- Global Voices ní-Yorùbá - https://yo.globalvoices.org -

Àwọn obìnrin ní Nàìjíríà kojú àdó-olóró àgbẹ́sẹ̀léró àgbàwí ọ̀rọ̀ ìṣèlú lórí ẹ̀rọ-ayélujára

Sàwáwù : Ìlú Gúúsù Aṣálẹ̀ Sahara, Nàìjíríà, Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn, Ìròyìn Ọmọ-ìlú, Ìṣèlú, Obìrin àti Akọtàbábo, Ìgbàwí GV

Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Mother's Savings Club, Nàìjíríà. I'm Àwòrán láti ọwọ́ [1] Karen Kasmauski/USAID ní Ilẹ̀-Adúláwọ̀ ní orí United States government work, public domain. [2]

Ní Nàìjíríà, àdó-olóró àgbẹ́sẹ̀léró ni gbàgede àgbàwí ọ̀rọ̀ òṣèlú. Àgbàwí àti ọ̀rọ̀ ìṣèlú sábà máa ń fi ti ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn àti ẹlẹ́yàmẹyà ṣe. Àwọn alágbàwí tí ó gbajúmọ̀ lórí ẹ̀rọ-alátagbà — pàápàá jù lọ lórí Twitter — ní láti lè fi ara gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ gbas gbos (èdè àdàlù-mọ́-Gẹ̀ẹ́sì Nàìjíríà fún “ìkànṣẹ́”) ní orí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá.

Àwọn alágbàwí tí ó jẹ́ obìnrin — ní àfikún sí títẹ àwọn ohun ìdánimọ̀ tí ó ń mú ìpalára wá mọ́lẹ̀ — bákan náà ni wọ́n ń kojú ìkọlù tí ó ti ara ìkórìíra tẹ̀gbintẹ̀gbin ẹ̀yà jẹ yọ.

Báwo ni àwọn alágbàwí l'óbìnrin ní Nàìjíríà ṣe ń farada ìkorò orí ẹ̀rọ-ayélujára bíi ìsọ̀rọ àlùfànṣá síni, ọ̀rọ̀ ìkórìíra tẹ̀gbintẹ̀gbin àti ìmọ̀ọ́mọ̀ yí-ọ̀rọ̀ wọn dà? Báwo ni wọ́n ṣe ń tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ wọn tàbí fọnrere iṣẹ́ wọn?

Àwọn ajìjàngbara orí ẹ̀rọ alátagbà méjì ní Nàìjíríà fi ìrírí àwọn àgbàwí àti ìkórìíra ìwà abo hàn: #BringBackOurGirls, tí Dókítà Oby Ezekwesili jẹ́ aṣíwájú; àti #ArewaMeToo, tí Fakhriyyah Hashim jẹ́ agbátẹrù, gbogbo wọn ni wọ́n ní ìrírí ìkórìíra tẹ̀gbintẹ̀gbin abo nínú agbo òṣèlú tí ó ń fa ìlọsíwájú wọn sẹ́yìn.

Ìjàngbara #BringBackOurGirls (#BBOG) 

Ọdún mẹ́fà sẹ́yìn, ní ọjọ́ 15, Oṣù Igbe ọdún 2014, ó tó 200 àwọn ọmọdébìnrin tí ọjọ́ orí wọn ò ju ọdún 15 àti 18 lọ, láti iléèwé Gíga Ìjọba Obìnrin ní Chibok ẹ̀bà Maidiguri, ní àríwá-ìlà-oòrùn Nàìjíríà ni ẹgbẹ́ afẹ̀míṣòfò èlẹ́sìn Mùsùlùmí Boko Haram sọ di ẹni tí a fi túláàsì mú sí ìgbẹ̀sìn [3].

