Òṣèré Soca, Machel Montano ní Ayẹyẹ OVO ní Toronto, ní Òjọ́ 30 Oṣù Agẹmọ Ọdún 2016. Àwòrán láti ọwọ́ Charito Yap fún Ètò tó ń bọ̀ lọ́nà láti ọ̀dọ̀ Flickr, CC BY-ND 2.0.Bí Ayẹyẹ àjọyọ̀ wíwà ní ara, àkọ́kọ́ Láti ọdún 2020 ṣe ń gbaradì láti wáyé ní orílẹ̀-èdè Trinidad and Tobago ní Ọjọ́ 20 àti 21 Oṣù Èrèlé, àwọn olólùfẹ́ ayẹyẹ ti ń kópa níbi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdánilárayà náà, àwọn àjọ̀dún orin àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ètò tó rọ̀ mọ́ ọn ní ìpàlẹ̀mọ́ fún ìwọ́de ìlú ọlọ́jọ́ méjì náà.
Òṣèré akọrin Soca Machel Montano ni ẹni tí àwọn èrò ń fẹ́ rí jùlọ, bẹ́ẹ̀ ní ọdún yìí, lẹ́yìn tí ó ti sọ pé àgbéjáde àjọ̀dún-orin ọlọ́dọọdún òun ọdún 2020 (tí wọ́n mọ̀ sí “Machel Monday” bí ó ṣe jẹ́ wí pé yóò wáyé ní ọjọ́ Ajé síwájú ọjọ́ ayẹyẹ) ní yóò jẹ́ ìkẹyìn, ni ó kéde láìpẹ́ yìí pé òun yóò ṣeré níbi ayẹyẹ kan tí wọ́n pè ní “Machel 40,” níbi tí òun yóò ti ṣe ayẹyẹ ogójì ọdún gẹ́gẹ́ bí Òṣèré soca .
Ìkéde yìí mú àwọn ènìyàn dunnú lọ́pọ̀lọpọ̀, nítorí pé àwọn eré orin orí-ìtàgé Montano jẹ́ ohun tí ó máa rinlẹ̀, tí ó sì máa ń lágbára pẹ̀lú, ní èyí tí yóò mú kí àwọn èrò ìwòran mọ rírí ayẹyẹ náà lára. Síbẹ̀síbẹ̀, gbajúmọ̀ Òṣèré soca náà ń kojú àríwísí fún àsìkò ètò rẹ̀, tí àkọsílẹ̀ wà fún pé yóò wáyé ní Ọjọ́ Ẹtì Ayẹyẹ, Ọjọ́ 17 Oṣù Èrèlé, Ọjọ́ tó kọlu ọjọ́ ayẹyẹ Ayẹyẹ Àjọ̀dún-orin ti Ilẹ̀-Òkèèrè (ISM):
MACHEL 40
ÈTÒ 🌍 KANKÁÀBỌ̀ SÍ ÌLÚ TÍ A BÍ NI SÍ🪘
TÍKẸ́Ẹ̀TÌ WÀ FÚN TÍTÀ NÍ ỌJỌ́ 1 OṢÙ ṢẸẸRẸ#MM40 #MONK#ÈTÒkan #Káàbọ̀síìlúabínibí#ẸtìAyẹyẹ #Ayẹyẹ2023 @monkmusicgroup pic.twitter.com/vRAh0kNaW1
— Machel Montano (@machelmontano) Ọjọ́ 21 Oṣù Ọ̀pẹ, 2022
Àkọ́kọ́ ìdíje Ayẹyẹ Àjọ̀dún-orin ti Ilẹ̀-Òkèèrè wáyé ní ọdún 1993, pẹ̀lú èróngbà láti pèsè “àwùjọ tí a ti lè máa ṣe àfihàn orin soca ní ìtàgé àgbáyé bí àwọn olólùfẹ́ Irúfẹ́ ẹ̀yà orin bẹ́ẹ̀ ṣe ń jẹ̀gbádùn rẹ̀.” Lára èyí tí àwọn òṣèrè àsìkò kọ̀ọ̀kan tó gbajúmọ̀ jùlọ yóò kojú ara wọn fún àmì-ẹ̀yẹ náà àti ẹ̀bùn owó tó wà pẹ̀lú rẹ̀, èyí tí ó jẹ́ wí pé ní ọdún 2009 jẹ́ 1 million owó orílẹ̀-èdè Trinidad and Tobago (ó dín díẹ̀ sí 150,000 owó DỌ́LÀ). Ètò náà ti máa ń wáyé ní gbogbo ọjọ́ Ẹtì tó ṣíwájú ọjọ́ Ayẹyẹ, èyí tí wọ́n ń pè ní “Ọjọ́ Ẹtì-Alárinrin.”
