Má bi AI, bí ojúgbà ẹ: Àpilẹ̀kọ alájùmọ̀kọ oníṣísẹ̀ntẹ̀lé

Image by Gustavo Nascimiento via the Association for Progressive Communications (APC), used with permission.

Àwòrán láti ọwọ́ Gustavo Nascimiento tí a mú lórí Association for Progressive Communications (APC), a sì gba àṣẹ láti lò ó.

Láti ọwọ́ Ameya Nagarajan, Debora Prado, àti Hija Kamran

Àpilẹ̀kọ yìí jẹ́ ọ̀kan lára àpilẹ̀kọ oníṣísẹ̀ntẹ̀lé “Má bi AI, bí ojúgbà ẹ,” àjùmọ̀kọ láàárín Global Voices, Association for Progressive Communication, àti  GenderIT. Àfojúsùn àwọn àpilẹ̀kọ oníṣísẹ̀ntẹ̀lé náà ni láti tẹnumọ́ pàtàkì ìpàṣípààrọ̀ ìmọ̀ láàárín àwọn ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe ń ṣe láti ayédáyé. O lè ka àwọn àpilẹ̀kọ oníṣísẹ̀ntẹ̀lé náà lórí APC.orgGenderIT.org, àti globalvoices.org. Bákan náà ni ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Àfihàngbangba sójú aráyé oníṣísẹ̀ntẹ̀lée ti Ohùn Àgbáyé oṣù Kẹ́rin ọdún 2026,Ìwòye Ẹ̀dá-ọmọ-ènìyàn nípa AI.” Ó lè ṣe àtìlẹ́yìn fún ìtẹ̀síwájú ìjábọ̀ ìròyìn yìí nípa fífowósílẹ̀ níbí.

Èrò yìí jẹ́ ajọkọ àwọn olóòtú mẹ́ta, tí ó jẹ́ ohùn àti ìṣọwọ́kọ̀wé ẹni mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, èyí tí a ò tíì ṣe láméètọ́ọ rẹ̀. Ohun kan ṣoṣo tí a ṣe ni yíyẹ àwọn ọ̀rọ̀ wò bóyá yíyán ọ̀rọ̀ lórí àti ìṣọwọ́kọ ọ̀rọ̀ọ́ tọ̀nà. A mọ̀ ọ́n mọ̀ pinnu láti tan imọlẹ̀ sí ọgbọ́n-àtinúdá àti ìyàtọ̀ ọmọ-ènìyàn, èyí tí ó jẹ́ domudómú àpilẹ̀kọ oníṣísẹ̀ntẹ̀lé yìí.

Gẹ́gẹ́ bíi olóòtú àwọn gbàgede ìkọ̀ròyìn tí ó dúró ṣánṣán fún dídáààbò bo ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn àti alukoro fún ohùn àti ìròyìn nípa àwọn ènìyàn tí kì í sábà jáde sí etí ìgbọ́ ọmọ-aráyé, ọ̀pọ̀ ìgbà nínú àwọn ọdún tó rékọjá ni a ti kojú ìṣòro yíyan ìròyìn tí a ó tẹ̀ jáde: ọ̀nà tí a lè tọ̀ láti wá nǹkan ṣe sí ti àwọn àìmọye ìwífún orí ẹ̀rọ-ayélujára tí àwọn ẹ̀rọ-àwòsíṣẹ́ akọ́pọ̀lọpọ̀ ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń pè ní Ẹ̀rọ Ònímọ̀ Tí-kìí-ṣetẹ̀dá-ọmọ-ènìyàn, tàbí AI ní àgékúrú, ń dàrọ.

Bí ó ti lẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìlọsíwájú àti ìgbèrù àwọn ẹ̀rọ-àmúṣẹ́ṣe wọ̀nyí pẹ̀lú ìlànà agbàlọ́wọ́ọ-méèní tí àwọn ilé iṣẹ́ yìí ń lo fi kò èrè jọ fún ara wọn nìkan tí ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ewu àti ipa búburú — bẹ̀rẹ̀ láti orí ìbàjẹ́ tí wọ́n ń mú bá àyíká títí kan ṣíṣe àmúlò ilẹ̀ ọ̀gẹ́rẹ́ àti àwọn ohun àlùmọ́ọ́nìi rẹ̀ nílòkulò fún ìṣọ́nipẹ́kípẹ́kí àti ogun jíjà, àti àwọn ìṣe mìíràn tí ó tàpá sí àwọn ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn. Síbẹ̀síbẹ̀, a mọ́ wí pé àwọn ohun-èlò báwọ̀nyìí lè jẹ́ ohun tí ó rọrùn láti mú lò nítorí kò sí òmíràn, bí àpẹẹrẹ, fún àwọn òǹkọ̀wé láti àwọn Ìlú Tóńdìdegòkè-àgbà tí wọ́n ń làkàkà láti kọ̀wẹ́ ní àwọn èdè àjòjì tí kì í ṣe ti ìbílẹ̀, gẹ́gẹ́ bíi èdè Gẹ̀ẹ́sì tàbí Sípéènì. Bákan náà ni a mọ̀ wí pé àwọn ènìyàn tí ó ní ìpèníjà-ara máa ń ṣàmúlò AI gẹ́gẹ́ bí ohun-èlò àranilọ́wọ́ nínú iṣẹ́ wọn.

