Ìbẹ̀rù Àwọn Àjọ ní France Lóri Èdè Tó Pọ̀: Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Pẹ̀lú Abẹnugan Fún Èdè; Michel Feltin-Palas

France jẹ́ orílẹ̀ èdè tí ó ń sọ èdè tó pọ̀, tí àwọn èdè àdùgbó ibẹ̀ sì lé ní ogún, àmọ́ ìjọba àpapọ̀ ṣì ń lọ́ra láti tẹ́wọ́ gba àwọn èdè yìí àti láti fún wọn ní àtilẹyìn tó yẹ. Nínú ìfọ̀rọ̀wérò pẹ̀lú Global Voices, ògbóntarìgì àti abẹnugan fún èdè,Michel Feltin-Palas ṣe àlàyé àwọn ohun tí ó ṣe okùnfà irúfẹ́ ìlóra yìí.

Feltin-Palas jẹ́ akọ̀ròyìn ní French weekly L’Express, níbi tí ó ti máa ń gbé àwọn ìròyìn kékéèké àtìgbàdégbà tí ó fi máa ń sọrí orílẹ̀ èdè France gẹ́gẹ́ bi elédè púpọ̀ jáde. Ó tún jẹ́ ònkọ̀wé tí ó ti kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé tí ó fi sọrí kókó tí à ń jíròrò lé, pẹ̀lú èyí tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ  “Sauvons les langues régionales” (“Ẹ jẹ́ kí a gba àwọn ẹ̀ka èdè sílẹ̀”), tí wọ́n tẹ̀ jáde ní ọdún 2022, níbi tí ó ti yànnàná àwọn ìdí tó ní ṣe pẹ̀lú ìtàn àdáyébá àti ètò ìṣejọba tí ìjọba ilẹ̀ France sọ pé ó fa ìfojúkéré àwọn èdè tí a pè ní “langues régionales” (“àwọn ẹ̀ka èdè”). Ìwé náà tọ́ka sí àwọn èdè 20 tí ó wà nínú ìtàn pé wọ́n ti ń sọ láti ayébáyé títí di òní ní ìgboro France.

Feltin-Palas ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórì àwọn orísun ìbẹ̀rù onírúurú èdè yìí nínú apá kan àwọn àjọ kọ́ọ̀kan tó fìdí múlẹ̀ ní France, pàápàá jùlọ láàárín ẹ̀ka ìgbìmọ̀ aṣòfin àti ẹ̀ka ẹ̀kọ́:

La France est un pays qui pourrait ne pas exister. A priori, il n’y avait aucune raison pour qu’un Alsacien se retrouve un jour dans le même État qu’un Basque, un Corse et un Auvergnat. Le pouvoir central a donc toujours craint que ces cultures diverses ne débouchent sur des revendications séparatistes. En conséquence, il a cherché à imposer une langue unique, le français. Quant aux cultures locales, elles sont réduites à de simples folklores et bannies de l’école. « Uniformiser constitue un excellent moyen pour mieux diriger un pays aussi vaste et divers que la France », souligne l’historien Olivier Grenouilleau (Nos petites patries, Gallimard).

Pendant longtemps, la diffusion de la langue française dans des territoires où elle n’était pas parlée a été perçue comme une manière d’apporter la « civilisation ». De ce point de vue, en effet, un parallèle peut être en effet établi avec la colonisation. Jules Ferry déclarait ainsi le 28 juillet 1885 devant les députés : « Il faut dire ouvertement qu'en effet les races supérieures ont un droit vis à vis des races inférieures […] parce qu'il y a un devoir pour elles. Elles ont un devoir de civiliser les races inférieures ». ll n’est pas abusif de considérer que la même vision a eu cours pour l’Hexagone, où Paris, incarnation de la « civilisation », s’est fixé pour « devoir » d’arracher le bas-peuple à la médiocrité de ses « patois » à travers l’école publique.