Ìjínigbé àwọn ọmọdébìnrin Chibok náà ṣe okùnfà ìlọ́wọ́sí àwọn orílẹ̀ èdè kárí àgbá ńlá ayé. Iléeṣẹ́ oníròyìn BBC jábọ̀ wí pé nínú oṣù Igbe ọdún 2014, #BringBackOurGirls náà gbajúmọ̀ ní orí Twitter [4] pẹ̀lú nǹkan bíi àwọn ènìyàn ẹgbẹẹgbẹ̀rún 3.3 tí ó tún túwíìtì náà túwíìtì, ìdá 27 àwọn túwíìtì wọ̀nyí ni ó wá láti Nàìjíríà, ìdá 26 láti orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà àti ìdá 11 láti Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.

Dókítà Oby Ezekwesili ń dáhùn ìbéèrè níbi ètò àwọn obìnrin àjọ UN pẹ̀lú àwọn alákòóso ìpolongo #BringBackOurGirls. Àwòrán láti ọwọ́ UN Women/Ryan Brown [5], ọjọ́ 14, oṣù Ọ̀wẹwẹ̀ ọdún 2014. (CC BY-NC-ND 2.0 [6])

Dókítà Obiageli (Oby) Ezekwesili, igbá-kejì ààrẹ Ilé ìfowópamọ́ Àgbáyé ìgbà kan, àti mínísítà ètò ẹ̀kọ́ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà nígbà kan rí, bẹ̀rẹ̀ sí túwíìtì nípa àwọn ọmọdébìnrin Chibok ní ọjọ́ tí wọ́n jí wọn gbé gan-an gan-an. Ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí ó ti ṣẹlẹ̀ tí àwọn àjínigbé jí àwọn ọmọdékùnrin gbé ní iléèwé Kọ́lẹ̀jì ìjọba Àpapọ̀ ti Buni Yadi ní Ìpínlẹ̀ Yobe, àríwá-ìlà-oòrùn Nàìjíríà lọ́jọ́ 25, oṣù Èrèlé ọdún 2014 ló ṣí i lójú sí ìpolongo yìí. Àwọn ọmọdékùnrin kankàndínlọ́gọ́ta ni ó ti ara ọta ìbọn àti ọgbẹ́ ọbẹ̀  [7], nígbà tí iná sì jó àwọn mìíràn pa.

Síbẹ̀síbẹ̀, àfi ìgbà tí ó di ọjọ́ 23, oṣù Igbe, nígbà tí àjọ UNESCO gbà á lálejò ní Port Harcourt, ibi tí ó kún fún epo-rọ̀bì ní agbègbè Niger Delta, ni ó ti ké gbàjarè fún ìdásílẹ̀ àwọn ọmọdébìnrin tí ó fi di ohun tí gbogbo orílẹ̀ èdè àgbáyé gbà bí igbá ọtí:

Fi ohùn sí ìdásílẹ̀ àwọn ọmọdébìnrin wa. Ẹ dákun, ẹ lo àmì #BringBackOurGirls [8] TÍTÍ tí wọn á fi dá wọ́n SÍLẸ̀.

— Oby Ezekwesili (@obyezeks)  Ọjọ́ 23, Oṣù Igbe 23, ọdún 2014 [9]

Ní ọjọ́ 7 oṣù Èbìbí ọdún 2014, aya ààrẹ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ọ̀gábìnrin Michelle Obama ṣe àtẹ̀jáde àwòrán kan tí ó ti mú àmì “Ẹ dá àwọn ọmọdébìnrin wa padà” #BringBackOurGirls lọ́wọ́. Bákan náà ni ó tari àwòrán-olóhùn [10] kan láti inú Ilé Funfun síta — tí ìgbésẹ̀ yìí sì sọ ìṣẹ̀lẹ̀ ìjínigbé náà di ọ̀ràn tí gbogbo àgbáyé fẹ́ rí àbálọ-bábọ̀ rẹ̀.