Nínú akitiyan wa láti ní òye àwọn ìtakora báwọ̀nyìí àti láti la onírúurú àwọn ojú ìwòye àti ìlọ́júpọ̀ já láì dáwọ́ ìpèsè àyè fún àwọn òǹkọ̀wé àti òǹkàwé wa dúró, APC àti iṣẹ́ àkànṣe alàlẹ̀bíòṣùmàrèe rẹ̀ GenderIT.org ṣe àlàálẹ̀ ìlànà iṣẹ́ kan lọ́dún tó kọjá, láti ara ìmísí àti àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Global Voices, tí òun náà ṣẹ̀ṣẹ̀ tẹ àlàálẹ̀ ìlànà iṣẹ́ẹ tirẹ̀ náà jáde. Ní ọ̀nà méjèèjì, àwọn iléèṣẹ́ méjèèjì ń ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ìbéèrè tí ó ṣe gbòógì nípa ohùn, ìṣàkóso, ọgbọ́n-àtinúdá àti iṣẹ́ ọmọ-ènìyàn, ní ọ̀nà tí ó ń fi ìmọrírì ọgbọ́n-àtinúdá yìí hàn pẹ̀lú òdodo láì fi igbá kan bọ ọ̀kan nínú — dípò lílo ìrònú ìfèsìpadà tààrà bíi bẹ́ẹ̀ ni, bẹ́ẹ̀ kọ́, tàbí gbígbẹ́sẹ̀lé nǹkan, nítorí náà ni àlàkalẹ̀ ìlànà ṣe lọ báyìí:

Global Voices ṣe tán láti ṣe àtẹ̀jáde àwọn àpilẹ̀kọ, ògbufọ̀, àti àwòrán-ìṣàpèjúwe tí ó jẹ́ àtinúdá àwọn ènìyàn, fún àwọn ènìyàn, a sì fẹ́ kí àwọn akọ̀ròyìn wa náà ó tẹ́lẹ̀ òṣùwọ̀n yẹn láì yẹsẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bíi àjọ onírúurú àwọn ènìyàn tí ó fẹsẹ̀múlẹ̀, APC mọ rírì àwọn ìwífún orí ẹ̀rọ-ayélujára tí ó ti jẹ́ títẹ̀ jáde nítorí ọgbọ́n-àtinúdá ọmọ-ènìyàn, tí ó ti ara ìrírí, ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú ọmọ-ènìyàn, ìmọ̀ọ́ṣe àti ìyàtọ̀ àwọn ènìyàn àti àwọn iléèṣẹ́ tí ó wà nínú ẹgbẹ́ alájọṣepọ̀ náà.

Bí a ṣe gbáríjọpọ̀ láti wá ojútùú sí ìpèníjà kan yìí, èrò kan ṣẹ́ yọ: Bí a bá ṣe kọjáa bí a ti ṣe ń ṣe tẹ́lẹ̀ ńkọ́? Bí a kò bá kàn án tẹnumọ́ pàtàkì ìyàtọ̀ àti ọgbọ́n-àtinúdá ọmọ-ènìyàn lásán ńkọ́? Kí a fi hàn nípa ìṣe. Torí ìdí èyí ni èrò àpilẹ̀kọ oníṣísẹ̀ntẹ̀lé ṣe wáyé: Má bi AI, bi ojúgbà ẹ — àjùmọ̀kọ láàárín Global Voices àti àwọn gbàgede ìgbéròyìnsíta ti APC APC.org àti GenderIT.org.

