Ilé-Iṣẹ́ ònímọ̀-ẹ̀rọ tó làmìlaaka nnì, Google kéde wípé àwọn ti ṣe àfikún àwọn èdè ilẹ̀ Adúláwọ̀ 15 sí orí Voice Search, Gboard talk-to-type, àti Translate Dictation lọ́jọ́ 28 Oṣù Ọ̀wàrà. Àwọn èdè tí wọ́n fi kún àwọn ohun èlò ọ̀hún ní èdè Chichewa, Hausa, Igbo, Kikuyu, Oromo, Rundi, Shona, Somali, South Ndebele, Swati, Tigrinya, Twi, Tswana, Nigerian Pidgin, àti èdè Yorùbá.
Àṣeyọrí ńlá yìí yóò fàyè gba àwọn ọmọ ilẹ̀ adúláwọ̀ mílíọ̀nù 300 mìíràn láti máa fi ohùn ẹnu tẹ èdè wọn tí wọ́n bá fẹ́ ṣàmúlò ẹ̀rọ ayélujára. Síbẹ̀síbẹ̀, èyí ṣàfihàn iṣẹ́ ńlá tó kù láti dí àfo àìdógba ìṣàmúlò ẹ̀rọ-ayélujára tí ó wà láàárín ilẹ̀ Adúláwọ̀ àti àwọn àgbègbè mìíràn láàgbáyé.
Ní gbogbo àgbáyé Orílẹ̀ Afíríkà ní orílẹ̀ kejì tí ó ní iye ènìyàn púpọ̀ jùlọ, tí ó sì ní bílíọ̀nù 1.34 ènìyàn. Ìwádìí kan tí Statista tẹ̀ jáde ní oṣù Keje ọdún 2024 ṣàfihàn pé orílẹ̀ Áfíríkà ni orílẹ̀ tí àwọn ènìyàn tí ń sọ onírúurú èdè jù láàgbáyé nítorí pé wọ́n ń sọ èdè tí ó tó 2,158 ní iye. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n sọ ìdá 25 (520) àwọn èdè yìí ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, wọ́n ń sọ èdè 277 ní orílẹ̀èdè Cameroon àti èdè 214 ní Democratic Republic of Congo. Orílẹ̀èdè tí èdè tí wọ́n ń sọ tí kéré jù lọ ní orílẹ̀ Afíríkà ní orílẹ̀-èdè Seychelles, níbi tí wọ́n tí ń sọ èdè mẹ́rin péré.
Lẹ́yìn tí ìkéde náà tí jáde, Alamazan Jak, ònṣàmúlò kan láti ìlú Busoga ní orílẹ̀èdè Uganda, kọ ìsọsí tí ó tẹ́lẹ̀ ọ̀rọ̀ yìí láti fèsì sì ìkéde náà lórí ìkànnì àwùjọ àwọn atúmọ̀-èdè tí ilé iṣẹ́ Google:
Ẹ kú oríire ti ìkéde pàtàkì náà! Ṣíṣe ìfàyègbà fún lílo èdè ilẹ̀ Adúláwọ̀ 13 lórí àwọn ohun-èlò àpèkọ jẹ́ àṣeyọrí ńlá. Ìgbìyanjù yín lórí ìṣafikún àti àìfiyàtọ̀ẹ̀dáṣe gba kí a kan sárá sí i yín.
Ṣùgbọ́n, mo ṣàkíyèsí wípé Lusoga, èdè pàtàkì kan tí wọ́n ń sọ ní agbègbè ilà-oòrùn Orílẹ̀-èdè Uganda kò sí lára àwọn èdè tí ẹ kéde. Gẹ́gẹ́ bí olùsọ̀-èdè Lusoga, mo ń retí kí ẹ ṣe ìṣafikún rẹ.
Njẹ́ ẹ le ṣàlàyé èyíkéyìí ète tí ẹ ń pa tàbí ìgbésẹ̀ tí ẹ ń gbé láti fi èdè Lusoga kún àwọn èdè tí a le fi ṣàmúlò Google Translate? Ìgbìyanjù yín yóò ran àwọn olùsọ-èdè Lusoga lọ́wọ́ púpọ̀
Ẹ ṣeun fún akitiyan yín lórí fífi òpin sí àwọn ìdíwọ́ èdè lílò. N ó máa retí èsì yín.