Ọdún méjì ni ó gba àwọn ọmọ ogun orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti gba ọmọdébìnrin kan sílẹ̀ [11], nínú oṣù Òkúdù ọdún-un 2016. Nígbà tí ó máa fi di oṣù Ọ̀wàrà ọdún-un 2016, àwọn ọmọdébìnrin 21 darapọ̀ mọ́ [12] àwọn mọ̀lẹ́bí wọn. Ní oṣù Èbìbí 2017, ikọ̀ Boko Haram dá àwọn ọmọdébìnrin 82 sílẹ̀ [13] nínú ìgbẹ̀sìn. Síbẹ̀síbẹ̀, ó tó ọmọdébìnrin 112 tí ó di àwátì bí abẹ́rẹ́ tí ó sì jọ pé àwọn 13 tí ṣègbé, ìyẹn gẹ́gẹ́ bí ìwádìí  [14]ọdún 2018 kan ṣe tọ pinpin.

Ezekwesili àti àjọṣepọ̀ àwọn ènìyàn kan ni ó dá ìgbésẹ̀ ìjà fún ẹ̀tọ́ àwọn ọmọdébìnrin #BBOG tí ó kó àwọn ènìyàn jọ lágbàáyé fún ìdásílẹ̀ àwọn ọmọdébìnrin Chibok. Nígbà tí ó ṣe, ìgbésẹ̀ náà yírapadà di igi àràbà tí ẹnìkan kò leè ṣí nídìí tí ó fi ara da igbàgede ètò ìlú Nàìjíríà t'ó rorò [15]. Àmọ́ ṣá o, àṣeyọrí akitiyan yìí kò ṣẹ̀yìn-in ìnáwónára Ezekwesili.

Ní wéré kí ètò ìdìbò ààrẹ ọdún 2015 ó wá sáyé ni ìṣẹ̀lẹ̀ ìjínigbé àwọn ọmọdébìnrin Chibok ṣẹ̀, tí èyí sì mú kí àwọn kan ó máa fi ojú ìgbèlẹ́yìn ẹgbẹ́ olóṣèlú kan wo ìgbàwí tí Ezekwesili ń bá ká lórí ayélujára. Bí wọ́n ti fi ojú òtítọ́ inú rẹ̀ gbolẹ̀ ni wọ́n fa gbogbo aṣọ iyìi rẹ̀ ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ. Àwọn mìíràn sọ wípé gbogbo kùkùgẹ̀gẹ̀ akitiyan #BBOG rẹ kò ju kí ó ba lẹ́nu nínú ìṣèlú lọ.

Reno Omokri, olùrànlọ́wọ́ ààrẹ àná, fi ẹ̀sùn kan Ezekwesili wí pé ẹgbẹ́ olóṣèlú APC ni ó ń lò ó [16] fi ba ìjọba tí ó wà lórí àpèré jẹ́ àti láti “yẹpẹrẹ” ìjọba Ààrẹ Jonathan, nípa èyí náà ni ó fi lànà fún APC láti “gba ọ̀pá àṣẹ.”

Ní ọdún-un 2014 àwọn alátìlẹ́yìn Ààrẹ àná ààrẹ Jonathan àti ẹgbẹ́ olóṣèlú Peoples’ Democratic Party (PDP) fi “àwọn ọ̀kan-ò-jọ̀kan irọ́” léde ní orí ẹ̀rọ-ayélujára láti tako Ezekwesili. Dókítà náà sọ nínú àtẹ̀jáde àwòrán-olóhùn Twitter kan [17] ti ọjọ́ 14, oṣù Igbe ní ìsààmì ọdún mẹ́fà tí àwọn ọmọdébìnrin náà ti di àwátì wí pé: “kí á má purọ́ wọ́n tàbùkù mi, wọ́n sì ṣe kèéta…”

Àwọn ẹlẹ́nu èké sọ wí pé ìgbónára àì rí ipò nínú ìjọba Jonathan ló ń mú Ezekwesili tẹpẹlẹ mọ́ ìgbárùkù ti ọ̀ràn àwọn ọmọ tí ajínigbé jí gbé. Bí ó [17]ti ṣe sọ, àwọn tí ó kọ ẹnu ẹ̀gbin sí i lórí ayélukára-bí-ajere lérò “wí pé torí kí wọ́n ba fi òun j'òye mínísítà ni òun ò fi mẹ́nu kúrò lọ́ràn àwọn ọmọdébìnrin Chibok.”

