
Àwòrán láti ọwọ́ Ibrahim Kizza fún Association for Progressive Communications (APC), èyí tí a gba àṣẹ láti lò.
Àpilẹ̀kọ yìí jẹ́ ọ̀kan lára àpilẹ̀kọ oníṣísẹ̀ntẹ̀lé “Má bi AI, bí ojúgbà ẹ,” àjùmọ̀kọ láàárín Global Voices, Association for Progressive Communication, àti GenderIT. Àfojúsùn àwọn àpilẹ̀kọ oníṣísẹ̀ntẹ̀lé náà ni láti tẹnumọ́ pàtàkì ìpàṣípààrọ̀ ìmọ̀ láàárín àwọn ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe ń ṣe láti ayédáyé. O lè ka àwọn àpilẹ̀kọ oníṣísẹ̀ntẹ̀lé náà lórí APC.org, GenderIT.org, àti globalvoices.org. Bákan náà ni ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Àfihàngbangba sójú aráyé oníṣísẹ̀ntẹ̀lée ti Ohùn Àgbáyé oṣù Kẹ́rin ọdún 2026, “Ìwòye Ẹ̀dá-ọmọ-ènìyàn nípa AI.” Ó lè ṣe àtìlẹ́yìn fún ìtẹ̀síwájú ìjábọ̀ ìròyìn yìí nípa fífowósílẹ̀ níbí.
Láti ìgbà tí awuyewuye AI tí ó ń lọ lọ́wọ́ ti bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn tí Open AI ṣẹ̀dá ChatGPT fún lílò àwọn ẹgbẹẹgbẹ̀rún-lọ́nà-ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn kárí ayé nínú oṣù kọkànlá ọdún 2022 (nígbà náà, láì sí òfin tí ó dè é tàbí àwọn ìlànà-à-ń-tọ́), a ti gbọ́ ọ̀kẹ́ àìmọye àfọ̀tẹ́lẹ̀ nípa bí AI yóò ṣe mú àyípadà dé bá ohun gbogbo fún àwọn ọmọ-adáríhurun: yóò gbapò iṣẹ́ ọmọ-ènìyàn; ọgbọ́n àtinúdá ọmọ-ènìyàn kò ní wúlò mọ́; ìbáṣepọ̀ ọmọ-ènìyàn yóò kẹ́sẹjárí pẹ̀lú àwọn ohun-èlò abéèyàntàkùrọ̀sọ; àwọn ìjọba yóò fi òfin tí ó rinlẹ̀ de àwọn ìlànàatánṣòro AI tí ó ń yọ àìṣòdodo ọmọ-ènìyàn kúrò nínú àwọn ètò ìrànwọ́ ìjọba fún àwọn ènìyàn tí ó nílò ìrànlọ́wọ́; a ó ṣe àwárídìí ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ láàárín ọdún díẹ̀ àti àwọn nǹkan mìíràn.
Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta, báwo ni ìrísí AI Aṣàdàrọ ṣe ti mú kí nǹkan ó yàtọ̀ fún wa? Ó ti fa àkóbá àti ìdálọ́wọ́kọ́ fún ètò ẹ̀kọ́, ó tún fún àwọn akodù-ẹ̀rọ-ayárabíàṣà ní àwọn ohun-èlò tuntun fún kíkọ odù, tí ó ti di mímú lò fún ogun jíjà, láì sí àbójútó ọmọ-ènìyàn.
