- Global Voices ní-Yorùbá - https://yo.globalvoices.org -

Ní orílẹ̀-èdè Turkey, ẹgbẹẹgbẹ̀rún méjì àbọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ni wọ́n jókòó ṣe ìdánwò ìgbaniwọlẹ́ sí Ifásitì

Sàwáwù : Middle East & North Africa, Turkey, Àṣà àti Iṣẹ́-ọnà, Ẹ̀tọ́ Ìbálòpọ̀-akọakọ-aboabo (LGBT), Ìròyìn Ọmọ-ìlú, Iṣẹ́ ìkọ̀ròyìn àti Ìròyìn-kíkọ, Ìṣèlú, Ìtẹríbọlẹ̀, Òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ

Àwòrán ojú ìwò àwòrán-olóhùn orí YouTube  [1] ti orin kan láti ọwọ́ Mabel Matiz pẹ̀lú ọ̀rọ̀ orin náà ní àárín àìgbọ́raẹniyé tí ó súyọ látàrí Ìdánwò Ìgbaniwọlé sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gíga (YKS): “Gözümün gördüğü, göğsümün bildiği ile bir değil” ohun tí ojú mi rí kọ́ ni ọkàn mi mọ̀”)

Ní orílẹ̀-èdè Turkey, orílẹ̀-èdè tí ó lé ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélọ́gọ́rin ènìyàn (83 million), [2]ènìyàn ní láti peregedé nínú ìdánwò ìgbaniwọlé tí wọn ń pè ní Yükseköğretim Kurumları Sınavı ní èdè ilẹ̀ Turkey láti wọlé sí Fáfitì. Pẹ̀lú bí àjàkẹ́lẹ̀ COVID-19 ṣe ń jà rànhìn rànhìn, ìdánwò yìí sì jẹ́ ṣíṣe lójútáyé, ẹgbẹẹgbẹ̀rún méjì àbọ̀ ènìyàn (2.5 million) ni wọ́n jókòó ṣe ìdánwò náà.

Ní ọjọ́ 26 osù Kẹta, àjọ àwọn ilé-ìwé gíga [3] ilẹ̀ náà kéde ọjọ́ ìdánwò YKS yìí gẹ́gẹ́ bi ọjọ́ 25 sí ọjọ́ 26 oṣù Keje [4]. Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ 4 oṣù karùn-ún, Ààrẹ ilẹ̀ Turkey Recep Erdoğan yí ọjọ́ náà sí ọjọ́ 27 sí ọjọ́ 28 oṣù Keje [4].

Àyípadà yìí àti àìdájú ìdánwò yìí ti ń kọ àwọn ènìyàn ilẹ̀ Turkey lóminú, ní ààrín ìgboro ìlú àti ní orí àwọn èrọ alátagbà lórí pé: Báwo ni ọjọ́ yíyí ṣe ní ipá lórí ìrònú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọn ń múra sílẹ̀ de ìdánwò láti bí osù mélòó kan? Báwo ni àwọn àlàkalẹ̀ àti òfi ìdèènà ìtànkálẹ̀ COVID-19 yóò ṣe di títẹ̀lé (Jíjìnnà síra ẹni láwùjọ, ìwọn ìgbọ́nà/tutù, ìlò ạṣọ ìbomú) bí a bá ń kó ènìyàn tí ó tó mílíọ́nù méjì àbọ̀ papọ̀.

Ní ọdún 2019 [5], ìdá mẹ́rìnléláàádọ́rin ó lé díẹ̀ ni àwọn olùṣèdánwò tí wọ́n pegedé nínú ìdánwò náà. Nígbà tí ìdá mọ́kàndínlógójì pegedé sí ìpele ìkejì ìdánwò náà.

