
Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Ohùn Àgbáyé (Global Voices) níbi àpérò GV summit ní Kathmandu, Nepal, nínú Oṣù Kejìlá, 2024. Àwòrán láti ọwọ́ Jer Clarke. A gba àṣẹ kí a tó lò ó.
Lónìí, Ohùn Àgbáyé ń ṣe ìfilọ́lẹ̀ ìpolongo ètò ìkówójọ kan láti kó owó tí ó USD 250,000 jọ láti mú kí àwọn ibùdó-ìtakùn tí à ń fi ìròyìn àti ògbufọ̀ wa sí ó wà nígbàdégbà.
Láti ọjọ́ tí ó ti pẹ́, Ohùn Àgbáyé ti ń rí àtìlẹ́yìn láti ọ̀dọ̀ àwọn ilé-iṣẹ́ onínúrere àti àwọn afúninírànwọ́-owó, a sì dúpẹ́ fún àwọn owó tí a rí kó jọ lọ́nà wọ̀nyẹn. Ṣùgbọ́n àwọn owó ìrànwọ́ tí ogunlọ́gọ̀ àwọn ìjọba ń jẹ àǹfààníi rẹ̀ kò jẹ́ kí àwọn ilé-iṣẹ́ tí kì í kó èrè jọ ó jẹ nínú àǹfààní owó náà, tí ó sì jẹ́ wí pé àwọn ilé iṣẹ́ ajìjàgbara ẹ̀tọ́ sí àmúlò ohun-èlò orí ẹ̀rọ-ayélujára bí i tiwa ló ń fara gbá a jù.
Ìgbà líle ni fún àwọn ilé-iṣẹ́ oníròyìn àti ògbufọ̀ lákòókò tí a wà yìí, àgàgà bí àwọn ènìyàn ṣe ń ṣe àmúlò àwọn ohun-èlò ìgbàlódé láti fi dín òṣìṣẹ́ kù, tí ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ tí ò dúró lórí ìwà ọmọlúwàbí iṣẹ́ ìròyìn sì ń pọ̀ ju ìròyìn tí ó jẹ́ ojúlówó lọ. Síbẹ̀síbẹ̀, ìpèníjà yìí kò dí iṣẹ́ ìkọ̀ròyìn Ohùn Àgbáyé lọ́wọ́, níṣe ni àwọn òǹkàròyìn wa túbọ̀ ń lé sí i ni, ṣùgbọ́n látàrí pé a ò gbé owó lórí ojúṣe wa, a ò kí ń fi ìpolówó sórí àwọn ìròyìn tí a bá fi léde, ìgbẹ́kẹ̀lé wa ò ṣẹ̀yìn owó tí àwọn olólùfẹ́ wa ń dá jọ fún wa.
Ilé-iṣẹ́ kéreje tí ò nílò owó rọ̀gùrọ́gú láti ṣe àkóso ojúṣe rẹ̀ ni Ohùn Àgbáyé jẹ́: a ò ní ibi iṣẹ́, a ò sanwó àyè ibi iṣẹ́, yàtọ̀ sí àwọn nǹkan àfojúrí mélòó kan tí a máa ń rà. A máa ń sanwó fún àyè lórí apínṣẹ́ká tí à ń kó ìròyìn wa sí àti àwọn ìnáwó ìṣàkóso mìíràn, ṣùgbọ́n owó tí ó pọ̀ níbẹ̀ jẹ́ èyí tí à ń san fún àwọn òṣìṣẹ́ wa. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó ìrànwọ́ kì í fẹ́ gbé ju ìdá bíntín fún owó-ọ̀yà òṣìṣẹ́ wa lọ, nítorí wọ́n máa ń fẹ́ sanwó àwọn ètò àdáṣe tí wọ́n bá ṣe fún ara wọn, ṣùgbọ́n owó-ọ̀yà òṣìṣẹ́ jẹ́ ohun tí à ń náwó lé lórí jù lọ. Àwọn òṣìṣẹ́ àti àwọn àfínúfẹ́dọ̀ṣiṣẹ́ wa máa ṣe ìwádìí àwọn ìròyìn, wọ́n máa