
Àwọn afẹ̀hónúhàn dúró pẹ̀lú àsia orílẹ̀-èdè Algeria àti ti Amazigh nílùú Tizi Ouzou, Algeria. Àwòrán láti ọwọ́ Kader Houali, ìlò pẹ̀lú àṣẹ.
Láàárọ̀ ọjọ́ Ẹtì kan ní àsìkò ọ̀gbẹlẹ̀ ọdún 2019, obìnrin kan tí ó dá wà rìn kọjá ní àárín Algiers, ó rìn níwájú ọ̀wọ́ àwọn ọlọ́pàá kan, ó sì kígbe fún ìyọnípò ọ̀gágun ìgbà náà Ahmed Gaid Salah, tí ó ti di olóògbé báyìí — ní wákàtí díẹ̀ ṣáájú ìrìn-tako ìjọba tí ó wáyé ní ọ̀sán ọjọ́ náà..

Wọ́n fi òfin de àsiá Amazigh ní Algeria ní oṣù kẹfà ọdún 2019.
Ní ìbẹ̀rẹ̀ àsìkò ẹ̀ẹ̀rùn yẹn, ní oṣù kẹfà ọdún 2019, Gaid fòfin de àsiá Amazigh tí ó jẹ́ ti àwọn ará Kabyle Berbers, tí a mọ̀ sí àwọn Amazigh. Lẹ́yìn òfin yìí, wọ́n mú ọ̀pọ̀ àwọn afẹ̀hónúhàn fún mímì ín lẹ́gbẹ̀ẹ́ àsiá orílẹ̀-èdè nígbà ìfẹ̀hónúhàn Hirak tí ó gbajúmọ̀ ní oṣù kejọdún 2019 fún àtakò wọn sí ààrẹ ìgbà náà Abdelaziz Bouteflika fún gbígbé igbá ìbò fún sáà karùn-ún.
“Obìnrin yìí gbóya láti kojú ohun méjì: Wọ́n máa ń fòfin mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ní òwúrọ̀, kò sì sí ẹni lè sọ̀rọ̀ nípa Gaid,” gẹ́gẹ́ bí Meziane Abane, akọ̀ròyìn tí ó ya obìnrin náà ṣe sọ. Ó gbé fídíò náà sí ìkànnì ibùdó ìròyìn rẹ̀ L'Avant-Garde Algérie lórí Facebook, (àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Algeria dí ibùdó ayélujára náà pa).
Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀ tí ó gbé e sí ìkànnì Facebook, oríṣìíríṣi èébú bẹ̀rẹ̀ sí í jáde, àwọn èsì bí i “Ìwọ ni àlòkù France,””France ni ó bí ẹ,” àti “ọmọ France” gba gbogbo ààyè ìfèsì kan. Ní ọjọ́ kan ṣoṣo, àwọn tí wọ́n wo fídíò náà tó mílíọ̀nù kan, ó sì ní tó èsì mílíọ̀nù mérin.
Àwọn ará Kabyles máa ń ní nǹkan ṣe pẹlú France tí ó kó Algeria lẹ́rú tẹ́lẹ̀. Àwọn tí wọ́n ń wájà lórí ayélujára máa bú àwọn tí wọ́n ti Kabyles wa pé wọ́n ń fa ìpínyà wọ́n sì ń dúnrun mọ́ “ìṣọ̀kan orílè-èdè”.
Abane sọ nínú ìfọrọ̀wọ́rọ̀ orí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ pẹ̀lú Global Voices pé “Ìgbà yìí ni mo tó mọ agbára [àwọn tí wọ́n ń wájà lórí ayélujára yìí], mò ń bi ara mi pé ìgbà wo ni wọ́n máa dánu dúró? Tàbí ṣé wọ́n máa dánu dúró? Wọ́n dánu dúró ni aago mẹ́fà àárọ̀!”
Abane fúnrarẹ̀ wá láti ìlú Bouïra ní Kabylie, ìlú olókè tí ó ń pààlà láàárì òkun Mediterranean àti ilẹ̀ àwọn ará Amazigh. Àwọn èsì náà — tí ó gbilẹ̀ nínú ogun ìṣèlú — ń dójú sọ àwọn ajìjàngbara Kabyle pẹ̀lú ohùn wọn tí ó kún fún ìṣẹ̀yàmẹyà.
