- Global Voices ní-Yorùbá - https://yo.globalvoices.org -

Ìdílé Kútì tí ń fẹ̀hónúhàn nípasẹ̀ orin àti àwọn ọmọ Nigeria mìíràn tí wọ́n kọrin táko ẹlẹ́yàmẹ̀yà

Sàwáwù : Ìlú Gúúsù Aṣálẹ̀ Sahara, Nàìjíríà, Àṣà àti Iṣẹ́-ọnà, Ìròyìn Ọmọ-ìlú, Orin, A journey into African music, Music Club
Orlando Julias’ band (Nigeria). Image by Steve Terrell, September 26, 2015 (CC BY 2.0)

Egbẹ́ akọrin Orlando Julias’ (Nigeria). Àwòrán láti ọwọ́ Steve Terrell, ọjọ́ 26, Ọ̀wẹwẹ, 2015 (CC BY 2.0)

Àwọn olórin Nigeria máa ń fọhùn síta dáadáa nípa ìyànjẹ àwùjọ ní orílẹ̀-èdè náà. Èdè ìperí orin ẹ̀hónú gẹ́gẹ́ bí irúfẹ́ orin kan, tí ó di ìtẹ́wọ́gbà bí àṣà láàárín àwọn ọdún tí ó tẹ̀le 1970, ṣì ń tẹ̀síwájú títí di òní. Àwọn orin wọ̀nyí gbógun ti ìjọba ológun afipáṣèjọba, ẹlẹ́yàmẹ̀yà ní South Africa, àti ìwà ìkà ọlọ́pàá, bí ara àwọn ẹ̀hónú #EndSARS tí àwọn ọ̀dọ́ léwájú. 

Bàbá orin ẹ̀hónú orílẹ̀-èdè Nigeria

Iṣẹ́-ọnà tí ó jẹ́ àpèjúwe Fẹlá Aníkúlápò Kútì. Àwòrán láti ọwọ́  Danny PiG [1] ti a gbé sórí Flickr ní Ọ̀wẹwẹ 11, 2012. (CC BY-SA 2.0 [2])

Fẹlá Aníkúlápò Kútì (1938–1997), bàbá orin ẹ̀hónú Nigeria, ṣàmúlò oríṣi orin àrà ọ̀tọ́ Afrobeat (orin aṣàmúlò-àwọn nǹkan èròjà ilẹ̀ Adúláwọ̀) rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ orin tí ó kún fún “ẹ̀fẹ̀ ẹlẹ́dà-ọ̀rọ̀, títako àwọn aláṣẹ, àti mímọ̀ nípa òṣèlú” gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà láti gbógun ti ìrẹ́jẹ láwùjọ, àwọn àkíyèsí [3]Títílayọ̀ Rẹ̀mílẹ́kún Osuagwu, onímọ̀ nípa àṣà ní Fáfitì Port Harcourt ti Nigeria. 

Gbígbọ́n ṣáṣá Fẹlá dá lórí ìgbékalẹ̀ èròngbà rẹ̀ nípa àwọn okùnfà ìninilára. Ìdí nìyí tí orin rẹ fi wà — títí di òní — gẹ́gẹ́ bí ohun èlò alágbára nínú “ṣíṣe àtìlẹ́yìn fún àwọn ẹ̀hónú tí ó ń lọ lọ́wọ́,” Olúkáyọ̀dé ‘Ṣẹ́gun Èésúọlá, ẹni tí ó jẹ́ onímọ̀ nípa ẹ̀kọ́ ìmọ̀ sáyẹ́ńsì ìṣèlú ní Fáfitì Èkó ní Nigeria ni ó sọ èyí [4]. Nínú nnkan bíi ó lé ní ọgbọ̀n ọdún tí ó ti ń ṣiṣẹ́ orin, ó mú kí àwọn ìran ọmọ orílẹ̀-èdè Nigeria mọ̀ síi nípa ìmọ̀ òṣèlú. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, èyí fa àwọn àbẹ̀wo tó rorò láti ọwọ́ àwọn ẹ̀sọ́ elétò ààbò àwọn ìjọba orílẹ̀-èdè Nigeria tí ó tẹ̀léra. 

Lóòótọ́, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orin Fẹlá ni ó fi ṣe ìbáwí àṣejù àwọn ìjọba ológun tí wọ́n tẹ̀léra ní orílẹ̀-èdè náà. Nigeria wà lábẹ́ àkóso ìjọba ológun fún ọdún 29 (láti 1966 sí 1979 àti 1983 sí 1999).

