- Global Voices ní-Yorùbá - https://yo.globalvoices.org -

Rising Voices’ Activismo Lenguas gba Àmì-ẹ̀yẹ Èdè Abínibí Àgbáyé

Sàwáwù : Ìròyìn Ọmọ-ìlú, Ìkéde, Ohùn Tó-ń-dìde
[1]

Àwòrán ìwòjú ẹ̀rọ láti àwòrán-olóhùn fún ìlò gbogbo ènìyàn láti ọwọ́ Shahedul Khabir Chowdhury ti ayẹyẹ Èdè Abínibí Àgbáyé tí ó wáyé ní Dhaka, Bangladesh lọ́jọ́ 21 oṣù Èrèlé, 2021.

Ilé ẹ̀kọ́ Èdè Abínibí Àgbáyé (IMLI) [2] ti orílẹ̀ èdè Bangladesh ti fi àmì ẹ̀yẹ dá [3]Rising Voices’ Activismo Lenguas [4] (Ìjàngbara Èdè Lórí Ẹ̀rọ-ayárabíàṣá) lọ́lá, ìyẹn àmì ẹ̀yẹ Èdè Abínibí Àgbáyé 2021 t'ó gbayì, ní ìdámọ̀ “ìdúróṣánṣán iṣẹ́ àkànṣe náà ní ti ìdáàbòbò, ìgbélárugẹ àti ìmújídìde (àwọn) èdè abínibí.”

Sheikh Hasina, Alákòóso orílẹ̀ èdè Olómìnira Bangladesh àti Ọ̀gá Àgbà IMLI, gbé àwọn àmì ẹ̀yẹ náà fún àwọn tí ó tọ́ sí ní ibi ayẹyẹ kékeré kan [5] tí ó wáyé ní Dhaka, Bangladesh ní ọjọ́ 21 oṣù Èrèlé ọdún 2021. 

Èyí ni ọdún àkọ́kọ́ tí IMLI ti mọ rírì ènìyàn mẹ́rin àti àwọn iléeṣẹ́, ní inú ìlú àti ní àgbáyé, fún ipa ribiribi tí wọ́n ń kó ní ti iṣẹ́ tí ó jọ mọ́ èdè. A fi àmì ẹ̀yẹ náà sọ'rí Àyájọ́ Ọjọ́ Èdè Abínibí Àgbáyé [6], tí gbogbo ayé máa ń sààmì rẹ̀ ní ọjọ́ 21 oṣù Èrèlé láti ọjọ́ tí wọ́n ti kéde ìfilélẹ̀ ní ọdún 1999. Ìlànà ìyan'ni fún àmìẹ̀yẹ ọlọ́dọọdún méjì ni “ìkópa lọ́nà tí ó lákaakì lójúnà ìlò ìmọ̀ ẹ̀rọ-ayárabíàṣá fún ìpamọ́, ìdáàbòbò àti ìgbédìde èdè abínibí.”

Rising Voices [7], tí í ṣe ẹ̀ka Global Voices’ àti ẹ̀ka ìkàkún ẹ̀rọ ayárabíàṣá, ṣe ìfilọ́lẹ̀ Activismo Lenguas [8] fún àwọn Latin tí ó jẹ́ ọmọ Amẹ́ríkà ní ọdún 2014, lẹ́yìn Ìpéjọ àwọn Ajìjàngbara Èdè Abínibí tí ó ń lo ẹ̀rọ ayárabíàṣá [9] àkọ́kọ́ tí ó wá sáyé ní Oaxaca, Mexico, ní èyí  Rising Voices pawọ́pọ̀ ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀. Láti ìgbà ìpàdé àkọ́kọ́ yẹn, irúfẹ́ ìpéjọ bẹ́ẹ̀ ti wáyé ní Colombia [10], Peru [11], Bolivia [12], Ecuador [13], Guatemala [14] àti Chile [15], pẹ̀lú èròngbà láti ṣẹ̀dá àwọn àyè àti àjọṣepọ̀ fún àgbáríjọṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ àti ìpàṣípàrọ̀.

Ní àfikún sí àwọn ìpéjọ wọ̀nyí, Rising Voices ti ṣe agbátẹrù àwọn àkànṣe iṣẹ́ kéékèèké tí ó jẹ mọ́ ìjàǹgbara lórí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá ní orílẹ̀ èdè mẹ́rin, ṣe iṣẹ́ ìwádìí ìkópa méjì, ṣẹ̀dá àkọsílẹ̀ orí ẹ̀rọ ayélukára bí ajere [16] àwọn àkànṣe iṣẹ́ orí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá, kó Àgbáríjọ àwọn Ajàfẹ́tọ̀ọ́ Èdè Abínibí ní orí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá [17] jọ àti ìpolongo orí gbàgede ìbánidọ́rẹ̀ẹ́ @ActLenguas [18], níbi tí àwọn tí ó mọ oyún ìgbín nínú ìkarahun ọ̀ràn èdè abínibí ti máa ń sọ ìrírí wọn nípa lílo ìmọ̀ ìmúṣe ẹ̀rọ fún ìpamọ́ èdè.

“Àmì-ẹ̀yẹ yìí dúró gẹ́gẹ́ bí ipa tí àwọn ajìjàngbara èdè lórí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá ń ní jákèjádò agbègbè Latin Amẹ́ríkà àti arapa ribiribi iṣẹ́ wọn,” Olùdarí Rising Voices’ Director Eddie Avila sọ.

“Nípasẹ̀ ìmúlò agbára ìṣàsopọ̀ ẹ̀rọ ayárabíàṣá àgbáyé àti ìmọ̀ ẹ̀rọ ìgbàlódé, àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ wọ̀nyí ń ṣe àfihàn agbára tí àwọn ohun èlò wọ̀nyí ní láti fa àwọn ìran tuntun tí yóó fọ èdè mọ́ra àti kí èdè wọ́n ba figagbága lórí ìgbàgede ayélukára bí ajere. A tẹ́wọ́ gba àmì ẹ̀yẹ yìí ní orúkọ ọgọọgọ́rùn-ún àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ èdè abínibí àti àwọn tí ó ń bá wọn ṣe, tí wọ́n ti bùpín omi àníkún ìmọ̀ wọn àti ìrírí wọn fún ẹlòmíràn tí wọ́n sì mú kí ìgbésẹ̀ akitiyan yìí ṣe é ṣe. A níran láti túbọ̀ tẹ̀síwájú ìpèsè àtìlẹ́yìn fún wọn bí a ṣe ń forí lé Ọdún mẹ́wàá Èdè Abínibí Àgbáyé ní 2022.”

Àwọn mìíràn tí ó jáwé olúborí ní ọdún 2021 ni Ọ̀jọ̀gbọ́n Mohammad Rafiqul Islam àti Mathura Bikash Tripura ti àjọ Jabrang Welfare Association ti Bangladesh. Ẹni tí ó tún gba àmì ẹ̀yẹ lágbàáyé ni Islaimov Gulom Mirzaevich, fún ìdámọ̀ iṣẹ́ rẹ̀ tí ó dá lórí èdè Uzbek.