France jẹ́ orílẹ̀ èdè tí kò bá ti má sí lórílẹ̀ rárá. kò tilẹ̀ sí ìdí kan pàtó tí ẹni tó ń gbé Alsace yóò fi di ẹni tó ń gbé papọ̀ ní ìlú kan náà pẹ̀lú ẹni tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Basque, Corsica tàbí Auvergne. Ohun tó ń kọ ìjọba àpapọ̀ France lóminú ni pé àwọn onírúurú àṣà wọ̀nyẹn yóò ṣòkùnfà ìpínyà nígbẹ̀yìn. Nìtorí ìdí èyí ni wọ́n ṣe mú èdè kan ní kàn-án-pá, èdè Faransé. Ní ti àwọn àṣà ìbílẹ̀, wọ́n dín wọn kù sí àwọ́n àlọ́ onítàn kékéèké wọ́n sì fagilé lílò wọn ní àwọn ilé ìwé. Gẹ́gẹ́ bi akọ̀tàn èdè Faransé kan Olivier Grenouilleau ṣe kọ ọ́ nínú iwé rẹ̀ “Nos petites patries” [“Àwọn ìlú abínibí wa kékéèké”]: “Ìṣòkan ni ọ̀nà tó yè kooro láti darí orílẹ̀ èdè tó tóbi tí ó sì ní onírúurú èdè bíi ti France.”

Fún ìgbà pípẹ́, ìṣàfihàn èdè Faransé ní àwọn agbègbè tí wọn kìí sọ èdè náà tẹ́lẹ̀ rí gẹ́gẹ́ bí “ọ̀làjú” sí irúfẹ́ àwọn àgbègbè bẹ́ẹ̀. Bí a bá fi ojú ìwòye yìí wòó, eèyan tilẹ̀ lè fi wé ìjẹgàba. Jules Ferry [Adarí Ìgbìmọ̀ ìjọba tí ó padà di Aṣojù ìgbìmọ ètò Ẹ̀kọ́ lórílẹ̀ èdè France] sọ báyìí ní ọjọ́ 25, oṣù Agẹmọ, ọdún 1885, nínú ilé ìgbìmọ̀ ìṣòfin ti France pé,  “èèyàn gbọ́dọ̀ sọ gbangba-gbangbà pé àwọn ẹ̀yà tó ga jùlọ ní ẹ̀tọ́ lórí àwọn ẹ̀ya tó kéré sí i[…] nítorí pé wọ́n ní ojúse kan. Ojúṣe láti la àwọn ẹ̀yà tó kéré lójú. ” Torí ìdí èyí kò burú jù láti rò pé irú àfojúsùn yìí yóò borí ní France, níbi tí Paris, tó jẹ́ orísun ibi “ọ̀làjú”, ti sọ ọ́ di “ojúṣe” ríi dájú pé àwọn tálákà pa lílo àwọn ẹ̀ka èdè wọn tí kò kájú òṣuwọ̀n tì, kí wọ́n sì máa lo èdè gbogboogbo látàri pípèsè iléèwé ìjọba fún wọn.

Ọ̀pọ̀ nínú àwọn èdè 20 yìí ló dáńtọ́, ní sísọ àti kìkọ sílẹ̀ — síbẹ̀ èyí kò hànd nínu èto ẹ̀kọ́ àti gbogbo ohun tó jẹ mọ́ àṣà. Feltin-Palas ṣe àlàyé pé:

L’explication est la même. L’Etat français, à travers l’école, a tenté d’imposer une vision simple : il y aurait en France une seule culture, la culture française, les autres n’étant que de simples folklores sans intérêt. Apprendre aux élèves qu’il existe d’autres littératures n’est pas compatible avec cette vision. Un éditeur scolaire a ainsi osé écrire dans un livre scolaire que Bernat de Ventadour, l’un des
plus grands troubadours, écrivait en… « français du Sud » ! Et pourtant… Frédéric Mistral a reçu le prix Nobel de littérature pour une œuvre en provençal. Mais il n’est pas enseigné.

