Orílẹ̀-èdè Jamaica nílò ọgbà-ẹ̀wọ̀n tuntun, ṣùgbọ́n ìyínilọ́kànpadà pọn dandan

Àwòrán àfihàn láti orí Canva Pro.

Emma  Lewis, òkan nínú àwọn olùdásíi Ohùn Àgbáyé (Global Voices) ni ẹni tí ó kọ́kọ́ fi àtẹ̀jáde yìí léde lórí gbàgede-ìfìròhìnléde-ẹni rẹ̀. A gba àṣẹ láti tún un lò gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe wà nísàlẹ̀.

Ọ̀ràn dídá (àti ìjìyà) jẹ́ èyí tí ó máa ń wà ní oókan àyà àwọn ará Jàmáíkà. Irú u rẹ̀ ni ọ̀kan nínú àwọn ònkọ̀wé àtìgbàdégbà tí mo yàn láàyò, Fyodor Dostoevsky — ẹni tí ó kọ ìwé yẹn — ti sọ tẹ́lẹ̀ rí, “Ìgbà tí a bá wọ inú ọgbà ẹ̀wọ̀n àwùjọ kan ni a ó tó mọ òṣùwòn ọ̀làjú àwùjọ náà.”

Bí ó bá jẹ́ òtítọ́, dájúdájú, orílẹ̀-èdè Jàmáíkà ní ohun púpọ̀ láti ṣàlàyé. Ní ọjọ́ 11, oṣù Ògún, ọdún 2024, ìṣekúpa ọ̀pọ̀ ènìyàn tó burú jáì wáyé ní agbègbè kan tí a pè ní Cherry Lane Tree. Agbègbè tí ó rẹwà tó irú èyí tí ènìyán lè rò lókàn ni yóò jé, àmọ́ ó ti di agbègbè tó ń rin fún ẹ̀jẹ̀ lẹ́yìn tí àwọn ọkùnrin mẹ́ta pẹ̀lú ìbọn lọ́wọ́ yin ènìyàn méje níbọn pa finínfinín níbi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí kan. Lára àwọn tó fara kááṣá ìṣẹ̀lẹ̀ náà láti rí ọmọdékùnrin ọmọ ọ̣dún méje kan. Àwọn mẹ́sàn-án mìíràn pẹ̀lú ọmọ ìrákòrò kan farapa yánnayànna níbi ìṣẹ̀lẹ̀ láabi náà. Bí wọ́n ṣe rìn síwájú díẹ̀, àwọn ọkùnrin mẹ́ta yìí tẹsẹ̀ dúró, wọ́n tún yìnbọn pa ẹlòmìíràn tó wà nínú àpéjọ kan ní ojú òpópónà náà.

Látàrí rògbòdìyàn tó ṣẹlẹ̀ láàárín ọ̀sẹ̀ kan tàbí méjì lẹ́yìn tí ìpànìyàn nífọnáfọnṣu yìí wáyé, ìbéèrè fún ọgbà ẹ̀wọ̀n tuntun bẹ̀rẹ̀ sí ní gbérí — tí kò sì jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́. Kín ni ìdí tí èyí fi rí bẹ́ẹ̀? Nítorí àwọn ọlọ́pàá fi ẹ̀rí múlẹ̀ wí pé ẹnìkan tó wà látìmlọ́lé ló ṣe kòòkárí ète ìṣekúpa ọ̀pọ̀ ènìyàn tó wáyé náà pẹ̀lú àjọṣepọ̀ àwọn kan láti ẹ̀yìn odi.

Ọ̀rọ̀ ìwà ìbàjẹ́ àtọdúnmódún nínú àwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n, èyí tí ó ń fi ìgbà-dégbà dojú kọ wá àmọ́ tí wọ́n ń fi pamọ́ nígbàgbogbo. Ó jẹ́ ọ̀rọ̀ tó hàn gbangba-gbàngbà tí àwọn ará Jàmáíkà máa fojú fòdá nítorí ara kò ní balẹ̀ láti sọ ojú abẹ níkòó, pàápàá ní ibi àyè tóóró.