Orílẹ̀-èdè Turkey ṣe àkọsílẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ COVID-19 àkọ́kọ́ wọn ní ọjọ́ 11 oṣù kẹta [6] ọdún, ní ìgbà tí ó fi máa di ọjọ́ 15 oṣù keje ẹ̀nìyàn ẹgbẹ̀rún márùn-ún àbọ̀ ti pàdánù ẹ̀mí wọn sí ọwọ́ ààrùn náà [7] bẹ́ẹ̀ sì ni iye ènìyàn tí ó ti ní ààrùn náà ti lé ní igba ẹgbèrún.

Ní ọjọ́ 1 oṣù keje [8], Ìjọba gùnlé àwọn ìgbéṣẹ̀ ìdẹ́kun lóríṣiríṣi. Àwọn ilé oko-òwò bi ilé ounjẹ, àwọn oko òwò ẹ̀rọ ayélujára, ilé ìṣàfihàn eré, gbọ̀ngàn ạyẹyẹ ìgbeyàwó tí wọ́n tì pa fún bíi oṣù mẹ́ta ni wọ́n ti tún ṣí padà báyìí, àmọ́ ṣá pẹ̀lú àtẹ̀lé ìjíjìnà síra ẹni láwùjọ. Àwọn olùbẹ̀wò báyìí nílò láti máa bo imú wọ, wọn yóò sì máa ṣe àyẹ̀wò ìgbóná/tutù wọn.

Bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tilẹ̀ fi ìpè síta pé kí ìdánwò [9] YKS ó di sísún síwájú, ìjọba ò tẹ̀tì nínú àlàkalẹ̀ rẹ̀: Ní ìparí oṣù keje mílíọ̀nù méjì àbọ̀ ni ó jókòó ṣe ìdánwò náà..

Gẹ́gẹ́ bí a ṣe rí i ní inú túwíìtì yìí, tí ó nííṣe pẹ̀lú àsujù lórí ìmúnitẹ̀lẹ́ ìjìnnà sí ara ẹni láwùjọ:

Ìdánowò YKS ń lọ lọ́wọ́ pẹ̀lú mílíọ́nù méjì àbọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ ládúrúu gbogbo ìkìlọ̀: Ìjìnàsíra-ẹni láwùjo gan-an di àwátì.

Àìgbọ́raẹniyé Ìdànwò YKS tuntun: ìwà rere

Kì í ṣe COVID-19 nìkan ni famínfà tí ó yí Ìdánowò YKS ká ní ọdún 2020. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ ló ti ń jà rànhìnrànhìn láti ìbẹ̀ẹ̀rẹ̀ oṣù keje èyí tí ó nííṣe pẹ̀lú ìwé àyọkà fún ìdánwò èdè Turkish. Ọ̀kan nínú àwọn ìbéèrè abẹ́ rẹ̀ tọ́ka sí “Fırtınadayım, (mo wà nínú ìjì), orin olórin tàka-n-súfèé kan Mabel Matiz [13] tí í ṣe  LGBTQ “Fırtınadayım” (“I am in the storm”):

Ìbéèrè lórí ìtumọ̀ “Gözümün gördüğü, göğsümün bildiği ile bir değil” (tí a le tú sí ohun tí ojú mi rí kọ́ ni ohun tí aya mí mọ̀) ti ń da àwọn ìkànnì àwùjọ rú gùdùgùdù nítorí Mabel jẹ́ ẹni tí àwọn ọdọ́ mọ̀ bí ẹni mọ owó (ọ̀ [14]pọ̀ àwọn àwòrán-àtohùn rẹ̀ ní [14] ó máa ń ní ìwò tí ó tó àádọ́ta mílíọ́nù) àti ìṣe rẹ̀ lórí àwọn ohun tí ó jẹmọ́ akọ́ṣebíabo.

