
Ọjà ẹja bèbè òkun kan ní Dakar, Senegal, pẹ̀lú àwọn ọkọ̀ àti pẹjapẹja. Àwòrán láti orí Flickr. Ìwé-àṣẹ àtúnlò Creative Commons CC BY-NC-ND 2.0
Àwọn ọ̀dọ́mọdé ọmọ bíbí ìlú Senegal tí wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́, Moktar Diop àti Mohamed Jawo jẹ́ apẹja bíi ti àwọn òbí wọn, àwọn òbí wọn àgbà, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn tí wọ́n ń gbé ní etíkun ìlú Dakar.
Moktar ṣàlàyé bí òun ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ yìí:
Je me suis convertie à la pêche comme la plupart des membres masculins de ma famille car je n'arrivais pas à trouver du travail après avoir quitté l'université. J'ai joint mes forces avec mon ami Jawo pour faire face à la vie. Cependant, je ne gagne presque rien à cause de la présence de vaisseaux étrangers incontrôlés qui détruisent les nids de poissons.
Mo mú ẹja pípa níṣẹ́ bíi ti ọ̀pọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí mi tí ó jẹ́ ọkùnrin nítorí mi ò ríṣẹ́ lẹ́yìn tí mo kàwé gboyè ní ilé ìwé gíga. Mo fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ọ̀rẹ́ mi Jawo láti rọ́wọ́ mú dẹ́nu. Ṣùgbọ́n, agbára káká ni mo fi ń rí ère ní ìdí iṣẹ́ ọ̀hún nítorí àwọn ọkọ̀ ojú-omi àtọ̀húnrìnwá tí ń wó ilé àwọn ẹja.
Ní báyìí, àwọn ọ̀rẹ́ méjèèjì náà ń tiraka láti rọ́wọ́ tì bọ ẹnu, wọ́n sì ń gbèrò láti kúrò ní àdúgbò wọn láti wá ohun mìíràn ṣe. Orílẹ̀-èdè Senegal jẹ́ ọ̀kan lára àwọn orílẹ̀-èdè tí ń kojú ìṣòro àparun ẹja nítorí àwọn ọkọ̀ apẹja ńláńlá ti ilẹ̀ China tí ń pẹja lọ́nà tí kò bófin mu. Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí àjọ Greenpeace, ìyẹn àjọ kan tí ń mójútó àyíká tí ọwọ́jà rẹ̀ sì dé àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n jù 50 lọ lágbáyé, ní Ìwọ-Oòrùn Orílẹ̀ Áfríkà àti ní àárìn gbùngbùn ilẹ̀ Áfríkà ṣe fi hàn, ìwọ̀n àìníṣẹ́lọ́wọ́ ní orílẹ̀-èdè Senegal lọ sókè, èyí tí kò ṣẹ̀yín ìbẹ̀rẹ̀ ìlànà ẹja pípa pẹ̀lú àwọn ọkọ̀ ìpẹja ńláńlá ilẹ̀ China ti ó ṣokùnfa àìrẹ́ja pa lágbègbè ọ̀hún mọ́, tí ó sì ti sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ di aláìníṣẹ́.

Àwọn pẹjapẹja nínú ọkọ̀ apẹja tí àwọ̀ rẹ̀ ń dán jerejere, tí ó sábà máa ń wà ní àwọn agbègbè ẹja pípa ní bèbè òkun Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà. Àwòrán láti Wikipedia, ìwé-àṣẹ àtúnlò Creative Commons CC BY-SA 2.0
Àbọ̀dé àwọn ọkọ̀ ìpẹja ńláńlá ilẹ̀ China tí wọ́n kúrò ní sàkáání ìlú wọn àti àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn bíi Russia tí kó ìparun bá ètò ọrọ̀ ajé ẹja pípa agbègbè náà. Ó máa ń nira fún àwọn apẹja tí wọ́n ń lo ọkọ̀ ọlọ́pọ́n láti pa ẹja nígbà tí àwọn ọkọ̀ awa-ẹja ńláńlá bá wọ ojú omi. Àwọn ọkọ̀ a-wa-ẹja ńláńlá wọ̀nyí má ń lo àwọ̀n ẹja tí ó gùn tó ìwọ̀n máìlì kan, tí o má ń wa gbogbo ẹja títí kan ohun gbogbo tí ó wà lójú ibi tí wọ́n ju àwọ̀n náà sí, tí ó sì tún má ń bá àwọn àwọ̀n ẹja àwọn apẹja ìbílẹ̀ jẹ́ nígbà mìíràn.
