Òṣìṣẹ́ wà lóòrùn, ẹni tí ó jẹ ẹ́ wà níbòji ni ọ̀rọ̀ àwọn tó ń wá ìwòsàn sí ìpèníjà ara àti àwọn olórí ẹ̀sìn ní Nàìjíríà.

Damilola Olawoyin. Toheeb Babalola ni ó pèsè àwòrán, ó sì gba àṣẹ kí ó tó lò ó.

Láti ọwọ́ọ Toheeb Babalola

Àwọn eèyàn ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀kan-dínlọ́gbọ̀n tó ní ìpèníjà ara (PWDs) ló wà Naijiria tí wọ́n ń finú-fíndọ̀ rin ìrìnàjò ọlọ́nà jínjín láti wá ìwòsàn sí ìpèníjà ara wọn. Àmọ́, ó ṣe ni lááánú pé, ẹ̀tàn tútù lásán ní èyí máa ń yọrí sí lẹ́yìn ìgbà tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn bá ti náwó-nára.

Àkọsílẹ̀ Word Bank Disability Assessment fi hàn pé, ìdá 7 awọn ọmọ tó lé ní ọdún márùn-ún nínú ẹbí kan (bákan náà ni ìdá 9 àwọn tí ọjọ́ orí wọn tó 60 jùbẹ́ẹ̀lọ) ni wọ́n ní ìpèníjà, ó kéré tán, níbi ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀yà ara tó jẹ́ òpómúléró bíi ẹ̀yà ara ìríran, ẹ̀yà ara ìgbọ́nràn, èyí tí a fi ń sọ̀rọ̀, tí a fi ń wo òye, tí a fi ń rìn, tàbí èyí tó níi ṣe pẹ̀lú ìtọ́jú ara ẹni.

Tí ó bá jẹ́ ti kí a wá ìwòsàn, Damilola Olawoyin, olùkọ́ kan tó ni ìpèníjà ojú, ẹni ọjọ́ orí 32, ti ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrírí tí ó tò láti fún-un ní ọgbẹ́ ọkàn ayérayé.

Láti ọmọ ọdún 10 ni ojú ti bẹ̀rẹ̀ sí ni yọ Olawoyin lẹ́nu ṣùgbọ́n àwọn òbí rẹ̀ kò mọ̀. Gẹ́gẹ́ bi ọmọ́dé tó fẹ́ràn eré púpọ̀, Ó pa èyí mọ́ra títí ìṣoro ojú rẹ̀ fi kọjá ààlà. Ìdí èyí ni àwọn òbí rẹ fi ń gbe kiri láti ilé ìwòsàn òyìnbó kan sí òmíràn fún ìtọ́jú. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àyẹ̀wò ní University College Hospital (UCH) ní Ìbàdàn, Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, àwọn Oníṣègùn òyìnbó ní àgbáríjọpọ̀ ààrùn ojú tó máa ń ba òpó ojú (èyí tó n ṣokùnfà ìríran) jẹ́, tí àwọn olóyìnbó ń pè ní glaucoma ni ó ń bá Olawoyin jà.

Wọ́n gba àwọn òbí rẹ̀ ní ìyànjú láti má fi ọwọ́ kan ojúu rẹ̀ lẹ́yìn ìtọ́jú kí ojú yìí lè bọ́ sípò díẹ̀díẹ̀. Àmọ́, pàbó ni ìtọ̀jú yìí já sí. Nítorí náà, bí Olawoyin ṣe ń dàgbà si, kò leè dá rìn bí àwọn eèyàn ò ràn-án lọ́wọ́ nítorí ojúu rẹ̀ tí kò ríran dáadáa mọ.

