
Àwòrán ojú-ẹ̀rọ tí a yà láti ara àwòrán-olóhùn “Documentary on Burundi Chimpanzees” lórí OBPE Burundi YouTube channel
Àpilẹ̀kọ yìí láti ọwọ́, Arthur Bizimana, jẹ́ èyí tí a tẹ̀ jáde fún ìgbà àkọ́kọ́ lórí ìkànnì Ibihe.org ní ọjọ́ 25, Oṣù Bélú, Ọdún 2025, ó jẹ́ ara àwọn iṣẹ́ ìwádìí oníṣísẹ̀ntẹ̀lé mẹ́rin tí a ṣe pẹ̀lú àtìlẹyìn Pulitzer Center. Global Voices tún àpilẹ̀kọ yìí tẹ̀ síta gẹ́gẹ́ bí ara àdéhùn àjọṣepọ̀ iṣẹ́ ìròyìn.
Ní orílẹ̀-èdè Burundi, ṣíṣe ọ̀gbìn ohun mímu tíì tí ó gbalẹ̀ bí ẹní ń fa ìfàsẹ́yìn fún akitiyan ìdáààbò àwọn ẹranko tí wọ́n ti ń dínkù nígbó, bíi elégbèdè. Oko tíì kan ní etí Kibira National Park, ọgbà igbó ìpamọ́ ọba tí ó ṣe pàtàkì jù lọ nínú àwọn ọgbà igbó ìpamọ́ ọba mẹ́tẹ̀ẹ̀ta orílẹ̀-èdè Burundi tí ó wà ní ìwọ̀-oòrùn-àríwá orílẹ̀-èdè náà, níbi tí kíkọ́àgọ́ ilé-iṣẹ́ ìfomipèsè-iná Mpanda ti ń lọ lọ́wọ́ bákan náà tẹ́ lọ bí ilẹ̀ bí ẹní tí ó ṣòro láti mọ ibi tí ó pẹ́kun sí.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn àti àwọn onírúurú iṣẹ́ ìdàgbàsókè láti orí àwọn ará agbègbè ẹsẹ̀kùkú, àwọn ilẹ́-iṣẹ́ olùpèsè nǹkan, àti àwọn ilẹ́-iṣẹ́ ìjọba, bíi Ilé-iṣẹ́ Tíì Orílẹ̀-èdè Burundi (OTB), Ìlé-iṣẹ́ Ìpèsè àti àwọn Aláṣẹ Ìpínkiri Omi àti Iná Mọ̀nàmọ́ná Orílẹ̀-èdè Burundi (REGIDESO), Ilé-Ìwé Ẹkọ́ Ọ̀gbìn Orílẹ̀-èdè Burundi (ISABU), àti Ilé-iṣẹ́ Ìṣàkóso Àpapọ̀ fún Ọ̀gbìn àti Ohun-ọ̀sìn (DPAE) ni wọ́n ń ṣí lọ sí orí ilẹ̀ yìí. Àwọn iṣẹ́ ọmọ ènìyàn wọ̀nyìí ti fa ìpàdánù àti ìṣíkúrò àwọn ẹ̀ranko igbó.
Séverin Bagayuwitunze, ẹni ọdún 62, tí ó jẹ́ ọmọbíbí agbègbè yìí ní ìwọ̀-oòrùn àríwá ní orílẹ̀-èdè náà, wòye ohun pàtàkì kan:
On rencontrait des chimpanzés, des gorilles, des phacochères quand la forêt était encore dense, mais maintenant, ils ont disparu. On peut traverser le secteur Rwegura du parc national de Kibira sans rencontrer un seul chimpanzé.
Nígbà tí igbó náà ṣì díjú dáadáa, àwọn elégbèdè, àwọn ìnàkí àti àwọn ìmàdòó wà níbẹ̀, ṣùgbọ́n báyìí, wọ́n ti pòórá. Ẹ lè lọ káàkiri agbègbè Rwegura ti Ọgbà igbó ìpamọ́ Ọba Kibira láìrí elégbèdè ẹyọkan ṣoṣo.
Lónìí, àwọn elégbèdè tí ṣọ̀wọ́n káàkiri Ọgbà igbó ìpamọ́ Ọba Kibira. Pascal, tí ó ń gbé ní ìtòsí ọgbà igbó ìpamọ́ ọba náà, ló sọ èyí:
La dernière fois que j’ai vu un chimpanzé dans le parc de Kibira, c’était en 2018. Depuis, nous les rencontrons occasionnellement.
