Àwọn obìnrin ń léwájú nínú ìjà ìgbógunti ìwá-ipá ajẹmọ́ akọ àti abo ní apá àríwá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà

Àjọ gbogboogbò tí ó ń rí sí ìfopin sí ìfipá-munisìn (NAPTIP), Binta Adamu Bello lọwọ́ ọ̀tún pẹ̀lú Hafsat Muhammad Baba, nígbàtí wọ́n lọ ṣe àbẹ̀wò sí iléeṣẹ́ GIWAC láti leè fọwọ́ sowọ́pọ̀ kojú fifi ipá mú awọn obìnrin sìn. Àwòrán láti ọwọ́  GIWAC, a gba ìyọ̀nda kí a tó lò ó.

Mohammed Ibrahim ni ẹni tí ó kọ́kọ́kọ ìròyìn yìí tí iléeṣẹ́ Peace News Network sì tẹ̀ ẹ́ jáde ní ọjọ́ 5, oṣù Ẹrẹ́nà, ọdún 2025. Ẹ̀dà ìròyìn náà tí a  ṣàtúnkọ rẹ̀ ni Global Voices túntẹ̀jáde nípasẹ̀ àdéhùn àjọṣepọ̀ ìgbéròyìn jáde.

Ní apá Àríwá Orílẹ̀-èdè Nàíjíríà níbi tí àṣà baba-ló-nilẹ̀ ò fún àwọn obìnrin láyè láti ṣe tó, àwọn àjọ tuntun tí àwọn obìnrin jẹ́ aṣáájú wọn ti ń dìde, ṣùgbọ́n ìṣèdásílẹ̀ wọn kìí ṣe láti kojú ìwa-ipá ajẹmọ́ akọ àti abo (GBV) nìkan, wọ́n ń ṣe aáyan lórí ìbágbépọ̀ àlàáfíà àti ìbáṣepọ̀ tó lọ́ọ̀rìn láàárín àwọn èèyàn láwùjọ.

Ó ti pẹ́ tí a ti ń fọwọ́ rọ́ àwọn obìnrin sẹ́yìn níbi àwọn ọ̀rọ̀ tí ó jẹ mọ́ àlàáfíà, níbáyìí, àwọn obìnrin ti ń léwájú. Wọ́n ń ṣagbátẹ̀rú fún ọ̀rọ̀ ìdájọ́ òdodo, wọ́n ń ṣàtìlẹyìn fún àwọn tó ti ní ìrírí ìwa-ipá ajẹmọ́ akọ àti abo, wọ́n sì tún ń ṣí ojú ìwòye àwọn èèyàn àwùjọ sí ìwà ipá abẹ́lé láti jẹ́ kí wọ́n ó túbọ̀ mọ̀ pé ohun tí ó ń mú ìfàsẹ́yìn bá ìlọsíwájú àwùjọ ni.

Ìwà-ipá Ajẹmọ́ Akọ àti Abo gẹ́gẹ́ bí ìdínà fún àlàáfíà

Ìwádìí tí National Bureau of Statistics ti orílẹ̀-èdè Nàíjíríà ṣe ní ọdún 2019 fi hàn pé ìdá 30 nínú àwọn obìnrin ọgọ́rùn-ún tí ọjọ́ orí wọn wà ní 15-49 ni wọ́n ti ní ìrírí ìwà-ipá ajẹmọ́ ìjàmbá ara, tí ìdá 68 sì tí ní ìrírí ìwà-ipá ajẹmọ́ ìbanilọ́kànjẹ́, ìwà-ipá ajẹmọ́ àìrówóná tàbí ìfipábánilòpọ̀.

Hafsat Muhammad Baba, Olùdarì Ikọ̀ àjọ GIWAC. Àwòrán láti ọwọ́ GIWAC, a gba ìyọ̀nda láti lò ó.