Ní ọdún 2009, Ó rin ìrìnàjò oní-kílómítà 208 (máìlì 129) láti Ìkọ̀tún, Ìpínlẹ̀ Èkó, sí Ilé-Ifẹ̀ ní Ìpínlẹ̀  Ọ̀sun, Ìwọ̀ oòrùn-gúsù, ní ìrètí láti wá ìyanjú sí ìṣoro rẹ̀. Ọ̀kan nínú àwọn ẹbí ìyá rẹ pè é sí ibi ìsọjí ìta gbangba kan ní Pápá-ìṣeré-ńlá Ifẹ̀. Bí ìsọjí náà tí n lọ lọ́wọ́, obìnrin ajíhìnrere kan, ọ̀kan nínú àwọn alákòso ìsọjí náà lọ bá a, Ó sì sọ fún-un pé, “Jẹ́ kí n gbàdúrà fún ọ, kí o lè ríran padà”

“Ó ṣe bíi ẹni tó mọ̀ nípa ìṣoro àìríran mi láì bèèrè lọ́wọ́ mi,” Olawoyin sọ èyí nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú Global Voices. “Ṣàdédé ni àwọn ọkùnrin méjì kan wọ́ mí lọ sí orí pèpele láti jẹ́rìí pé ojú mi ti là, wọ́n fi ipá mú mi pa irọ́ .”

Lẹ́yìn tí Olawoyin jẹ́rìí èké yìí tán, tí ó padà sórí ìjókòó rẹ̀, ajíhìnrere náà ní kí Ó wá rí òun ní ọjọ́ kejì. Baba Olawoyin náà wá sí Ilé-Ìfẹ láti wá rí arábìnrin tó nì òun lè wo ojú ọmọ òun sàn yìí.

Ajíhìnrere yìí mú wọn mọ wòlíì obìnrin kan tí ó ní kí Olawoyin àti bàbá rẹ̀ lọ ra màálù funfun kan tí kò ní àbàwọ́n àti àpótí ẹyin kan wá, èyí tí àwọn máa lò láti pèsè àsèje ìríran fún Olawọyin

Ó jẹ́ kó di mímọ̀ pé,“Wọ́n ní n dúró lórí Àgbò náà kí n sì fi ọṣẹ kan wẹ̀. Lẹ́yìn èyí, mó bẹ̀rẹ̀ síi fọ́ àwọn ẹyin náà lẹ́yọ̀kọ̀ọ̀kan. Pẹ̀lú pé mo kọ̀ jálẹ̀, wọ́n padà ní kí n san NGN 17,000 (USD 10).”

Ojú Olawoyin túbọ̀ ń peléke si. Bàbá rẹ̀ kú, ìyá rẹ̀ sì fẹ́ ọkọ míràn.

Ní 2014, lẹ́yìn tí Ó padà sí Èkó, Funmilayo, ìyá Olawoyin wá ìwòsàn lọ sí ọ̀dọ̀ wòlíì kan ní ilé ìjọsìn Cherubim and Seraphim kan ní Ikotun-Egbe. Wòlíì obìnrin kan tó jẹ́ ọ̀rẹ́ sí ọkọ rẹ̀ tuntun ló mú-un mọ̀ ọ́. Olawoyin ṣàlàyé pé; “Wọ́n ní wòlíì náà ní agbára tó lè jí òkú dìde. Bí ó bá lé ṣe bẹ́ẹ̀, bí ìgbà tí eèyàn fi ẹran jẹ ẹ̀kọ ni dídá ojú mi padà sípò yóò jẹ́ fún-un”. Olawoyin àti àwọn míràn sọ ìrírí wọn nínú fọ́nrań YouTube ìsàlẹ̀ yìí:

Lẹ́yìn ìdúró pípẹ̀, Olawoyin àti ìyá rẹ fijú rinjú pẹ̀lú Wòlíì náà. Ó tẹ ojúu Olawoyin bí ó ti wù ú, Ó sì béèrè àwọn ìbéèrè kọ̀ọ̀kan lọ́wọ rẹ̀. Lẹ́yìn èyí ni ó ní kí wọ́n lọ wá NGN 60,000 (USD 37) wá. Ìyá rẹ̀ bẹ̀bẹ̀ títí fún ẹ̀dínwó, àmọ́ Wòlíì náà kọ̀ jálẹ̀.