Àlàyé náà jẹ́ ọ̀kaùn pẹ̀lú èyí tó wà lókè. Àwọn ìlú tí wọ́n ti ń sọ èdè Faransé gbìyànjù láti lo ọ̀nà ètò ẹ̀kọ́ fi àfojúsùn tó rọrùn kan lélẹ̀: pé France ní àṣà kan, àṣà Faransé, nígbà tí àwọn àṣà yóókù sì  jẹ́ ìfarahàn àlọ́ onítan lásán nítorí náà kò fani mọ́ra. Kíkọ́ àwọn ọmọ pé àwọn lítíréṣọ̀ míràn tún wà kò bá àfojúsùn bẹ́ẹ̀ mu. Òlùtẹ̀jádé àwọn ìwé ìkọ́ni ní iléèwé kan láyà láti kọ ọ́ pé  Bernat de Ventadour, ọ̀kan nínú àwọn gbajúgbajà troubadours [akewì tó ń kọ àwọn ewì ní èdè Occitan] , kọ ọ́ ní…”èdè Faransé ti ihà Gúúsù”! síbẹ̀. . . Frédéric Mistral gba àmì ẹ̀yẹ tó ga jù fún lítíréṣọ̀ [ní 1904] fún iṣẹ́ rẹ̀ tí ó kọ ní èdè Provençal [ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀yà ède Occitan]. Àmọ́ kò tilẹ̀ kọ́ èdè yìí ní iléèwé.

Ọ̀pọ̀ nínú “àwọn èdè àdúgbò” ló kún fún oríṣiríṣi àwọn ẹ̀ka èdè, nígbà míràn, oríṣiríṣi àkọsilẹ̀, bíi ti Occitan. Feltin-Palas fi òye tirẹ̀ hàn lóri ọ̀rọ̀ tí ó sábà máa ń jà ràyìn-ràyìn yìí:

La réponse est complexe. Il existe des points communs entre le provençal, le gascon, l’auvergnat, le languedocien, le limousin, le vivaro-alpin. Il existe aussi entre eux des différences. Dès lors, certains préfèrent insister sur ce qui les rassemble, d’autre sur ce qui les sépare.
Concernant la graphie, il en existe deux grandes familles. La première, dite graphie « classique », se réfère à une période glorieuse de la langue occitane, celle des troubadours, et s’inspire de leurs habitudes d’écriture. Elle a l’avantage du prestige, elle a le défaut de la complexité car, depuis, la prononciation a beaucoup changé. Les locuteurs qui ne la connaissent pas ont donc du mal à retrouver leur langue en la lisant. Les non-locuteurs la prononcent très mal. La seconde, dite « mistralienne » ou « fébusienne », a été définie plus récemment. Elle a l’avantage d’être plus facile à maîtriser par un lecteur francophone. Elle a l’inconvénient d’être plus proche du français.
Pour ma part, je préfère ne pas entrer dans ces deux querelles, aussi légitimes soient-elles. De mon point de vue, tous ceux qui défendent ces langues appartiennent au même camp, quel que soit le nom qu’ils leur donnent, et doivent rester unis face à ceux qui veulent les voir disparaître.

