- Global Voices ní-Yorùbá - https://yo.globalvoices.org -

Ní Burundi, àwọn akọ̀ròyìn mẹ́rin tí a fi sátìmọ́lé ń dúró de ìpinnu ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn

Sàwáwù : Ìlú Gúúsù Aṣálẹ̀ Sahara, Burundi, Ètò ìjọba, Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn, Ìròyìn Ọmọ-ìlú, Iṣẹ́ ìkọ̀ròyìn àti Ìròyìn-kíkọ, Ìṣèlú, Ogun àti ìjà, Òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ, Ìgbàwí GV
https://www.flickr.com/photos/dw-akademie-africa/5736248375/in/photolist-9LgF9r-9LgERD-9LgEXg-9Ljtrw-9LgDZa-9LgEip-9LgDHv-9LjtiW-9LjrK5-9LjtwE-9Ljsrs-9LjsbG-9LgF3R-9LjtcS-9LgELx-9Ljs79-9LgE4g-9Ljszq-9JTLN4-9LjrzN-9JWBzd-9LgDxZ

Iléeṣẹ́ Oníròyìn náà ní Bujumbura, níbi tí a yọ àwọn ilé ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ kúrò lórí ìlà. Ọjọ́ 19 oṣù Èbìbí 2010. Àwòrán láti ọwọ́ DW Akademie [1] – Africa ní orí Flickr, CC BY-NC 2.0 [2].

Àwọn akọ̀ròyìn mẹ́rin — Agnès Ndirubusa, Christine Kamikazi, Térence Mpozenzi àti Egide Harerimana — ni a dá lẹ́jọ́ ìgbésẹ̀ láti yẹpẹrẹ ààbò ìlú tí a sì rán wọn lọ sí ẹ̀wọ̀n nínú oṣù Kìn-ín-ní ọdún-un 2020.

Àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí ó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìwé ìròyìn Iwacu kò fi méní pe méjì níṣe ni wọn sọ wí pé àwọn kò ṣẹ̀ sófin. Ní báyìí wọ́n ń dúró [3] de ìpinnu ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí àtìmọ́lé wọn, lẹ́yìn ìgbẹ́jọ ọjọ́ 6 oṣù Karùn-ún. 

Antoine Kaburahe, olùdásílẹ̀ ìwé ìròyìn tí ó ń gbé ní ẹ̀yin odi, kọ [4]

Ní yàjóyàjó: Òpin ìgbẹ́jọ́ ní Bubanza. Iwacu bọ́rí. Ẹ̀sùn tí a kà sí àwọn akọ̀ròyìn náà lọ́rùn kì í ṣe tiwọn. Iṣẹ́ẹ wọn ni àwọn akọ̀ròyìn náà ń ṣe: ìkóròyìnjọ. Ọkàn-án balẹ̀! Àmọ́ adájọ́ kò tíì dájọ́, àbálọ-bábọ̀ ọ̀rọ̀ di lẹ́yìn oṣù kan. Ẹ dúró ṣinṣin!

Àtìmọ́lé fún ìkóròyìnjọ

Ní ọjọ́ 22, oṣù Ọ̀wàrà, àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò Burundi wà á kò pẹ̀lú ẹgbẹ́ [8] agbébọrìn alátakò ìjọba kan — tí à ń pè ní [9] RED-Tabara, tí ó fi Democratic Republic of Congo ṣe ilé — ní agbègbè ibodè igbó Kibira. Àwọn ẹgbẹ́ ọlọ́tẹ̀ agbébọrìn ti máa ń fi ibí yìí kiri àgbègbè náà. Nínú ìjà akátá náà, àwọn agbébọrìn 14 ni ikú pa, tí ẹ̀ṣọ́ aláàbò 10 sì bá a lọ. [10]

Ní ọjọ́ yẹn náà, àwọn ọlọ́pàá fi àwọn akọ̀ròyìn Iwacu mẹ́rin àti awakọ̀ wọn Adolphe Masabaakiza sí àtìmọ́lé [11], nígba tí wọn lọ kóròyìn jọ [12] ní àdúgbò Musigati, ní Bubanza, níbi tí wọ́n ti fẹ́ bá àwọn ènìyàn tí ó sá kúrò ní àdúgbò nígbà tí ìjà náà bẹ́ sílẹ̀. Lákọ̀ọ́kọ́, a fi wọn sí àtìmọ́lé [13] láì fi ẹ̀sùn kàn wọ́n, tí a sì lu Christine Kamikazi nígbà tí wọ́n mú wọn. Ọlọ́pàá gba ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀  àti àwọn ohun èlò iṣẹ́ wọn tí àwọn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ sí béèrè fún gbólóhùn ìfiwọlé sí orí ẹ̀rọ wọn láti yẹ̀ ẹ́ wò fínnífínní.

