- Global Voices ní-Yorùbá - https://yo.globalvoices.org -

Boji rè é, Ajá tí ó máa ń jayé orí i rẹ̀ kiri ìgboro Istanbul nínú ọkọ̀ èrò

Sàwáwù : Middle East & North Africa, Turkey, Ẹ̀fẹ̀, Ìròyìn ayọ̀, Ìròyìn Ọmọ-ìlú

Boji, ajá àdúgbò kan láti ìlú Istanbul máa ń wọ ọkọ̀ èrò láti rin ìrìn-àjò káàkiri Istanbul lójoojúmọ́.

Boji tilẹ̀ ní ìkànnì Twitter [5] àti Instagram [6]. Ní kòpẹ́kòpẹ́ yìí, ó kí [7] Olórí ìlú Istanbul  Ekrem Imamoglu nítorí pé ìyẹn tẹ̀ lé e lórí gbàgede Twitter.

Orúkọ rẹ̀, Boji jẹyọ láti ara ẹ̀rọ tí ó ń ti ẹsẹ̀ ọkọ̀ sí ìrìn, tí í ṣe ibi tí ó sábà máa ń fara tì, tí ó bá ti wà nínú ọkò èrò.

Ẹka ìjọba tó ń bójú tó ìlú náà, Istanbul Metropolitan Municipality (IMM) ti rí i dájú wí pé ó gba gbogbo abẹ́rẹ́ ìdèènà ààrùn tó yẹ. Kí ó tó di pé wọn ó jọ̀wọ́ọ rẹ̀ láti padà wọ àárín ìgboro, wọ́n sì ṣe àgbékalẹ̀ ẹ̀rọ GPS tí ó ń mú àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ka náà mọ ibi tí ó bá wà.

Gẹ́gẹ́ bí IMM ṣe sọ, ìrìn-àjò àrìn kẹ́yìn [8] Bójì ní Istanbul tó ọgbọ̀n ibùsọ̀.

Gbajúgbajà Ajá Ìgboro Istanbul, Boji máa ń lo gbogbo àwọn ọkọ̀ ìrìnnà ti ó wà ní ìgboro ìlú náà bí i Ọkọ̀ ojú-irin abẹ́ ilẹ̀, ọkọ̀ orí ilẹ̀, ọkọ̀ orí ilẹ̀ ọlọ́pọ̀-èrò, àti ọkọ̀ ojú-omi.

Púpọ̀ nínú àwọn ọmọ ìlú tí ó ti agbègbè jínjìn wá ni ó máa ń ṣe alábàápàdé Boji nígbà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọ́n sì máa ń pín àwọn àwòrán-an rẹ̀ sórí ẹ̀rọ alátagbà.

Boji ti ní àwọn alátẹ̀lé tí ó ju 50,000 lọ lórí Twitter. Àwọn àtẹ̀jáde rẹ̀ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan bóyá lórí Twitter tàbí Instagram ni ó máa ń ní àwọn kókó tí ó ń gba àwọn tí wọn ń wọ ọkọ̀ èrò níyànjú láti máa tẹ̀lé àwọn òfin ààbo ìlú.

Fún ti ààbò, Mi ò kọjá ìlà àwọ̀-ìyeyè rí. Ìwọ náà kò gbọdọ̀ kọjá rẹ̀.

Àwọn olùgbé Istanbul tí wọ́n ti pàdé Bojì, bákan náà ti sọ ìrírí wọn pẹ̀lú ajá náà:

Díẹ̀ nínú ọkọ̀ ojú-omi àsọdá, díẹ̀ awon ẹyẹ-àkẹ.

View this post on Instagram

A post shared by İstanbul'u Turlayan Köpek? (@boji_ist) [13]

Ojúu wa dí lónìí díẹ̀, a bẹ̀rẹ̀ láti Fatih, a rin ìrìn-àjò gba Bayrampasa, Basaksehir, a pàpà dé Uskudar. Àwọn ènìyàn díẹ̀ dá mi mọ̀. Nítorí náà, mo ya àwòrán-àyàfúnraẹni pẹ̀lú wọn.

Àwọn èrò ọkọ̀ tí wọ́n ti ṣe alábàápàdé Boji sọ pé ara rẹ̀ balẹ̀, kì í sì í kọjá àye rẹ̀.