“Báwo ni yó ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn tí mo kọ ipò mínísítà ní ọdún mẹ́ta sẹ́yìn kí àwọn ọmọdébìnrin Chibok ó tó di ìgbẹ̀sìn?” Ezekwesili wí nínú àwòrán-olóhùn Twitter náà [17].

Ó di ọ̀kan nínú àwọn òǹdíje sí ipò ààrẹ ọdún-un 2018, ṣùgbọ́n ó ju ọwọ́ sílẹ̀ [18] nígbà ó yá.

Ní orí Twitter, Ezekwesili mú ìbànújẹ́ rẹ̀ wá sí ìrántí [17]: “Ẹ̀dùn ọkàn ni fún mi pé àwọn ọmọdé tí a rán nílé ìwé di pípa bí ẹran dé ibi wí pé àwọn òbí wọn kò lè dá àwọn ọmọ wọn mọ̀.”

Àmọ́ ìṣààta ti olóṣèlú nípa ìgbésẹ̀ ìpolongo #BBOG ti gbé ìbínú tòun t'ìbánújẹ́ rẹ̀ mì.

#ArewaMeToo àti NorthNormal 

Ní ọjọ́ 3, oṣù Èrèlé ọdún-un 2019, ọ̀dọ́bìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Khadijah Adamua gbójúgbóyà láti túwíìtì nípa ìlòkulò ajẹmára [19] tí ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ ìgbà kan lo òun. Adamua, ẹni tí ó ń gbé ní ìpínlẹ̀ Kano tí í ṣe àríwá-ìlà-oòrùn orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ti ṣáájú kọ búlọ́ọ̀gù [20] nípa ìrírí rẹ̀ tí ó banilẹ́rù.

Ọmọ Nàìjíríà rere Fakhriyyah Hashim túwíìtì àtìlẹ́yìn rẹ̀ fún Adamua pẹ̀lú lílo àmì #ArewaMeToo:

Àìfiyèsí àwọn tí ó farapa yóò túbọ̀ jẹ́ kí àṣà ìfipábánilòpọ̀ àti ìyọlẹ́nu ó gbilẹ̀ sí i, tí ó sì di “kò tán ń dìí ‘ẹ” fún àwọn tí ń jìyà ìpalára tí ó gbóyá láti sọ ìrírí tí ó ń pààrà ọkàn wọn síta. Gbogbo wa ni a mọ bí àwọn tí ó farapa ní Gúúsù orílẹ̀ èdè yìí ṣe máa ń gba ẹ̀bi.

— Fakhrriyyah (@FakhuusHashim) Ọjọ́ 10, Oṣù Èrèlé 2019 [21]

#ArewaMeToo di ẹ̀dà ìgbésẹ̀ Èmi Náà àgbáyé #MeToo ní àríwá Nàìjíríà. (Árẹ̀wá ni èdè-ìperí fún “Àríwá” ní èdè Haúsá) — tí ó tan ìjì àsọgbà ọ̀rọ̀ lórí ìfipábánilòpọ̀ [22] àti irú àwọn ìwà-ipá sí àwọn obìnrin [23]ní orí ẹ̀rọ ayélukára-wọn-bí-ajere.

Ìwà-ipá sí obìnrin wọ́pọ̀ jákèjádò orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà. Síbẹ̀, Relief Web [24] sọ wí pé ní àárín oṣù Belu ọdún-un 2014 àti oṣù Ṣẹẹrẹ ọdún un 2015, àríwá-ìlà-oòrùn Nàìjíríà, pàápàá jù lọ Ìpínlẹ̀ Borno, ní àkọsílẹ̀ ìwà-ipá sí obìnrin ti pọ̀ jọjọ. Ní agbègbè àríwá tí àwọn Mùsùlùmí pọ̀ sí jù lọ, àsọgbà nípa orí ọ̀rọ̀ èèwọ̀ wọ̀nyí ṣòro, tí ó máa pàpà sọ àwọn tí ó ń jìyà ìpalára sì ìpa kẹ́kẹ́ [25].