Ìdáhùn yìí fẹjú. Àwọn àbùdá tó wọ́pọ̀ kan wà tí ó so Provençal, Gascon, Auvergnat, Languedocien, Limousin, Vivaro-alpin [àwọn orúko tí àwọn tó ń sọ àwọn ojúlówó ẹ̀ka èdè Occitan mẹ́fẹ́ẹ̀fà sọ àwọn èdè náà] pọ̀. Àwọn ìyàtọ̀ tún wà. Ní ojù tí a fi wòó yìí, àwọn kan fẹ́ràn láti fúnka mọ́ ohun tí ó so gbogbo àwọn èdè náà pọ̀, nígbà tí àwọn míràn fúnka mọ́ ohun tó yà wọ́n sọ́tọ̀. Nípa ti sípẹ́lì, ọ̀wọ́ méjì gbòòrò ló pín sí. Ákọ́kọ́ ni à ń pè ní  “Sípélì àtijọ́” èyí tó tọ̀ka sí ìgbà àtètèkọ́ṣe èdè Occitan, èyí tì àwọn a-kọ-ewì èdè Occitan máa ń lò. Ó dá lóri bí a ṣe ń sípélì ọ̀rọ̀ nígbà náà, ó sì wuyì púpọ̀ àmọ́ ó fẹjú, gẹ́gẹ́ bí ìdàgbàsókè ṣe ti bá àpèjádè rẹ̀ bí igbà ṣe rọju díẹ̀ . Torí náà àwọn tó n sọ èdè yìí nisinsìnyí tí wọn kò mọ èyí máa ń kojú ìṣòro láti dá èdè wọn mọ̀, àwọn tí kìí ṣe elédè yìí sì máa n ṣìí pè. Ìkejì ní à ń pè ní “sípélì òde òní”, èyí tí wọ́n ṣẹ̀dá ní àìpẹ́ yìí. ojúlówó ànfààní tó ni ni pé ó rọrùn fún àwọn elédè Faransé láti pè, àkùdè rẹ̀ sì ni pé, ó súnmọ́ èdè Faransé jù. Ní tèmí, ó pe mi láti má ṣe ègbè kankan lóri fàákája wọ̀nyìí, nítorí mo mọ̀ pé ó bá òfin mu. Èro tèmi ni pé ọdẹ kan náà ní gbogbo àwọn tó n ṣègbè fún àwọn èdè náà ń dẹ, àwọn ọ̀rọ̀ ìperí ti wọn kò báà wù wọ́n kí wọ́n lò, wọ́n ṣì gbọdọ̀ wà ní iṣọ̀kan nítorí àwọn tó n lépa bí àwọn èdè náà yóò ṣe parẹ́.

Bí a bá wo pàtàkí orúkọ, àwọn ọ̀rọ̀ àmúyẹ wo ni ẹ rò pé ó bójúmọ tí ó sì ní àpọ́nlé jùlọ fún ohun tí France ń pè ní “ẹ̀ka èdè”?

Si je suivais mes convictions, je parlerais de langues « historiques », « autochtones », « minoritaires » ou « minorisées ». Mais tous les spécialistes d’Internet que j’ai interrogés sont formels : dans les moteurs de recherche, ces termes ne sont quasiment pas usités. Dès lors, je ne toucherais par mes articles que les personnes déjà convaincues, pour lesquelles j’ai évidemment le plus grand respect, mais tel n’est pas mon but. Ce que je tente de faire, à ma modeste mesure, c’est de sensibiliser un public plus large. Dès lors, j’ai dû faire un choix. Rester sur ces appellations, plus justes linguistiquement, et être peu lu. Ou utiliser « langues régionales » et diffuser plus largement ces idées. A partir du moment où je cherche l’efficacité, j’ai opté pour la seconde option. Je ne prétends pas avoir raison, mais tel est l’état de mes réflexions.

Bí ó ṣe yé èmi sí, mo máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn èdè “ayébáyé”, “abínibí”, “oní ìpín kékeré”, tàbí “oní ìdínkù ní ìlò”. Àmọ́ àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ẹ̀rọ ayélujára tí mo ti bá ṣọ̀rọ̀ nípa àkórí ṣe àlàyé tí kò rújú: Lórí àwọn ẹ̀rọ tí a fi ń wá ọ̀rọ̀, kò sí ẹni tó ń lo irúfẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ àmúyẹ náà. Àmọ́, bí mo bá lò wọ́n nínu áwọn àkọsílẹ̀ kékéèké, àwọn ti àwọn ọ̀rọ̀ àmuye náà yé nìkan ni yóò mọ ìtumọ̀ rẹ̀. Mo ní àpọ́nlé tó ga fún àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀, àmọ́ àfojúsùn mi ni láti dá àwọn èeyan tí wọ́n ń ṣàmúlò ẹ̀rọ ayélujára lẹ́kọ̀ọ́ bí ó ti tọ́ àti bí ó ti yẹ. Nítorí náà, mo ní láti ṣe ìpínnu kan: Yí ò bójúmu ní ìlànà ìmọ̀ ẹ̀dá èdè láti ṣe ìmúdúró àwọn àṣàyàn ọ̀rọ̀ tí mo mẹ́nubà lókè, àmọ́ ìwọ̀nba èèyan ni yóò lè máa ka àkọsílẹ̀ mi. Tàbí mo lè lo “àwọn ẹ̀ka èdè” kí n sì fi èrò mi hàn ní pẹrẹu. Nítorí ipa tí mo fẹ́ kó ni ó jẹ mi lógún jùlọ, mo pinnu láti faramọ́ àṣàyàn kejì. N kò sọ pé bẹ́ẹ̀ ló rí, àmọ́ ìbí tí òye mi mọ nísìnyí nìyẹn.