Irúfẹ́ àwọn ọkọ̀ ńláńlá wọ̀nyí tí ń fà àwọn awuyewuye jákèjádò àgbáyé lórí àkóbá tí wọ́n ń ṣe fún àyíká nítorí ẹja pípa dé ibú omi lè ṣe àkóbá fún àwọn ẹ̀dá inú omi àti okùnfà ikú àwọn ẹ̀yà ẹja tí oúnjẹ, ibùgbé, àti ètò ìbísíi wọn kò ṣẹ̀yìn àyíká omi, tí ó lè mú àkúrun bá àmúrò ẹja pípa lómi pẹ̀lú ìrúkèrúdò ibú-òkun tó ń peléke sí i.

Ọkọ̀ awẹja ilẹ̀ China. Àwòrán láti Picryl. Ó wà ní Àkàtà Gbogbo Mùtúmùwà láti lò.
Àjọ Greenpeace ní iye ọkọ̀ apẹja ńláńlá ilẹ̀ China tí wọ́n ń peja ní etíkun Ìwọ̀-Oòrùn Orílẹ̀ Áfríkà lọ́wọ́lọ́wọ́ jú 400 lọ. Gẹ́gẹ́ bí ìṣirò tí a gbà láti ọ̀dọ̀ ẹ̀ka ìjọba tí ó ń ṣe àmójútó ètò ẹja pípa lórílẹ̀-èdè Ilẹ̀ Olómìnira Àwọn Èèyan China, àwọn ọkọ̀ ìpẹja ńlá yìí máa ń pa owó tí ó ju mílíọ̀nù 400 owó EUR lọ lọ́dọọdún láti ara iṣẹ́ ẹja pípa.
Àwọn èèyàn tí wọ́n tọ́ 220000 níye ni wọ́n ń jẹ nídìíi iṣẹ́ ẹja ṣíṣe ní orílẹ̀-èdè Senegal; ti idá 90 nínú ọgọ́rùn-ún wọn mú iṣẹ́ ẹja pípa gẹ́gẹ́ bíi iṣẹ́ ọwọ́, tí àwọn ìdá 10 tókù sì ń siṣẹ́ yálà lórí àwọn ọkọ̀ ìpẹja ńláńlá àwọn àtọ̀húnrìnwá, òwò alajọṣepọ̀, tàbí oníṣòwò ọkọ̀ awa-ẹja-dé-ìsàlẹ̀-òkun agbègbè náà.
Àwọn èèyàn tí wọ́n tó 220000 níye ni wọ́n ń jẹ nídìíi iṣẹ́ ẹja ṣíṣe ní orílẹ̀-èdè Senegal; ti idá 90 nínú ọgọ́rùn-ún wọn mú iṣẹ́ ẹja pípa gẹ́gẹ́ bíi iṣẹ́ ọwọ́, tí àwọn ìdá 10 tókù sì ń siṣẹ́ yálà lórí àwọn ọkọ̀ ìpẹja ńláńlá àwọn àtọ̀húnrìnwá, òwò alajọṣepọ̀, tàbí awa-ẹja-dé-ìsàlẹ̀-òkun àgbègbè náà.
Ní báyìí, Moktar àti Jawo ni láti dẹ odò dé ọ̀nà jínjìn kí wọ́n tó rí ẹja pa nítorí àwọn ọkọ̀ ìpẹja ńláńlá ilẹ̀ China tí gba gbogbo orí omi náà. Wọ́n ní ó ṣòro fún àwọn ọkọ̀ àwọn ará agbègbè náà láti pẹja bíi ti àwọn ọkọ̀ apẹja ńláńlá àwọn ará China, pẹ̀lú pẹ̀lú ní orílẹ̀-èdè tí ìwọ̀n aláìníṣẹ́lọ́wọ́ ju ìdá 23 nínú ọgọ́rùn-ún lọ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀dọ́ máa ń sọ ìrètí nù.
Láti wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdá sí ìfàsẹ̀hìn ẹja pípa lórí omi ìtòsí, Orílẹ̀èdè China ti ṣe imúgbòòrò ètò ẹja pípa ní agbègbè tí ó jìnà sí sàkáání ìlú wọn láti ọdún 2000. Ìmúgbòòrò ètò ẹja pípa lọ́nà jínjìn Orílẹ̀èdè China náà ti fa awuyewuye káàkiri àgbáyé lórí bí ètò náà kò ṣe tọ ìlànà àgbéró àti ìfòtítọ́ṣe.