Ilẹ̀ Kabylie ni ó ti jẹ́ gbungbun ibi ìfẹ̀hónúhàn Hirak jù. Lẹ́yìn tí Bouteflika fi ipò sílẹ̀ ní oṣù kẹ́rin, ẹgbẹ́ náà tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìfẹ̀hónúhàn ní gbogbo ọjọ́ Ìsẹ́gun àti ọjọ́ Ẹtì láti béèrè fún àtúntò ètò ìṣèjọba (títi di oṣù Kẹ́ta, tí wọ́n ‘sinmi’ fún ọ̀rọ̀ ìlera gbogboògbò látàrí ọ̀rọ̀ COVID-19).
Ní oṣù kejìá, àwọn ajìjàǹgbara Hirak yẹra fún ìdìbò orílẹ̀-èdè. Bí ìdá 40 nínú gbogbo orílẹ̀-èdè ni ó dìbò, ó sì hàn pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ibi ní Kabylie ni wọn ò ti dìbò rárá.
Ìṣẹ̀yàmẹyà sí àwọn ajìjàǹgbara àti àwọn ọmọ ilẹ̀ Kabyle yìí kò jẹ́ tuntun, ṣùgbọ́n ó tún ṣẹ̀ṣẹ̀ peléke sí i ní ọdún 2019, gégẹ́ bí Abane ṣe sọ.
.
Ìtàn bí èébú ‘zouave’ ṣe bẹ̀rẹ̀

Zouave ará Algeria, tí ó jẹ́ ọmọ ogun àwọn Faransé, ọdún 1886, láti inú ọ̀wọ́ àwọn ajagun (N224) tí ilé-iṣẹ́ Kinney Tobacco gbà láti polówó sìgá Sweet Caporal. Àwòrán láti Wikimedia Commons nípasẹ̀ Ilé-iṣ̣ẹ̣́ Kinney Brothers Tobacco / C.C.0.
Wọ́n rán akọ̀ròyìn ará Algeria Khaled Drareni, tí ó ṣe ìyàwòrán ìjìjàǹgbara lọ sẹ́wọ̀n oṣù méje ní oṣù kẹ́rin fún ẹ̀sùn ìdárúgúdù sílẹ̀ àti “Ìṣàtakò ìṣọ̀kan orílẹ̀-èdè”. Ó sọ fún Global Voices nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ kan lọ́dún tó kọjá pé ìyàwòrán Hirak rẹ̀ fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ èsì “àdàkọ” tí ó ń fẹ̀sùn kàn án pé ó ń ṣiṣẹ́ fún orílẹ̀-èdè France, pé àwọn èèyàn Faransé ń sanwó fún, wọ́n sì ń pè é ni zouave.
Ouissal Harize tí ó jẹ́ akékọ̀ọ́ PhD ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga Durham, tí ó ń ṣèwádìí ìwà ìpá gẹ́gẹ́ bí ìpìlẹ̀ Ìmúnisìn ní Algeria sọ̀rọ̀ ní pa ọ̀rọ̀ náà pé, zouave túmọ̀ sí ọ̀wọ́ àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Algerian tí wọ́n wá láti Kabylie tí àwọn ará France gbà síṣẹ́ nígbà tí wọ́n gbàjọba Algeria, láti jẹ́ ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ ẹ̀ka iná àwọn ajagun orí ilẹ̀ tí ó ń ṣiṣẹ́ fún àwọn ajagun Faransé láti ọdún 1830.
Àwọn àkọsílẹ̀ tí ó takora wà lórí ìtumọ̀ ìpìlẹ̀ ọ̀rọ̀ náà. Harize tọ ìpasẹ̀ rẹ̀ ló sídìí ọ̀rọ̀ Kabyle izouf tí ó túmọ̀ sí “jíju nǹkan.” Ṣùgbọ́n ó tún ní ọ̀rọ̀ náà lè wá láti inú àṣìsọ ọ̀rọ̀ lárúbáwá kan agawaw — tí ó jẹ orúkọ orílẹ̀-èdè àwọn ẹ̀yà Kabyle.
Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ní àwọn ọdún 1860s, àwọn ajagun mìíràn náà sọ àwọn ajagun orí-ilẹ̀ wọn ní zouave. Àwọn ayàwòrán Europe bí i Vincent Van Gogh yan orúkọ náà zouave gẹ́gẹ́ bí orúkọ àwòrán rẹ̀ tí ó gbajúmọ̀.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdí wíwà àwọn ara Kabyle láàárín àwọn ajagun Faransé hàn gedengbe, “àwọn kan wọ́n ti ń fi ọ̀rọ̀ náà sọ gbogbo àwọn ọmọ Kabyle lẹ́nu, wọ́n sì ti ń lò ó gẹ́gẹ́ bí ohun èlò ìṣẹ̀yàmẹyà,” Harize ṣàlàyé.