Pàtàkì jùlọ, àwọn ẹlẹ́wọ̀n máa ń san owó fún àwọn ohun tí kò yẹ kí wọn ó lẹ́tọ̀ọ́ sí, nǹkan bíi yíyọ́ mú ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ wọlé. Ó hàn wí pé, ó ti pẹ́ tí èyí ti ń ṣẹlẹ̀, ipa tí wọ́n ń sà kò tó láti dísà ejò yìí kò tó nǹkan, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìṣe àwọn ẹlẹ́wọ̀n kan máa ń fa ikú àwọn tó wà níta ọgbà ẹ̀wọ̀n. Wọ́n á pàṣẹ “ìṣekúpani”. Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ nípa ẹ̀sùn “ìṣekúpani” wọ̀nyí, ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n, ní wí pé wọn “kò kàn wá láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn lásán, àwọn ènìyàn tí ò lágbára, [bí kò ṣe] láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn ńláńlá, bákan náà,” Wọn ò tíì gbé ìgbésẹ̀ tó gbópọn lórí ọ̀rọ̀ yìí.

Ọ̀rọ̀ lórí ọgbà ẹ̀wọ̀n tuntun kọ́kọ́ jẹyọ ní ọdún 2015, nígbà tí Alákòóso Ìjọba nílé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ti ìlú Ọba, David Cameron bẹ orílẹ̀-èdè Jàmáíkà wò. Ó dámọ̀ràn wí pé ìjọba òun yóò kọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n tuntun tí yóò fi àyè gba àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí ó jẹ́ ọmọ Jàmáíkà tí wọ́n pọ̀ nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n ní ilẹ̀ òun tí àwọn yóò dá padà sílé lẹ́yìn tí wọ́n bá lògbàa wọn tán, nígbà tó bá yá.

Àbá náà kò bá ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ọmọ Jàmáíkà lára mu bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó jọ pé Portia Simpson Miller tí í ṣe Alákòóso Ìjọba nígbà náà, fẹ́ gba èrò náà rò. Bí ó bá jẹ́ wí pé ìwé àdéhùn ti jẹ́ bíbọwọ́lù nígbà náà, ó ṣe é ṣe kí ó ti di fìfàya báyìí. Nísinsìyìí, bí ó tijẹ́ jẹ́ wí pé àwọn adarí ètò ìjọba wá mo rírì ìwùlò ọgbà ẹ̀wọ̀n tuntun. Alákòóso Ìjọba Andrew Holness ti dá a lábàá wí pé kò sí owó tó tó owó nínú àpò ìjọba fún irú iṣé àkànṣe ńlá bẹ́ẹ̀. Bóyá a ò bá kúkú ti gba àbá Ọ̀gbẹ́ni Cameron wọlé.

Nítorí náà, mo mú u ní ojúṣe láti kọ nípa ipò tí àwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n-ọn wá wà. Kì í ṣe ohun tó dùn ún sọ rárá. Bí ènìyán bá wo ọgbà ẹ̀wọ̀n-ọn Tower Street tó wà ní Kingston fìrí, a óò rí ibi ìkáàánú, ilé ẹgẹrẹmìtì oní bírìkì pupa tí irin wọ̀rọ̀kọ̀ yí ògiri odi rẹ̀ ká àti àwọn ilé-ìṣọ́ ìdáàbò, tí wọ́n fìdí sọlẹ̀ níbi tí kò jìnà sí èbúté-ọkọ̀ọ Kingston Harbour olómi dúdú rẹrẹ bí aró.

Púpọ̀ nínú wa ni kìí wò ó, kàkà bẹ́ẹ̀, à á wo àwọn ilé gíga Kingston. Mo kẹ́fin, ó sì ṣeni láàánú, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ọmọ orílẹ̀-èdè Jàmáíkà ni kò bìkítà nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n tàbí àwọn tí a fi sínú àhámọ́ nínú u rẹ̀ (àyàfi bí wọ́n bá jẹ́ gbajúgbajà olórin ìbílẹ̀). Gẹ́gẹ́ bí Carla Gullotta, olùdásílẹ̀ àjọ ajàfẹ́tọ̀ọ́mọnìyàn Dìde Fún Jàmáíkà – Stand Up For Jamaica (SUFJ) ṣe sọ, àwọn ènìyàn “kì í sábà bá àwọn tí wọ́n bá tàpá sófin ìjọba kẹ́dùn, nítorí ìwà ìpáǹle jọba ní orílẹ̀-èdè Jamaica.” Ohun tí àwọn ènìyàn gbàgbọ́ ni wí pé ẹ̀wọ̀n nílé arúfin, kí a tì wọ́n mọ́lé, kí a sì sọ kọ́kọ́rọ́ nù sígbó.

