- Global Voices ní-Yorùbá - https://yo.globalvoices.org -

Olórin Calypso Trinidad àti Tobago, Black Stalin, àwòkọ́ṣe ‘ọkùnrin Caribbean,’ jáde láyé ní ẹni Ọdún 81

Sàwáwù : Caribbean, Trinidad & Tobago, Àṣà àti Iṣẹ́-ọnà, Ìròyìn Ọmọ-ìlú, Ìròyìn Yàjóyàjó, Orin
    Photo [1]Àwòrán [1] òǹkọrin Calypso Trinbago Leroy ‘Black Stalin’ Calliste, láti ọwọ́ triniwebdiva lórí Flickr (CC BY-NC-ND 2.0 [2])

Wọ́n máa ń sọ pé tí àgbàlagbà bá kú, yóó dà bí ẹni pé ilé-ìkàwé kan ti jó lulẹ̀ ráúráú. Ìpàdánù náà gbòòrò tí àgbàlagbà tí à ń mẹ́nu bà bá jẹ́ òǹsọ̀tàn nílànà ewì, ògbóǹtarìgì òǹpìtàn tí ó jẹ́ ibi-ìṣura àṣà àti àgbà ọ̀jẹ̀ nínú ìtàn àtẹnudẹ́nu. Ní ọjọ́ 28 oṣù Ọ̀pẹ, orílẹ̀-èdè Trinidad àti Tobago rí àdánù nígbà tí ògbólògbó òǹkọrin Leroy Calliste [3],  tí orúkọ ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ “Black Stalin,” jáde láyé [4] ní ẹni ọdún 81.

Ó jẹ́ gbajúgbajà fún orin kíkọ́ àti eré ṣíṣe lọ́nà tí yóò ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ohun tí ó jẹ mọ́ ìmúnisìn àti ìrẹ́jẹ, ìrínisí àti ìhùwàsí rẹ̀ dídára lórí ìtàgé, ní ìdàpọ̀ pẹ̀lú ẹ̀bùn àwọn ọ̀rọ̀ orin apanilẹ́rìn-ín tí ó ń gúnni lára àti orin àlùjó, sọ ọ́ di ààyò láàárín àwọn ẹgbẹ́ olórin calypso àti àwọn ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ olùwòran tí yóò tú yáyá tú yàyà láti wò ó.

A bíi ní gúúsù Trinidad ní ọjọ́ 24, oṣù Ọ̀wẹwẹ̀ ọdún 1941, Calliste kópa nínú ijó limbo àti lílu irin fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ (steelpan) nígbà ọ̀dọ́-ọ rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ orin [5] calypso kíkọ́ lẹ́ni ọdún 17. Ó darapò mọ́ àgọ́ orin calypso àkọ́kọ́, Southern Brigade, lẹ́yìn ọdún mẹ́ta, kò sì wẹ̀yìn wò. Nínú àwọn ọdún tí ó tẹ̀lé 1960, nígbà tí àgbà ọ̀jẹ̀ olórin calypso kan — nínú bàtà ti Stalin, Lord Blake fún un ní orúkọ ìnagijẹ (gẹ́gẹ́ bí ìṣe), ìràwọ̀ Stalin bẹ̀rẹ̀ síí kàn. Ó darapọ̀ mọ́ àgọ́ olókìkí olórin calypso nì Lord Kitchener Calypso Revue ní 1967 ó sì kógo já dé ìparí ìdíje [5] Ọba Calypso ọdún yẹn.

Ó tẹ̀síwájú láti gba àmì ẹ̀yẹ Ọba Calypso tí ọ̀pọ̀ ń wá fún ìgbà àkọ́kọ́ ní 1979 pẹ̀lú àkójọpọ̀ orin àgbọ́ṣífìlàa rẹ̀ “Caribbean Man [6]” àti “Play One [7],” ewì kúkúrú tó wà fún wíwárìrì ìlu steelpan àti àwọn tí ó dá calypso sílẹ̀. Stalin tún [8] gba àmì ẹ̀yẹ náà ní ìgbà mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀: ní 1985 (“Ism Schism” [9] àti “Wait Dorothy Wait” [10]), 1987 (“Mr. Panmaker” [11] àti “Bun ‘Dem” [12]), 1991 (“Look on the Bright Side” [13] àti “Black Man Feelin’ to Party” [14]) àti 1995 (“In Times” [15] àti “Tribute To Sundar Popo” [16]).

Ó tún gba àmì ẹ̀yẹ Ọba orin Calypso ti Àgbáyé ní 1999, ayẹyẹ àgbáyé níbi tí ó jẹ́ pé, nígbà ìfílọ́lẹ̀ ìdíje àkọ́kọ́ irú ẹ̀ ní 1985, ipò kejì [5] ni Stalin wà sí The Mighty Sparrow [17], Ọba orin Calypso Àgbáyé tí gbogbo aráyé ń wárí fún. Ní àárín ọ̀rúndún 1990, Stalin tọwọ́bọ̀wé pẹ̀lú ilé-iṣẹ́ agbórinjáde Grant Ice Records ti Barbadian Eddy, tí ó ṣe àgbéjáde àwo rẹ “Rebellion” [18] ní 1994 àti “Message to Sundar” [19] ní ọdún tí ó tẹ̀lé e.

