inú ẹ̀rọ̀-amúnáwá, ṣùgbọ́n èyí kò ṣe ìgbà gbogbo nítori ọ̀wọ́n gógó epo bẹntiróòlù.
Mo mọ̀ dájú wí pé tọ́rọ́ fọ́n kálé ni ọ̀rọ̀ ooru yìí jẹ́, gbogbo èèyàn ló kàn, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ní ìgbèríko ò mọ ewu tó rọ̀ mọ́ ooru àpọ̀jù. Ìdí nìyí tí a fi ní láti jẹ́ kí ó di mímọ̀ fún wọn, kí wọ́n sì lè gbé àwọn ìgbésẹ̀ ààbò bíi mímu omi púpọ̀ àti ríríi dájú pé atẹ́gùn ń wọlé sí inú ilé e wọn dáadáa.
Adéwálé Afọlábí, tí ó ń fi alùpùpù kérò ní Òṣogbo, Ìpínlẹ̀ Òṣun, Nàìjíríà, sọ pé, ooru náà kọjá ìfaradà:
Ooru náà pọ̀ lápọ̀jù, ó sì ń dí iṣẹ́ mi lọ́wọ́, ṣùgbọ́n mi ò gbọdọ̀ dáwọ́ iṣẹ́ dúró kí n lè gbọ́ bùkátà ara mi àti ti àwọn ẹbí mi.
Muh’d Tasi’u Jibril, onímọ̀ ẹ̀dá-èdè tí ó ń gbé ní Bauchi, ṣàlàyé ipa ti ooru yìí ní lórí àwọn èèyàn tí ó ń gbé ní apá Àríwá orílẹ̀-èdè Nàíjíríà:
Ooru yìí kọja ìfaradà láti bíi ọ̀sẹ̀ méjì sẹ́yìn. Fún irú èmi tí mo jẹ́ gbélé-pawó báyìí, mi ò kí ń lè ṣiṣẹ́ láàárín aago 11 àárọ̀ sí aago 3 ọ̀sán nítorí ooru tó kọjáa sísọ yìí. Báyìí náà ni ooru yìí ṣe pọ̀ ní àwọn ọjọ́ mẹ́wàá tó kẹ́yìn oṣù Ramadan. Ooru yìí pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ débi pé àwọn èèyàn tó ní àìsàn ọgbẹ́ inú ní láti já ààwẹ̀ wọn.
Lọ́dọ̀ wa níbí, oṣù Ọ̀pẹ, Ṣẹẹrẹ àti Èrèlé ni ọyẹ́ máa ń mú, ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀ ní ọdún yìí.
Ooru náà kò ní ipa kankan lórí iṣẹ́ mi nítorí ilé ni mo ti ń ṣiṣẹ́. Iná mànàmáná ìjọba tó ń ṣe ségesège ló ń jẹ́ kí ooru ó máa mú mi nítorí àìní àǹfààní sí lílo ẹ̀rọ afátẹ́gùn àti ẹ̀rọ amúlétutù. Lọ́pọ̀ ìgbà ni n ò kí ń rí oorun sùn lálẹ́. Ìgbà tí mo bá rí apèsè iná mànàmáná mìíràn lò tí ó gbé àwọn ẹ̀rọ afátẹ́gùn àti ẹ̀rọ amúlétutù ni mo tó máa ń rórun sùn. Bákannáà, ó nira láti rí omi tútù mu lásìkò yìí nítorí iná mànàmáná tí kìí sí. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, a máa ń sùn síta lásìkò ooru, ṣùgbọ́n èyí ò rí bẹ́ẹ̀ mọ́ nítorí ààbò ìlú tó mẹ́hẹ. Àwọn tó rówó ra àwọn ẹ̀rọ̀ asòòrùn diná mànàmáná tó lágbára láti gbé ẹ̀rọ afátẹ́gùn àti ẹ̀rọ amúlétutù nìkan ni kìí màlá àpọ̀jù ooru yìí.
Iná mànàmáná ọba orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó ṣe mọ́namọ̀na ń dá kún ìṣoro náà
Iná mànàmáná orílẹ̀-èdè náà tí ó ń ṣe mọ́namọ̀na ń mú kí ìṣoro náà ó peléke sí i. Orísùn ìpínáká orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti dẹnu kọlẹ̀ láìmọye ìgbà ní ọdún 2026. Èyí ti ó ń fa òkùnkùn birimù jákèjádò orílẹ̀-èdè, tí ó sì mú un nira fún àwọn aráàlú láti farada àpọ̀jù ooru náà. Nítorí iná tí ò sí, ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà kò lè lo àwọn ẹ̀rọ ilé tí ó ń lo iná mànàmáná bíi ẹ̀rọ-afátẹ́gùn àti ẹ̀rọ-amúlétutù tí o lè mú kí ara ó tuni.
Ní ọjọ́ 24 oṣù kẹ́ta, Mínísítà fún iná mànàmáná; Adébáyọ̀ Adélabú tọrọ àforíjì lọ́wọ́ gbogbo ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà fún bí iná mànàmáná ṣẹ ń ṣe ségesège.