Ní ìbámu pẹ̀lú fàmínfà orí ìkànni Twitter, Halis Aygün Ààrẹ Center for Measurement, Selection and Placement (ÖSYM), ẹ̀ka ìjọba tí ó bójú tó ìṣètò ìdánwò sọ nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwọ̀ [15] pẹ̀lú àgbà òṣìṣẹ́ ìròyìn kan, Yeni Akit. Níbẹ̀ ni ó ti sọ pé wọn yóò ṣe ìwádìí ọ̀rọ̀ náà, gbogbo àwọn tí wọ́n bá sì lọ́wọ́ nínú fífi ìwé náà si abẹ́ ìdánwò ọ̀hún ni wọ́n yóò lé kúrò lẹ́nu iṣẹ́:

Ìdánwò YKS ọdún 2020 kẹ́sẹ járí kákàkiri àwọn ibùdó ìdánwò méjìdínnígbà (188) ní ìṣí ẹ̀ẹ̀mẹta, tí àwọn akópa nínú rẹ̀ sì ń lọ bíi mílíọ́nù méjì àbọ̀. Àwọn ìdánwò rẹ̀ jẹ́ èyí tí àwọn onímọ̀ akadá káàkiri àwọn fáfitì orílẹ̀-èdè wa ṣètò. Ìkíyèsí àwọn ẹ̀kọ́ ilé àti ọgbọ́n ìbágbépò láwùjọ fùn àwọn ilé-ìwé gíga wa máa ń jẹ́ kíkíyèsí. Àwọn òṣìṣẹ́ tí èyí bá ṣí mọ́ lórí ni wọn yóò di gbígbọ́n dànù kúrò nínú ìṣètò ìdánwò. Àwọn òṣìṣẹ́ tí èyí bá ṣí mọ́ lórí ni wọn yóò di gbígbọ́n dànù kúrò nínú ìṣètò ìdánwò.

Fún àwọn asàmúlò ìkànnì Twitter kan, ìdájọ́ yìí kò tó:

[Òkè] Ààrẹ ÖSYM sọ̀rọ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́ lẹ́yìn ìdánwò!
“Wọ́n ti fi ìdí ìwádìí lọ́lẹ̀ láti wo ibi tí ìṣòro náà ti wọ́wá. Àwọn tí wọ́n bá lọ́wọ́ nínú rẹ̀ yóò di gbígbọ́n dànù kúrò nínú ìṣètò ìdánwò.”

[Ìsàlẹ̀] Kò tó [lá ti yọ ọ́] nìkan, Ààrẹ tí kò ka nǹkan sí náà gbọdọ̀ jẹ́ yíyọ kúrò nínú ìṣàkósọ gbogbo kí ojú rẹ̀ le wálẹ̀.

Ọ̀wọ́ àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ láwùjọ náà tún rí wí sí ìpinnu àti ṣètò irú ìbéèrè báyìí:

Nínú ìdánwò #YKS2020 tí ó wáyé lónìí, ẹ kò rí ẹlòmìíràn fi ṣe àpèjúwe fún àwọn ọmọdé wọ̀nyí àfi ọkùnrin oníbálòpọ̀-akọsíakọ nnì Mabel Matiz? (Ènìyàn tí ó gbé àkólé tí ó fi ń polongo pé “Oníbálòpọ̀-akọsíakọ ni àwa” Kí ni ẹ̀ ń gbìyànjú láti ṣe?

Èrò àwọn aṣàmúlò ìkànni Twitter kò ṣọ̀kan pẹ̀lú bí àwọn mìíràn ṣe ń tọ́ka sí àwọn àṣeyọrí Mabel Matiz àti bí ó ṣe lókìkí sí:

Èyin ọmọ ìgbìmọ̀ aṣèwádìí. Mo fẹ́ kí ẹ wo àwọn fọ́nrán Mabel Matiz. Nítorí pé a kò ní eléré mìíràn tí ó ti ṣe àmúlò àṣà wa tó báyìí ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn. Ìdí nìyẹn tí mabelmatiz ṣe jẹ́ ìsúra wa.