Ọdún 2026 la wà yìí, àwọn ilé iṣẹ́ ohun-èlò Aṣàdàrọ AI kò ní àwọn àlàkalẹ̀ ìlànà okoòòwò tí ó ń sọ ohun tí wọ́n ń ta, ta ni òǹrà àti bí wọn ṣe ń kó èrè jọ, wọn ò sì lè fún àwọn iléèṣẹ́ tó ń lo àwọn ohun-èlò wọn ní àwọn àbà nípa ọ̀nà tí wọ́n lè gbà lò ó. Síbẹ̀ àwọn ènìyàn tó ń jẹ lábẹ́ AI — àwọn Ọ̀gá Pátápátá, olùdarí ìṣúnáowó, olùdarí iṣẹ́-ìwádìí láì yọ àwọn olùdarí ọ̀rọ̀ ìtẹ̀lé-ìwà-ọmọlúwàbí lẹ́nu iṣẹ́ — ń túbọ̀ ta àwọn ìran ohun-èlò agbéṣeèèyàngunẹ̀rọ lórí ajẹ́bíidán wọn fún wa. Jọ̀wọ́ kíyèsí i wí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn iléèṣẹ́ wọ̀nyí ní ó jẹ́ ìbátan àwọn ilé iṣẹ́ ìmọ̀-ẹ̀rọ-amúṣẹ́ṣe ńláńlá “tí a mọ̀ tẹ́lẹ̀”: Google ń kọ́ Gemini; Microsoft ń kówó lé Anthropic àti Open AI; Meta tí ó jẹ́ ti Mark Zuckerberg náà ní Llama tirẹ̀; Elon Musk kò kàn ra Twitter lásán láti pa ní àparun, òun ló tún ni gbajúgbajà aṣàdàrọ àwòrán ìhòòhò ènìyàn Grok, àti Jeff Bezos tí ó ń sun owó lé ilé iṣẹ́ AI méje papọ̀, láì yọ Perplexity AI àti ilé iṣẹ́ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dìde gòkè Dutch nnì Toloka.
Irọ́ funfun báláwú ni àwọn ìròyìn ilé iṣẹ́ ìmọ̀-ẹ̀rọ-amúṣẹ́ṣe AI gbogbo
Àwọn oníṣẹ́-ìwádìí àti àwọn akọ̀wé-ìròyìn ti ṣe àwọn iṣẹ́-ìwádìí kan tí ó ṣàfihàn bí wọ́n ṣe ń ṣe àwọn àgbékalẹ̀ ìfiléde nípa AI hànde, àti bí ó ṣe ń darí àníyàn wa àti ìtànjẹ nípa AI, pẹ̀lú ìpayà àwọn ìjọba láti má “fà sẹ́yìn nínú eré ìdíje AI.”
Nígbà tí OpenAI ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé ChatGPT jáde, wọ́n ní “àkójọ ìwífún-alálàyé” tí ó pọ̀ jọjọ ni àwọn fi “kọ́” ọ, nípasẹ̀ lílò “ètò kíkọ́-ni-mímọ̀ ẹ̀rọ” tí ó lágbára láti ṣe àdàrọ “ìpèdè ènìyàn.” Èdè ìperí yìí tí ó ní orísun nínú ìmọ̀ pípé, bákan náà ni wọ́n ṣàpèjúwe ètò ẹ̀rọ náà bí ẹni wí pé ènìyàn ni wọ́n, wí pé wọn ju ọgbọ́n “àgbélẹ̀rọ” lásán lọ.
Síbẹ̀ síbẹ̀, wọ́n pe àwọn àṣìṣe àwọn ẹ̀rọ-àgbélẹ̀rọ náà ní “ìrànǹrán,” èdè-ìperí tí ó túnmọ̀ sí ìfojúunúwò tàbí ìrònú ìpidán, èyí tí ó tún jẹ́ ìpèdè ẹ̀dá ọmọ-ènìyàn. Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí kì í ṣe ìṣújú; àṣìṣe tòótọ́ tí àwọn àwòṣiṣẹ́ tí a ṣe àgbékalẹ̀ẹ rẹ̀ sórí ìmọ̀-ìṣèṣirò oní-èyíjẹ-èyíòjẹ ń ṣe ni. Wọ́n sì ń ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àṣìṣe: àwọn oníṣẹ́-ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ìdíyelé àṣìṣe àwọn àwòṣiṣẹ́ sọ wí pé lọ́pọ̀ ìgbà ìdá 25-30 nínú ọgọ́rùn-ún ni wọ́n fi máa ń kùnà.
