
Àwọn elétò ìlera-bìnrin agbègbè níbi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kan ní Dankpen Prefecture, tí ó wà ní ẹkùn Kara ní apá Àríwá Togo. Àwòrán láti ọwọ́ Émile Bobozi. A gba àṣẹ láti lò ó.
Láti ọwọ́ Emile Bobozi
Ní àwọn ìgbèríko orílẹ̀-èdè Togo, àwọn obìnrin ló ń gbé èyí tó jù nínú bùkátà ẹbí. Síbẹ̀, wọ́n tẹramọ́ ìdàgbàsókè ìlú wọn bíótilẹ̀jẹ́pé àwọn àṣà àjogúnbá ń fínná mọ́ wọn.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìgbèríko ní ẹkùn Kara ní apá àríwá Togo ni àwọn ohun amáyédẹrùn ti di ẹgẹrẹmìtì, tí ó sì ń tàbùkù ìgbé-ayé ìrọ̀rùn fún àwọn ará agbègbè Bassar, Kabye, Lamba àti Konkomba. Lọ́pọ̀ ìgbà ni àwọn ojú ọ̀nà wọn kìí ṣe é gbà, àwọn ọ̀nà ojú omií mú kí ìrìnàjò sí ilé-ìwòsàn ó nira, tí èyí sì ń fà àwọn ìdènà sí ìrọ́wọ́tó ètò ìlera. Àwọn òṣìṣẹ́ ìlera-bìnrin ní láti pa iṣẹ́ oòjọ́ àti ojúṣe wọn nínú ẹbí pọ̀ láti lè pèsè ètò ìlera tó péye fún àdúgbò wọn.
Nínú èèyàn bíi ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ 9 tó wà ní Togo, ìdá 51.3 nínú ọgọ́rùn-ún ni iye àwọn obìnrin. Ìdá 33 nínú ọgbọ́rùn-ún niye àwọn ọkùnrin tí kò mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà, tí àwọn obìnrin sì fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlọ́po méjì iye àwọn ọkùnrin.
Àwọn ìdojúkọ tí ó jẹ́ tàwọn obìnrin ní àwọn ìgbèríko
Gẹ́gẹ́ bí àṣà ìbílẹ̀ Togo, ìfojútẹ́mbẹ́lú abó ṣì fẹsẹ̀ ranlẹ̀ dain-dain, tí ó sì ń pa àwọn obìnrin lẹ́nu mọ́ lọ́pọ̀ ìgbà tí kò sì fàyè gbà wọ́n láti lè dá ìpinnu ṣe.
Iṣẹ́ agbẹ̀ ni olúborí iṣẹ́ ní àwọn ìgbèríko. Òun ni iṣẹ́ tí ìdá 80 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tí ó jẹ́ obìnrin àgbẹ̀ alárojẹ ń ṣe, tí ó ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lè gbọ́ bùkátà ara wọn àti ti ẹbí. Sibẹ̀, ìdá 15 nínú ọgọ́rùn-ún péré nínú wọn ni ó ní ìwé ilẹ̀. Àìní àrọ́wọ́tó sí ilẹ̀ àti owó ìrànwọ́ fún ọ̀gbìn ṣíṣe yìí ni ó jẹ́ kí wọ́n ó máa gbára lé àwọn ọkùnrin kí wọ́n tó lè gbé ìgbéṣẹ̀ lórí àwọn ohun tí wọ́n nílò. Àwọn obìnrin máa ń kojú ìṣojúṣàájú àti ìwà-àìmúnirówólò, èyí tí ìwádìí àbùdá-iye-ènìyàn kan fi hàn wí pé ìwà-ipá ajẹmọ́ ìjàmbá ara máa ń túbọ̀ jẹ́ kí ó peléke sí i. Ohun tí àkọsílẹ̀ tọ́ka sí ni pé ìdá 32 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn obìnrin Togo ló ti jìyà ìpalára ìwà-ipá ajẹmọ́ ìjàmbá ara tàbí ìbálòpọ̀ láti ọjọ́ orí 15.