Báwo ni ẹ ṣe lè ṣàlàye aṣeyọrí Euskara, tàbí ède Basque, bí a bá fi wọ́n wé àwọn ẹ̀ka èdè yóókù ní France?

Le basque constitue une exception. Il s’agit en effet de la seule langue régionale de métropole à gagner des locuteurs, et ce grâce au développement massif de l'enseignement en langue basque, qui permet de “produire” des locuteurs suffisamment nombreux pour remplacer les plus anciens. Ce succès s’explique lui-même par la mobilisation de la société civile basque. Le développement d'une langue dépend en effet de trois facteurs principaux : la densité de locuteurs dont on dispose autour de soi ; le sentiment de compétence linguistique et la motivation de chacun. Ce dernier élément, décisif, comprend lui-même deux dimensions. Un aspect utilitaire : une personne sera plus encline à apprendre une langue si celle-ci permet la réussite dans les études et l'obtention d'un emploi (ce pour quoi de nombreux Français cherchent à maîtriser l'anglais). Et un aspect identitaire, lié au sentiment d'appartenance, à l'amour de son territoire, à l'attachement que l'on porte à sa culture. Côté espagnol ces deux dimensions se cumulent. Côté français, c'est surtout l'aspect identitaire qui joue, même si l'aspect utilitaire est en progression.

Èdè Basque yàtọ̀ ní tirẹ̀: kódà, òhun nìkan ni ẹ̀ka èdè ni orílẹ̀ èdè France tí àwọn tó ń sọ ọ́ lé si ní iye. Èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí ètò ẹ̀kọ́ aládàá-ńlá ní èdè Basque tó ṣokùnfà “ṣisẹ̀dá” àwọn ọ̀pọ̀ eèyàn tó ń sọ èdè yìí dípò àwọn péréte tí ó ń sọọ́ tẹ́lẹ̀. Àṣeyọrí yìí wáyé nítorí ìpéjọpọ̀ àwọn tó ń gbé ní àwùjọ Basque. Òpó mẹ́ta gbòógì kan ni ó máa ń ṣe okùnfà ìdàgbàsókè èdè kan: bí àwọn tí ó ń sọ èdè náà bá ṣe gbóná sí, bí wọ́n bá ṣe lè lo èdè náà sí, àtí ohun tó ń gún àwọn olúsọ kọ̀ọ̀kan ní kẹ́ṣẹ́. Èyí tó jẹ́ ìkẹ́ta yìí gan ni ó ṣe kókó, ó sì pín sí méjì. Abala tó ní ṣe pẹ̀lú lílò: Èèyan máa mú èdè kíkọ́ ní ọ̀kúnnúdùn bí ó bá rọrùn láti lè fi kẹ́kọ̀ọ́-gboyè, kí wọ́n sì lè fi wá iṣẹ́ (èyí tó jẹ́ ìdí tí ọ̀pọ̀ eèyàn ní orílẹ̀ èdè France fi ń kọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì). Fún ìdánimọ̀: Èyí ní ṣe pẹ̀lú níní ìfọkànbalẹ̀ pé èeyan ní orísun, ó jẹ́ ará agbègbè kan, àti ànfààní sí àṣà ẹni. Ní ti àwọn Spanish [ní àwọn agbègbè wọn tó ń sọ Basque], gbogbo kókó náà ni wọ́n kó papọ̀. Ní ìha ti àwọn France,  kókó tó ní ṣe pẹ̀lú ìdánimọ̀ ló fi ẹsẹ̀ rinlẹ̀ jùlọ, àmọ kókó tó mọ lílò náà ti ń di pàtàkì.