“Ogun náà ti wà látilẹ̀” láàárin àwọn ará Arabù àti àwọn ajìjàǹgbara Amazigh, gẹ́gẹ́ bí Nacer Djabi, tí ó jẹ́ Ọjọ̀gbọ́n nínú ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ àwùjọ ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga Algiers ṣe ṣàlàyé:
Àwọn ará Arabù ń pe àwọn ará Kabylie ní zouave láti sọ pé wọ́n faramọ́ ìjọba ìmúnisìn láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀, [láti lè] fa ìrújú fún àwọn ará Kabyle tí wọ́n ń fi ara wọn hàn gẹ́gẹ́ bí aṣàtúnṣe lásìkò ogun tí wọ́n jà fún òmìnira. Ìṣèdàrúdàpọ̀ ìtàn fún ọ̀rọ̀ òṣèlú òde-òní ni èyí.
‘Ọ̀rọ̀ Ìkórìíra gidi‘
Lónìí, àwọn aṣàtakò ń so ìtumọ̀ Zouave mọ̀ ìtàn yìí wọ́n sì ń gbìmọ̀pọ̀ dìtẹ̀ pé “ará Faansé mọ́ Berber kan tí ó gbajúmọ̀ tí ó ń fẹ́ ni í ni ó ń darí ìfẹ̀hónúhàn Hirak,” gẹ́gẹ́ bí Redouane Boudjema, ọ̀jọ̀gbọ́n Mídíà àti Ìbánisọ̀rọ̀ ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga Algiers ṣe sọ.
Boudjema sọ pé wọ́n ti fi ìsọkiri irọ́ ṣe ìba lórúkọ jẹ́ orúkọ àwọn ẹni jànǹkan inú ìtàn tí wọ́n jẹ́ ará Kayble, bí i Hocine Aït Ahmed, tí ó jẹ́ apàṣẹ àwọn ajagun àkọ́kọ́ tí ó bá àwọn ìjọba amúnisìn jà, ó sì wà lára ìjọba àkọkọ́ lẹ́yìn òmìnira kí ó tó di pé ó fẹ̀yìntì tí ó sì ṣẹ̀dá ẹgbẹ́ òṣèlú aṣàtakò Algeria àkọ́kọ́.
Boudjema ṣàlàyé pé:
Ìròyìn irọ́ nípa ìtàn Algeria ni wọ́n fi ń ṣe àgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ ìkórìíra tako ẹ̀yà kan [Kabylie], tí ó ti máa ń ṣíwájú nínú ọ̀rọ̀ ìjọba alágbádá.
Ní ọdún tó kọjá, ìjọba tí ó wà níbẹ̀ ti lo ọ̀rọ̀ tí ó ń tako Kabyle gẹ́gẹ́ bí ohun èlò láti gba agbára lọ́wọ́ àwọn afẹ̀hónúhàn Hirak.
Wọ́n rí “Ìṣe-Amazigh” gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọ̀n ìdánimọ̀ jíjẹ́ ọmọ Algeria nínú ìwé òfin, àwọn aláṣe sì ti gbé ìgbésẹ̀ ní àwọn ọdún díẹ̀ sẹ́yìn láti mú àṣà Amazigh wọ̀ ọ́: Wọ́n fi Tamazight lọ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí èdè orílẹ́ èdè ní ọdún 2016, wọ́n sì fi oṣù àkọ́kọ́ nínú ọdún Amazigh— yannayer — ṣe àsìkò ìsinmi ní ọdún 2018.
Pẹ̀lú gbogbo èyí, ní oṣù Kẹfà 2019 bí àwọn afẹ̀hónúhàn Hirak ṣe ń kọ́wọ̀ọ́rìn, Gaid ṣíjú lé àwọn ará Amazigh nípa fífi òfin de ìlò àsiá wọn tí ó sì ń fòfin mú gbogbo àwọn tí ó bá gbé e hàn.

Àwọn afẹ̀hónúhàn kọ́wọ̀orìn ní títì pẹ̀lú àsia Amazigh lọ́wọ́ nílùú Tizi Ouzou, Algeria. Àwòrán láti ọwọ́ Kader Houali, ìlò pẹ̀lú àṣẹ.