Lẹ́yìn-ò-rẹyìn, Ó gbà láti san owó náà, wòlíì gbàdúrà fún ọmọ rẹ̀. Oríṣiríṣi ìbéèrè ló ń sọ lọ́kàn Olawoyin bí wọ́n ṣe ń padà sílé.

Gọngọ sọ ní ilé ìjọsìn náà lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjì tí ìyá Olawoyin ń tu owo tí wọ́n fẹ́ kó fún Wòlíì náà jọ. Ìyá rẹ̀ sáré lọ sí ilé ìjọsin yìí, ó bá ọkọ àwọn Ọlọ́pàá ní ìta tí wọ́n sì ti fọ́ gbogbo pẹpẹ yángá. Àwọn agbófinró ti kó sẹkẹ́ṣẹkẹ̀ sí Wòlíì lọ́wọ́, wọ́n sì jẹ́ kó di mímọ̀ pé Òun ni aṣáájú àwọn ọ̀dájú adìgùnjalè tí wọ́n ṣokùnfà oríṣi ìtàjẹ̀sílẹ̀ ní Èkó àti àwọn ibòmíràn.

Olawoyin ní; “Ọgbẹ́ ọkàn ní èyí jẹ́, kò sí ẹni tó lè rokàn irú èyí sí. Ọ̀gá àwọn adigunjalè ni, Ó ń fi ilé ìjọsin bojú”.

Àwọn Ọlọ́pàá bá owó, ìbọn méje, oògùn abẹnu gọngọ, àti àwọn ohun èròjà olóró míràn ní ilé ìjọsìn náà. Wọ́n gbe ẹjọ́ Wòlíì yìí lọ́ sí ilé ẹjọ́, wọ́n sì dájọ́ fún-un ní ilé ẹjọ́ tó ga jù ní Èkó (Lagos Magistrate’s Court).

Ní Apẹtẹ, Ibadan,  Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ridwan Tijani, ọmọ ọdún 30, Aránbàtà tí ó ń fi àga-oní-kẹ̀kẹ́ rìn náà ní irú ìrírí bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú oníwòsàn ìbílẹ̀ kan tí wọ́n ń pè ní “Ìyá Ọ̀sun” nígbà tí ó ń wá ìwòsàn sí ààrùn rọpá-rọsẹ̀ rẹ̀.

Ridwan Tijani. Toheeb Babalola ni ó pèsè àwòrán, ó sì gba àṣẹ kí ó tó lò ó.

Gẹ́gẹ́ bi ẹni tó ti rọ lẹ́sẹ̀ láti kékeré,Tijani ò ní ìmọ̀ kíkún lóri okùnfà ìpèníjà ara. Ó jẹ́ kó di mímọ̀ pé, bàbá rẹ mú-un lọ sí Ìjẹ̀bú Òde ní ọ̀sán ọjọ́ kan láti lọ bá ìyá náà ní ojúbọ rẹ̀ tí wọ́n ń pè ní ojúbọ Ọ̀ṣun.

Lẹ́yìn tí wọ́n rin ìrìn kìlómítà 73 (máìlì 45) láti Ìbàdàn sí Ìjẹ̀bú Òde ní Ìpínlẹ̀ Ògùn, Tijani fí ojú rinjú pẹ̀lú Ìyá Ọ̀ṣun. Ó wọ asọ funfun ní ìbámu pẹ̀lú ojúbọ rẹ̀. Ìyá yìí fi abẹ ge ẹsẹ̀ Tijani méjéèjì, Ó fi ẹnu fa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, Ó sì tu ú sí ara àwọn àjákù ìwé funfun tí wọ́n fi òwú dúdú àti funfun wé.

Tijani ṣàlàyé fún Global Voices pé;“Ní àsìkò náà, ẹni kan tó ń jẹ́ Ifá ń dọfẹ lọ, dọfẹ bọ̀ ní iwájú mi tí ó sì n bá mi sọ̀rọ̀. Kò dá mi lójú pé eéyán ní. Kò sí ǹkan kan tó ṣiṣẹ́, n ò sì rí wọn mọ́ lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ díẹ̀. “Ìwòsàn ní à ń wá àmọ́ àwọn apidán ni a bá pàdé”

Ọkùnrin míràn tó ní ìpèníjà ojú, Samuel Oluwasegun Dabiri, tó kẹ́kọ̀ọ́ gboyé nínú ìmọ̀ tó níi ṣe pẹ̀lú àjọṣepọ̀ ilẹ̀ okèèrè ní ilé Ẹ̀kọ́ gíga Obafemi Awolowo University (OAU).

Samuel Oluwasegun Dabiri. Toheeb Babalola ló pèsè àwòrán. Ó gba àṣẹ kí ó tó lò ó.

Ilẹ̀ gbígbóna lo kọlu Dabiri ní ọdún 1996, àwọn òbí rẹ̀ ò sì ní agbára ìwòsàn òyínbọ̀ títí àìsàn yìí fi wọ̀ ọ́ lára tí ó sì mú ojúu rẹ̀ méjéèjì lọ.

Bàbá rẹ̀ gbé e lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn olùsìn Orìṣà Ṣàngó, níbi tí wọ́n ti sọ pé kí wọ́n fi àwọn èròjà bíi àgbò, ewúrẹ́, epo pupa àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó ṣe ètùtù.

Dabiri sọ fún Global Voices pé, “Àwọn ǹkan wọnyìí wọ́n gógó nígbà náà ju ìsínyìí lọ. Bàbá mi ná owó tó jọjú láti ríi pé ètùtù yìí wáyé àmọ́, a kàn fi owó, àkókó àti ìgbìyànjú wa ṣòfò lásán ni”.

Lẹ́yìn fífara da ìbanilọ́kànjẹ́ tó níi ṣe pẹ̀lú ìpèníjà ara fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, Olawoyin, Tijani àti Dabiri gba kámú lóri ìpènijà wọn, wọ́n sì gbájú mọ́ isẹ́ẹ wọn. Wọ́n rọ ìjọba Nàíjíríà láti fi òntẹ̀ lu òfin tó mú ìgbàláàyè wà fún àwọn tó ní ìpèníjà ara ti ọdún 2018.

Kí ni àwílé àwọn Akọ́ṣẹ́mọsẹ́?

Grace Fehintola, Olùdásílẹ̀ God Grace Health Centre, fi èhónú rẹ̀ hàn lóri àwọn Wòlíì tó ń tẹ àwọn ojú tó ní ìpènijà bí ó ti wù wọ́n, èyí tí ó lè túbọ̀ fa akoba fún ojú bẹ́ẹ̀. Ó tún kìlọ̀ pé àwọn ọṣẹ tí wọ́n ń lò fún ètùtù tí kìí ṣe pé àwọn akọ́ṣẹ́mọsẹ́ fi òǹtẹ̀ lù, lè ṣe àkóbá fún ara.

Yinka Olaito, Olùdarí àgbà fún Centre for Disability and Inclusion Africa (CDIA), sọ pé, ẹ̀sìn ti di ọgbà tí àwọn eèyàn ń sá di ní gbogbo ọ̀nà, àwọn olórí ẹ̀sìn tó jẹ́ páńda sì sọ àwọn tó ní ìpènijà ara (PWDs) di jẹun jẹun. Ó dá àbá pé “Ó yẹ kí ẹ̀kọ́ wà fún àwọn àjọ tó ń rí sí ẹ̀sìn àti àwọn olùdarí wọn lórí ewu tó wà nínú èyí. Fún ìlọsíwájú tó gbòòrò, ó yẹ kí àwọn agbófinró àti àwọn àjọ PWD fi ọwọsowọ́pọ̀”

 

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.