
Arábìnrin aráa Togo tó ń wa kùsà. A mú àwòrán nàá láti inú fọ́nrán tó dá lóri “Àwọn obìnrin Áfíríkà tí wọ́n ń wa kùsà” ní L’écologiste Infos YouTube channel.
Wíwa kùsà jẹ́ iṣẹ́ tí ọ̀pọ̀ èèyàn kà sí isẹ́ ọkùnrin torí àwọn ọkùnrin ló wọ́pọ̀ nídìí ẹ. Àmọ́, àwọn obìnrin ti pọ̀ nídi iṣẹ́ yìí bí ó ṣe ń gboòrò si.
Ní gbogbo àgbàyé, Áfíríkà ló ní àwọn ohun àlùmọ̀nì tó pọ̀ jùlọ. Ìdá 50 nínú gbogbo ohun àlùmọ́nì àgbáyé ni ó wá láti ilẹ̀ Áfíríkà. Àwọn ohun àlùmọ́ní yìí ló sì pe àkíyèsí àwọn ògbóntarigì awakùsà lókè òkun tí wọ́n n wá bí wọ́n ṣe máa gboòrò ní àwọn orílẹ̀ èdè tí ó ń lo wíwa kùsà gẹ́gẹ́ bi ọ̀nà kan gbòógì fún ètò ọ̀rọ̀ ajé wọn.
Aïssatou Fofana, akàròyìn tó níi ṣe pẹ̀lú àyíkà ní Ivory, ṣe àgbàsílẹ̀ ìròyìn ipa ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin ilẹ̀ Áfíríkà tí wọ́n ń ṣíṣẹ́ yìí nínú fọ́nrán ìròyìn rẹ̀ àkọ́kọ́. Àkásílẹ̀ ìròyìn yìí dá lórí bí nnkan ṣe ń lọ ní Côte d'Ivoire àti Togo. Kàkà kí òun náà tẹ̀lé èrò àjògúnbá lóri pé àwọn ọkùnrin ni ó ń ṣe iṣẹ́ yìí, Aïssatou Fofana fi ọrọ wérọ̀ pẹ̀lú àwọn obìnrin yìí ó sì ká fọ́nrán wọn sílẹ̀ bí wọ́n ṣe ń sọ ìrírí wọn lọ́lọ́kan-o-jọ̀kan
Nínú ìfọ̀wọ̀wérọ̀ pẹ̀lú Global Voices lórí WhatsApp, agbaròyìn-káròyìn silẹ́ nàá sọ̀rọ̀ nípa ìrírí rẹ̀ àti àwọn ìdí abájọ tí ó fi dáwọ́ lé ìròyìn àwọn obìnrin yìí.
Jean Sovon (JS): Kílódé tí o fi ká ìròyìn nípa àwọn obìnrin tó ń wa kùsà ní ilẹ̀ Áfíríkà sílẹ̀? Báwo ni o ṣe mọ̀ nípa èyí?
Aïssatou Fofana (AF) : Ce film a été réalisé dans le cadre du projet final du programme de Bourse consacrée aux médias et aux créateurs de contenu de l'Union africaine. On devait faire un choix entre diverses thématiques proposées dans le cadre de la bourse et réaliser un projet. Cela pouvait être un film documentaire, un article de presse (dossier), des émissions radio, des podcast….
Mon choix s’est porté sur les femmes de ce secteur. J'avais remarqué qu'on entendait pas beaucoup parler d'elles dans les médias, alors qu'elles participent à leur niveau, au développement de socio-économie de leur pays. C'est en cela que mon choix s'est porté sur la Côte d'Ivoire et le Togo. Voilà un peu comment se situe le contexte du choix de ce sujet là.