Irúfẹ́ ìwà-ipá yìí tí ó ti wọ́pọ̀ láwùjọ kì í ṣe ìtàbùkù ẹ̀tọ́ ọmọniyàn nìkan, ó tùn gbégidínà àlááfíà àwùjọ tó lọ kánrinkése. Hafsat Muhammad Baba, Olùdarí ikọ̀ àjọ GIWAC  ní Kaduna jẹ́ kí ó di mímọ̀ pé “nígbà tí ọkàn àwọn obinrin kò bá balẹ̀, awùjọ náà ò ní lè tòrò,” Ó tún fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé Ọ̀rọ̀ ìfìdí àlàáfíà àwujọ̀ múlẹ̀ ò leè wáyé níwọ̀n ìgbà tí àwọn obìnrin bá ń gbé ilé wọn fọrùn rọ́”

Àwọn àjọ tó jẹ́ ti obìnrin ń di àwọn ààfo ibi tí ìgbófinró kò ti rinlẹ̀ àti àwọn ètò ìjọba tí ò tó, wọ́n sì tún ń pèsè àwọn ètò ìrànwọ́ tí ó ń ṣe arugẹ ìmáradá àti ìlàjà, bí wọ́n ṣe ń lépa kí àyípadà rere ó dé bá àwùjọ tí ìwà-ipá yóò sí di ohun ìgbàgbé.

Ríró àwọn obìnrin lágbára gẹ́gẹ́ bí aṣojú fún àlàáfíà

Olùdarí ikọ̀ àjọ Global Initiative for Women and Children (GIWAC) náà, Baba, sọ wí pé ó pọn dandan láti wá ojútùú sí ọ̀ràn lórí GBV ṣe kókó fún àlàáfíà àwùjọ kánrinkése. Ó tún sọ fún Peace News Network (PNN) pé “a gbọdọ̀ ṣe àrídájú pé a fún àwọn obìnrin ní ànfààní lati ṣe àròyé ẹnu wọn kí ìwà-ipá ó tó di ohun tí apá kò ní ká.”

Àjọ rẹ̀ ń rí sí ìṣègbè fún àwọn èèyàn ní esẹ̀kùkú, ó sì tún ń kọ́ àwọn obìnrin bí wọ́n ṣe lè tètè kẹ́ẹ́fín àwọn àmì ìkìlọ̀ ìwà-ipá, kí wọ́n sì lè tètè ké gbàjarè kó tó di pé yóò burú sí i. Bàbá ṣàlàyé pé:

Àwọn tí wọ́n ti farakááṣá nílò àtìlẹyìn àti bí wọ́n ṣe lè sọ ìríríi wọn láì fòyà. Èyí kìí ṣe nítorí ìdájọ́ òdodo nìkan ṣoṣo; bí kìí ṣe nítorí ìmáradá, ìmúfọkàntán, àti dídá iyì padà bọ̀ sípò.

Ó tún ń ṣe alágbàwí fún ìlọ́wọ́sí àwọn ọkùnrin nínú akitiyan ìwàlálàáfìá àwùjọ kárinkése, ó sì tún jẹ́ kó di mímọ̀ pé lílo agbára ọkùnrin lórí obìnrin àti àwọn ojúṣe kan tí àwùjọ rò pé ó tọ̀nà ni ó ń fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwà-ipá abẹ́lé.

Àwọn ọkùnrin ní láti mọ̀ pé agbára kì í ṣe nípa ìwà-ipá bí kò ṣe nípa ṣíṣe àpọ́nlé àti àjọṣepọ̀ tó gún láàárín akọ àti abo láwùjọ.

Hafsat Muhammad Baba pẹ̀lú àwọn aṣojú fún Gender Awareness Trust (GAT) ní iléeṣẹ́ GIWAC tí àwọn méjèèjì ń ṣíṣẹ pọ̀ láti gbógunti GBV ní Apá àríwá orílẹ̀-èdè Nàíjíríà. GIWAC ni ó ni àwọ̀rán, a lò ó pẹ́lù ìyọ̀nda.

Láti le fìdí akitiyan iṣẹ́ ìgbàwí tí wọ́n ń ṣe múlẹ̀, Baba rọ àwọn olórí ẹ̀sìn àti àwọn lọ́balọ́ba gbogbo láti kó ipa tí ó tópa lórí ọ̀rọ̀ náà.