Ìbínú #ArewaMeToo ní orí ẹ̀rọ-ayélujára ṣe àtọ́nà ìyíde ìfẹ̀hònúhàn [26] ìta gbangba NorthNormal ní Bauchi, Kano, àti Niger. Ìyíde ọlọ́jọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ti NorthNormal wá sáyé nínú oṣù Belu ọdún t'ó kọjá ní àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́jọ ní òkè Ọya àti ní Abuja. Wọ́n rí ipa rere látàrí ìyíde tí àwọn aṣòfin “sì rí ìdí tí ó fi yẹ kí àwọn gbọ́ sí àwọn ọ̀dọ̀ ìbílẹ̀” lẹ́nu torí wọ́n ń “lé iwájú nínú ìjà fún VAPP,” Hashim ṣàlàyé ọ̀rọ̀.

Hashim tẹ̀síwájú wí pé,” síbẹ̀, ní Ìpínlẹ̀ Sokoto, ìjọba ń kó àwọn tí ó ń yíde NorthNormal”. Àwọn ọlọ́pàá ṣe ọ̀kan lára àwọn olórí ìbílẹ̀ tí í ṣe alágbèékalẹ̀ ìyíde náà ṣìbáṣìbo [27]. Lẹ́yìn wá, ọba Sokoto, tí í ṣe olórí àwọn Mùsùlùmí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà fagilé ìwọ́de.

Gẹ́gẹ́ bí Hashim ti ṣe wí, NorthNormal súyọ láti ara àmì #ArewaMeToo, tí ó sì ní èta méjì: ìgbàwí fún “ìṣàmúlò Ìfòfinde Ìwà-ipá sí àwọn Ènìyàn (VAPP),” àti ìléwájú nínú ìtàkùrọ̀sọ “onírúurú ìwà-ipá sí obìnrin àti àṣà ìfipábánilòpọ̀ jákèjádò àríwá Nàìjíríà.”

Àbà Òfin Ìwà-ipá sí Àwọn Ènìyàn (Ìfòfindè) [28] ọdún-un 2015 di títọwọ́bọ̀ lọ́jọ́ 23, oṣù Èbìbí, ọdún-un 2015. Lábẹ́ Àbá VAPP — ìlọsíwájú [29] òfin ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà — àbá ìwà-ipá sí àwọn obìnrin jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ lábẹ́ òfin. Lára rẹ̀ ni ìfipábánilòpọ̀, nína aya, ìfipálé aya jáde nílé, ìfipá sọ obìnrin di adábùkátà gbọ́ tàbí ìjìyà ti ọrọ̀-ajé, àṣà opó tí ó ń fa ìpalára, dídábẹ́ fún obìnrin tàbí gígé ida, àti/tàbí ìkọ̀sílẹ̀ ọmọ.

In Nigeria, rape is punishable with life imprisonment. A minor can face up to 14 years in prison. In cases of gang rape, offenders are jointly liable to 20 years imprisonment without the option of a fine.

Ní Nàìjíríà, ẹ̀wọ̀n gbére ni ìjìyà ìfipábánilòpọ̀. Ọmọdé lè fi ara gbá ẹ̀wọ̀n ọdún 14. Bí ó bá jẹ́ ọ̀ràn ìfipábánilòpọ̀ ẹni púpọ̀, ẹ̀wọ̀n ọdún 20 ni àwọn ẹlẹ́sẹ̀ yóò fi gbára láì san owó ìtanràn.