Ọdún 2018 ni mo rí elégbèdè kẹ́yìn. Láti ìgbà náà, ẹ̀ẹ̀kanlọ́gbọ̀n ni à ń rí wọn.
Gẹ́gẹ́ bí àwọn àbájáde iṣẹ́ ìwádìí kan ṣe sọ, lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí ọgbà igbó ìpamọ́ yìí jẹ́ ilé fún àwọn elégbèdè 200, tí ó kéré sí nǹkan bíi 500 tẹ́lẹ̀ kí ó tó di wí pé a ṣíjú le ọgbà igbó ìpamọ́ náà.
Ní Oṣù Ọ̀wàrà ọdún 2019, Ìkéde Kẹta Ìjọba Àpapọ̀ lórí Àyípadà Ojú-ọjọ́ fọn rere ìpàdánu ibùgbé àwọn elégbèdè yìí láàárín ọdún 2009 sí 2019. Kibira pàdánù ilẹ̀ tí ó ní igi lórí tí ó tó hékà 10,000 sí 12,000. Lẹ́yìn ọdún mẹ́fà tí a kéde ewu tí ó ń wu ọgbà igbó ìpamọ́ ọba yìí, a ò mọ bí ipa igbó-bíbì-lulẹ̀ ti ṣe tó.
Nínú ìwé àpilẹ̀kọ ìjìnlẹ̀ náà, “Chimpanzee (Pan troglodytes schweinfurthii) Population Density and Abundance in Kibira National Park, Burundi,” èyí tí Fásitì Liège gbé jáde ní ọdún 2013, Dismas Hakizimana, oníṣẹ́ ìwádìí àti olùkọ́ni ní Fásitì Burundi, àti Marie-Claude Huynen, oníṣẹ́ ìwádìí àti olùkọ́ni ní Fásitì Liège jábọ̀ pé:
Leur habitat étant menacé, certains chimpanzés y ont laissé la vie et les rescapés ont déserté les secteurs de Kibira notamment Rwegura, Teza et Musigati. Ils se sont réfugiés dans le secteur Mabayi directement contigu au Parc National de Nyungwe/National Nyungwe Park (NNP) au Rwanda où ils recherchent la sécurité alimentaire et physique.
Pẹ̀lú bí ibùgbé wọn ṣe wà nínú ewu, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn elégbèdè ni wọ́n pàdánù ẹ̀mí wọn, àwọn tí wọ́n yè é sì sá jìnà sí agbègbè Kibira, pàápàá jùlọ Rwegura, Teza, and Musigati. Wọ́n forí pamọ́ sí agbègbè Mabayi tí ó wà nítòsí Ọgbà igbó ìpamọ́ Ọba Nyungwe (NNP) ní orílẹ̀-èdè Rwanda, níbi tí wọ́n ti ń rí oúnjẹ àti ààbò ara wọn.
Ìbàyíkájẹ́ Ọwọ́ Ẹ̀dá-ọmọ-ènìyàn
Oko Ilé-iṣẹ́ Tíì Burundi, tí ó wà ní ìpẹ̀tẹ́lẹ̀ ilẹ̀ gíga ní agbègbè yìí, gba àwọn òṣìṣẹ́ 1,000 tí wọn ń sanwó oṣù fún àti àwọn oníṣẹ́-ojúmọ́ tí ó tó 7,500 sí 8,000 tí wọn ń fẹ́ ewé láti ara ọwọ́ igi tíì, àwọn tí wọn ń ṣiṣẹ́ nínú ilé ẹ̀rọ apèsè ohun, àwọn olúṣètọ́jú oko tíì, àwọn onímọ̀ ìkànsíraẹni àti ìbánisọ̀rọ̀, àti òṣìṣẹ́ tí ó ń rí sí ìṣàmúlò igbó nílòkulò láì bìkítà. Léonidas Nzigiyimpa tí ó jẹ́ onímọ̀ nípa ìgbépọ̀ ẹ̀dá láyìíká wòye pé:
Ces ouvriers produisent un grand bruit sonore nuisant à l’habitat des chimpanzés, espèce phare de Kibira. Ils jettent les restes des nourritures, les sachets… En gros, ils polluent l’habitat des chimpanzés.