Ní ọjọ́ 31 oṣù Ká, 2008, Stalin di dókítà Leroy Calliste nígbà tí St. Augustine, ọgbà ọmọléèwé Yunifásitì West Indies ti Trinidad dá a lọ́lá [20] pẹ̀lú àmì akẹ́kọ̀ọ́ gboyè fún àwọn ipa ribiribi tí ó kó láwùjọ àwọn orin Calypso, tí ó tẹ̀lé àmì ẹ̀yẹ orílẹ̀- [21]è [21] [21], the Hummingbird Medal rẹ̀ (fàdákà), ìjọba fi dá a lọ́lá ní 1987 fún àwọn akitiyan rẹ̀ níbi ìgbáṣà lárugẹ.

Ọjọ́ méjì sí àyájọ́ ọjọ́ ìbíi rẹ̀ 73, ní oṣù Kẹsàn-án ọdún 2014, Black Stalin lùgbàdì [22] àrùn rpársẹ̀ [23] kan lẹ́yìn tí ó kọ́rin [24]ní ibi ètò ìkówójọ inú-rere ní gúúsù Trinidad. Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé ó ń tẹ̀síwájú, kò ní padà sí orí ìtàgé mọ́ pẹ̀lú ara tí ó jí pépé.

Ní gbogbo ìgbà tí ó fi ń ṣiṣẹ́ orin kíkọ rẹ̀ pẹ̀lú ara líle, Stalin máa ń tiraka láti fi ojúlówó, ọgbọ́n inú àìlẹ́lẹ́gbẹ́ sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀rọ̀ náà tó ń lọ lọ́wọ́. Ó jẹ́ aládàánìkàn ronú tó gbóná àti olùpilẹ̀sẹ̀ ọ̀rọ̀ orin tí yóò pè é gẹ́gẹ́ bí ó ti hàn sí i. “Wait Dorothy Wait,” bí àpẹẹrẹ, jẹ́ ìró ohùn tó dùn-ún gbọ́ tí ó sì ṣe ìlérí fún àwọn olólùfẹ́ẹ rẹ̀ pé òun yóò kọ orin atunilára, calypso arínilára — ṣùgbọ́n lẹ́yìn àwọn kùdìẹ̀kudiẹ àwùjọ bíi ìwà ìbàjẹ́, àìdọ́gba àti ìṣẹ́ bá dópin nìkan. Orin náà, tí ó ṣe é jó sí, tí ó sì jinlẹ̀, ṣe àfihàn bí ojú-ọnà rẹ̀ ṣe lọ́ọ̀rìn sí, tí ó sì gbèjà ẹ̀tọ́ rẹ láti kọ orin nípa àwọn kókó ohun tí ó kan àwùjọ.

Orin rẹ̀ tí ó kọ ní 1979 tó mìgboro tìtì “Caribbean Man” [25] (tí a tún mọ̀ sí “Ìọ̀kan Caribbean”), dá rúgúdù sílẹ̀ káàkiri ẹkùn, bí ó ṣe ṣe àfihàn ìrò ìsọdọ̀kan Caribbean tó ṣòro [26]. Ilé-iṣẹ́ Ìfi-nnkan-pamọ́-sí Ìjọba Trinidad àti Tobago s ọ́ báyìí [27]:

Pàápàá ní òní, orin náà ṣì n fa àríyànjiyàn káàkiri ìsọdọ̀kan Caribbean látàrí àwọn ìdojúkọ ìọ̀kan ẹkùn kò jẹ́ tuntun. Wòye pàtàkì àwọn ọ̀rọ̀ orin […]: ‘Wò ó ọkùnrin tí kò mọ ìtàn-an ara rẹ̀/kò le jẹ́ kí ìsọ̀kan wáyé. Báwo ni ọkùnrin kan tí kò mọ orísun rẹ̀/lè gbé èrò tirẹ̀ kalẹ̀?’

Olóògbé akọ̀rọ̀yìn ará Trinidad Terry Joseph ṣe àkọsílẹ̀ [5]ní ọdún 2001 pé Stalin jẹ́ “olórin calypso tí ó yàrà ọ̀tọ̀”, pẹ̀lú àwọn àseyege tí ó sábà máa ń wá “ní ọ̀nà àrà” dípò àwọn ọ̀gá ńlá olórin calypso tí ó jinlẹ̀. Ó kọ́ àpadé-àludé ohun gbogbo láti orí orin ayẹyẹ dé orí orin alálàyé, orin ìfẹ́ dé orí orin òṣèlú:

Stalin fòpin sí wàhálà ṣíṣojú èrò àwọn tí ìnilára ń bá. Àsọyé rẹ lórí àwùjọ àti òṣèlú kò fi ìgbà kan máà kún ojú òṣùwọ̀n, ṣùgbọ́n ó ṣe àfihàn òye bí àtúnṣe ṣe lè wáyé, tàbí kí ó dábàá àwọn ọ̀nà láti kápá ségesège ìdíyelé.