Gẹ́gẹ́ bí ìwé China Fisheries Statistical Yearbook, lọ́dún 2022, iye ẹja tí orílẹ̀-èdè China pa nínú omi òkun jẹ́ òṣùwọ̀n 2,329,800, tí iye àwọn ọkọ̀ ìpẹja ńláńlá tí nínú omi òkun fẹ́ẹ̀ẹ́ tó 2,551.
Gégé bíi àtẹ̀jáde kan láti ọwọ́ àjọ Environmental Justice Foundation (EJF), ọ̀pọ̀ nínú àwọn ọkọ̀ ìpẹja orílẹ̀-èdè China ni wọ́n ń ṣiṣẹ́ káàkiri àwọn orílẹ̀èdè tí wọ́n ò tíì gòkè àgbà, tí idà kan nínú mẹ́ta ẹja pípa náà sì wà ní orílẹ̀ Áfríkà, Áṣíà àti Gúúsù Orílẹ̀ Amẹ́ríkà. Àwọn agbègbè wọnyí kìí sábà pa ẹja tí ó pọ̀ látàrí àìsí ohun-èlò tí ó yẹ ṣùgbọ́n ìdàgbàsókè ọrọ̀ ajé àti oúnjẹ wọn gbáralé ẹja pípa. Àwọn ọkọ̀ ìpẹja orílẹ̀-èdè China máa ń ṣàmúlò àwọn ìlànà ẹja pípa lọ́lọ́pọ̀ yanturu tí ó máa ń ká iṣẹ́ ẹja pípa àti ọrọ̀ ajé iṣẹ́ ẹja pípa lẹ́sẹ̀kùkú lọ́wọ́ kò. Àwọn ìṣe mélòó kan kò bá òfin mu, láì sí lábẹ́ ìtọ́sẹ̀ òfin (IUU), tí kò sì sí ẹni tó ṣe ìfilọ, èyí sì ń fa ìtọpinpin àwọn àtìta wá.
Láti ọdún 1989 ni orílẹ̀-èdè China ti dipò orílẹ̀-èdè tó ń pẹja jùlọ lágbáyé mú, tí wọ́n sì pa ẹja tí òṣùwọ̀n rẹ̀ tó mílíọ̀nù 13.14 lọ́dún 2021, èyí tí o fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlọ́po méjì 7.2 MMT, iye ẹja tí orílẹ̀-èdè Indonesia tí ó wà nípò kejì orílẹ̀-èdè tí ń pẹja jùlọ lágbáyé pa. Lọ́dún 2022, àpapọ̀ iye ẹja tí orílẹ̀-èdè China pa jẹ́ ìdá 40 nínú ọgọ́rùn-ún gbogbo iye ẹja tí àwọn ènìyàn pa lágbàáyé, tí èyí tí ó pọ̀ níbẹ̀ jẹ́ láti ọwọ́ àwọn ọkọ̀ ìpẹja tí ń dẹ odò lọ́nà jínjìn.
Ẹja Àpajù ní Ìwọ̀-oòrùn Ilẹ̀ Áfíríkà
Gẹ́gẹ́ bí àlàyé àjọ International Collective in Support of Fishworkers, ẹja pípa lọ́nà tí kò bá òfin mu tí ṣokùnfà ìpàdánù iṣẹ́ ìpẹjalódó nílànà ìṣẹ̀nbáyé tí ó tó 300,000 ní Ìwọ̀-oòrùn Orílẹ̀ Áfíríkà. Nítorí ìdí èyí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ni wọn ti yà sí ìdí iṣẹ́ mìíràn tàbí wá iṣẹ́ lọ sẹ́yìn odi. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ti wọ́n kò leè dúró sí ìlú wọn mọ́, máa ń gbìyànjú láti gba Morocco wọ Yúróòpù, tí wọ́n sì máa ń fẹ̀mí wọn wéwu lọ́nà.
Àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà ní etíkun Ìwọ̀-oòrùn Orílẹ̀ Áfíríkà bíi orílẹ̀-èdè Guinea-Bissau àti Gambia náà ń dójúkọ irú ìpèníjà yìí.