Adéṣẹwà Pópóọlá, olùdáṣẹ́sílẹ̀ kan ní ìlú Èkó, ṣàlàyé bí ìna ọba tí ó ń ṣe ségesège náà ṣe ń dá kún nǹkan:
Mò ń gbé ní àdúgbò tí àwọn ilé fi ẹ̀gbẹ́ ti ara wọn. Àìsí àyè láàárín ilé sí ilé yìí ń mú kí atẹ́gùn máà ríbi fẹ́ wọlé dáadáa. Mo ti ṣe àkíyèsí ìyípadà àkókò ooru láti bíi ọdún díẹ̀ sẹ́yìn. Mo rí i wí pé oṣù Kejìlá ni àkókò Ọyẹ́, tí ó ṣe é ṣe kí ojú ọjọ́ gbóná ní ọ̀sán kí ó sì tutù ní alẹ́. Ṣùgbọ́n a ò rí ọyẹ́ rárá ní ìlú Èkó ni gbogbo oṣù Kejìlá àti oṣu Kínní. Ojú ọjọ́ kàn ń fi gbogbo ọ̀sàn gbóna lala ni. Ooru yìí ti ṣe ìdíwọ́ fún iṣẹ́ mi àti ìgbéayé ojoojúmọ́ mi. Àwọn ìgbà kan wá ti mo ní láti jáde lọ ṣe àwọn nǹkan kan ṣùgbọ́n bí aago 10 àárọ̀ bá ti kọjá, mi ò ní lè jáde nítorí ooru tó pọ̀ lápọ̀jù yìí. Ìgbà tí mo bá rí ọkọ̀ tí yóò gbé mi dé ibi tí mò ń lọ níkàn ni mo máa ń jáde. Tí mí ò bá rí ọkọ̀, mo máa ń dúró di ìrọ̀lẹ́ nígbà tí oorú bá relẹ̀ kí ń tó jade.
Bí mo bá ní ìjáde, mo ní láti múra sílẹ̀ fún ooru. Ooru yìí tún ní ipa lórí ìmúra mi; ọ̀pọ̀ nínú àwọn aṣọ mi ni mí ò lè wọ̀ nítorí ooru.
Mo máa ń dúrò sílé nítorí ooru nígbà mìíràn, mo sì máa ń wẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà, mo sì tún ń mu omi déédéé.
Nípa níní ìmọ̀ lórí ọ̀rọ̀ ooru yìí, mo rò pé àwọn èèyàn ò ní ìmọ̀ kíkún lórí ewu tó bá àpọ̀jù ooru dé.
Gbogbo wa la mọ bí iná mànàmáná ọba ṣe rí ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lọ́wọ́lọ́wọ́. Nítorí iná mànàmáná tí ò dúró déédéé, ó ṣòro láti fi ara da ooru tó ń mú, pàápàá jù lọ ní alẹ́ nígbà tí ooru náà máa ń pọ̀ lápọ̀jù. Iná tí kò sí ò jẹ́ kí àwọn ènìyàn ó lè tan ẹ̀rọ afátẹ́gùn wọn. Bí ìyà ńlá bá gbéni ṣánlẹ́, kékeré a máa gun orí ẹni ni ti epo bẹntiróòlù tí ó wọ́n gógó, tí ò ṣe é rà, àti ooru ṣe jẹ́. Àpọ̀jù ooru náà ó bá ṣe é fi ewé mọ́ bí iná mànàmáná bá ń wà déédéé.
Òkùnfà àpọ̀jù ooru àti àwọn àmọ̀ràn
Àwọn olùwádìí ti fi ooru tí ó pọ̀ ní àpọ̀jù náà kọ́ àyípadà ojú-ọjọ́ ní ọrùn.
Ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù Kẹta, àjọ tí ó ń ṣe àmojútọ́ Ojú-ọjọ́ (NiMet) fi ìtanijí kan nípa ewu tí àpọ̀jù oorú lè fà ní àwọn apá kan ní orílẹ̀-èdè náà léde. Àjọ náà tún gba àwọn ènìyàn níyànjú pé kí wọ́n rí i dájú wí pé ooru ò mú wọn jù. Nínú ìfiléde wọn lórí X, NiMet rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà pé kí wọ́n máa mu omi púpọ̀, kí wọ́n máa wà níbi tí atẹ́gùn wà dáadáa tàbí iyàrá tí ó ní ẹ̀rọ-amúlétutù, ki wọ́n máa wọ aṣọ to fẹ́lẹ́ tí ó lè fi àyè gba atẹ́gùn, kí wọ́n máa wọ fìlàìbojú, ìgò ojú agboòrùn àti ìpara ata-òòrùn-dànù. Wọ́n tún gba àwọn òbí nímọ̀ràn pé kí wọ́n máa fún àwọn ọmọ kéékèèké ni omi lóòrèkóòrè kí wọ́n sì rí i dájú pé atẹ́gùn ń fẹ́ sí wọn lára, kí wọ́n mà sì ti ọmọ mọ́ inú ọkọ̀.
Àwọn ènìyàn ń retí pé kí òjò ó dé láìpẹ́ kí ooru náà ó dínkù.






