
Àwọn afẹ̀hónúhàn lásìkò ìwọ́de #EndSars. Àwòrán láti ọwọ́ Asokeretope tí a mú lóríi Wikimedia Commons (CC BY 4.0 DEED).
Bí orílẹ̀èdè Nàìjíríà se ṣe àjọyọ̀ àjọ̀dún òmìnira kẹrìnlélọ́gọ́ta (64th) lọ́jọ́ ìṣẹ́gun, èyí tí ṣe ọjọ́ 1 oṣù Ọ̀wàrà, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ará ìlú ni wọ́n ṣe ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn ní ìlú Abuja, èyí tí í ṣe olú ìlú orílè-èdè náà, àti àwọn ìlú ńlá mìíràn bíi Ẹ̀kọ́ àti Port Harcourt. Ìwọ́de náà tí wọ́n pé ní “FearlessinOctober,” bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n lo ìkànnì ìbánidọ́rẹ̀ẹ́ orí ẹ̀rọ-ayélujára fi kérò jọ, ṣùgbọ́n tí ó túká bí ìgbà tí iná bá tú ìjàlọ ká látàrí gáàsì atanilójú tí àwọn ọlọ́pàá yín sí àárín àwọn olùwọ́de.
Ìwọ́de Ọjọ́ Òmìnira: Àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà fi ẹ̀hónú hàn látàrí ìjọba fàmílétèntutọ́ lọ́jọ́ Àyájọ́ Òmìnira lọ́wọ́ amúnisìn ní abẹ́ afárá tí ó wà ní Ikeja.#October1 #EndbadGovernment #Protest #nigeria pic.twitter.com/shU8h9oJHB
— SNOW TV® 📡🎥📺 RC 3662284 (@OfficialSnowtv) October 1, 2024
Bíi ti àtẹ̀yìnwá, a ya ọjọ́ 1 oṣù Ọ̀wàrà sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bíi ọjọ́ ìsinmi fún sísa ààmì àjọ̀dún òmìnira orílè-èdè náà láti owó àwọn òyìnbó Gẹ̀ẹ́sì amúnisìn èyí tí ó wáyé lọ́jọ́ 1 oṣù Ọ̀wàrà ọdún 1960. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ́rí, Eagle Square ní olú ìlú ní Abuja ni àjọyọ̀ àjọ̀dún náà ti máa wáyé, ìbùdó àjọyọ̀ náà ti wá sún sí ilé Àpáta Àgbára (Aso Villa) nínú oṣù Ọ̀wàrà ọdún 2023. Akọ̀wé ìjọba àpapọ̀, George Akume, kéde pé ìjọba ò ní fa ayẹyẹ náà nítorí ètò ọ̀rọ̀ Ajé tí ò ń ṣòjòjò.
Ọ̀gọ̀rọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà ní wón ti fohùn lédè lórí ìkànnì ìbánidọ́rẹ̀ẹ́ X (èyí tí a mọ̀ sí Twitter tẹ́lẹ̀):
Independence my foot . The colonial masters are even better than we the owners of the country. We are ruled by syndicates rather than governments. There was a country . APC has ruined the little democracy we had left . #protest #IndependenceDay pic.twitter.com/UZ1B8amuj2
— Ghost Of Trafford (@ghostoftrafford) October 1, 2024
Òmìnira àbí omi ìnira. Àwọn òyìnbó amúnisìn gan-an sàn ju àwaarawa tí à ń darí orílẹ̀-èdè yìí lọ. Àwọn ọ̀jẹ̀lú ló ń tukọ̀ ìjọba wa kì í ṣe òṣèlú. Orílẹ̀èdè yìí kò rí bíi tàtijọ́ mọ́. Ẹgbẹ́ APC ti tapo sálà ìwọ̀nba ìjọba àwaarawa tí à ń rí tẹ́lẹ̀.
Olùdíjedupò ààrẹ lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ Labour Party nínú ètò ìdìbò gbogbogbò ọdún 2023, Peter Obi, ti rọ àwọn adarí àti ará ìlú láti ṣàròjinlẹ̀ lórí ipò tí orílẹ̀èdè náà wà lọ́wọ́lọ́wọ́.
Nínú ọ̀rọ̀ tó fi léde lórí ìkànnì X, ó ní: Ní ìwòye tèmi, ó yẹ kí òní ó jẹ́ ọjọ́ tí tolórítẹlẹ́mù lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà yó pe àró àti ọ̀dòfin inú rẹ̀, pàápàá jù lọ àwa tí a jẹ́ adarí tí ìgbésẹ̀ àti àìbìkítà wa ṣokùnfà ìfàsẹ́yìn àti wàhálà tí à ń dójúkọ lórílẹ̀èdè yìí lọ́wọ́lọ́wọ́.” Ó tẹ̀síwájú nínú ọ̀rọ̀ rẹ, ó tẹnumọ́ ìdí tí orílẹ̀èdè náà fi gbọdọ̀ di “Nàìjíríà Tuntun àti Ìlọsíwájú” tí yóò mú ìgbáyégbádùn àwọn ará ìlú lọ́kùnúnkúndùn.