Láti ṣe ìgbéga àgbéró ètò iṣẹ́ ẹja pípa, orílẹ̀-èdè China tí náwó ribiribi lórí ọ̀sìn ẹja láti bí ọdún mélòó kan sẹ́yìn tí ó sì ti mú àdínkù bá ẹja pípa lórí òkun. Gẹ́gẹ́ bí àjọ United Nations Food and Agriculture Organization (FAO) ti fi léde, ẹja pípa lórí òkun orílẹ̀-èdè China tí fi ìwọ̀n 18 dínkù láti iye òṣùwọ̀n mílíọ̀nù 14.4 ní ọdún 2015 sí òṣùwọ̀n 11.8 ti lọ́dún 2022.
Ṣùgbọ́n, iṣẹ́ ẹja pípa lọ́nà jínjín sí sàkání orílẹ̀-èdè China kò tẹ̀. Nínú ìwé China Fisheries Statistical Yearbook, iye ẹja tí ó jẹ́ pípa lọ́nà jínjín sí sàkání orílẹ̀èdè China tó òṣùwọ̀n mílíọ̀nù 2.33 lọ́dún 2022, èyí tí ṣe àlékún ìdá mẹ́rin tí ọdún tó ṣáájú, tí ó sì jẹ́ ìdá 18 nínú ọgọ́rùn-ún gbogbo ẹja tí wọ́n pa lágbàáyé.
Orílẹ̀-èdè China tí ń ṣe àgbéga ọ̀sìn ẹja àgbéró nínú ìlú wọn láti ọdún 2021, tí wọ́n sì tẹramọ ìṣàmúlò àwọn ìlànà oko dídá tí kò ba àyíká jẹ́, ìṣàmójútó omi onípàntí, mímú àdínkù bá lílo òògùn fún àwọn ohun abẹ̀mí inú omí, àti rírọ́pọ̀ àdàlù oúnjẹ fún awon ẹja kéékèèké. Ìwọ̀n ọ̀sìn ẹja ti ròkè sí i lọ́dọọdún, pẹ̀lú bíi orílẹ̀-èdè China nìkan ṣe dá pèsè ìdá 55.4 (òṣùwọ̀n mílíọ̀nù 3.3) nínú ìwọ̀n ẹja pípa ní ìpín ojú-ilẹ̀ Asia lọ́dún 2022. Síbẹ̀, orílẹ̀-èdè China kòì tíì má ṣàmúlò àwọn ìmọ̀ ọ̀sìn ẹja àgbéró wọ̀nyí ní àwọn orílẹ̀-èdè Ìwọ̀-oòrùn Áfíríkà, dípò bẹ́ẹ̀ wọ́n ń ṣe ètò ẹ̀kọ́ fún àwọn apẹja agbègbè,wọ́n sì tún ń dá àwọn ilé-iṣẹ́ aṣaáyan ẹja sílẹ̀, èyí tí ó túbọ̀ mú kí wọn ó tẹmpẹlẹ mọ́ ẹja nílẹ̀ onílẹ̀ láì sí ẹ̀mú tí yóó mú wọn.
Àwọn ọ̀fìn àdéhùn ìlànà ẹja pípa
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé orílẹ̀èdè China fi ọ̀rọ̀ léde lórí ìdáàbòbò iṣẹ́ ẹja pípa, àwọn ìròyìn lónírúurú ń lọ lóde wí pé àwọn ọkọ̀ ìpẹja ńláńlá orílẹ̀-èdè ọ̀hún ń pẹja lọ́nà tí kò bófin mu. Fún àpẹẹrẹ, nínú oṣù Èbìbí lọ́dún nìí, ẹ̀ka ètò iṣẹ́ ẹja pípa àti ọ̀rọ̀ Ajé òkun (Ministry of Fisheries and Maritime Economy) orílẹ̀-èdè Senegal tẹ àtẹ̀jáde àtòjọ orúkọ àwọn ọkọ̀ tí ìjọba fọwọ́ sí, ṣùgbọ́n kò sí àwọn ọkọ̀ ojú-omi orílẹ̀-èdè China níbẹ̀. Ṣùgbọ́n, àwọn apẹja ẹsẹ̀kùkú ṣàlàyé pé àwọn ń rí àwọn ọkọ̀ ìpẹja ńláńlá orílẹ̀-èdè China lórí omi.

Ààrẹ Ilẹ̀ Olómìnira Àwọn Èèyan China Xi Jinping ń bọwọ́ pẹ̀lú Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Guinea-Bissau Umaro Mokhtar Sissoco Embaló. Àwòrán Àgékù YouTube. Ó wà fún lílò lọ́fẹ̀ẹ́.