Àwọn èèyàn lórí ayélujára pé àkíyèsí sí i pé fífi ojú sun olórin tí ó jẹ́ oníbálòpọ̀-akọsíakọ, àwọn olóṣèlú yóò pa àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ṣe kókó tì:

Kò sí ẹni tí ó figbe ta lórí àwọn afipábánilòpọ̀, síbẹ̀ ìwádìí Mabel Matiz ni wọ́n ń gbà bí ẹni ń gba igbá ọtí.

Eléyìí kó gbogbo rẹ̀ nílẹ̀:

Ẹ sọ pé “ìdààbò bo ìṣe wa” ṣùgbọ́n Mabel Matiz ni ẹni tí ó ṣe ìgbéjáde àṣà wa jùlọ. Ó wa yẹ kí ìwádìí ó dá lé àwọn èyí tí ó tàbùkù Mabel Matiz tí wọ́n sì ṣẹlẹ́yàmẹ́yá rẹ̀. #MabelMatizisnotalone [Àtẹ̀jáde òkè]

Èsì Mabel Matiz sí àìgbọ́raẹniyé náà

Ní ọjọ́ 3 oṣù Keje, bí fàmínfà náà ṣe ń gbóná sí i, Matiz padà la ohùn:

Ẹ ǹlẹ́ o:) Inú mi dùn pé orin mi jẹ́ lílò fún irú ìdánwò pàtàkì bí èyí. Ní báyìí, ìyàlẹ́nu lójẹ́ fún mi bí ìgbéayé mi ṣe di ohun tí ó kan ìdánwò tí à ń sọ yìí. Ẹ wo ohun tí a fi dán mi wò..bí a ṣe gbé ààmi kan ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú orúkọ mi. Kò burú, Ìdánwò ayé kò lópin:) Iyán tún di àtúngún wàyí. Mo ka ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àtẹjáde tí ó ṣègbè lẹ́yín mi. Òhun tí mo fẹ́ sọ nínú orin yẹn yémi, mó nímọ̀ pé ó yé ẹ̀yin náà, ara mi sì tún yá gágá sí i. N ó tẹ̀síwájú láti máa kọ orin sí i, láti máa sọ ìtàn àti láti jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè yìí.
Ká tún pàdé nínú ìdánwò mìíràn…

Matiz sì lókìkí síbẹ̀: lẹ́yìn ọjọ́ kan tí Aygun sọ̀rọ̀ sáfẹ́fẹ́, ó gba àmì-ẹ̀yẹ méjì nínú ìdíje àmì-ẹ̀yẹ kan nípasẹ̀ ìbò tí ó pọ̀jù. Ó gba àmì-ẹyẹ ipele méjì, “Orin tí mùṣèmúṣè rẹ̀ dá múṣé jùlọ [32]” àti “Olórin ọkùnrin tí mùṣèmúṣè rẹ̀ dá múṣé jùlọ” ní ìdíje àmìẹyẹ Pantene Golden Butterfly ẹlẹ́ẹ̀kẹrìndínláàádọ́ta irú rẹ̀ [33]. Èyí fi hàn pé ọ̀pọ̀ ènìyá̀n ni wọ́n wà lẹ́yìn rẹ tako ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀-akọsíakọ tí ìjọba àti àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ tí ìjọba ń sọ.

Ní ọjọ́ 5 oṣù Keje, Mabel Matix tún túwíìtì:

Mo gba àmì-ẹyẹ “àwòrán-àtohùn orin tí mùṣèmúṣè rẹ̀ dá múṣé jùlọ” àti “Olórin ọkùnrin tí mùṣèmúṣè rẹ̀ dá múṣé jùlọ” nínú ìdíje àmì-ẹyẹ Pantene Golden Butterfly ẹlẹ́ẹ̀kẹrìndínláàádọ́ta irú rẹ̀, Inú mi dùn! Ẹ ṣé gan ẹ̀yin olùgbọ́ mi gbogbo. Màá fẹ́ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Erhan Arik àti DOP Meryem Yavuz, àwọn tí wọ́n darí àwòrán-àtohùn [orin mi] “I Have a Red in My Wipe” clip tẹ́lẹ̀. [14]