Kader Houali, tí ó jẹ́ agbẹjọ́rò àti ajàfẹmtọ̀ọ́ ọmọnìyàn láti ìlú Tizi Ouzou ní Kabylie sọ pé“Ìyàsọ́tọ̀ àwọn ará Kabylie ti wà dáadáa kí ó tó di ọjọ́ 22 Osù Kejì, ó sì ti wà ní ìpele gíga,” ó ń ṣàfihàn bí ó ṣe pẹ́ tó kí wọ́n tó fi èdè wọn kún èdè orílẹ̀-èdè. Ó fi kún un pé irú ìyàsọ́tọ̀ yìí ń wáyé ní àwùjọ àti nínú ìjọba, àti àwọn èèyàn tí ó gbajúmọ̀ kan àti àwọn akọ̀ròyìn kan ni ó ń dáná sí ọ̀rọ̀ náà.
Houali, àti àwọn agbẹjọ́rò méjì mìíràn, kọ̀wé ẹ̀sùn kan tako Naima Salhi, tí ó jẹ́ ààrẹ ẹgbẹ́ Parti de l’équité et de la proclamation (PEP), fún “dídà ìkórìira ẹ̀yà sílè àti pípè fún pípa àwọn ọmọ Kabyle.” Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olóṣèlú àti akọ̀ròyín tí ó ń tako gbogbo ohun tí ó bá yàtọ̀ [ti kò jẹ́ ti Arabù tàbí kò jẹ́ Mùsùlùmí],” ó sọ̀rọ̀.
Salhi ń lo ojú ìwé Facebook ẹgbẹ́ òṣèlú láti ṣe àpínká àwọn fídíò tí ó ń sọ fún àwọn ará ìlú láti “ya àwọn ará Kabyles sọ́tọ̀, kí wọ́n sì pa gbogbo ohun tí wọ́n bá ń pè ní zouaves àti ‘àwùjọ bìlísì,’ ìpè fún ìwà ipá àti ikú ni ó jẹ́,” gẹ́gẹ́ bí Houali ṣe wí. Àwọn Young bloggers náà ń gbé ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀ sórí ayélujára, ó sọ.
Nínú fídíò kan tí wọ́n gbé jáde ní òpin 2019, Salhi sọ ọ́ pé àwọn Kabyles kì í ṣe ọmọ Algerian, pé “aṣíkiri” ni wọ́n láti ẹ̀yà àwọn ará Vandal. Nínú fídíò náà, ó sọ pé ohun tí ó ń dójútini ni kí “àwọn ará Algerian máa jẹ́ kí àwọn ajá wọ̀nyí máa ṣe ohun tí ó wù wọ́n.”
Nínú fídíò mìíràn tí wọ́n yà lẹ́yìn ikú Salah ní ọjó 23, oṣù Kejìlá ọdún 2019, Salhi kìlọ̀ pé: “Ẹ ṣọ́ra fún ẹgbẹ́ oró yìí àti àsiá yìí.”
Nínú ọ̀wọ́ ọ̀rọ̀ ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀, ó pe àwọn ará Kabyle ní ará Júù ó sì sọ pé, “ìdí tí a ò fi bá a yín rẹ́ nìyí.” Ó tún pe àsiá àwọn ará Amazigh tí wọ́n fòfindè ní “àsiá zouave.”
Bí ó ṣe jẹ́ pé kò sí òfin tí ó fòfinde ìyàsọ́tọ̀ àti ìṣẹ̀yạ̀mẹyà, Houali ní ìrètí pé àwọn máa lè lo apá ibi tí ó fòfinde “ìdúnrunmọ́ ìṣọ̀kan orílẹ̀-ède” nínú ìwé òfin” — ìyẹn òfin kan náà tí wọ́n fi mú àwọn afẹ̀hónúhàn, tí wọ́n gbé àsiá náà hàn.
Abane rò pé àwọn aṣàtakò ìpolongo zouave ti yọ lára àwọn afẹ̀hónúhàn kúrọ̀. “Èyí ni àìgbatara-ẹni; ìṣẹ̀yàmẹyà pọ́ńbélé ni — wón ń dójúsọ àwọn ará Kabylie wọn kò sí gbé ìgbésẹ̀ kankan, lórí Facebook àti nínú ẹ̀ka ìṣèdájọ́ Algerian,” ó sọ.
Lọ́wọ́lọ́wọ́ yìí, gbogbo ohun tí ó lè ṣe ò ju kí ó máa yọ àwọn ọ̀rọ̀kọrọ̀ náà kúrò lórí ibùdó Facebook rẹ̀, ṣùgbọ́n ìyẹn kò tí ì dáwọ́ ìṣàtakò náà dúró — wọ́n máa ń fi ọ̀rọ̀ kan fèsì pè é ni azouave dípò èyí.