Aïssatou Fofana (AF):
Mo ṣe àgbàsílẹ̀ ìròyìn yìí fún iṣẹ́ àkànṣe African Union Media Fellowship Programme project. Á ní láti parí iṣẹ́ àkànṣe wa lórí ọ̀kan nínú àwọn irúfẹ́ àkòrí ọ̀rọ̀ tí àjọ yìí là kalẹ̀. Iṣẹ́ àkànṣe yìí lè jẹ́ gbígba ìròyìn-káròyìn silẹ́, ìròyìn ọlọ́rọ̀ geere, ìròyìn orí ẹ̀rọ agbóhùnsáfẹ́fẹ́, tàbí ètò alanilọ́yẹ̀ kékéèké…
Mo mú ọ̀rọ̀ àwọn obìnrin tó ń wa kùsà nítorí a fẹ́rẹ̀ má tilẹ̀ gbọ́ ohunkóhun nípa wọn nínú ìròyìn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ipa wọn nínú ìdàgbàsókè ètò ọrọ̀ ajé àti àwùjọ kò kéré. Nítorí náà ni mo ṣe gbájú mọ́ àkòrí ọ̀rọ̀ yìí bí ó ṣe rí ní Côte d’Ivoire àti Togo.
Nínú abala àkọ́kọ́ gbígba iròyìn alálàyé yìí sílẹ̀, àwọn obìnrin tó ń wa kùsà ní Côte d’Ivoire sọ nípa iṣẹ́ wọn:
JS: Kí ni àwọn ìṣòro tí àwọn obìnrin wọnyìí ń dojúkọ lẹ́nu iṣẹ́ yìí ní pàtó? Ojú wo ni àwọn ọkùnrin akẹgbẹ́ wọn àti àwùjọ lápapọ̀ fi ń wò wọ́n?
AF: Le premier défi qui me vient à l’esprit, c'est le fait d'évoluer dans un secteur qui est à majorité dominé par les hommes. Vous pouvez comprendre que c'est pas vraiment évident d'évoluer dans un tel domaine, surtout si la plupart d’entre eux ont une vision “traditionnelle” ou “patriarcale” de la femme dans la société : celle dont la place est d’emblée à la cuisine ou encore à la maison à s’occuper de son époux et de ses enfants. Cela occasionne des frictions pour celles qui s’y aventurent.
Le second challenge est au niveau de la famille. Si elle est mariée et a des enfants, c'est sûr qu'il va falloir faire la part des choses et vraiment s'organiser pour pouvoir travailler convenablement pour que son travail n'empiète pas sur sa famille. C’est dans ce type de contexte qu’avoir un partenaire de vie compréhensif et ouvert tient tout son sens ! Car sinon, ce serait un problème de plus auquel il faudra faire face au quotidien.
En général, les informations sont limitées sur ce milieu, en particulier celles sur les femmes qui y travaillent; d'où mon intérêt sur cette question. L’idée était de réaliser un documentaire afin de lever un coin de voile sur ce qu'elles font, les réalités qu'elles traversent, comment elles font face à ces défis et comment elles arrivent aussi à faire carrière dans ce secteur dit d’hommes.
AF:
Ìdojúkọ àkọ́kọ́ tò sọ sí mi lọ́kàn ni èyí tó ní ṣe pẹ̀lú akitiyan láti ní ìlọsíwájú nídi iṣẹ́ tí ọkùnrin ti wọ́pọ̀ jùlọ. Ẹ máa ri pé ó nira púpọ̀ fún obìnrin láti kógo já nínú irúfẹ́ iṣẹ́ yìí pàápàá jùlọ láàárín awùjọ aláṣà ọkùnrin-ló-nilẹ̀, níbi tí àṣà ti jẹ́ kí wọ́n rí obìnrin gẹ́gẹ́ bi abiyamọ àti olùtọ́jú ilé lásán. Àṣà yìí jẹ́ okùnfà ìfàsẹ́yìn fún obìnrin láti ṣe nǹkan tuntun to tayọ.