Àwọn akọ̀ròyìn náà di ẹni tí à ń gbé kiri lọ [14] sí túbú mìíràn tí kò sunwọ̀n. Ní ọjọ́ 26 oṣù Kẹwàá, ní Bubanza, a jàjà fẹ̀sùn [15] “Ìlọ́wọ́sí ìdúkokò mọ́ ààbò ìlú” kàn wọ́n. Ní ọjọ́ 31, oṣù Kẹwàá, abánirojọ̀ náà fi ẹ̀rí èyí lélẹ̀ [16] ó sì fẹ̀sùn kàn wọ́n ní pé wọ́n mọ̀ sí ìkọlù àwọn kọ̀lọ̀rànsí ẹ̀dá náà. 

Àwọn iléeṣẹ́ ní ẹ̀ka-ò-jẹ̀ka ni ó ti pè [17] fún ìdásílẹ̀ wọn, títí kan Human Rights Watch, International Federation of Journalists, Olucome [18], African [19] Journalists’ Federation àti Àjọ Burundaise des Radiodiffuseurs [20]. Síbẹ̀, Iléeṣẹ́ Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ Àpapọ̀ sọ [21]wí pé  àwọn kò tíì lè sọ sí ọ̀ràn náà báyìí. Iwacu bu ẹnu àtẹ́ [22] ohun tí àjọ náà sọ, ní pé wọn kò fẹ̀sùn kankan kàn wọ́n nígbà tí wọ́n mú wọn àti pé ojúṣe àjọ náà ni láti gbèjà àwọn akọ̀ròyìn. 

Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ní ó gbè lẹ́yìn [23] àwọn akọ̀ròyìnnáà tí wọ́n sì fi ọwọ́ bọ ìfẹ̀sùnkàn [24]lórí ẹ̀rọ-ayélujára. Àwọn iléeṣẹ́ oníròyìn [25] ríi gẹ́gẹ́ bí ìfojú-ẹ̀tọ̀ sí òmìnira oníròyìn gbolẹ̀, tí Iwacu sì ń tọ okùn [26] ọ̀ràn [27] náà lọ pẹ́kípẹ́kí. 

Akọ̀ròyìn Esdras Ndikumana túwíìtì [28]

Burundi: àwọn akọ̀ròyìn Iwacu mẹ́rin (àti awakọ̀ wọn) ni a fi ẹ̀sùn  “ìlọ́wọ́sí ìdúkokò mọ́ ààbò ìlú” kàn nítorí wọ́n lọ kó ìròyìn ìkọlù tí ó wá sáyé tí wọ́n sì di ẹ̀rọ ọgbà ẹ̀wọ̀n  Bubanza (Àwòrán láti ọwọ́ Yaga)

Ìgbẹ́jọ́

Lẹ́yìn tí wọ́n ti ní ẹjọ́ tí ó fi àwọn sí inú àtìmọ́lé náà kò tẹ́ àwọn lọ́rùn, a dá ọjọ́ [31] ìgbẹ́jọ́ wọn sí ọjọ́ 18, oṣù Kọkànlá, kàyéfì ni ó jẹ́ fún wọn nígbà tí wọ́n gbé wọn lọ sílé ẹjọ́ [32] ní ọjọ́ 11, oṣù Kọkànlá kí wọn ó wá gbọ́wọ́ pọ̀nyìn rojọ́ níwájú adájọ́ — láì sí àwọn agbẹ́jọ́rò. Wọ́n kọ̀ wọn kò fèsì nítorí kò sí àwọn agbẹ́jọ́rò wọn níkàlẹ̀, wọ́n sì dá wọn padà sí àtìmọ́lé, kí ọjọ́ 18 tí a dá fún ìgbẹ́jọ́ ó kò. 

Ní ọjọ́ 20 oṣù Kọkànlá, ìpinnu dé tí wí pé àwọn akọ̀ròyìn [33] mẹ́rẹ̀ẹ̀rin yóò padà sínú àtìmọ́lé, àmọ́ wọ́n dá awakọ̀ sílẹ̀. Ìdájọ́ tí a fún wọn [34] tó ọdún 15 nínú ẹ̀wọ̀n [35]

Ààrẹ Pierre Nkurunziza sọ [36] níbi àpéjọ àwọn akọ̀ròyìn kan tí ó wá sáyé ní ọjọ́ 26 oṣù Kejìlá wí pé ohun ohun kò ní fẹ́ dídijú mọ́rí dájọ́ àmọ́ ó dìgbà tí a bá ti ṣánpá tí kò ṣe é ṣán mọ́ ni òun yóò tó ká a lérí, pẹ̀lú pé ó lè fi àṣẹ tí ó ń bẹ ní ìkáwọ́ rẹ da ẹjọ́ náà nù. 

Ìránsẹ́wọ̀n

Lọ́jọ́ 30, oṣù Kìn-ín-ín ní Bubanza [37], a rán [38]to àwọn akọ̀ròyìn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin náà lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún méjì àti àbọ̀ pẹ̀lú kí ẹnìkọ̀ọ̀kan ó sanwó ìtanràn ẹgbẹẹgbẹ̀rún owó francs ($521 owó orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà) lábẹ́ òfin 16 ti Òfin Ọ̀daràn [37], tí awakọ̀ sì gba ilé-e rẹ̀ láì sanwó ìtanràn. 