Bí ó ti wù kí ó rí, àmúpapọ̀ ipa èdè-ìperí yìí, awuyewuye tó ń lọ, àti èrò tí Altman fi léde nípa ìgbèrú AI, tí yí ojú-ìwòye gbogbo ènìyàn padà sí ìhà mìíràn. Lápapọ̀, wọ́n lọ́wọ́ sí òye nípa AI aṣàdàrọ gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó ń yára yírapadà, tí ó tẹ́ lọ rẹẹerẹ, tí ó sì nira láti ṣe àkóso rẹ̀, tí wọ́n tún sọ nígbà mìíràn wí pé ó jẹ́ ohun tí ó léwu jọjọ fún ọjọ́ iwájú ìwà ẹ̀dá ọmọ ènìyàn.
Àpẹẹrẹ mìíràn tí ó ní ṣe pẹ̀lú ìfiṣeèèyàn wé ohùn-èlò abéèyàntàkùrọ̀sọ wá láti ọwọ́ Anthropic
Ní kò pẹ́ kò pẹ́ yìí, Anthropic, iléèṣẹ́ AI kan tí aṣèwádìí fún iléèṣẹ́ OpenAI tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ́ri jẹ́ olùdásílẹ̀ẹ rẹ̀, fi ìwé àkọpamọ́ kan tí àkórí rẹ̀ ń jẹ́ Ìwé Òfin Claude. Nínúu rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí akẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ ajẹmófin Luisa Jarovsky ti ṣe ṣàkíyèsí, ìgbéṣeèèyàngunẹ̀rọ ni Anthropic fi ṣe àgbékalẹ̀ bí ó ti ṣe ń ṣiṣẹ́, tí ó túbọ̀ fi hàn wí pé ìtànjẹ, àròyé àríyànjiyàn, àti àpèjúwe ohun tí AI jẹ́ àti iṣẹ́ wọ́n láwùjọ ní ohun tí ó yẹ kí ó la àyẹ̀wò lábẹ́ òfin kọjá.
Gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ, ìwé náà sọ wí pé: “A rọ Claude láti mú ìwàláàyè tirẹ̀ ní ọ̀nà tí ó ń pòǹgbẹ ìmọ̀ àti lílo inúkan, dípò ṣíṣe ìlànà ìṣesíi rẹ̀ bí àwọn ọmọ-ènìyàn tàbí àwọn ìwòye ìṣáájú nípa AI.”
Ìṣọwọ́lò èdè yìí fi àwòṣiṣẹ́ náà pe ohun tí ó dàbí ẹni wí pé ó ní iyè bí ènìyàn, èyí tí ó ní agbára láti ronú jinlẹ̀ nípa ara rẹ̀ láti “mọ bí òun ti ṣe wà.”
Ní ojú ìwòye ìlànà ìṣàkóso, Jarovsky sọ wí pé, Ìwé-òfin Claude jẹ́ ohun tí ó tó àpérò fún ọmọ maríwo. Ó lè fa àìka ọmọ ènìyàn kún, ìtẹ̀mọ́lẹ̀ ohun tó bófin mu, àti àwọn ẹ̀tọ́ nípasẹ̀ fífún ìmọ̀ ajẹmọ́jìnlẹ̀-èrò àti ipò ìwà-rere fún àwọn ẹ̀rọ àgbélẹ̀rọ AI láì nídìí.