Ní àsìkò ikú rẹ̀ ní ọdún 1997, àwọn àkójọ orin amúbíiná Fẹlá ti fi í sí ipò láwùjọ àwọn olórin “ní àgbáyé gẹ́gẹ́ bí àwòkọ́ṣe òǹkọrin òṣèlú,”” èyí ni ọ̀rọ̀ [6]Tẹjúmọ́lá Ọláníyan, Ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ àwọn Èdè àti Lítírésọ̀ ilẹ̀ Adúláwọ̀ ní Fáfitì Wisconsin-Madison nínú ìwé àtinúdá rẹ̀ “Arrest the Music! Fẹlá & His rebel art and politics” (Mú orin náà! Fẹlá tòun ti ọnà ìdìtẹ̀ ìjọba àti òṣèlú rẹ̀).” 

Fẹ́mi àti Ṣeun Kútì, àwọn ọmọ Àjànàkú ò yaràá

Àwọn ọmọkùnrin Fẹlá méjèèjì, Fẹ́mi àti Ṣeun, ti jogún wọ́n sì gbá ìfẹ́ bàbá wọn fún ìdájọ́ àwùjọ nípasẹ̀ orin “ [7]” ṣinṣin.

Fẹ́mi Kútì, ń ṣeré níbi Warszawa Cross Culture Festival. Àwòrán láti ọwọ́ Henryk Kotowski lórí Wikimedia Commons [8], 25 Ọ̀wẹwẹ 2011 (CC BY-SA 3.0 [9])

Fẹ́mi Kútì, [10] ọmọkùnrin Fẹlá tí ó dàgbà jù lọ, jẹ́ olórin Afrobeat tó mọ oyún-ìgbín-nínú-ìkarahun àti afọnfèrè sáàsì tó dára bí ó ti tọ́. Àwọn orin Fẹ́mi bíi “Sorry Sorry [11]” (Ó ṣe Ó ṣe), “What Will Tomorrow Bring [12]” (Kín ni Ọjọ́ Ọ̀la yóò mú wá) àti “'97 [13]” — kò dá àwọn adarí oníbàjẹ́ tí wọ́n joyè àwòdì má leè gbẹ́dìẹ sí. Fún àpẹẹrẹ, nínú “Sorry Sorry” (Ó ṣe Ó ṣe), Fẹ́mi sọ̀ lórí ìgbìyànjú àgàbàgebè àwọn adarí, tí wọ́n ba orílẹ̀-èdè náà jẹ́ níkọ̀kọ̀ ṣùgbọ́n tí wọ́n ń díbọ́n láti wá àwọn ojútùú ní gbangba: 

Politicians and soldiers make meeting/Our country dem wan repair/Dem dey make like say/Dem no know/Say na dem a spoil our country so

Àwọn olóṣèlú àti àwọn ológun ń ṣe ìpàdé/Wọ́n fẹ́ ṣàtúnṣe sórílẹ̀-èdè wa/Wọ́n ń hùwà bí ni pé/Wọn kò mọ̀/Pé àwọn ni wọ́n ba orílẹ̀-èdè wa jẹ́

Fẹ́mi, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ti jẹ́ fífi sílẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ìgbà fún àmì ẹ̀yẹ Grammy, jẹ́ ẹni tí ó láyà tí kò sì ní sùúrù gẹ́gẹ́ bíi bàbáa rẹ̀ olóògbé. Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan pẹ̀lú Vanguard, ìwé ìròyìn Nigeria kan, ní oṣù Èrèlé 2011, ó bu ẹnu àtẹ́ lu àwọn ọ̀jẹ̀lú Nigeria [14]: “Ó hàn gbangba gbàngbà pé nǹkan ò ṣẹnu ‘re ní orílẹ̀-èdè wa; àwọn olóṣèlú kò yéé jí owó, a kò ní àwọn òpópónà tí ó dára, ètò-ẹ̀kọ́ tí ó yẹ, àti omi tí ó ṣe é mú àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Èmi ò lè gba ìyẹn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nigeria ń jìyà. Èmi kò gba èyí bẹ́ẹ̀ ni bàbá mi ti fi ọ̀nà kan hàn wá láti máa fi ẹ̀hónú hàn nípasẹ̀ orin èyí sì ni ohun tí mò ń ṣe.”

Ṣeun Kútì ní Marsatac Festival ti 2008 ní Marseille, France. Àwòrán láti ọwọ́ Benoît Derrier [15] lórí Wikimedia Commons (CC BY-SA 2.0 [2]). 

Ọmọkùnrin Fẹ́la tí ó kéré jù lọ, Ṣeun Kútì jẹ́ olórin àti agbẹnusọ ìdájọ́ àwùjọ. Ṣeun jẹ́ olùkópa tí ó ṣaápọn nínú àwọn ẹ̀hónú #OccupyNigeria ti 2012 tí ó tako ìgbówólé iye owó epo rọ̀bì. Ó tún kópa bákan náà [16] nínú àwọn ẹ̀hónú #EndSARS ti 2020.