Ìdojúkọ kejì níí ṣe pẹ̀lú àwọn ẹbí wọn. Bí irúfẹ́ obìnrin náà bá ti wà nílé ọkọ tí ó si ti bímọ, ó ní láti wa bí yóò ṣe lè ṣe déédéé láàárìn isẹ́ àti ẹbí tí ọ̀kan kò sì ní pa ekèjì lára. Ó rọrùn púpọ̀ bí irú obìnrin bẹ́ẹ̀ bá ní ọkọ tó mọyì, bí bẹ́ẹ̀kọ́, èyí ni iṣòro tí yóò máa fi ojoojúmọ́ rán.
Ìròyìn péréte ni àwọn eèyàn ń gbọ́ nípa iṣẹ́ yìí, pàápàá jùlọ nípa àwọn obìnrin tó wà nibẹ̀, èyí gan-an ni ó túbọ mú àkòrí ọ̀rọ̀ yìí ká mi lára. Mo fẹ́ ṣe àgbàsílẹ̀ iròyìn alálàyé tí yóò tan ìmọ́lẹ̀ sí ohun tí wọ́n ń ṣe ní pàtó, àwọn ìdíwọ́ wọn, bí wọ́n ṣe ń kojú àwọn ìdojúkọ yìí, àti bí wọ́n ṣe n gboòrò nídi iṣẹ́ tí gbogbo eèyàn lérò pé ọkùnrin nìkan ló lè ṣe é yìí.
JS: Kíni pàtó ohun tí àwọn obìnrin ń ṣe nídi iṣẹ́ yìí? Njẹ́ Ẹnjiníà lásán ni wọ́n ni àbí àwọn náà ń wa kùsà?
AF: Dans le film documentaire, les femmes interviewées exercent à différents niveaux, et selon leur domaine d’expertise au sein de leurs sociétés de mines. Dans la société de mine d’Ity en Côte d’Ivoire, Laetitia Gadegbeku Ouattara est la directrice Pays d'Endeavour Mining ; Carine Kouko est géologue de production sénior ; Kadidiatou Diarra, est géologue d’exploration junior ; et Marthe Bertine Yavo est superviseur camp et voyage.
Quant aux femmes du Togo, Rosine Atafeinam Abalo est Dr en géologie et géotechnique et chargée d'investissement à Togo Invest. Dotse Akouavi Jeannette et Aladouadjo Belam, sont toutes deux sont des conductrices d’engins lourds appelés dumper.
AF:
Àwọn obìnrin tí mo fi ọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò nínú ìròyìn alálàyé tí mo ká silẹ̀ yìí ni wọ́n di ipò oríṣiríṣi mú, ní àwọn ẹ̀ka tí wọ́n ti jẹ́ akọ́sẹ́mọsẹ́ ní àwọn iléeṣé tó ń wa kùsà lọ́lọ́kan-ò-jọ̀kan. Ni Côte d’Ivoire’s La Société des Mines d’Ity (Ity Mining Company), Laetitia Gadegbeku Ouattar jẹ́ alákoso gbogboogbò ní Endeavour Minning; Carine Kouko jẹ́ onímọ̀ ìjìnlẹ̀ àgbà nínú ṣíṣe ètò àwọn ohun àlùmọ́nì; Kaddiatou Diarra jẹ́ olùṣàwárí ohun àlùmórì kekere ti Marthe Bertine Yavo sì jẹ́ alákoso ibùdó àti ìrìnàjò.
Ní ti àwọn obìnrin tó wà ní Togo, Rosine Atafeinam Abalo jẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́-gboyè àgbà nínú imọ̀ Jiọ́lọ́jì àti Geotechnics, ó sì tún jẹ́ alákoso fún Togo Invest. Dotse Akouavi Jeanette àti Aladouadjo Belam jẹ́ awakọ̀ ọkọ̀ ńlá tí àwọn olóyìnbó ń pè ní dumpers.
Nínú abala kejì ìròyìn alálàyé yìí, àwọn obìnrin aráa Togo tí Aïssatou Fofana fi ọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò sọ ìrírí wọn àti àwọn àkùdè tí wọ́n ní láti kojù kí wọn tó le máa ṣiṣẹ́ bíi awakùsà àti bí wọ́n ṣe ṣe àṣeyọrí:
JS: Kílódé tí wọ́n ń ṣe irúfẹ́ iṣẹ́ yìí? Ṣé wọ́n ń rí owó tó pọ̀ níbẹ̀ yàtọ̀ sí àwọn isẹ́ míràn ni?