Síbẹ̀, Abala 47 ti Àbá òfin VAPP fi lélẹ̀ wí pé Abuja, olú ìlú orílẹ̀ èdè Nàìjíríà nìkan ni òfin yìí ti f'ẹsẹ̀ rinlẹ̀ [30]. NorthNormal àti àwọn iléeṣẹ́ mìíràn ti ń polongo [31] kí gbogbo ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ 36 ó sọ àbá yìí d'òfin.

Àtakò àwọn alágbàwí 

Ọdún kan lẹ́yìn tí #ArewaMeToo gba ìgboro, Hashim sọ fún Ohùn Àgbáyé wí pé adi ìgbàwí wọn tí ó tú “ìbàjẹ́ àwùjọ jáde,” ó sì tún ní arapa tirẹ̀.

Hashim ní ìrírí ìyọlẹ́nu lórí ayélujára nígbà tí ẹgbẹ́ rẹ̀ kojú “ẹnìkan tí ó máa bá àwọn ọmọdé lò ní ṣísẹ̀ntẹ̀lé kiri àdúgbò” ẹni tí ó ń ṣiṣẹ́ ní iléeṣẹ́ ìṣúná-owó gẹ́gẹ́ bí ìgbàwí orí ayélujára wọn. Ó sọ fún Ohùn Àgbáyé:

We launched a campaign against him [the serial abuser], demanding that he be sacked by the minister; some people did not like that so they orchestrated an online targeted harassment campaign to delegitimise ArewaMeToo.

A ṣe ìfilọ́lẹ̀ ìpolongo tako rẹ̀ [abọ́mọdé sùn], kí ó bá gba ìwé ìyọniníṣẹ́ láti ọwọ́ mínísítà; àwọn kan kò fẹ́ bẹ́ẹ̀ torí ìdí èyí ni wọ́n ṣe gbé ìgbésẹ̀ ìpolongo ìyọlẹ́nu orí ayélujára láti sọ #ArewaMeToo di èyí tí ó lòdì sí òfin.

Gẹ́gẹ́ bí Hashim ṣe sọ, àwọn ayọnilẹ́nu gbèrò láti sọ ArewaMeToo di ohun tí ó tasẹ̀ àgẹ̀rẹ̀ sí òfin nípa “síso ArewaMeToo pọ̀ mọ́ LGBTQ [obìnrin-tó-ń-fẹ́-obìnrin, ọkùnrin-tí-ó-ń-fẹ́-ọkùnrin, àwọn abo àti akọ tí ó yíra padà di akọ tàbí abo àti àwọn ènìyàn tí ó ṣe àjèjì tí kò sí ní ìbámu] àti “ète wọ́n ṣiṣẹ́ bí ìyọlẹ́nu orí ayélujára ṣe ń lékún sí i”.

Ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ìgbéyàwó láàárín ọkùnrin àti ọkùnrin lòdì sófin [32] bẹ́ẹ̀ náà ní abẹ́ òfin Sẹ́ríà àti òfin ìfìyàjẹ ẹlẹ́sẹ̀, ìbálòpọ̀ ihò ìdí àti ìbálòpọ̀ láàárín obìnrin àti obìnrin ní ìjìyà [33] ní àwọn ìpínlẹ̀ kan.

Nípasẹ̀ dída ìgbésẹ̀ ìpolongo Hashim papọ̀ mọ́ ẹ̀tọ́ LGBTQ, àwọn ènìyàn ní orí ẹ̀rọ-ayélujára lọ́ ìpolongo wọn po wọ́n sì pe #ArewaToo àti NorthNormal ní ohun tí kò tọ́.

Bí-ó-ti-wù-kí-ó-rí, Ohùn Àgbáyé kò rí àyè sí àwọn túwíìtì tí ó sọ ìgbésẹ̀ ìpolongo Hashim ní ìjà fún ẹ̀tọ́ LGBTQ.

Síbẹ̀, Hashim ṣe àtẹ̀jáde àwọn ọ̀rọ̀ ìrètí sí orí Twitter:

Fakhriyyah Hashim, ọ̀kan lára àwọn olùdásílẹ̀ #ArewaToo àti NorthNormal (a gba àṣẹ láti lo àwòrán rẹ̀.