Ẹ̀rín àfanimọ́ra àti ìwà pẹ̀lẹ́ bo àgbọ́nṣáṣáà rẹ̀ mọ́lẹ̀, èyí tí ó ti fìmọ̀ṣọ̀kan pẹ̀lú àkójọpọ̀ ogunlọ́gọ̀ orin mánigbàgbé àti àwọn orin àjọkọpọ̀, láti ràn án lọ́wọ́ láti ní àwọn olólùfẹ́ kárí àgbáyé.

Lóòótó, Stalin rin òkun [5] ó rọ̀sà, ó ń kọrin ní Yúróòpù, Àríwá Amẹ́ríkà àti jákèjádò Caribbean — pẹ̀lú àìdilẹ̀ rẹ̀, ó jẹ́ baálé ilé tí ó ń ṣe ojúṣe rẹ sí aya rẹ Patsy àti àwọn ọmọ wọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Nígbà tí wọ́n gbọ́ ìròyìn [28] ikú u rẹ̀, àwọn ará-orí-ẹ̀rọ-ayélujára bẹ̀rẹ̀ sí ní fi [29] ìbánikẹ́dùn [30]wọn hàn lórí àwọn onírúurú gbàgede àwùjọ orí ẹ̀rọ-ayélujára, tí wọ́n ń fi ìdúpẹ́ wọn hàn [31] fún “orin àti àwọn ìrántí.”

Òǹṣàmúlò Facebook àti akọ̀ròyìn nígbà kan rí Neil Giuseppi sọ [32] pé “Àgbà ọ̀jẹ̀ ti fi wá sílẹ̀,” nígbà tí deejay Jus Jase ṣe ìdágbére [33]sí “òòṣà Calypso tòótọ́.”

Akọrin calypso akẹgbẹ́ rẹ̀ Austin Lyons, tí àwọn ènìyàn mọ̀ sí Superblue, ṣe àtẹ̀jádé [34]:

Ọba ni ọkùnrin yìí, ó máa ń kọrin ó máa ń ṣeré, ó sì máa ń fi gbogbo ara ṣe é.

Ọmọ Superblue, ìràwọ̀ olórin soca Fay-Ann Lyons, ṣọ [35]:

Máa rìn nínú ògo. Fò lókè lálá. […] Àgbà ọ̀jẹ̀ mìíràn tún ti fi wá sílẹ̀ pẹ̀lú orin aládùn àti àwọn ìrántí. #BlackStalin [36]

Bákan náà ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ ìjúba lórí Twitter:

Ìràwọ̀ olórin Soca Bunji Garlin náà twíìtì:

Orin [44]Stalin jẹ́ aláìlákòókò ó sì ń fa àwọn ọ̀dọ́ mọ́ra, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ní ọjọ́ 21 oṣù kọkànlá tí ó kọjá, nígbà tí orin àgbọ́ṣífìlà rẹ “We Can Make It” [45] di kíkọ [46]nígbà ètò ìṣíde Ìpàdé Ọ̀dọ́ Commonwealth Youth Parliament ìkọkànlá irú ẹ̀ tí ó wáyé ní Red House ní Port ti Spain, ibùjókòó ìgbìmọ̀-ìjọba Trinidad àti Tobago.

Fún àyájọ́ ọjọ́ ìbí 80 òǹkọrin náà ní 2021, Stalin di [47] ẹni tí ó kọ́kọ́ gba àmì ẹ̀yẹ Legacy láti Presentation College tí ó wà ní ihà gúúsù, ọ̀kan lára ilé-ẹ̀kọ́ ìwé mẹ́wàá tí ó níyì ní Trinidad. Ní ibi ayẹyẹ náà, àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ olórin calypso akẹgbẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀ [47] nípa bí wọ́n ṣe mọ iyì ìtọ́sọ́nà àti ìbánirẹ́pọ̀ rẹ̀, nígbà tí Alákòóso fún ọ̀rọ̀ Àṣà Randall Mitchell mọ rírì [47] ìkópa Stalin nínú ìgbáṣà lárugẹ ní orílẹ̀-èdè náà.

Wọ́n mọ ìwúlò Stalin gan-an fún ènìyàn iyì tí ó jẹ́ [48] àti fún orin náà [49]tí ó kọ, àpapọ̀ tí ó ṣọ̀wọ́n èyí tí ó fi hàn pé lóòótọ́ ni oyè “àgbà ọ̀jẹ̀” tọ́ sí i.