AF: Au cours de mes entretiens, jamais ces femmes n'ont parlé du fait que c'était un métier mieux payé que d'autres métiers ou un métier qu’elles voulaient pour pouvoir être riche, avoir beaucoup d'argent. C'est un secteur qui les a attirées et elles voulaient faire carrière là-bas. C'est cette motivation et cette passion qui a déterminé leur choix et elles ont tout fait pour intégrer ce secteur et y évoluer. Donc ce n'est pas pour des raisons financières.
Est-ce que ce secteur est mieux payé que d'autres, je ne saurais le dire parce que je n'ai pas focaliser mon travail sous cet angle et je n'ai même pas eu à poser cette question. Ce qui m'intéresse, c'est le parcours, les challenges qu'elles ont traversés, comment elles ont pu relever ces défis et comment elles continuent d'évoluer dans ce secteur là malgré tous ces problèmes auxquels elles ont fait face.
Elles n’ont également pas fait mention de ce que c’était un métier mal payé. Ce que je peux vous assurer, c’est qu’elles sont épanouies et heureuses de leur choix de carrière.
AF:
Nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tí mo ṣe, àwọn obìnrin yìí ò sọ pé iṣẹ́ yìí ń sanwó ju àwọn iṣẹ́ míràn lọ tàbí pé ó jẹ́ iṣẹ́ tí ó ń sọ eèyàn di olówó tabua. Wọ́n kàn nífẹ̀ẹ́ láti ṣe iṣẹ́ yìí kí wọ́n sì gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ nídìí ẹ̀ ni. Ìpinnu yìí ni ó gún wọn ní kẹ́ṣẹ́, tí wọ́n sì fi sa gbogbo agbára wọn láti ṣe iṣẹ́ náà tí wọ́n sì ń gboòrò si. Nítorí náà, kìí ṣe nítori owó rárá.
N kò tilẹ̀ lè sọ bóyá iṣẹ́ yìí ń mú owó wá ju àwọn iṣẹ́ míràn lọ nítorí n ò fi ojú ibẹ̀ wo ọ̀rọ̀ náà rárá. N ò tilẹ̀ beèrè ìbéèrè tó jọ bẹ́ẹ̀. Ohun tí ó jẹ mí lógún ni bí iṣẹ́ wọn ṣe ń lọ, àwọn ìdojúkọ tí wọ́n ń kojú, bí wọ́n ṣe ń kojù wọn àti bí wọ́n ṣe ń ní ìlọsíwájú lẹ́nu iṣẹ́ náà pẹ̀lú bí ìṣòro náà ṣe pọ̀ tó.
JS: Njẹ́ iléeṣé tí àwọn obìnrin yìí ti ń wa kùsà yìí jẹ́ ti ìjọba gbogboogbò, ti ilẹ̀ okèèrè tàbí èyí tí kò tọ̀nà lábẹ́ òfin? Ǹjẹ́ àwọn obìnrin yìí ní ìgbìmọ̀ ti wọn?
AF: Les sites miniers que j’ai visités sont légalement constitués. Le Société des Mines d'Ity est en activité depuis 1991. L’État ivoirien y est actionnaire à 10% et la Société des Mines, à 5%, et les 85% sont détenus par Endeavour Mining. Les femmes ont également leurs associations. En Côte d’Ivoire, au niveau national, il y a le Réseau des Femmes du Secteur Minier de Côte d’Ivoire (FEMICI), et He For She Mines Côte d’Ivoire. Au niveau de la Société des mines d'Ity, il y a l’Association des Femmes des Mines de Ity(AFEMI). Au Togo, l’Association des Femmes du Secteur Minier ou en Entreprise du Togo (AFEMET) existe au niveau national. Mme Rosine Atafeinam Abalo, l’une des femmes que j’ai interviewée, en est la présidente.