Oríṣìíríṣìí ọ̀nà ni àwọn obìnrin tó ń dáko tàbí ṣiṣẹ́ ní ìgbèríko ń gbà ní ìrírí ajẹmọ́ ìwà-ipá. Bí àpẹẹrẹ, bí wọ́n bá di opó, ní ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn àbúrò tàbí ẹ̀gbọ́n ọkọ wọ́n ọkùnrin yóò gbẹ́sẹ̀ lé irè oko wọn, ti èyí yóò sì já wọ́n sí kolobo. Àwọn obìnrin míràn máa ń ṣe iṣẹ́ agbára bíi fífi ọwọ́ bó èpo èso àti omi gbígbé láì gba owó. Gẹ́gẹ́ bí ìjábọ̀ ìwádìí UN Women kan ti ṣe fi hàn, ìda 42 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn àgbè obinrin ṣe afisun ìwà-ipá tó wáyé ní àwọn oko tó jìnnà sí abúlé. Wọ́n tún ní ìrírí jìbìtì ara níbi tí wọ́n tí ń wá ajílẹ̀ àti owó ìrànwọ́ kiri.

Àwòrán àwọn obìnrin níbi tí wọ́n ń ti ń gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí ìmọ̀ ìwà-ipá ajẹmọ́ akọ àti abo ní Basar. Àwòrán láti ọwọ́ Émile Bobozi, a gba ìyọ̀nda láti lò ó.
Àṣeyọrí àwọn ìyàwó wọn ń pòkuuru mọ́ àwọn ọkùnrin
Sarakawahalou Awilia, ẹni tí ó ti bí ọmọ mẹ́ta, jẹ́ òṣìṣẹ́ ètò ìlèra àdúgbò (CHW) tó ń ṣojú ẹ̀ka Manga ti Bassar Prefecture, ní Kara, èyí to tó kìlómità 490 ní apá Àríwá Lomé, olú orílẹ̀-èdè Togo. Òun ni adarí fún àwọn òṣìṣẹ́ ètò ìlèra tó wà ní agbègbè rẹ̀, ó sì ń ṣojú ìdílé 450 àti jù bẹ́ẹ̀ lọ nínú àwọn ìlú márùn-ún tó wà lábẹ́ àkóso rẹ̀. Àṣeyọrí rẹ̀ ṣàfihàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi akọ́ṣẹ́mọṣẹ́: torí kò sí ikú ọmọ́dé tí kò tíì pé ọmọ ọdún márùn-ún bẹ́ẹ̀ sì ní àwọn aboyún kò bí ọmọ sílé.
Láti ọdún 2018 ni Awilia ti ń ṣakitiyan lórí bí ìmúdárasíi ṣe lè bá ìráàyèsí ètò ìlèra ní agbègbè rẹ̀. Yàtọ̀ sí àṣeyọrí iṣẹ́ rẹ̀ yìí, ó ní iná tó ń jó o lábẹ́ aṣọ. Èyí sì ni pé ọkọ rẹ̀, ẹni tí ó fẹ́ jẹ gàba lórí owó oṣù rẹ̀, ń dúnkokò mọ́ ọ, ó sì ń fìyà abẹ́lé jẹ ẹ́.
Sarakawahalou jẹ́ ọ̀kan lára àwọn 195 obìnrin tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú NGO Integrate Health, tí wọ́n sì ti di akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ elétò ìlera. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdá 35 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn obìnrin yìí ni ó ti ní ìrírí ìwà-ipá ajẹmọ́ akọ àti abo (GBV). Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pe Sarakawahalou ti ṣègbéyàwó láti ọdún 2010, ọkọ rẹ̀ gbógun tìí nígbà tí àjọ ètò ìlera (CHW) tí ó ń bá ṣiṣẹ́ fi owó kún owó oṣùu rẹ̀. Ó níye tó máa ń gbà nínú owó oṣùu rẹ̀, bí ó bá sì kọ̀ láti fúń-un, ìyìyà ni ó máa ń yọrí sí nígbàkúùgbà.
Bíótilẹ̀jẹ́pé àwọn NGO tí ó ń bá ṣiṣẹ́ àti àwọn aláṣẹ ìbílẹ̀ agbègbè bá wọn dá sí ọ̀ràn náà, Sarawahalou padà juwọ́sílẹ̀ fún ọkọ rẹ̀ kí àlááfíà ó ba à lè jọba nínú ilé wọn. Ó sọ ohun tí ọkọ rẹ̀ wí:
Bí o kò bá fún mi ní FCFA 25,000 (USD 44) lóṣù yìí, kí o yáa kó ẹrù rẹ jáde kúrò nínú ilé mi ni. O gbàgbé wí pé ìlọ́wọ́sí mi ni o fi ríṣẹ́ yìí. Bí n kò fẹ́ ọ, kò le è bọ́ sí ọ lọ́wọ́.