Ìsọsí yìí ṣàfihàn pé wọn kò ì tíì ṣe ìṣafikún lílo èdè Lusoga àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn èdè ilẹ̀ Adúláwọ̀ mìíràn tòun ti bí àwọn ọ̀nṣàmúlò ṣe ń fẹ́ ìmúdárasíi lílo ẹ̀rọ-ayélujára ní èdè wọn. Lusoga (tí wọ́n tún pè ní Soga) jẹ́ èdè tí iye àwọn ènìyàn tí ó ju mílíọ̀nù mẹ́ta lọ ń sọ ní orílẹ̀-èdè Uganda.
Bí ìmọ̀ tí-kìí-ṣe-tẹ̀dá-ọmọ-ènìyàn (AI) ṣe ń gbòòrò sí i tí ó sì ń di tọ́rọ́-fọ́n-kalé káàkiri àgbáyé ní à ń lò wọ́n láti fi ṣẹ̀dá àwọn ohun èlò tí a fi ń ṣiṣẹ́ lójoojúmọ́, tí èyí sì ń mú kí ìgbé-ayé àti iṣẹ́ siṣẹ́ rọrùn fún àwọn ènìyàn. Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé àwọn tí wọ́n ń lo ẹ̀rọ tí ó ń lò ìmọ̀ tí-kìí-ṣe-tẹ̀dá-ọmọ-ènìyàn ń pọ̀ síi lórílẹ̀ Áfíríkà lójoojúmọ́, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn aṣàmúlò ni kòì tíì le lo àwọn ẹ̀rọ náà ní èdè wọn. Tí à kò bá fi àwọn èdè bíi Soga kún àwọn èdè tí a ń lò láti ṣẹ̀dá àwọn ẹ̀rọ wọ̀nyí ọ̀kẹ́ àìmọye mílíọ̀nù ọmọ ilẹ̀ Adúláwọ̀ ni kò ní le kófà ọ̀pọ̀lọpọ̀ àǹfààní tí ó wà lára lílo ìmọ̀ tí-kìí-ṣe-tẹ̀dá-ọmọ-ènìyàn. Àìṣàfikún yìí yóò túbọ̀ mú kí àìdógba ìṣàmúlò ẹ̀rọ-ayélujára tí ó wà láàárín ilẹ̀ Áfíríkà àti àwọn àgbègbè mìíràn lágbàáyé peléke sí i.
Ìdíwọ́ èdè lílo lórí ẹ̀rọ ayélujára le ṣe àkóbá fún ìdàgbàsókè ètò ọrọ̀ Ajé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orílẹ̀èdè ilẹ̀ Adúláwọ̀ látàrí àìfàyègbà àwọn tí wọ́n sọ èdè abínibí wọn láti le gba iṣẹ́ tàbí ṣe káràkátà lórí ẹ̀rọ-ayélujára. Àìṣàfikún àwọn èdè abínibí ilẹ̀ Adúláwọ̀ nínú ìṣẹ̀dá àwọn ẹ̀rọ ìmọ̀-tí-kìí-ṣe-tẹ̀dá-ọmọ-
Àwọn àǹfààní tó wà nínú ìṣàfikún èdè ní ilẹ̀ Adúláwọ̀
Iṣé ọ̀gbìn ni òpómúleró ètò ọrọ̀ Ajé ilẹ̀ Adúláwọ̀. Ẹ̀ka iṣẹ́ ọ̀gbìn jẹ́ ọ̀kan gbòógì nínú ẹ̀ka tó ń pa owó wọlé sí àpò ìjọba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orílẹ̀èdè ilẹ̀ Adúláwọ̀ jùlọ. Ohun tó ju ìdá 43 iye àwọn ènìyàn ilẹ̀ Adúláwọ̀ tí wọ́n le siṣẹ́ lọ ni wọ́n ń siṣẹ́ ọ̀gbìn ní àwọn ìgbẹ̀ríko. Síbẹ̀, àwọn àgbẹ̀ ń dójúkọ àwọn ìṣòro bíi àìṣedédé ojú-ọjọ́, ìyárabàjẹ́ àwọn èrè oko, àìlená ọjà orí ẹ̀rọ-ayélujára, àìrajaja ètò ọ̀rọ̀ Ajé, àìkàwé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àgbè, àti àwọn nǹkan mìíràn. Ìlò àwọn ẹ̀rọ orí ẹ̀rọ-ayélujára èyí ti a fi ìmọ̀-tí-kìí-ṣe-tẹ̀dá-ọmọ-
Orílẹ̀ Áfíríkà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àṣà àjogúnbá àti ìṣe. Èdè sì ni ọ̀pọ́múléró àwọn àṣà àti ìṣe wọ̀nyí. Èdè dúró gẹ́gẹ́ bíi ohun tí a fi ń pa ìmọ̀ àti àṣà mọ́, ó sì tún jẹ́ ohun tí a fi ń pa àṣà àjogúnbá àwọn ẹ̀yà ènìyàn mo tí a sì fi ń tàn án láti ìran dé ìran.