Au niveau africain, l’AWIMA (Association of Women in Mining in Africa) le réseau d’organisations et d’associations nationales de femmes africaines dans les secteurs de l’exploitation minière, du pétrole et du gaz.
Au niveau international, les prix WIN100 récompensent les 100 femmes qui sont pionnières, qui apportent des changements positifs et significatifs pour que le secteur minier puisse fonctionner de manière responsable, durable et inclusive.
AF:
Àwọn iléeṣẹ́ tó ń wa kùsà tí mo lọ ló tọ̀nà lábẹ́ òfin tí wọ́n sì fi orúkọ sílẹ̀ lábẹ́ ìjọba. La Société des Mines d'Ity ti wà láti ọdún 1991. Ìjọba Ivory ní ìdá 10 nínú ìpín ìkòwò náà, ìdá 5 jẹ́ ti la Société des Mines, tí Endeavour Mining sì kó ìdá 85. Àwọn obìnrin ní ẹgbẹ́ bákan náà. Ní Côte d’Ivoire, wọ́n ní ẹgbẹ́ gbogboogbò bíi Mining Sector Women’s Network ( FEMICI) àti He For She Mines Côte d’Ivoire La Société des Mines d’Ity ní Association des Femmes des Mines d'Ity (Association of the Women Miners of Ity or AFEMI). Ní Togo, wọ́n ní ẹgbẹ́ gbogboogbò tó ń jẹ́ Association des Femmes du Secteur Minier ou en Entreprise du Togo (Association of the Women Miners and Entrepreneurs of Togo or AFEMET), , èyí tí Rosine Atafeinam Abalo, ọ̀kan nínú àwọn tí mo fi ọ̀rọ̀ wá lẹnu wo jẹ́ aàrẹ wọn.
Ní Áfíríkà, ẹgbẹ́ bíi Association of Women in Mining in Africa (AWIMA), èyí tó jẹ́ àgbáríjọ̀ ẹgbẹ́ gbogboogbò fún àwọn obìnrin ilẹ̀ Áfíríkà tó ń wa kùsà, àwọn tó ń wa epo àti afẹ́fẹ́ ìdáná.
Ní òkè òkun, the WIN100 Awards mọ rírì àwọn obìnrin 100 àkọ́kọ́ tí wọ́n mú ìyípàdà tó lóòrìn bá iṣẹ́ wíwa kùsà, tí wọ́n n ṣé iṣẹ́ yìí ní ọ̀nà tó tọ̀ àti èyí tó ń mú-un gbèèrú si.
JS: Kí ni ìlànà àtẹ̀lé tí ó jẹ mọ́ àyíká tí àwọn ilé iṣẹ́ yìí ní?
AF: Les sites miniers que j'ai visité en Côte d'Ivoire au Togo sont légalement constitués, avec le respect des consignes de sécurité pour entrer sur les sites. La société des Mines d'Ity par exemple, à un axe environnement et développement durable dans sa politique de gestion. Nous avons également pris part à un planting d’arbres lors du tournage du film.
AF:
Àwọn iléeṣé ìwakùsà tí mo lọ ní Côte d'Ivoire àti Togo ni wọ́n fi orúkọ sílẹ̀ lábẹ́ òfin tí wọ́n sì ní àwọn ìlànà wọn lọ́lọ́kan-ò-jọ̀kan. Bí àpẹẹrẹ, La Société des Mines d'Ity ní ìlànà tó de ìdàgbàsókè àti ìmúgbòòrò àyíká ńinú àwọn ìlànà wọn. A tún gbin àwọn igi nígbà tí à ń ká ìròyìn alálàyé yìí sílẹ̀.
Nínú iṣẹ́ tí ó ń gbeèrú tí ó sì túbọ̀ ń gòkè òdò yìí, àwọn obìnrin ilẹ̀ Áfíríkà ń gba aàyè wọn ní dọ́gba-dọ́gba pẹ̀lú àwọn ọkùnrin.