Àfojúsùn wa ni láti lo àwọn àpilẹ̀kọ àkọlẹ́sẹẹsẹ náà fi tẹnumọ́rọ̀ kí iṣu pàtàkì ìpàṣípààrọ̀ ìmọ̀ láàárín ọmọ-ènìyàn, bí ó ti ṣe wà láti ayébáyé ó má ba à jóná: àtagbà ọ̀rọ̀ àti ìmọ̀ àtijọ́, tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìrírí ayé àwùjọ, èyí tí ó jẹ́ ọ̀nà pàtó láti bára ẹni ṣepọ̀. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú àmúwáa ẹ̀rọ AI aṣàdàrọ, ìbáṣepọ̀ yìí ti ń di ohun ìgbàgbé díẹ̀ díẹ̀, bí àwọn ènìyàn ṣe ń darí àwọn ìbéèrè wọn sí àwọn ohun-èlò AI aṣàdàrọ fún èsì dípòo kí wọ́n bi àwọn àgbàlagbà, ọmọlẹ́bí, ọ̀rẹ́, alábàáṣiṣẹ́pọ̀ àti àwọn ènìyàn ní àdúgbò.

Àfojúsùn àwọn àpilẹ̀kọ àkọlẹ́sẹẹsẹ wọ̀nyí ni láti ta àwọn ènìyàn jí padà sí ìbáṣepọ̀ láàárín ọmọ-ènìyàn, láti rí i wí pé ọmọ-ènìyàn túbọ̀ ń jẹ́ ọmọ-ènìyàn ní àwùjọ. Lásìkò tí à ń fi oríkorí, a ṣàkíyèsí wí pé ó pọn dandan láti mú ìpàṣípààrọ̀ ìmọ̀ àjùmọni padà, ní èyí tí olúkúlùkù lè bí “ìbéèrè” bí wọ́n bá ti ṣe mọ̀ ọ́n bi, tí wọ́n sì lè fèsì bí ìmọ̀ wọ́n bá ti ṣe mọ. Orí èyí ni a dúró lé lórí láti tan imọlẹ̀ sí ìyàtọ̀ọ̀tọ̀ iyè inú ẹnìkọ̀ọ̀kan wa — ohun tí AI, tí ò ní ìṣesí ọmọ-ènìyàn, kò le è lé bá.

Nítorí náà fún àwọn àpilẹ̀kọ àkọlẹ́sẹẹsẹ yìí, a kọ́kọ́ ṣètò àwọn ìbéèrè méjì ní ọ̀nà kan náà tí ènìyàn lè bi AI:

  • Kí ni ó fi pọn dandan láti mọ rírì ọgbọ́n-àtinúdá àti ìbáṣepọ̀ láàárín ọmọ-ènìyàn ni ayé AI?
  • Kí ni a lè ṣe láti jẹ́ kí AI ó pa ààbò àti ọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn mọ́?

Ṣùgbọ́n àwọn òǹkọ̀wé àti ayàwòrán-ìṣàpèjúwe láti oríṣìíríṣìi orílẹ̀-èdè, pẹ̀lú ìrírí àti ojú-ìwòye tí ó yọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ni yóò máa ṣe ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí. Àwọn ènìyàn ni yóò ṣe láméètọ́ọ àti ògbufọ̀ àwọn àpilẹ̀kọ yìí. Yóò kún fún ìmọ̀lára, àròjinlẹ̀ àti ìjàníyàn ọmọ-ènìyàn. Ẹni tí ó bá kópa nínú iṣẹ́ náà yóò gba owó ọ̀yà, a ó sì júbà onítọ̀hún fún akitiyan rẹ̀. Dípò àwọn èsì tí àwọn atánṣòro tí kò lè ṣe ju àdàrọ ohun tí a ti wé sílẹ̀ sórí rẹ lọ tí a ṣe lọ́nà tí yóò de àwọn òǹṣàmúlò mọlẹ̀ láti má leè lọ sí ibòmíràn, ojú ìwòye ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àti àwọn èrò inú aláròjinlẹ̀ tí ó lè fa ìtàkúrọ̀sọ. Ọpọlọ ọmọ-ènìyàn yóò sì wá ọ̀nà àrà láti fi ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.

Gẹ́gẹ́ bíi akẹgbẹ́, àwa olóòtú tí sùn, a sì ti kọrí sí ibìkan náà, a ti ṣe ìfọhùnsí àpilẹ̀kọ àkọlẹ́sẹẹsẹ tí a fi lọ́lẹ̀ lónìí. Bákan náà ni a ti hun onírúurú ojú ìwòye papọ̀ bí òwú aṣọ, bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ni a ṣe èyí tí ò ń kà yìí, àpilẹ̀kọ àjọkọ. Nípasẹ̀ fífi àpilẹ̀kọ àkọlẹ́sẹẹsẹ náà àti àwọn èròńgbà tí a ní léde báyìí, èròo wa ni pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wa yóò dìde, wọ́n á sọ ti ẹnu wọn, wọ́n á ṣe àìrẹ́, ó sì lè jẹ́ àwọn ibi ìfẹnukò, àti láti kọ́mọlùbọ́pọ̀ ṣẹ̀dá àwọn ìbéèrè tuntun fún àwọn àpilẹ̀kọ mìíràn lọ́jọ́ iwájú.