Ní ìfèsì sí ìdúnrunmọ́ ọkọ rẹ̀, ó wí báyìí:
Nínú owó oṣù mi ni mo ti ń dáná tí mo sì ń tọ́jú àwọn ọmọ. Eélòó gan-an lo ti ná sórí ìtọ́jú ìlera àwọn ọmọ. Kàkà kí o máa dúnkokò mọ́ mi, á dára kí a fohùnṣọ̀kan.
Ọpẹ́ púpọ̀ fún àtìlẹ́yìn tí ó rí gbà láti pẹ̀tù si aàwọ̀ yìí, Sarakawahalou àti ọkọ rẹ̀ ṣì ń gbé papọ̀ lónìí. Ó sì ní ìrètí wí pé àwọn àlékún akitiyan ìpolongo ìmọ̀ lórí ìwà-ipá yóò mú kí ọkọ òun ó mọ rírí iṣẹ́ tí òun ń ṣe.
Kí ni ojúwòye òfin lórí aàbò obìnrin ní Orílẹ̀ Togo?
Onírúurú òfin tó ń dáàbò bo ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin tí ó sì ń kojú ìfọ́wọ́rọ́nisẹ́yìn àti ìwà-ipá ajẹmọ́ akọ àti abo ni orílẹ̀ Togo ní. Ní ti ẹ̀tọ́ tí àwọn obìnrin ní nílé ọkọ, Àkọsílẹ̀ òfin 391 tó níi ṣe pẹ̀lú Òfin tó de Ẹni áti Ẹbí ṣàlàyé sọ pé:
Àparò kan ò jù kàn ni ẹ̀tọ́ obìnrin àti ọkùnrin nínú ìgbéyàwo, ìkọraẹnisílẹ̀, ogún jíjẹ àti mímójútó àwọn ohun ìní ẹbí.
Women have the same rights as men in marriage, divorce, inheritance, and family property management.
Àkọsílẹ̀ òfin 232 sí 237 ti Òfin Tuntun nípa Ìjìyà, èyí tí wọ́n fi lélẹ̀ ní oṣù Kẹwàá, ọdún 2015 wà fún ìdáàbòbo àwọn obìnrin lórí ìwà-ìyọnilẹ́nu ajẹmọ́ ìjàmbá ara, ìwà-ẹ̀tọ́ àti rírówólòrírówóná. Títẹnumọ́ àwọn ìjìyà tó wà fún àwọn ìwà burúkú wọ̀yìí, bíi híhu ìwà-ipá sí aláboyún tàbí ìfojútẹ́mbẹ́lú obìnrin yóò mú kí àwọn oníwà ìbàjẹ́ yìí dẹ́kun àwọn ìwà náà. Àkọsílẹ̀ òfin 234 sọ pé:
Ẹnikẹ́ni tó bá jẹ̀bi ẹ̀sùn híhú ìwà-ipá ajẹmọ́ ìjàmbá ara tàbí ajẹmọ́ṣẹ́-ọkàn sí aláboyún yóò fi ẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún sí mẹ́wàá gbára, irú ẹni bẹ́ẹ̀ yóò sì san FCFA 500,000 (USD 885 ) sí FCFA 2,000,000 (USD 3,538) gẹ́gẹ́ bí owó ìtanràn tàbí ọ̀kan nínú àwọn ìjìyà wọ̀nyìí. Bí olùfaragbà ìwà-ipá yìí bá tibẹ̀ kú, ẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún sí mẹ́wàá ni ìjìyà náà.
Anyone convicted of physical or psychological abuse against a pregnant woman shall be sentenced to five to ten years imprisonment and fined FCFA 500,000 (USD 885 ) to FCFA 2,000,000 (USD 3,538) or one of these two penalties. The sentence is five to ten years imprisonment if this violence results in the victim’s death.