Bí wọn ṣe rí ìwọ̀n tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdè fi ń kú fìrìfìrì, Àjọ Ìsọ̀kan Àgbáyé (United Nations) kéde ọdún mẹ́wàá láti dáàbò bo àwọn èdè tí wọ́n kú lọ àti àṣà àjogúnbá ọmọ ẹ̀dá ènìyàn tí wọ́n tí fẹ parun lọ́dún 2020. Nǹkan bíi 523 nínú àwọn èdè 3000 tí wọ́n ń kú lọ tí yóò sì kú àkúrun nígbà tí yóò bá fi di ìparí ọ̀rúndún kọkànlélógún ní àwọn ènìyàn ń sọ ní orílẹ̀ Afíríkà. Àìṣàfikún àwọn èdè tí wọ́n ń kú lọ yìí nínú ìṣẹ̀dá àwọn ẹ̀rọ ìmọ̀-tí-kìí-ṣe-tẹ̀dá-ọmọ-
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn oníṣòwò, onímọ̀ ẹ̀rọ, àti onísẹ́ ìwádìí tí wọ́n jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Adúláwọ̀ ni wọ́n tí dìde, tí wọn sì ń gbé ìgbésẹ̀ láti ṣẹ̀ àwọn nǹkan tí ó ń sàfikún àwọn èdè abínibí ilẹ̀ adúláwọ̀ sínú àwọn ohun-èlò ìmọ̀-ẹ̀rọ. Àpẹẹrẹ kan ni ilé-iṣẹ́ tuntun kan ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Awarri, tí ó fẹ́ ṣẹ̀dá ẹ̀rọ ìmọ̀-tí-kìí-ṣe-tẹ̀dá-ọmọ-
Bí àwọn akitiyan yìí ṣe ń lọ láti dí àfo àìdógba èdè, ó yẹ kí a sàfikún àwọn èdè mìíràn, pàápàá jù lọ àwọn èdè tí wọ́n ń sọ ní àwọn àgbègbè tí kò ì tíì sí ìgbésẹ̀ tí ó rinlẹ̀ láti fòpin sí àìdógba ìṣàmúlò ẹ̀rọ-ayélujára. Àwọn ilé-iṣẹ́ onímọ̀-ẹ̀rọ tó ti lààmìlaaka bíi Meta, Amazon, Uber, IBM, AWS àti àwọn ilé-iṣẹ́ mi ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ní ilẹ̀ Áfíríkà ń lo àwọn ohun-èlò ìmọ̀-ẹ̀rọ tí wọ́n ṣẹ̀dá ní ipa láti kó látàrí mímú ìṣafikún àwọn èdè ilé Áfíríkà tí iye olùsọ èdè wọn kò pọ̀ ní ọ̀kúnkúndùn nígbà tí wọ́n bá ń ṣẹ̀dá àwọn ohun-èlò tí wọ́n ń ṣe jáde. Ó yẹ kí àwọn ilé-iṣẹ́ ìbílẹ̀ tuntun àti àwọn ìjọba ìbílẹ̀ fọwọ́sowọ́pọ̀ láti ṣẹ̀dá àwọn ohun-èlò ìmọ̀-ẹ̀rọ tí yóò wúlọ̀ ní àwọn àgbègbè tí akitiyan àwọn ilé-iṣẹ́ àtọ̀húnrìwá kò dé.