Lónìí, a fi ìwé pè ọ́ kí o darapọ̀ mọ́ wá. Bi àwọn akẹgbẹ́ẹ̀ rẹ, ka ohun tí wọ́n ní láti sọ, ṣe àpínkiri ìwífún orí ẹ̀rọ-ayélujára wọn, kí ìwọ náà ó ṣẹ̀dá èrò inúu tìrẹ àti àtinúdá tí àwọn ènìyàn lè ṣe àpínkiri rẹ̀ — yálà àdáṣe tìrẹ nìkan tàbí ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Nípasẹ̀ ṣíṣe nǹkan ní ọ̀nà àrà, a lè wò ó ṣààkun wí pé ó kù sí wa lọ́wọ́, a sì lágbára láti gbà láti lo ohun-èlò ìmọ̀ ẹ̀rọ amúṣẹ́ṣe, kọ̀ láti lò ó tàbí dín ìṣàmúlò rẹ̀ kù. Àwọn ọ̀nà mìíràn tí a lè gbà ṣe nǹkan ń bẹ láti ayé alálùmọ́lẹ̀, tí yóò sì túbọ̀ máa bẹ.

Ó lè máa bá àwọn àpilẹ̀kọ àkọlẹ́sẹẹsẹ náà bọ̀ títí tí oṣù Kẹrin yóò fi jálẹ̀ lórí APC.org, GenderIT.org àti globalvoices.org. Bí o bá fẹ́ máa gba àwọn ìsọfúnni tuntun lóríi àpilẹ̀kọ àkọlẹ́sẹẹsẹ yìí, àti àwọn ìwífúnni láti àwọn iléèṣẹ́ wọ̀nyí sínú àpò ìkọ̀wéránṣẹ́ orí ẹ̀rọ-ayélujára rẹ, fi ọwọ́ sí i níbí láti máa gba àkọránṣẹ́ láti ọwọ́ APC àti níbí fún àkọránṣẹ́ láti ọwọ́ Global Voices.

Ameya Nagarajan (abo) ni alákòóso ìròyìnkíkọ fún yàrá ìkọ̀ròyìn Global Voices, òun náà sì ni olóòtú Advox.

Débora Prado (abo) ni olóòtú àgbà fún APC.org, akọ̀ròyìn tí ó ní ìrírí nínú ìmọ̀ ète ìkànsíni àti ìbánisọ̀rọ̀, ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn àti onígbàgbọ́-nínú-ìdọ́gba-akọ-àtabo.

Hija Kamran (abo) jẹ́ olóòtú àgbà fún GenderIT.org, bákan náà ni ó jẹ́ agbẹnusọ ète nínú Ètò Ẹ̀tọ́ àwọn Obìnrin ti APC.

Àjọ Association for Progressive Communications (APC) jẹ́ ẹgbẹ́ aláfowówọ̀ àwọn iléèṣẹ́ ajíjàngbara. APC.org gangan ni olórí ibùdó-ìtakùn àgbáyé wa, níbi tí àwọn ìròyìn, ìsọfúnni tuntun, àwọn àkọọ́lẹ̀, àwọn àpilẹ̀kọ ìgbàdégbàwa, àti àwọn àtẹ̀jáde wa gbogbó wà, tí ọ̀rọ̀ nípa bí ẹ̀rọ-ayélujára àti ICT ṣe lè jẹ́ ohun tí ó ṣe é mú lò fún ìlọsíwájú àwùjọ, ìrinakọbábo, àti àyíká tí ó dára fún ìgbé ayé ẹ̀dá gbogbo.

GenderIT.org jẹ́ àtẹ̀jáde tí ó ń lukoro fún ìdọ́gba-akọ-àtabo, tí ó ti agódo Ètò Ẹ̀tọ́ àwọn Obìnrin ti APC, èyí tí ó ń ṣe àgbélẹ́wọ̀n àwọn èrò oríṣìíríṣìi tó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ọ̀nà tí ọ̀rọ̀ ìrinakọbábo, èwù ìmọ̀lára sákọsábo, àti ìmọ̀ ẹ̀rọ amúṣẹ́ṣe ṣe wọnú ara wọn.

Global Voices jẹ́ àjọ àgbáyé àwọn òǹkọ̀wé elédèpúpọ̀, àwọn òǹgbifọ̀, àti àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́-ọmọnìyàn. Ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀, à ń ṣe àmúlò agbára ẹ̀rọ-ayárabíàṣá láti sọ àwọn ìròyìn tí ó ń mú kí àwọn ènìyàn àti àṣà káàkiri àgbáyé ó ní òye kíkún nípa ara wọn.

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.