Àwọn òṣìṣẹ́ wọ̀nyìí máa ń pariwo tí ó pọ̀ tí ó ń nípa púpọ̀ lórí ibùgbé àwọn elégbèdè, àwọn ẹ̀dá tí ó fẹ́ àmójútó ní Kibira. Wọ́n máa ń ju àwọn oúnjẹ àjẹkù àti àwọn àpò ọlọ́ràá, tí ó ń ṣe ìbàjẹ́ àyíká sí ibùgbé àwọn elégbèdè.
Nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ nínú oko, àwọn òṣìṣẹ́ kan máa ń wọnú ọgbà igbó ìpamọ́ náà ní ọ̀nà tí kò bófinmu. Nzigiyimpa tọ́ka pé:
Les entrées et sorties ne sont pas régulées et restent largement incontrôlées. Ils cueillent la nourriture des chimpanzés, notamment les fraises sauvages.
Wọn kò fi òfin lélẹ̀ tí ó ń de ìwọlé àti ìjáde, bẹ́ẹ̀ ni àbójútó kò sí. Wọ́n máa ń ká oúnjẹ àwọn elégbèdè pàápàá jùlọ àwọn èso tí wọ́n ń pè ní strawberry.
Berchmans Hatungimana, Olùdarí àgbà Ilé-iṣẹ́ fún Ààbò Àyíká Orílẹ̀-èdè Burundi, náà fi ìwòye rẹ̀ hàn bákan náà.
Ní ẹ̀gbẹ́ ojú-ọ̀nà Márosẹ̀ àkọ́kọ́, tí ó sún mọ́ ọgbà igbó ìpamọ́ ọba, àwọn ènìyàn máa ń ta àwọn èso igbó tí ó ṣeéjẹ bíi èso strawberry láti rówó ná. Pascal, ẹni tí ó sọ ohun tí ó wà ní òkè yìí, náà ló sọ pé:
Nous avions atteint un stade où nous cueillions des fruits qui ne sont pas mûrs. Nous les conservions dans un lieu sûr et attendions qu’ils soient mûrs. Maintenant, ce commerce est quasi-inexistant. Les fraises sauvages ont presque disparu. Même les arbousiers ne portent plus leurs fruits.
A ti báa débi pé, èso tí kò pọ́n ni à ń rà. A ó kó wọn pamọ́ síbi tí nǹkankan ò ti ní í ṣe wọ́n, kí wọn ó lè baà pọ́n. Ṣùgbọ́n báyìí, òwò yìí gan-an ò fẹ́rẹ̀ẹ́ sí mọ́. Gbogbo àwọn èso igbó strawberry ni wọ́n ti pòórá, kódà àwọn igi èso strawberry náà gan-an alára ni ò so mọ́.
Nzigiyimpa, onímọ̀ nípa ìgbépọ̀ ẹ̀dá láyìíká náà tún sọ ọ́ pé ó burú jáì fún àwọn ará-ìlú tí wọ́n ń dọdẹ àti tí wọ́n sì ń dẹ páńpẹ́ láti mú àwọn ẹranko nínú ọgbà igbó ìpamọ́ ọba. Gẹ́gẹ́ bí Ọ̀jọ̀gbọ́n Richard Habonayo, Olùkọ́ni kan ní Fásitì Burundi ṣe sọ, àwọn nǹkan báwọ̀nyí máa ń jẹ́ kí àwọn ẹranko máa bẹ̀rù ìwàláyìíká àwọn ẹ̀dá ọmọ-ènìyàn, tí wọn yóò sì máa sá lọ sí igbó réré níbi tí wọn kò ti ní ṣalábàápàdé ènìyàn.
Pẹ̀lú ìwífún yìí, Berchmans Hatungimana sọ pé:
Nous avons des employés qui gardent le parc de Kibira 24 heures sur 24 pendant toute l’année. S’il advient qu’un ouvrier entre illégalement dans le parc et outrepasse les lois de la protection du parc, il est arrêté et livré à la société qui l’emploie pour qu’il soit puni conformément à la loi.
A ní àwọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n ń ṣọ́ ọgbà igbó ìpamọ́ ọba Kibira fún wákàtí 24 lójoojúmọ́, jálẹ̀ ọdún. Bí òṣìṣẹ́ kan bá wọ inú ọgbà igbó ìpamọ́ ọba náà lọ́nà tí kò bófin mu, tàbí rú òfin ààbò ọgbà igbó ìpamọ́ ọba náà, a máa ń fi páńpẹ́ òfin gbé wọn, a ó sì fà wọ́n lé àwọn tó gbà wọ́n ṣíṣẹ́ lọ́wọ́ fún ìfìyàjẹ ní ìbámu pẹ̀lú òfin.
Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí láti ilé-iṣẹ́ KÒṢÈJỌBA Conservation and Community Change (3C) ṣe sọ, iye àwon páńpẹ́ náà ti pọ̀ síi pẹ̀lú bí àwọn iṣẹ́ ìdàgbàsókè náà ṣe ti gbéra sọ, bẹ́ẹ̀ ni iye àwọn ènìyàn ní àyíká ọgbà náà ti pọ̀ sí i bákan náà. Léonidas Nzigiyimpa, aṣojú ẹ̀ka òfin, ṣàlàyé pé:
Outre les activités humaines, les plantations de thé constituent une barrière pour les chimpanzés dans leurs mouvements quotidiens de recherche de nourriture, car elles sont serrées et enchevêtrées. Elles coupent également la communication entre elles (différentes familles de chimpanzé) et limitent les femelles à retrouver les mâles issus d’une autre famille afin de s’accoupler et de se reproduire. Or, la reproduction des chimpanzés est lente. Cela limite la multiplication de la population des chimpanzés et contribue à réduire les effectifs.
Yàtọ̀ sí àwọn ohun tí àwọn ènìyàn ń ṣe, àwọn oko tíì ń ṣe ìdíwọ́ fún àwọn elégbèdè láti rí oúnjẹ ìhejẹ ojoojúmọ́, pẹ̀lú bí ó ṣe jẹ́ pé, wọ́n ṣe ọgbà ká, tí wọ́n di sísé mọ́ inú. Wọ́n tún ń dí ìbánisọ̀rọ̀ láàárín àwọn ẹbí elégbèdè lọ́wọ́, wọ́n sì ń dí àwọn abo lọ́wọ́ láti rí akọ nínú ẹbí mìíràn fún ìbálòpọ̀ àti láti bímọ. Bákan náà, ìṣabiyamọ àwọn elégbèdè kì í yá, èyí mú kí wọn ó máa joro tí wọ́n sì ń dínkù níye.
Nzigiyimpa sọ pé àwọn elégbèdè máa ń mú kí igbó kún sí i ni, wọ́n sì ń jẹ́ kí ìgbépọ̀ ẹ̀dá láyìíká ó wà ní ìwọ̀ntún-ìwòsì. Ó ṣèkìlọ̀ pé bí àwọn elégbèdè bá pòórá, oríṣìiríṣìi àwọn ewéko kan náà yóò di ohun ìgbàgbé.
Ìlọ́wọ́sí àwọn ará ìgbèríko
Gẹ́gẹ́ bí Ọ̀jọgbọ́n Habonayo ṣe sọ, òṣì ni ó ń mú kí àwọn ènìyàn igbèríko ó máa wo inú igbọ́ láti wá nǹkan mú, pàápàá jùlọ agbègbè Batwa, tí ó jẹ́ pé wọ́n máa ń wọnú ìhà Great Lakes gidi gan-an.
Láti mú ìdàgbàsókè bá ìgbáyégbádùn wọn, kí wọ́n má baà gbọ́kàn lé àwọn igbó mọ́ láti ríhun jẹ, ìjọba nílò láti ṣàgbékalẹ̀ iṣẹ́ àkànṣe tí yóò máa mú owó wọlé wá fún àwọn ènìyàn ìgbèríko.
Ṣíwájú síi, Habonayo dábà ìṣaáyan lórí àwọn ìdánilẹ́kọ̀ àti ìdàgbàsókè àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ lábẹ́lé nínú àmójútó àwọn ohun-àlùmọ́nì igbó. Ó sọ pé:
Il est impossible de protéger le parc de Kibira sans associer les communautés locales. On doit leur faire comprendre qu’elles ont une grande place dans la protection de sa biodiversité, qu’elle soit faunique ou florique.
Kò ṣeéṣe láti dààbò bo Ọgbà igbó ìpamọ́ ọba Kibira láì ní ìlọ́wọ́sí àwọn ara igbèríko. A gbọdọ̀ jẹ́ kí ó yé wọn pé wọ́n kó ipa pàtàkì nínú ìdáàbò bo ìgbépọ̀-àwọn-ẹ̀dá, yálà àwọn ẹ̀dá ẹrankọ ni o, tàbí ẹ̀dá ewéko.