ń kọ ìròyìn, wọ́n á ṣe làméètọ́, wọ́n á ṣe ògbufọ̀ ìròyìn sí oríṣìíríṣìí èdè, bákan náà ni wọ́n ń ṣe agbẹ́nusọ fún ìjìjàǹgbara — nígbà mìíràn ẹ̀wẹ̀wẹ̀, wọ́n máa ń ṣe àtinúdá ìṣọnà àwòrán tàbí yíyàn àwòrán, ìpolongo lórí àwọn gbàgede ìbánidọ́rẹ̀ẹ́, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn tí à ń gbìyànjú láti ṣe àtìlẹ́yìn fún nìyẹn pẹ̀lú owó tí a bá ti ara ìpolongo yìí kó jọ — àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wa, àwọn ènìyàn tí ó ń kọ àwọn àròkọ àti àpilẹ̀kọ, ògbufọ̀, ìjábọ̀ iṣẹ́-ìwádìí, àti àwọn àkásílẹ̀ ohùn tí ẹ̀ ń rí lórí ibùdó-ìtakùn wa.
Bí a bá ń rí owó dọ́là kan lórí ẹni kọ̀ọ̀kan tí ó ka àwọn ìròyìn wa, a ò ní nílò láti ṣe ìkéde ìkówójọ! Bí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn owó dọ́là wọ̀nyẹn bá ń wọlé lóṣooṣu, a ó lè ṣètò ọlọ́jọ́ pípẹ́ sílẹ̀ ní èyí tí yóò mú kí ìdààmú wa ó fẹ́rẹ́. Ṣùgbọ́n a mọ̀ dájú wí pé ìkà ò dọ́gba, nítorí ìdí èyí a wòye wí pé bí ẹnìkan nínú àwọn ènìyàn márùn-ún tí ó bá ń ka àwọn ìròyìn wa lóṣooṣù bá fi dọ́là márùn-ún fún wa, tàbí owó dọ́là mẹ́wàá láti ọwọ́ ènìyàn kan nínú àwọn ènìyàn mẹ́wàá tí ó bá ń ka ìròyìn wa, àbí bóyá ẹni tí ò bá tíì ka ìròyìn wa kankan ní oṣù yìí ṣùgbọ́n tí ó ní ìgbàgbọ́ nínú akitiyan wá bá fi dọ́là márùndínlọ́gbọ̀n ta wá lọ́ọrẹ, àbí bí ẹlòmíràn tí ó fẹ́ràn-an ògbufọ̀ bá fi dọ́là mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ṣọwọ́ àti… mo lérò wí pé ó yé.
A ní ìrètí wí pé o lè jẹ́ ọ̀kan lára àwọn aṣètọrẹ owó wọ̀nyẹn, bí owó bá pọ̀ lọ́wọ́ ẹ, a nírètí wí pé o máa padà wá láti ka àwọn ìròyìn wa, tí wà á sì fọnrere rẹ̀ fún àwọn ẹlòmíràn. A ju ibùdó-ìtakùn ìròyìn lásán lọ, àjọ àwọn ènìyàn jákèjádò dúníyàn ni Ohùn Àgbáyé jẹ́, inú wa yóò sì dùn dẹ́yìn bí ó bá gbárùkù tì wá. A ó máa fi ìpolongo ìkówójọ yìí àti ọ̀rọ̀ nípa Ohùn Àgbáyé lédè lórí àwọn Gbàgede Ìbánidọ́rẹ̀ẹ́, torí náà a rọ̀ ọ́ kí o bá wa ṣe àtúnǹtúnpín àwọn ìfiléde wa kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ó ba mọ ohun tí à ń gbéṣe àti ọ̀nà tí àwọn náà lè gbà kín wa lẹ́yìn. O ṣeun fún àtìlẹ́yìn rẹ!