Ní ọdún 2021, oníròyìn Laura Dowrich-Phillips kíyèsí, “Bí ó ti jẹ́ pé ìdíje náà ti wà ní abala tí yóò ti gbèrú sí i tàbí kí ó kú, òun ló ti gbayì jù láàárín ọ̀pọ̀lọpọ̀ láti àìmọye ọdún sẹ́yìn gẹ́gẹ́ bí àwọn ètò àkọ́kọ́ tí a kọ́kọ́ ṣe àfihàn níbi ayẹyẹ náà.”
Lára àwọn olólùfẹ́ ayẹyẹ náà bákan náà, ti ń wòye pé ISM ni yóò pàdánù jùlọ bí ó bá ní láti figagbága pẹ̀lú Montano tó jẹ́ onífọ̀n-léèékanná fún àwọn aláfẹ̀hìntì kan náà:
— NΣ§§シ™ (@gottaluvness69) December 22, 2022
Àwọn mìíràn sì ń kọminú pé ayẹyẹ méjèèjì yóò wáyé lọ́jọ́ kan náà:
Mo rí i pé Machel yóò ṣeré ní ọjọ́ Ẹtì-Alárinrin. 🤨 Àbí kò ní sí Soca Monarch 2023 ni tàbí agbègbè mìíràn ni yóò ti wáyé?
— JoAnna E. 🇹🇹🇺🇸 (@joannaeblog) Ọjọ́ 22 Oṣù Ọ̀pẹ, ọdún 2022
Lórí ìkànnì Twitter, Dowrich-Phillips kò nígbàgbọ́ pé ISM ní agbára láti padà wá, bí wọn ò ṣe ti ṣeré fún bí ọdún díẹ̀ sẹ́yìn:
Ó dájú pé Soca Monarch ti kú, bí wọ́n bá ń wo ọ̀nà láti gbé e dìde padà. MM ti gba àkóso Ẹtì-Alárinrin ọdún 2023.
— Laura Dowrich (@ldowrich) Ọjọ́ 21 Oṣù Ọ̀pẹ, 2022
Ó fi kún un:
Èé ṣe tí àwọn ènìyàn ń ṣe bí ẹni pé kì í sáábà sí ayẹyẹ ní ọjọ́ Ẹtì-Alárinrin àti pé àwọn èrò ìwòran Soca Monarch ti dínkù pátápátá lẹ́yìn tí MM àti àwọn ògúnná-gbòǹgbò ò kópa mọ́? Àwàdà ni gbogbo yín ń ṣe, bẹ́ẹ̀ni.
— Laura Dowrich (@ldowrich) Ọjọ́ 7 Oṣù Ṣẹẹrẹ, Ọdún 2023
Ìdíje Àjọ̀dún-orin Ilẹ̀ Òkèèrè Soca bẹ̀rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ètò ìpawówọlé kan, èyí tí ó jẹ́ àgbékalẹ̀ Olùṣe-agbátẹrù Ayẹyẹ Ọ̀gbẹ́ni William Munroe. Ní nǹkan bí ọdún 2011, ètò náà bẹ̀rẹ̀ sí í rí àtìlẹ́yìn láti ọ̀dọ̀ ìjọba ìbílẹ̀, pàápàá èyí tí ó dá lórí abala ti àṣà rẹ̀, ṣùgbọ́n ọgbọ́n àgbékalẹ̀ rẹ̀ ò ju fún ìdíje lọ.