Ó ní ó yẹ kí mọṣálááṣí, ṣọ́ọ̀ṣì àti àwọn ibi ìpéjọ láwùjọ jẹ́ gbàgede fún ìfọnréré ọ̀rọ̀ àwùjọ tí ìwà-ipá ti di àfì-sẹ́yìn, tí àpọ́nlé àwọn obìnrin ó sì jọba.

Bákan náà ni Baba tún sọ wípé àwọn gbàgede wọ̀nyí lè jẹ́ lílò fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àwọn ọkùnrin lórí ohun tí àwọn ìwé-mímọ́ sọ ní pàtó nípa bíba obìnrin gbé pọ̀ pẹ̀lú àpọ́nlé.

Bíborí àwọn ìdínà ìdájọ́ òdodo àti ìwà-ní-àlàáfíà

Hannatu Ahuwan láti àjọ Legal Awareness for Nigerian Women mẹ́nuba àwọn ìṣòro tí obìnrin máa ń kojú nígbàkúùgbà tí wọ́n bá ń wá ìdájọ́ òdodo.

Ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n tí ó faragbà ìwà-ipá ni wọ́n máa ń ní láti da ẹjọ́ náà nù lẹ́yìn-ò-rẹyìn, èyí tí ó ń mú kí ìbọ́lọ́wọ́ìyà ó tẹ̀síwájú.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti fi Òfin Tó Wọ́gí lé Híhu Ìwà-ipá Sí Ẹlòmíràn (VAPP) lélẹ̀ ní àwọn Ìpínlẹ̀ tó wà ní Àríwá Nàìjíríà, síbẹ̀ àìrídìí múlẹ̀ àwọn òfin yìí jẹ́ ìṣòrò. Ó ṣàlàyé pé, àìsí àwọn ibi ìfisùn fún ọ̀rọ̀ ìwà-ifipábánilòpọ̀; Sexual Assault Referral Centres (SARCs), àfẹ́kù owó, àti àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ ètò ààbò túbọ̀ ń dá kún ìṣòro ìgbógunti GBV.

Ètò ààbò tí kò péye ní àwọn agbègbè náà kò jẹ́ kí ó rọrùn fún wa láti lè ṣiṣẹ́ ní àwọn ibi tí ìwà-ipá sí àwọn obìnrin ti peléke jùlọ.

Ahuwan gbà wípé ètò ìgbèlẹ́yìn GBV tí ó mọ́yànlórí ò ní ṣèrànwọ́ fún àwọn tó faragbà ìwà-ipá akọ àti abo nìkan, yóò túbọ̀ tún so okùn ìrẹ́pọ̀ àti àlááfíà le dain-dain.

Àwọn agbègbè tí ó mú ìgbógunti GBV lókunkúndùn máa ń bí àwùjọ tí ìpẹ̀tù sí aáwọ̀ máa ń wáyé nírọ̀wọ́-ìrọsẹ̀, dípò ìwà-ipá.

Ìgbenusọ lábẹ́ ofin àti ṣíṣe onílàjà gẹ́gẹ́ bi ọ̀nà ìfìdí àlááfíà múlẹ̀

Olúfúnkẹ́ Bámikọ́lé, Alága àwọn Agbẹjọ́rò-bìnrin nílé-lóko; International Federation of Women Lawyers (FIDA), ti ẹ̀ka Kaduna. Àwòrán láti orí Olúfúnkẹ́ Bámikọ́lé.

Olúfúnkẹ́ Bámikọ́lé, Alága àwọn Agbẹjọ́rò-bìnrin nílé-lóko; International Federation of Women Lawyers (FIDA), ti ẹ̀ka Kaduna mẹ́nuba ipa tí ìgbẹnusọ lábẹ́ òfin ń kó láti rí i dájú wípé ìrẹ́pọ̀ tó lọ́ọ̀rìn ó wáyé: Ó ní “àwùjọ tó bá kọ̀ láti dáàbò bo àwọn obìnrin ò lè ní àlàáfíà àti ìrẹ́pọ̀ tó pẹ́ kánrinkése.”