Wọ́n ti ṣe àpèjúwe Ṣeun gẹ́gẹ́ bíi “Àrẹ̀mọ orin Afrobeats,” ní ipasẹ̀ bàbá rẹ̀, ọba orin Afrobeats. Tóyìn Fálọlá, òpìtàn ọmọ Nigeria àti ọ̀jọ̀gbọ́n nípa ẹ̀kọ́ Adúláwọ̀ fìdíi rẹ̀ múlẹ̀ síwájú [17]pé: “Ibọ́sípòo Ṣeun kò ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ní àkókò yìí. Ó fi ìfẹ́ sí orin hàn láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, pàápàá jù lọ irúfẹ́ orin tí bàbá rẹ̀ ń kọ, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣeré pẹ̀lú Fẹ́la àti ẹgbẹ́ olórin Egypt 80 nígbà tí ó wà ní ọmọ ọdún mẹ́sàn-án péré. Kò ní jẹ́ àsọdùn láti pe ìyẹn ní ìṣe kànkà.”

 

Ohùn àwọn ọmọ Nigeria tako Ẹlẹ́yàmẹ̀yà ní South Africa

Àwòrán àwo orin Sonny Okosun

Orin tí ó jinlẹ̀ tí ó ń takò adarí òṣèlú kò mọ lórí àwọn adarí ìjọba ológun afipáṣèjọba nìkan. 

Àwọn òǹkọrin orílẹ̀-èdè Nigeria bíi Sonny Okosun, Majek Fashek, Onyeka Onwenu — àti àwọn mìíràn —  náà fi ẹ̀hónú hàn tako ẹlẹ́yàmẹ̀yà ní South Africa, tí wọ́n pè fún ìdásílẹ̀ Nelson Mandela.

Sonny Okosun (1947—2008), ìràwọ̀ olórin highlife àti régè Nigeria, nínú “Papa’s Land [18]” Ilẹ̀ẹ Bàbá (1977) àti “Fire in Soweto [19]” Iná ní Soweto (1978) bu ẹnu àtẹ́ lu ìtẹ̀bọlẹ̀ àwọn ọmọ South Africa dúdú láti ọwọ́ ìjọba ẹlẹ́yàmẹ̀yà wọn.

Ẹni tí ó ń tọ̀pasẹ̀ Okosun ni atagìtá àti ìràwọ̀ olórin régè ọmọ Nigeria, Majek (Májẹ́kódùnmí) Fashek [20] (1963-2020) fi orin rẹ̀ “Free Africa, Free Mandela” (Dá Ilẹ̀ Adúláwọ̀ sílẹ̀, Dá Mandela sílẹ̀) sọrí Nelson Mandela ọmọ orílẹ̀-èdè South Africa, ẹni tí ó ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bíi ẹlẹ́wọ̀n ẹ̀rí ọkàn. 

Onyeka Onwenu (Àwòrán láti Onyeka Onwenu Facebook Fan Club [21])

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ọ̀kan nínú àwọn orin ẹ̀hónú tako ẹlẹ́yàmẹ̀yà tí ó múnìlọ́kàn tí ó sì mú ìmọ̀lárá dání jù lọ wá láti ọwọ́ òǹkọrin, òṣerébìnrin, àti akọ̀ròyìn Nigeria Onyeka Onwenu [22] nínú orin rẹ̀, “Winnie Mandela [23].” Onwenu ṣe àpèjúwe Winnie Mandela gẹ́gẹ́ bíi “ẹ̀mí orílẹ̀-èdè, tí ó ń jà láti gba òmìnira!” 

Onwenu ṣàlàyé pé òun kọ orin náà lẹ́yìn ìgbà tí òun wo àkásílẹ̀ alálàyé ìṣẹ̀lẹ̀ kan nípa àwọn Mandela, èyí tí ó gba omijé lójú rẹ̀. Ó “kẹ́dùn” pẹ̀lú “ìdáwàa Winnie àti àwọn ìrora rẹ̀ kan.” Ní alẹ́ àìrí-oorun-sùn tí ó tẹ̀lé e, òǹkọrin Nigeria náà fi “ìrora rẹ̀ sínú orin” láti “ṣe ìsanpadà fún Winnie fún fífi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún ìlàkàkà Ẹlẹ́yàmẹ̀yà,” Onwenu ṣe àkọsílẹ̀ [24] ní Igbe 2018. 

Àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nigeria mìíràn tí wọ́n kọrin tako ìbàjẹ́ àwùjọ ti ẹlẹ́yàmẹ̀yà ni Victor Essiet àti Mandators nínú orin “Apartheid. [25]

Ká Apá Kejì ìròyìn àtẹ̀léra yìí níhìn-ín [26].

Ṣé àwárí àkójọ orin Spotify ti Global Voice tí ó ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan wọ̀nyí àti àwọn orin mìíràn tí wọ́n ti fi òfin dè káàkiri àgbáyé níhìn-ín. [27] Fún àlàyé síi nípa orin tí wọn ti fòfin dè, wo àkànṣe ìròyìn wa, Títẹ àwọn kọ́kọ́rọ́ orin tí kò tọ́ [28].