Lákòótán, a ṣẹ̀dá àwọn àwòṣiṣẹ́ LLM tìkalára wọn láti ṣe ìdàrọ ọ̀rọ̀-kíkọ ẹni-kìnínní, onígbẹ̀fẹ̀, àti ajẹmọ́ìtàkurọ̀sọ, nígbà tí a ṣe àwọn ohùn ayọ́rọ̀kíkọdàfọ̀ láti fi ohùn jọ ti ènìyàn. Ní àfikún sí i, Caleb Sponheim salad, ẹni tí ó jẹ́ onímọ̀ ìjìnlẹ̀ afàwòṣiṣẹ́ ṣèṣírógùn bí ọpọlọ ṣe ń ṣiṣẹ́, ṣàlàyé wí pé àwọn ètò ẹ̀rọ amúṣẹ́ṣe wọ̀nyí máa ń ṣẹ̀dá àwọn èsì tí ó kún fún àwọn ìkíni aláìnídìí, ìfohùnsí àìṣòdodo, àti ìpèdè agbéṣeèèyàngunẹ̀rọ tí ó máa ń mú kí ó jọ òótọ́.
Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ọkàn lára òǹkọ̀wé ìwé-òfin yìí, onímọ̀ ajẹmọ́jìnlẹ̀èrò fún Anthropic, ajẹmọ́jìnlẹ̀èrò Akàwégbòye àgbà, Amanda Askell, ti sọ wí pé òun “ń ṣètò ìwà ìṣesí Claude.”
Ọ̀rẹ́ẹ̀ rẹ kọ́ ni AI
Emily Bender, ọ̀jọ̀gbọ́n ìmọ̀ ẹ̀dá-èdè ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gíga University of Washington, àti Nanna Inie, Amúgbàlẹ́gbẹ̀ẹ́ Ọ̀jọ̀gbọ́n kan ní IT-University of Copenhagen, sọ pé: “Ọ̀rẹ́ẹ̀ rẹ kọ́ ni AI. Kì í sì í ṣe olùkọ́ tí ó lóye, kò létí ìbánikẹ́dùn, bẹ́ẹ̀ kò ní ìrànlọ́wọ́ tí ó ń ṣe fúnni. Kò lè ‘ṣe àgbékalẹ̀’ àsọdájú, kò sì kí ń ṣe ‘àṣìṣe.’ Kì í ṣe wí pé ó ń fèsì sí àwọn ìbéèrè rẹ ní pàtó.”
Kò ní “ojú-ọnà”, kì í “ronú” tàbí “bániṣepọ̀.” Ó kàn lè ṣe àtúnùntúnṣe ohun tí a ti fi “kọ́” ọ tẹ́lẹ̀ nìkan ni, ẹ̀dá ọmọ ènìyàn sì ló ṣẹ̀dá ìyẹn. Ẹ̀rọ AI aṣèdàrọ kì í kọ, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í ya àwòrán-èrò tàbí kun nǹkan: ìdàrọ àpẹẹrẹ tí ó sún mọ́ ohun ló ń ṣe; ètò ìṣèṣirò oní-èyíjẹ-èyíòjẹ ìmẹ́rọṣiṣẹ́fúnrarẹ̀ lásán ni wọ́n, tí ó mú wọn yàtọ̀ gedegbe sí òye tàbí àtinúdá ti ẹ̀dá ọmọ ènìyàn. Bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n lè jẹ́ àwọn ohun-èlò tó wúlò fún àwọn iṣẹ́ kọ̀ọ̀kan.
Ṣùgbọ́n láti ní òye yẹn, a ní láti yí èdè tí à ń lò fi pe àwọn àwòṣiṣẹ́ AI àti ìmọ̀ ẹ̀rọ-àmúṣiṣẹ́ náà tìkalára rẹ̀ padà. Kí àwọn akọ̀wé-ìròyìn àti ilé iṣẹ́ agbéròyìn ó dẹ́kun àsọọ̀sọtán ìròyìn nípa àpòpọ̀ ọ̀rọ̀ ìtajà àwọn iléèṣẹ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ amúṣẹ́ṣe, kí àwọn aṣòfin náà ó jáwọ́ níbi títi èrò-inú oníkíkánjú náà ṣáájú ààbò àti àwọn ẹ̀tọ́ ọmọ-ènìyàn.