Àìrajaja ètò ọ̀rọ̀ Ajé àti àwọn ìpèníjà
Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí í ṣe orílẹ̀èdè elérò púpọ̀ jùlọ ní orílẹ̀ Áfíríkà ń dójú kò ìṣòro àìrajaja ètò ọ̀rọ̀ ajé tó lágbára gidi gan-an, èyí tí ó ń ṣokùnfà ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ jákèjádò orílẹ̀èdè náà.
Àwọn ènìyàn tí bu ẹnu àtẹ́ lu Ààrẹ Bọ́lá Ahmed Tinúubú fún àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀ méjèèjì ti yíyọ owó ìrànwọ́ ẹpo bẹntiróòlù àti ìsọdọ̀kan pàṣípààrọ̀ iye owó òkè-òkun, èyí tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà nígbàgbọ́ pé ó ṣokùnfà ọ̀wọ́ngógó ohun gbogbo pátápátá porongodo. Iyé owó ohun àmúṣagbára ti fi ìlọ́po mẹ́ta wọ́n ju iye tí ó wà tẹ́lẹ̀ kí Ààrẹ Bọ́lá Ahmed Tinúubú ó tó górí àléfà ní ọjọ́ 29 Oṣù Karùn-ún ọdún 2023. Iye owó jálá epo bẹntiró kan fò sókè fẹ́rẹ́ láti 200 owó Náírà (USD 0.12) ó sì di 1,000 owó Náírà (USD 0.60), nígbà tí owó iná mànàmáná gbówó lórí sí i ní ìlọ́po mẹ́rin tí èyí sì mú ìnira ńlá bá àwọn ẹ̀ka ilé-iṣẹ́ àti ìṣúná owó àwọn ìdílé kọ̀ọ̀kan lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Nínú ìwádìí kan tí Ilé Ìfowópamọ́ Ìjọba Àpapọ̀ (CBN) ṣe láti ọjọ́ 22 sí 26 oṣù Kéje ọdún 2024, wọn ṣàkíyèsí wí pé ọ̀wọ́ngógó nǹkan yóò jẹ́ kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdílé ná owó púpọ̀ lórí oúnjẹ rírà. Ìwádìí Household Expectation Survey náà tí wọ́n ṣe lórí ìdílé 1665 káàkiri Ìpínlẹ̀ 36 àti agbègbè olú ìlú orílẹ̀èdè náà ní ó ní ìwọ̀n olùkọ́pa ìdá 99.7 nínú ọgọ́rùn-ún. Gẹ́gẹ́ bíi àlàyé National Bureau of Statistics (NBS), ìwọ̀n ọ̀wọ́ngógó nǹkan náà wà ní ìdá 32.15 nínú ọgọ́rùn-ún lọ́wọ́lọ́wọ́ tí ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ sì ń gbéra lọ sí ìdá 39.5 nínú ọgọ́rùn-ún.
Nínú ìfọ̀rọ̀léde rẹ̀ lórí ẹ̀rọ-amóhùnmáwòrán lọ́jọ́ àyájọ́ òmìnira, Ààrẹ Tinuúbú ṣàlàyé pé orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní láti fọwọ́ mú ọ̀kan nínú fífi ara mọ́ ṣíṣe àtúntò tí ó lè mú ìtẹ̀síwájú àti ìrọ̀rùn wá tàbí kí a túbọ̀ máa tẹ̀lé àwọn ìlànà tí à ń lò tẹ́lẹ̀ títí tí nǹkan yóò fi bàjẹ́ kọjá àlà. Ó ṣàlàyé bí ìjọba ohun tí ó gorí oyè ní oṣù 16 sẹ́yìn ṣe ń ṣe akitiyan láti ṣe àtúntò ètò ọrọ̀ Ajé tó dẹnukọlẹ̀ àti ètò ààbò tó mẹ́hẹ.
O ní, “Bí a ti ṣe ń ṣe àjọyọ̀ ìlọsíwájú tí ó ti débá àwùjọ wa láti ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́ta sẹ́yìn, a gbọdọ̀ rántí àwọn àǹfààní tí ó fò wá ru àti àwọn èèṣì tí a ti ṣe sẹ́yìn. Tí a bá fẹ́ di ọ̀kan lára àwọn orílẹ̀-èdè tó làmìlaaka lágbáyé, gẹ́gẹ́ bíi Ọlọ́run ti kọ ọ́ fún wa, a kò gbọdọ̀ jẹ́ kí àwọn èèṣì wa kò ṣàkóbá fún ọjọ́ ọ̀la wa.”