N jẹ́ ẹ rò pé “ètò ẹ̀kọ́ tó lóòrìn”, níbi tí wọ́n ti ń fi ẹ̀ka èdè tí àwọn ọmọ ń sọ̀ kọ́ gbogbo iṣẹ́ ní ọdún péréte àkọ́kọ́, padà jẹ́ ohun tí àwọn ìlú tẹ́wọ gbà gẹ́gẹ́ bi ọ̀nà kan ṣoṣo tó yè kooro láti gbé àwọn èdè náà lárugẹ?

La réponse est complexe. D’un point de vue pédagogique, on sait qu’il s’agit de la meilleure méthode pour « produire » de bons locuteurs dans une société désormais francophone. On sait aussi que les élèves qui suivent ce cursus ne sont aucunement handicapés en français, au contraire : un rapport officiel du ministère de l’Education nationale à propos du réseau Diwan (les écoles immersives en breton) reconnaît que ses élèves obtiennent de meilleurs résultats en français que le reste du système scolaire !

L’enseignement immersif constitue donc le moyen idéal de combiner réussite scolaire et respect de la diversité culturelle. Hélas, il faut aussi compter avec l’idéologie… A Paris, de puissantes institutions– le ministère de l’Education nationale, le Conseil constitutionnel, le Conseil d’Etat – continuent de considérer que les langues dites régionales menacent l’unité de la nation et l’apprentissage du français. Espérons que les faits finissent par apaiser les esprits…

ìdáhùn yìí fẹjú. Bí a bá fi ojú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ wò ó, ọ̀nà yìí ló dára jùlọ láti “ṣẹ̀dá” olùsọ èdè tó dáńtọ́ ní àwujọ tó ti jẹ́ pé èdè Faransé ló gbajúmọ̀ níbẹ̀. Ó tún di mímọ̀ pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n fi ẹ̀ka èdè kọ́ nì ọdún péréte àkókó yìí tún gbọ́ èdè Faransé dáadaa. Ní ìdakejì:  Ìjábọ̀ tó bá òfin mu láti French Ministry of Education lóri ètò ẹ̀kọ́  Diwan [Ètò ẹ̀kọ́ tó lóòrìn ní Brezhoneg tàbí Breton, tó jẹ́ èdè Celtic ] rí i pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó wà ní irúfẹ́ àwọn iléèwé bẹ́ẹ̀ ní èsì ìdánwò tó dárá nínú èdè Faransé ju àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú ètò ẹ̀kọ́ tó wà tẹ́lẹ̀ lọ! Torí náà, ètò ẹ̀kọ́ tó lóòrìn yíì ni ọ̀nà tó dàra jùlọ láti kógo já nínu kíkọ́ ẹ̀kọ́ ìwé àti àṣà lóniruùru. Ó ṣe ni láàánú pé, èèyàn ní láti mójútó ojú ìwòye. . . ní Paris, àwọn àjọ tó lágbára bíi Àjọ Ètò Ẹ̀kọ́, Ìgbìmọ̀ Aṣòfin,  Ìgbìmọ̀ ìjọba, ṣì ń rí àwọn ẹ̀ka èdè gẹ́gẹ́ bi ohun tó ń dúnkokò mọ ìṣọ̀kan orílẹ̀ èdè àti kíkọ́ èdè Faransé. Ẹ jẹ́ kí a ní ìrètí pé wọn yóò rí àrídájú tí yóò jẹ́ kí wọ́n tún ọ̀rọ̀ náà rò.

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.