Ó sọ wí pé gbogbo ìrírí yìí ran òun lọ́wọ́ láti “ní ìfarada tí ó pọ̀”:

In my experience of being loud on political Twitter for good governance, I’ve grown a really thick skin, but even that didn't prepare me for the amount of backlash we got through ArewaMeToo and NorthNormal. Though I mustered all of that and did not retreat to any cave, I did begin feeling demoralised about Northern Nigeria’s governanace and response to sexual violence…After every episode of attacks, we did gather more strength and energy to push back because the backlash made us see how society enforced the culture of silence and if we allowed our lips to be sealed then that would be the real tragedy.

Ìrírí mi nípa ìgbóhùnsókè lórí ọ̀rọ̀ òṣèlú ní orí Twitter fún ìṣèjọba tí ó dára, ti kọ́ mi ní ìfaradà, àmọ́ ìyẹn kò mú mi gbaradì fún ọ̀kan-ò-jọ̀kan ìtakò tí a fojú rí látàrí ìpolongo ArewaMeToo àti NorthNormal. Àmọ́pé mo fi gbogbo rẹ̀ ṣe osùn mo fi para n ò sì jẹ́ kí ó fà mí sẹ́yìn, mo bẹ̀rẹ̀ sí ní í ní ìrẹ̀wẹ̀síọkàn nípa ìṣèjọba Àríwá orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti bí wọ́n ṣe fi ọwọ́ mú ìwà ìfipábánilò… Lẹ́yìn ìkọlù kọ̀ọ̀kan, a máa ń ní okun àti agbára láti tẹ̀síwájú nítorí ìtakò mú wa rí bí àṣà ìdákẹ́ rọrọ ti ṣe rinlẹ̀ tó ní àwùjọ àti pé bí a bá fi àyè gba ìpanumọ́, a jẹ́ wí pé oko ìparun ni à ń fi orí lé.

Ó ṣeni láàánú, Hashim àti Ezekwesili ṣì ń janpata pẹ̀lú ìyà “àìsí àánú ọmọlàkejì” tí ó dìrọ̀ mọ́ ọ̀ràn ìwà ìjìyà àwọn obìnrin lórí ayélujára àti lójú ayé tòótọ́.

Ní ti Hashim, “ìmọ̀ọ́mọ̀ ṣààta ìgbésẹ̀ tí ó ń gbèrò láti fi ohùn fún àwọn tí ó ń jìyà ìfarapa” nira láti gbá mú.

Àròkọ yìí jẹ́ ọ̀kan lára àkànṣe iṣẹ́, “ Orísun ìdánimọ̀: òfin gbàgede orí ẹ̀rọ-ayélujára bí ajere tí ń gbégi dínà ìdàgbàsókè ọ̀rọ̀ sísọ ní Ilẹ̀ Adúláwọ̀”. Àtẹ̀jáde yìí ṣe ìbéèrè ipa ìdánimọ̀ ọ̀rọ̀ ìkórìíra tẹ̀gbintẹ̀gbin tàbí ìyàsọ́tọ̀ọ̀tọ̀ tí ó dá fìrìgbagbòó lórí èdè tàbí agbègbè ilẹ̀ ayé, àṣìwífún àti ìyọlẹ́nu (pàápàá jù lọ ìyọlẹ́nu àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn àti akọ̀ròyìn l'óbìnrin) lórí ẹ̀rọ ayélujára bí ajere tí ó wọ́pọ̀ ní orílẹ̀ èdè Ilẹ̀ Adúláwọ̀ méje: Algeria, Cameroon, Ethiopia, Nigeria, Sudan, Tunisia àti Uganda.  Africa Digital Rights Fund ti  [36] Collaboration on International ICT Policy for East and Southern Africa (CIPESA [37]) ni ó kówó fún à kànṣe iṣẹ́ yìí.