Kìí ṣe gbogbo ọkọ̀ ìpẹja ńláńlá orílẹ̀-èdè China ló ń pẹja lọ́nà tí kò bá òfin mu. Fún àpẹẹrẹ, orílẹ̀-èdè China ń tẹ̀lẹ́ àdéhùn ẹja pípa tí wọ́n ṣe pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè Ìwọ̀-oòrùn Áfíríkà bíi orílẹ̀-èdè Guinea-Bissau, níbi ti ilé-iṣẹ́ China National Fisheries Corporation fi idi ẹ̀ka ilé-iṣẹ́ wọn òkèèrè àkọ́kọ́ lọ́lẹ̀ sí lọ́dún 1985, tí wọ́n sì ń fi ọkọ̀ a-wa-ẹja ńláńlá 11 siṣẹ́ lọ́wọ́lọ́wọ́.
Ṣùgbọ́n, àwọn àdéhùn àgbérò ẹja pípa wọ̀nyí pàápàá ń mú àjórẹ̀yìn bá àwọn orílẹ̀-èdè Ìwọ̀-oòrùn Áfíríkà. Ìwádìí kan tó ń ṣe àgbéyẹ̀wọ̀ àdéhùn àgbérò ẹja pípa láàárín EU àti Ìwọ̀-oòrùn Áfíríkà fi hàn wí pé àwọn àdéhùn yìí kìí ṣe àǹfààní tó jẹ́ ọgbọọgba — owó tí àwọn orílẹ̀-èdè Ìwọ̀-oòrùn Áfríkà máa ń rí kò tó nǹkan sí iye àlùmọ́ọ́nì omi òkun wọn. Orílẹ̀-èdè China àti Russia wà lára àwọn akópa tí ó ṣe àwọn àdéhùn wọ̀nyìí.
Àwọn orílẹ̀-èdè Ìwọ̀-oòrùn Áfíríkà kan ti ṣàkíyèsí àwọn ìrẹ́jẹ àwọn àdéhùn ẹja pípa wọ̀nyìí. Fún àpẹẹrẹ, ìjọba orílẹ̀-èdè Senegal tuntun ti kéde ète láti tún àwọn àdéhùn ètò ọrọ̀ Ajé ìṣáájú tí wọ́n ní pẹ̀lú EU ṣe fún àtúntò ètò ẹja pípa.
Láfikún, orílẹ̀-èdè bíi Senegal àti àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ni Áfíríkà gbára lé ìrànwọ́ orílẹ̀-èdè China púpọ̀ tí ó máa ń gbé owó sílẹ̀ fún àwọn iṣẹ́ àkànṣe ìjọba ìpín ojú-ilẹ̀ àgbáyé náà àti ní orílẹ̀-èdè Senegal bákan náà nípasẹ̀ Ètò Ìmúgbòòrò Ọrọ̀ Ajé àti Àjọṣepọ̀ tó gbámúṣé kárí ayé rẹ̀.
Nísisìyìí náà, àwọn tí wọ́n fi ara da ìlànà wọ̀nyìí jù lọ ni àwọn oníṣòwò apẹja kéréjekéréje tí ó jẹ́ wí pé àtayédáyé, ni ìran wọn ti ń fi iṣẹ́ ẹja pípa létíkun fi gbọ́ bùkátà ara wọn àti àwọn ẹbíi wọn. Mohammed Jawo sọ pé: “A ní àwọn ọgbọ́n ìmọ̀ọ́ṣẹ́, ṣùgbọ́n kò sí ohun tí a lè ṣe sí ìrẹ́jẹ tí à ń dojú kọ yìí nítorí àwọn àdéhùn tí ó ti fi àṣẹ ẹja pípa lórí omi òkun wa fún àwọn ẹlòmíràn tí wọ́n ń wá pa owó sápò ara wọn. A nírètí pé ìjọba tuntun ti Ousmane Sonko yóò tún àwọn àdéhùn aláìníláárí wọ̀nyìí ṣe.”
áti kà síwájú sí i nípa ìlọ́wọ́sí orílẹ̀-èdè China nínú àwọn iṣẹ́ àkànṣe ìdàgbàsókè àti wíwá ọ̀nà àbáyọ sí ìṣòro àyípadà ojú-ọjọ́ tí àgbáyé ń dójú kọ, wo Iṣẹ́ àkànṣe Àjùmọ̀ṣe Ọ̀nà àbáyọ Àyípadà Ojú-ọjọ́ wa.: