Elfredah Kevin-Alerechi ni Akọ̀rọ̀yìn, The Colonist Report ti ilẹ̀ Áfíríkà ní ó kọ́kọ́ tẹ iròyìn yìí jade, Faith Imbu àti Kevin Woke sì ṣe àfikún sí iròyìn náà. Global Voices ṣe àtúntẹ̀ ìròyìn yìí ní ṣókí gẹ́gẹ́ bí apá kan nínú àdéhùn ajẹmọ́ gbígbé àkóónú jade.
Ìwádìí tí The Colonist Report Africa ṣe fi hàn pé àwọn obìnrin ní Ìpínlẹ̀ Rivers ṣì ń kojú ìṣòro ilẹ̀ níní, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ofin ti wọ́gi lé fífí ẹ̀tọ́ dun obìnrin nínú jíjẹ ogún ẹbí bí ó ti hàn ní abala òfin kejì, ọdún 2022.
Ní àsìkò tí òfin yìí jáde, àjọ tó ń gbẹnusọ fún àwọn obìnrin tí a mọ̀ sí International Federation of Women Lawyers (FIDA) jẹ́ kó di mímọ̀ pé ofin túntún yìí yóò fún àwọn obìnrin ìpínlẹ Rivers ní ànfààní láti mọ ipò ara wọn àti láti lè jẹ́ kí ẹ̀tọ́ wọn tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́, tí yóò sí jẹ́ kí irúfẹ́ ojúṣàájú yìí di ohun àgbéyẹ̀wò ní ilé ẹjọ́.
The Colonist Report ṣe àbẹ̀wò sí àwọn agbègbè mẹ́ta kan ní Ìpínlẹ̀ Rivers láti lè mọ̀ bóyá àwọn alákoso agbègbè náà ń tẹ̀lẹ́ òfin, ṣùgbọ́n a ríi pé àgbọ̀nrín èsí ni àwọn kan ṣì ń jẹ lọ́bẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ náà.
Iṣẹ́ àgbẹ̀ ni wọ́n yàn láàyò ní àwọn agbègbè tí a lọ yìí, ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin wọn ni ó sì jẹ́ pé oko dídá àti èrè oko títà ní ọjà ni wọ́n fi ń gbọ́ bùkátà ẹbí wọn.
A ríi pé, bí wọ́ ṣe ń fi ilẹ̀ oko dun àwọn obìnrin tó, àwọn obìnrin kan ń ra ilẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọmọ kékéèké tí wọ́n ní ilẹ̀ àmọ́ tí wọn ò ní owó láti ṣíṣẹ́ lórí ilẹ̀ náà, wọ́n sì kọ́ ilé lé sórí ilẹ̀ náà tàbí kí wọ́n fi dá oko.
Síwàjú si, àwọn obìnrin ń lọ́ra láti sọ̀rọ̀ tó níí ṣe pẹlú ilẹ̀ wọn látàrí ìbẹ̀rù pé kí àwọn ẹbí ọkọ tàbí olórí àdúgbò wọn má baà gbà ilẹ̀ náà lọ́wọ́ wọn.
Àwọn àṣà àdáyébá tó ń tẹ àwọn obìnrin mẹ́rẹ̀
Àsà àti ìṣe Ogoni kò gba àwọn àkọ́bí obìnrin láàyè láti lọ sílé ọkọ amọ, aàyè wà fún wọ́n láti bímọ sí abẹ́ orùlé bàbá wọn. Láisì àní-àní, ẹbí ọmọbìnrin ni ó ni àwọn ọmọ tí wọ́n bí yìí kìí sẹ bàbá wọn. Àṣà yìí ni wọ́n ń pè ní Sirah Syndrome (ẹbí ìyá ló lọmọ).
Susan Serekara-Nwikhana, ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dógún tí ìyá rẹ̀ ń jẹ́ Salome Nwiduumteh Nwinee, tó jẹ́ ọ̀kan lára awọn ọmọ́ ilé ẹbí ìyá ló lọmọ yìí ṣàlàyé pé:
“Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, gbogbo àwọn ọmọ yìí ni wọ́n jẹ́ ojúlówó ọmọ nínú ẹbí ìyá wọn dípò ti bàbá tó fún ìyá wọn lóyùn”
Serekara-Nwikhan jẹ́ kí ó di mímọ̀ pé, bí iya òun ṣe rẹwà tó, tí ò sì jẹ́ pé ẹwà rẹ̀ máa ń pe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkunrin láti fẹ́ ẹ, wọn kọ̀ọ́ fún láti fẹ́ ọkọ.
Serekara-Nwikhana ṣàlàyé pé; “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pe kò sí nínú àṣà pé kí obìnrin máa lọ sílé ọkọ, síbẹ̀ wọn kìí pín ilẹ̀ kan àwọn obìnrin, ní èyí tí ó sì jẹ́ ọ̀nà kan gbòógì tí wọ́n fi ń gbọ́ bùkátà ẹbí wọn. Níwọ̀n ìgbà tí ilẹ̀ pínpín yìí ò bá sì kàn wọ́n, ìyà àjẹbánu a máa jẹ àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ wọn”.
Agbègbè Rumuwhara
Justine Ngozi Orowhu , a farmer in the Rumuwhara community in Obia-Akpor, told us that she inherited 14 plots of land from her father, which she used for farming. However, after he died, community leaders seized the land and sold it to local men because she had no male siblings.
Justine Ngozi Orowhu, àgbẹ̀ kan ní agbègbè Rumuwhara ní Obia-Akpor, sọ fún wa pé òun jogún èèbú ilẹ̀ mẹ́rìnlá lọ́wọ bàbá òun tí òun fi ń dá oko. Àmọ́ lẹ́yìn tí bàbá òun kú, àwọn olórí àdúgbò náà fí ipá gbá ilẹ̀ náà, wọ́n sì tà á fún àwọn ọkùnrin ìlú nàá. Èyí wáyé bẹ́ẹ̀ nítórí òun kò ní ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò ọkùnrin kan.
Orowhu di ẹni tí ó n ta ọjà pẹ́pẹ́ẹ̀pẹ́ torí àtijẹ-àtimu. Sùgbọ́n, ó dáwọ́ ọjà pẹ́pẹ́ẹ̀pẹ́ náà dúró lẹ́yìn tí ọkọ rẹ̀ dùbúlẹ̀ àìsàn. Ní ọdún 2014, Ó pe àwọn olórí agbègbè náà lẹ́jọ́ pẹ̀lú ẹ̀sùn pé wọ́n gba ilẹ̀ òun àmọ́, gẹ́gẹ́ bí alàyé rẹ̀, kò rí ìdájó òdodo lórí ọ̀rọ̀ náà. Ní báyìí, ó ń dáko lóri ilẹ̀ ìjọba, ní èyí tí ó sì mọ̀ pé òun ní láti fi sílẹ̀ nígbàkúgbà tí ìjọba bá fẹ́ lo ilẹ̀ náà.
Àgbékẹ̀lẹ́ rẹ̀ wà nínú òfin tó fún àwọn obìnrin ní ànfààní láti jogún ilẹ̀ baba wọn ti Nyesom Wike, Gómìnà tẹ́lẹ̀rí ní Ìpínlẹ̀ Rivers, bu ọwọ́ lù. Ó ní “bí mo ba rí agbẹnusọ tí ó lè jà fún mi, mo máa tún asọ ṣí lójú ẹjọ́ náà ní ilé ẹjọ́”
Chris Wopara, Akọ̀wé àwọn ọ̀dọ́ ní Rumuwhara ṣàlàyé pé, obinrin ko le jogun ilẹ̀ nínú àṣà àti ìṣe agbègbè náá, bẹ́ẹ̀ ọmọkùnrin gbọ́dọ́ ti lé ní ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n, kí ó sì máa kópa nínu àwọn ojúṣe tí ó ń lọ nínú ẹbí kí ó tó lè ní ànfààní sí ilẹ̀. Ó ní “Pínpín ilẹ̀ fún ọmọ ọkunrin máa ń wáyé lẹ́yìn iṣẹ́ àtìgbà-dégbà fún ẹbí láàárín ọdún kan.
Ọ̀kan nínú àwọn àgbà ní agbègbè náà, Fineface Wopara sọ wípé “Àwọn ìjọba ò ní ẹ̀tọ́ látí fi ipá mú wa pé kí a máa fún àwọn ọmọbinrin wà ní ilẹ̀ nìtorí pe ọmọbìnrin á lọ sílé ọkọ”
Ó tún fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé “Bí ọmọbìnrin bá jẹ ogún ní ilé bàbá rẹ̀, ó túmọ̀ sí pé anfaani rẹ yoo ga ju ti ọmọkunrin lọ. Ogún ilé ọkọ ni tirẹ̀”
Agbègbè Omuanwa
Ní agbègbè Omuanwa, gbogbo ọmọkùnrin, kóda ọmọ ọdún kan, ni wọn máa ń bu ilẹ̀ fún ní gbogbo àyájọ̀ ilẹ̀ pínpín tó má ń wáyé ní ọdọọdún. Ẹ̀wẹ̀, wọ̀n kìí fún àwọn obìnrin ní ilẹ̀ láti fi kọ́ ilé; dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n á yá àwọn àgbẹ̀ inú wọn ní ilẹ̀ tí wọn sì gbọ́dọ̀ dá pádà lẹ́yìn tí wọ́n bá ti kó èrè oko wọn.
Lẹ́ẹ̀kannáà, a fi ọ̀rọ̀ wá àwọn obìnrin mẹ́fà àti àwọn àgbààgbà ọkunrin méjì lẹ́nu wò láti fí lè ní ìmọ̀ tó kún lóri bóyá awọn obìnrin ti ní anfaani sí ilẹ̀ ní agbègbè náà gẹ́gẹ́ bíi àlàkalẹ̀ òfin tí wọ́n fi oǹtè lù ní ọdún 2022.
Àwọn obìnrin tí a fi ọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò jẹ́ kí ó di mímọ̀ pé, ní ọdún 2023, àwọn ọkùnrin, kóda dé orí kékeré wọn ni wọ́n ń pín ilẹ̀ fún ní agbègbè Omuanwa. Kò sí obìnrin kan tí wọ́n ń pín ilẹ̀ kàn , yálà “omidan, opó tàbí abílèkọ”, Florence Ejinya, àgbẹ̀ kan tí ìyà ilẹ̀ oko ń jẹ ni ó sọ èyí di mímọ̀ fún wa. Ó tún fi kún-un pé “Kò tilẹ̀ sí ilẹ̀ kan báyìí mọ́ fún obìnrin láti fi dáko ní agbègbè Omuneji”
Nígbà tí a beèrè bóyá àwọn obìnrin ti fi ìgbà kan ṣe ìwọ́de ìfẹ̀họ́nùhàn lóri ojúṣàájú yìí, wọ́n ni irú èyí kò tíì wáyé rí. Ọ̀kan nínú àwọn àgbà àdúgbò, Gibson Ajoku ṣàláyé pé, àṣà kí wọ́ má maa fún obìnrin ní ilẹ̀ kìí ṣe tuntun, ó ti wà láti ìgbà ayé àwọn babá-ńla àwọn tí kò sì lè yí padà.” Ó tún ṣàfikún ọ̀rọ̀ náà pé, ilé ọkọ obìnrin ni ó yẹ kí wọ́n ti máa retí àti jogún ilẹ̀. Nígbà tí a beèrè nípa òfin tuntun tó fi ọwọ́ sí kí obìnrin lẹ́tọ̀ọ́ láti jogun, Ó ni oun kò mọ̀ nipa irú ofin bẹ́ẹ̀.
Ọkan lara awọn ará agbègbè náà, ThankGod Ejiowhor jẹ́ kí a mọ̀ pé lóòótọ̀ ni ofin yìí wà àmọ́, kò tíì sí ìgbàláyè fún obinrin láti jogún tàbí pín nínú ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà sì ní kíkópa nínú owó orí pínpín.
Agbègbè Rumukurushi
Agbègbè Rumukurushi ti ìjọba ìbílẹ̀ Obio Akpor, ní Ìpínlẹ̀ Rivers ní tiẹ̀ wà ní àárín ìgboro. Ọjà Oil Mill, ẹsẹ̀ ò gbèrò kan gbòógì, jẹ́ ibi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn eèyàn nílé lóko ti máa ń dúnà dúrà oríṣiríṣi ọjà. Síbẹ̀, àwọn obìnrin ṣì n ní ìpèníjà tí ó jẹmọ́ ọ̀rọ̀ ilẹ̀ níní. Pabanbarì ibẹ̀ ni pé, ìdàgbàsokè tún ń ṣe àfikún sí ìpèníjà yìí.
Blessing Amam mú bí wọ́n ṣe wọ́n ya àwọn obìnrin sọ́tọ̀ gedegede nínú ilẹ̀ pínpín ní ọdun 2021 wá sí ìrántí.
Amam sọ pé: “Kò sí ogún kankan fún obìnrin tí kò bá bí ọmọkùnrin àyàfi bí obìnrin bẹ́ẹ̀ bá ní àbúrò tàbí ẹ̀gbọn ọkọ lọ́kùnrin tó dáa tí ó lè fún-un lára ilẹ̀ tiẹ̀ láti dáko”
Akitiyan Ìjọba àti àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọniyàn.
Roseline Uranta, Kọ́míṣọ́nà fún ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ obìnrin ní Ìpínlẹ̀ Rivers, yànnàná ẹ̀ pé kii ṣe ofin tabi ilakalẹ awọn ijọba ló sọ ilẹ̀ níní di eèwọ̀ fún àwọn obìnrin bí kìí ṣe aṣa àti ìṣe tó ti di bárakú fún wọn.
Nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tí a ṣe, Uranta rọ àwọn obìnrin tí ọ̀rọ̀ ìfẹ̀tọ́dunni yìí kàn pé kí wọ́n fi tó àwọn àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ obìnrin létí. Kò ṣàí jẹ́ kó di mímọ̀ pé àwọn obìnrin kan máa ń wá fi irú ẹjọ́ yìí sùn, a sì máa ń ṣe ìwádìí láti yanjú irú àwọn ọ̀rọ̀ yìí. Ó tún ní, “Bí ọ̀ran náà bá sì le, FIDA ni a máa ní kó yanjú ẹ̀”
Bio Adata, alága fún FIDA, fi ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ hàn lóri ìrẹ́jẹ obìnrin tí kò kásẹ̀ nílẹ̀ yíì àmọ́ ó ní ìrètí pé òfin yóò ró wọn lágbára láti rí ìdájọ́ òdodo gbà.
Wole Soyinka Centre for Investigative Journalism (WSCIJ) ló ṣe ìgbòwó fún ìròyìn The Colonist Africa lábẹ́ àjọ Champion Building component of its Report Women! News and Newsroom Engagement project.