Ó pohùn-réré-ẹkún pé orílè-èdè Naijiria wà ní àkókò tí ó kan gógó nítorí àwọn ìṣisẹ̀gbé àtẹ̀yìnwá, ó sì ń rọ àwọn ará ìlú láti máà jẹ́ kí àṣìṣe wọ̀nyìí mú ìfàsẹ́yìn bá ọjọ́ ọ̀la orílẹ̀-èdè náà. Ààrẹ náà tún ṣàlàyé pé ìjọba òhun ti rán àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ikọ̀ alákatakítí Boko Haram àti “ọ̀gá àwọn agbésùnmọ̀mí” tó lé ní 300 ní ẹkùn àríwá-ìlà-oòrùn àti àríwá-ìwọ̀-oòrùn, pẹ̀lú níbòmíràn lọ sí ìrìnàjò àrìnmabọ̀.
Ó ṣàfikún pé àwọn àtúntò ètò ọrọ̀ Ajé tí ó ń lọ lọ́wọ́ ti mú kí àwọn ilé-iṣẹ́ láti ilẹ̀ òkèèrè wá dá okoòwò tí ó lé ní bílíọ̀nú dọ́là 30 sílẹ̀ láàárín ọdún tó kọjá sí ìgbà yìí.
Ìrètí fún ọjọ́ ọ̀la
Nígbà tí ó ń fi ọ̀rọ̀ lédè lórí afẹ́fẹ́ fún ti àyájọ́ Ọjọ́ òmìnira, Ààrẹ Tinuúbú kéde ìpè fún àpèjọ kan “Àpérò Ọ̀dọ́ Orílè-èdè Naijiria.” Ó ní àpérò náà yóò wáyé fún ọjọ́ 30 láti jíròrò lórí àwọn ìpèníjà tí àwọn ọ̀dọ́ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà , tí ó tó ìdá 60 nínú ọgọ́rùn-ún iye àwọn ènìyàn ọmọ orílẹ̀èdè Nàìjíríà ń dójúkọ.
Ìgbésẹ̀ yìí wáyé látàrí ìfajúro àwọn ọ̀dọ́ jákèjádò orílẹ̀èdè náà, èyí tí ó ti ń fà àwọn ìfẹ̀hónúhàn àtìgbàdégbà láti ìgbà ìwọ́de #EndSARS ọdún 2020 àti ìwọ́de #EndBadGovernance nínú oṣù Kẹjọ ọdún 2024.
Láti ṣe àjọyọ̀ àyájọ́ ọjọ́ òmìnira kẹrìnlélọ́gọ́ta (64th) ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ilé-iṣẹ́ Apple Music ṣàfihàn àwọn orin àti àwo-orin mẹ́wàá láti ọwọ́ àwọn akọrin tí wọ́n jẹ́ ọmọ Nàìjíríà èyí tí àwọn ènìyàn ń gbọ́ jùlọ. Ìgbésẹ̀ yìí jẹ́ èyí tí ó ń ṣe ìmọrírì àṣeyọrí àwọn olórin tí wọ́n jẹ́ ọmọ orílẹ̀èdè Nàìjíríà lórí ìgbàgede ìgbọ́-orin lórí ẹ̀rọ-ayélujára ọ̀hún, tí ó sì tún ń ṣàfihàn àwọn olórin àti àwo-orin tí àwọn ènìyàn ń gbọ́ jùlọ. “Made In Lagos” tí í ṣe àwo-orin olórin tàkasúfèé nnì Wizkid ni ó wà lókè téńté, tí àwo-orin mẹ́rin láti ọwọ́ọ Burna Boy sì tẹ̀lé e lórí àtòjọ náà.
Ẹ̀ka iṣẹ́ orin orílẹ̀èdè Nàìjíríà ti ròkè lálá láàárín ọdún mẹ́wàá tí ó kọjá tí ó sì ti di ọkàn lára àwọn ẹ̀ka tí ó làmìlaaka lórílẹ̀èdè náà, tí ó mú kí ọrọ̀ Ajé orílẹ̀èdè náà ó gbé pẹ́ẹ́lí bí ó ṣe ń pa owó tó kọjá bílíọ̀nù 2 owó USD wọlé lọ́dọọdún. Nínú àtẹ̀jáde àfojúsùn ilé-iṣẹ́ PriceWaterhouseCoopers, owó tí ẹ̀ka náà ń pa wọlé yóò to bílíọ̀nù 12.9 owó USD nígbà tí yóò bá fi di ọdún 2027.
Bákannáà, Nollywood, ẹ̀ka iṣẹ́ fíìmù tí ó tóbi jùlọ ṣìkejì lágbàáyé, ń pa owó tó rékọjá mílíọ̀nù 600 owó USD wọlé lọ́dọọdún, tí ó sì pèsè ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́, pàápàá fún àwọn ọ̀dọ́ ọmọ orílèèdè Nàìjíríà.
Pẹ̀lú bí àìrajaja ètò ọrọ̀ Ajé ṣe ń han orílẹ̀èdè náà léèmọ̀, àwọn ẹ̀ka iṣẹ́ àtinúda orílẹ̀èdè Nàìjíríà dúró gẹ́gẹ́ bíi ohun ìrètí fún orílẹ̀èdè tí ó ní ènìyàn púpọ̀ júlọ ní Áfíríkà náà.