Iṣẹ́ tí FIDA ń ṣe tayọ dídá sí ọ̀rọ̀ àti pípẹ̀tù sí aáwọ̀. Bámikọ́lé ṣàlàyé pé kìí ṣe gbogbo ẹjọ́ ni ó ní láti dé yàrá-ìgbẹ́jọ́”. Bí a bá parí àwọn aáwọ̀ ní tùbí-ǹ-nùbí, àwọn olùfaragbà ìwà-ipá máa ń rí  èyí bí ọ̀nà ìrónilágbára lọ́pọ̀ ìgbà, àwùjọ náà sì máa ń ríi gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà tó rọrùn láti parí aáwọ̀.”

Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àwùjọ, ìjọba àti àwọn ohun ìgbéròyìnjáde fún ìrẹ́pọ̀

Baba, Ahuwan, àti Bámikọ́lé, gbà pé iṣẹ́ tí ó pọ̀ di ọwọ́ àwọn ohun ìgbéròyìnjáde níbi fífi ìròyìn nípa GBV léde. Baba sọ pé, “tí àwọn èèyàn bá ń rí i bí àwọn olùfaragbà ìwà-ipá ṣe borí ọgbẹ́ ọkàn tí ó ti ara ìṣẹ̀lẹ̀ ìbànújẹ́ tí ó ṣẹ̀ wọ́n, èyí yóò jẹ́ kí wọ́n lè ṣakitiyan láti dẹ́kun ìwà-ipá láwùjọ.

Ahuwan rọ àwọn ìjọba láti túbọ̀ gbé àwọn ìgbésẹ̀ tó kájú òṣùwọ̀n lórí mímójútọ́ àwọn ọ̀nà ìrànwọ́ àti láti dìde sí ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ GBV.

Fífẹ ojúṣe àwọn obìnrin lójú nínú aáyan ìrẹ́pọ̀ àti àlàáfíà

Baba ṣàlàyé pé, pẹ̀lú àwọn ìfàsẹ́yìn gbogbo, àwọn àjọ tí obìnrin ń tukọ̀ọ wọn túbọ̀ ń jà fún ìpòo wọn nínú àjọrò tó jẹ ti ìwàlálàáfíà:

Àdámọ́ obìnrin ni láti máa mú kí ìrẹ́pọ̀ ó wà. Wọ́n máa ń ṣe onílàjà nínú ẹbí, wọ́n máa ń parí aáwọ̀, wọ́n sì tún máa ń ṣe ìfilélẹ̀ ìsọ̀kan. Síbẹ̀, wọ́n kìí fún wọn láyè láti kópa níbi àwọn àjọrò tó jẹ ti ìwàlálàáfíà tó kọjá ti abélé.

Ó ní ó yẹ kí wọ́n fún àwọn obìnrin láyè láti dá sí ọ̀rọ̀ ètò-aàbò ìlú, ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn àti òfin ṣíṣe.

Ó ní àwùjọ tí ó ń dáàbò bo obìnrin, tí ó sì tún ń fún obìnrin láyè níbi ṣíṣe òfin tó lapa rere nínú ayé wọn ni a lè rí gẹ́gẹ́ bi àwùjọ tó ní àlàáfíà.

Ìpè fún akitiyan ìfẹsẹ̀rinlẹ̀ àlàáfíà

Gbígbógunti GBV ní apá àríwá orílẹ̀-èdè Nàìjírìà tayọ jíjà fún ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin, ò ń pè fún àlàáfíà àti ààbò tó péye. Wíwà ní àlááfíà ọlọ́jọ́ pípẹ́ kò leè wáyé nígbà tí ìdajì àwọn ará-ìlú túbọ̀ ń kojú ìwà-ipá àti ìṣojúṣàájú.

Bí àwọn àjọ tí obìnrin ń léwáju ṣe ti gbòde yìí, iṣé wọn gbọ́dọ̀ di mímọ̀, mímúgbòòrò, àti àtìlẹ́yìn tó yẹ láti lè fẹsẹ̀múlẹ̀. “Baba sọ pé “Kíkọtí ọ̀gbọìn sí ohùn àwọn obìnrin ti dẹ́kun”. “Ipa wọn láti jà fún òdodo àti ẹ̀tọ́ olórí-òjorí jẹ́ ìjàngbara ọjọ́ iwájú apá àríwà Nàìjíríà fún ìgbòòrò ìrẹ́pọ̀ tí ó fẹsẹ̀rinlẹ̀.”

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.