Ọgbà-ẹ̀wọ̀n ò ní láti jẹ́ ibi tó rẹwà, ṣùgbọ́n ọ́ gbọ́dọ̀ máa ṣiṣẹ́ bí ó ṣe yẹ. Ààbò wọn gbọdọ̀ péye; ó gbọdọ̀ hàn gbangba kí ó sì ṣe é rí. Ènìyàn 800 ni Ilé Ẹ̀wọ̀n Àgbàlagbà Tower Street lè gbà, ṣùgbọ́n ẹlẹ́wọ̀n 1,700 ló wá nínú rẹ̀.

Fún àjọ SUFJ, síbẹ̀, ọgbà-ẹ̀wọ̀n ìgbàlódé ti ìbànújẹ́ ti Tower Street kọ́ ni ọ̀nà àbáyọ; ọgbà-ẹ̀wọ̀n ìyí-ó-wù tuntun tí ò bá à jẹ́ kíkọ́ gbọdọ̀ jẹ́ èyí tí yóò mú àyípadà bá ayé ẹlẹ́wọ̀n. Wọ́n gbọdọ̀ mọ̀ pé; àjọ náà ń ṣe iṣẹ́ ribíribi nínú àwọn ọgbà-ẹ̀wọ̀n, pẹ̀lú gbogbo àwọn ìpèníjà tí ó kojú àwọn ohun tí ẹ̀ka ìmárúfinyọ́kànpadà orílẹ̀-èdè Jàmáìkà ìyẹn Department of Correctional Services ṣàwárí, ti béèrè fún ìrànlọ́wọ́ ẹ̀ka náà láti ṣe ìdásílẹ̀ ètò ìyọ́kànpadà gẹ́gẹ́ bí i ònà tó dára jù láti tún ayé àwọn ẹlẹ́wọ̀n ṣe.

Lọ́wọ́lọ́wọ́, àǹfààní sí ètò ẹ̀kọ́ nínú ọgbà-ẹ̀wọ̀n kò pọ̀ tó. Ṣíṣe pọ̀ láti ṣe, ìgbé ayé tí ò sunwọ̀n nínú ọgbà-ẹ̀wọ̀n ń peléke sí i, tí kò bá ìlànà àgbáyé dọ́gba.

Gẹ́gẹ́ bí àjọ olùdásílẹ̀ SUFJ ti sọ ọ́ di mímọ̀ nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò orí ẹ̀rọ-amóhùn-máwòrán kan ní kò pẹ́ kò pẹ́ yìí, “àwọn ẹlẹ́wọ̀n kò ní àyè láti nara nínúu túbú.” Ilé náà, bí ó ti ṣe rí i, “ti fẹ́ dàwó.” Lẹ́yìn àwọn ìṣẹ́lẹ̀ tó wáyé láìpẹ́, àwọn apá kan ọgbà-ẹ̀wọ̀n Tower Street àti St. Catherine di títì pa nígbà tí wọ́n ṣàkíyèsí wí pé ó léwu fún ènìyàn, tí ó sì ṣokùnfa àkúnfàya.

Ṣùgbọ́n, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ síbi tí ọ̀rọ́ wà: ọgbà-ẹ̀wọ̀n kì í ṣe ohun àfisíwájú tó jẹ́ kókó, yálà ó ń ṣe ìmúdára sí i, ìyínilọ́kànpadà, tàbí kíkọ́ àwọn ẹ̀wọ̀n tuntun. Èyí dà bí fífi ẹ̀tẹ̀ sílẹ̀ pa làpálàpá. Àkórí ọ̀rọ̀ náà kò múlẹ̀ mọ́ lórí afẹ́fẹ́ ilé iṣẹ́ oníròyìn.

Lẹ́ẹ̀kan sí i.

ìbéèrè náà kò yí padà: Ǹjẹ́ a lè ṣe láì máa kọ́ ọgbà-ẹ̀wọ̀n tuntun?

1 ìsọsí

Darapọ̀ mọ ìtàkùrọ̀sọ

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.