Bákan náà, Òfin tó de àwọn Òṣìṣẹ́ fi ààbò tó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ fún iṣẹ́ àwọn obìnrin, pàápàá jùlọ lásìkó tí wọ́n bá wà nínú oyún tàbí bí wọ́n bá gba àyè ìsinmi lẹ́yìn ìbímọ. Àkọsílẹ̀ òfin 148 ṣàlàyé pé:
Aláboyún lè gba àyè fún ìsinmi láì sí àsọtẹ́lẹ̀ tí kò sì ní sí ìjìyà kan fún-un. Aboyún lẹ́tọ̀ọ́ sí ìsinmí lẹ́yìn ìbímọ ọlọ́sẹ̀ 14, pẹ̀lú àfikún ìsinmi ọ̀sẹ̀ mẹ́fà lẹ́yìn ìbímọ, tí ó sì lè jù bẹ́ẹ̀ lọ bi àwọn ọmọ ìkókó náà bá ju ẹyọ̀kan lọ tàbí tí àìlera bá wáyé.
A pregnant woman can take leave without prior notice or penalty. She is entitled to 14 weeks of maternity leave, including six weeks after the delivery, with the possibility to extend in the event of complications and multiple births.
Àkọsílẹ̀ òfin 158 náà sọ pé:
A kò gbọdọ̀ yọ àwọn ọjọ́ ìsinmi tí wọ́n làkalẹ̀ nínú Akọsílẹ̀ òfin 148 fún àwọn aboyún, àti àwọn ìgbà tí wọ́n pa ibiṣẹ́ jẹ látàrí àárẹ̀ tí àwọn oníṣègùn tí ó tọ́ ti jẹ́rìí sí kúrò nínú àyè ìsinmi tí wọ́n máa ń gbà gẹ́gẹ́ bí ìlànà.
The rest periods outlined for pregnant women in Article 148 of this Code, and absences due to illnesses that approved physicians duly certify, shall not be deducted from the duration of normal leave.
Ní àfikún sí àwọn òfin tó ń dáàbò bo àwọn obìnrin Orílẹ̀-èdè Togo wọ̀nyìí, àwọn àjọ tó ń jà fún ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin ń jà fìtafìta láti rí i dájú pé àwọn òfin náà fẹsẹ̀ rinlẹ̀ dain-dain.
Awọn Obìnrin tó ń ṣiṣẹ́ òfin àti ní Ẹ̀ka ìdàgbàsókè ní Áfíríkà-Orílẹ̀ èdè Togo (WILDAF-Togo) ni wọ́n ń ṣagbátẹ̀rú ẹ̀tọ́ àwọn obinrin, nípa ṣíṣe àwọn ètò ìfọ̀rànlọ̀ ajẹ́mọ́ ọ̀rọ̀ òfin, àti pípolongo ìmọ̀ kíkún lórí àwọn ẹ̀tọ́ ìbísíi ní àwọn ìgbèríko. Àgbáríjọpọ̀ àwọn Obìnrin fún Àjọ United Nations (AFTNU) ń ran àwọn obìnrin agbègbè Kara lọ́wọ́ láti lè dá dúró nípasẹ̀ yíyá wọn lówó tí kò ní èléwó lórí láti dókòwò, wọ́n sì ń dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ lórí ipò ìdarí nínú ètò òṣèlú. Ọpẹ́lọpẹ́ àjọ “Zéro mariage d’enfants” (Àgbẹdọ̀ Ni Ìgbéyàwó ọmọ tí ò tíì Bàlágà), tí wọ́n ṣe atọ́nà bí àwọn ọmọdébìnrin 200 ṣe lọ sílé ẹ̀kọ́ fún, tí wọ́n sì wọgilé ìgbéyàwó àwọn ọmọdébìnrin 87.
Bíótiwùkíórí, àwọn òfin tó ń dáàbò àwọn obìnrin yìí kò tíì rẹ́sẹ̀ walẹ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn obìnrin ni kò mọ ẹ̀tọ́ wọn, tí wọn ò sì tún rí àyè sí àwọn ìrànlọ́wọ́ tó yẹ. Àwọn ètò tí ìpolongo-ìmọ̀ àti ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ṣe pàtàkì láti rí i dájú wí pé àwọn òfin wọ̀nyìí fẹsẹ̀ múlẹ̀ kí àwọn obìnrin ó ba lè rí àǹfààní tó pọ̀ jẹ.
Emile Bobozi ni ó kọ́kọ́ kọ ìròyìn yìí nínú iṣẹ́ àkànṣe Aspen Global Innovators, Impact West Africa Fellowship.