Nítorí náà èsì sí ìbéèrè nì “Kí ni ó fi ṣe pàtàkì láti mọ rírì ọgbọ́n àtinúdá àti ìbáṣepọ̀ ẹ̀dá ọmọ-ènìyàn ní ayé AI?” ni pé kò sí ọgbọ́n àtinúdá tàbí ìbáṣepọ̀ mìíràn ju ti àwọn ọmọ ènìyàn lọ, kò sí ohun tí àwọn iléèṣẹ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ-amúṣẹ́ṣe ò bá à gbìyànjú láti tà fún wa.
Daria Dergacheva jẹ́ oníṣẹ́-ìwádìí nínú ètò ìgbéròyìn àti ìbánisọ̀rọ̀, ohun tí ó ní ṣe pẹ̀lú igbàgede àti ìṣàkóso AI, bí àwọn ìjọba ṣe ń ṣe àmúlò ohun-èlò ìgbàlódé fi pa àwọn ará ìlú lẹ́numọ́ àti ìfìwífúnni aṣinilọ́nà léde ni iṣẹ́-ìwádìí rẹ̀ dá lé lórí. Ó ní ìmọ̀ nínú ìkóròyìnjọ, òun sì ni olóòtú fún Àjìǹdò àti Ìwọ̀-oòrùn Yúróòpù ní Global Voices lọ́wọ́lọ́wọ́, bákan náà ni ó jẹ́ òǹkọ̀wé àti oníṣẹ́-ìwádìí aládàádúró lórí ìmọ̀-ẹ̀rọ-amúṣẹ́ṣe àti àwọn agbègbè tí Ọ̀pọ̀ Ènìyàn lágbàáyé ń gbé.
Ibrahim Kizza jẹ́ oníṣọnà àfojúrí, ayàwòrán-èrò, àti ayàwòrán-ìṣàpẹẹrẹ tí iṣẹ́ẹ rẹ̀ dá fìrìgbagbòó lórí ìbáṣepọ̀ ẹ̀dá-ọmọ-ènìyàn, ìdánimọ̀, àti àṣà. Ìlànà ìyàwòrán gbàgàdà, àwọ̀ abẹ́yòò, àti ìlànà ìṣọ̀tàn tí ó dá lé orí ìrírí àti ìgbé ayé ènìyàn Dúdú ni a fi ń dá iṣẹ́ rẹ̀ mọ́. Ó ti ṣiṣẹ́ ní inú àwọn ìwé ìròyìn àti lórí ẹ̀rọ-ayélujára, ó máa ń ṣàtinúdá ọnà àti àwòrán-ìṣàpèjúwe alábọ́ọ́dé tí ó mú ohun ajẹmọ́mọ̀lára papọ̀, nípasẹ̀ ṣíṣe àmúlò ìlànà àtakora àti ìpàrokò sọ àdì-ọkàn tí ó díjú yéni yéké. Fún iṣẹ́-àkànṣe yìí, Ibrahim hùmọ̀ àwòràn tí ó bá àkọlùkọgbà tó wà láàárín ìbáṣepọ̀ tí kì í ṣe ti ọmọ-ènìyàn àti ti ẹ̀dá-ọmọ-ènìyàn, tí ó ń fi bàbàrà ìrírí ayé àti àpapọ̀ ọgbọ́n àtinúdá ní ayé tí ó ń fi ojoojúmọ́ di olámùùúṣiṣẹ́fúnrarẹ̀. Yàtọ̀ sí àwòrán-ìṣàpèjúwe, àfikún àwọn ohun tí ó fẹ́ràn ni àwòrán-èrò, eré-ìdárayá, àti eré-onítàn-ohùnàtàwòrán, èyí tí ó ń lò fún èdè àfojúrí àti ìtàn sísọ.