Olùṣàmúlò Twitter Tillahwillah rán àwọn tí wọ́n ń tẹ̀lé e létí:
Lọ́wọ́ yìí gbogbo ohun tí kì í bá ń ṣe fún pípawówọlé ni ó máa ń kojú ìfi-ẹnu-gún lórí iye owó àti ìdíje. Ìbéèrè nípa ìdíje ṣe pàtàkì nìkan fún àwọn tí ó tọ́ tàbí tí wọ́n ní ẹ̀tọ́ láti rí owó ní ọ̀nà tí ẹ̀yin faramọ́. Lóòótọ́, lóòótọ́.
— Tillahwillah (@tillahwillah) Ọjọ́ 7 Oṣù Ṣẹẹrẹ, ọdún 2023
Ní ìgbẹ̀yìn, olùṣàmúlò Facebook kan Andy A. Neils rò ó pé ó kù sí ọwọ́ ohun tí ẹnìkọ̀ọ̀kan bá yàn:
Irúfẹ́ Ìdùnnú ọjọ́ ni wọ́n wòye pé ó yẹ kí ó di ìlọ́po bí ó ṣe jẹ́ pé ayẹyẹ méjì pàtàkì ni wọ́n ti là kalẹ̀ pé yóò wáyé ní ọjọ́ Ẹtì-Alárinrin. Lótìítọ́ ààyè wà fún ayẹyẹ méjèèjì láti wáyé ní ọjọ́ kan náà, ṣùgbọ́n ó kù sí àwọn tí wọ́n fẹ́ ṣe fàájì láti yàn nínú wọn…
Lára àwọn tó ń lo Facebook Dane S G Wilson bákan náà, gbà pé ààyè wà fún gbogbo ènìyàn:
Mo lérò pé Soca Monarch 2023 kò ní wáyé. Mo nígbàgbọ́ pé Machel yóò ṣe àṣeyọrí pẹ̀lú ayẹyẹ rẹ̀.
Ó tún faramọ́ èrò Simon Baptiste, adarí ọgbọ́n àtinúdá tẹ́lẹ̀rí fún ISM, tí ó sọ fún Trinidad and Tobago Newsday pé ìdíje náà jẹ́ ìtukọ̀ fún ṣíṣe àgbéjáde àwọn Òṣèré soca tuntun àti ọ̀nà láti bá wọn wá àwọn olùtẹ̀lé:
Ó ń ṣe ìrólágbára fún àwọn kan, ó sì ń ṣe ìwúrí fún àwọn yòókù, ó ń fún àwọn olùṣẹ̀dá ní ẹ̀tọ́ láti kéde fún àwọn olólùfẹ́ káàkiri gbogbo agbègbè àlà-ilẹ̀ ayẹyẹ náà.
Ní àìmọye ọdún sẹ́yìn, ogúnlọ́gọ̀ àwọn òṣèré pàtàkì soca , àti àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Trinidad and Tobago àti àwọn tó wá láti àwọn agbègbè Erékùṣù yòókù, ló ti gba ìdíje ISM náà, tí ó fi mọ́ Montano fúnra rẹ̀. Ní àsìkò náà, Baptiste jẹ́rìí pé ìdíje náà àti abala pípawó wọlé ayẹyẹ náà ṣe aburú àti dáadáa:
Àìlámòójútó tó péye, ìtajà àti àìfẹ́kópa láti ọ̀dọ̀ ẹ̀ka ìjọba àti àwọn aládàáni, kò sí àní-àní pé ó kó ìpalára bá a láti yè, ṣùgbọ́n ìgbàgbọ́ mi ni pé bí àwọn amòye tòótọ́ bá wà nídìí ìṣàkóso náà — àwọn tí kò ní èrò tàbí láti àníyàn fún ohun tí wọ́n yóò rí níbẹ̀ — Soca Monarch lè tún gbé ara rẹ̀ síwájú bíi ti àtẹ̀yìnwá […]
Bóyá a ó tún rí i ní ọjọ́ Ẹtì-Alárinrin 2023.