Ìdájọ́ náà kò fi hàn ní pàtó wí pé àwọn akọ̀ròyìn náà mọ ohunkóhun nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà, látàrí èyí ẹ̀sùn náà yíra padà di “ìgbésẹ̀ ìlọ́wọ́sí ìdúkokò mọ́ ààbò ìlú tí kò ṣe é ṣe”, ìyẹn ni pé — wọ́n pète láti dúnmọ̀rurumọ̀ruru mọ́ ààbò ìlú àmọ́ ó ṣòro láti gbé ṣe. 

Iwacu ṣàlàyé [39] wí pé àwọn akọ̀ròyìn náà lọ síbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà lẹ́yìn tí àwọn aláṣẹ tí fi léde, wọ́n gba ìwé àṣẹ kò sì sí òfin tí ó ní kẹ́nìkan [40] ó máa dé agbègbè ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Ẹ̀rí kan ṣoṣo tí wọ́n rí dìmú [9] tí ó kó àwọn akọ̀ròyìn náà sí yáwúyáwú ni àtẹ̀jíṣẹ́ orí WhatsApp tí ọ̀kan lára àwọn akọ̀ròyìn náà fi ṣọwọ́ sí ọ̀rẹ́ẹ rẹ̀ kan, tí ó sọ wí pé àwọn fẹ́ lọ “ran àwọn ọlọ́tẹ̀ ìjọba náà lọ́wọ́.” Àmọ́ ẹ̀fẹ̀ lásán ni wọ́n fi ṣe —  ìjọba ti máa ń sábà kó àwọn alátakò, ẹgbẹ́ olóṣèlú àti àwọn agbébọnrìn papọ̀ láti jàre irú ìgbésẹ̀ báyìí. [41]  the àtẹ̀jíṣẹ́ náà ni a fi kàn wọ́n mọ́lẹ̀.

Reporters Without Borders (RSF) sọ wí pé [38] àwọn akọ̀ròyìn náà lẹ́tọ̀ọ́ láti jábọ̀ ìròyìn tí ó kan gbogbo ìlú gbọ̀ngbọ̀n láì fòyà ìgbẹ̀san [42], papàá ní ìgbaradì ìbò orílẹ̀-èdèe Burundi ọjọ́ 20 oṣù karùn-ún tí ó ń bọ̀ lọ́nà. Wọ́n kọ [43] ìwé ìfẹ̀sùnkànni [44] kan tí ó ń pè fún ìdásílẹ̀ wọn, èyí tí ènìyàn tí ó tó 7,000 tọwọ́bọ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù Karùn-ún. 

Àwọn igbá-kejì [45]àjọ European Union, Ìgbìmọ̀ ìjọba Yúróòpù [46], àti àwọn àgbà UN nípa ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn wà lára àwọn tí ó ti pè [47] fún ìdásílẹ̀ wọn.

Kò-tẹ́-mi-lọ́rùn

Lọ́jọ́ 20 oṣù Kejì, àwọn akọ̀ròyìn náà ní ìdájọ́ náà kò-tẹ́ àwọn lọ́rùn [48], tí wọ́n sọ wí pé aláìṣẹ̀ ni wọ́n ń fìyà jẹ, àti àyípadà pàjáwìrì tí ó déédéé bá ẹ̀sùn tí wọ́n kọ́kọ́ fi kàn wọ́n. Lọ́jọ́ 6, oṣù karùn-ún, àwọn akọ̀ròyìn náà fojú hàn [49] nílé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn [50] kan, lẹ́yìn tí wọ́n ti fi ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́fà jura. 

Ní ìfèsìpadà sí ẹ̀sùn náà látàrí iṣẹ́-ìjẹ́ orí WhatsApp, ní èyí tí akọ̀ròyìn kan sọ wí pé àwọn ọlọ́tẹ̀ náà ń bọ̀ wá “dí àlàáfíà lọ́wọ́.” RFI tún ọ̀rọ̀ [50] agbẹ́jọ́rò wọn, Clément Retirakiza wí, wípé kkò sí ẹ̀rí tí dájú nípa ẹ̀sùn tí a fi kan àwọn akọ̀ròyìn náà, wọ́n kàn fẹ́ fi ọwọ́ ọlá gba aláìṣẹ̀ lójú ni.

Ọjọ́ ti pẹ́ tí Iwacu ti wà gedegbe [51] gẹ́gẹ́ bí ohùn tí ó fajúro [52] sí jágídíjàgan ìṣèlú — òun ni iléeṣẹ́ oníròyìn tí ó kẹ́yìn lẹ́yìn ìgbẹ́sẹ̀lé [53]ọdún-un 2015.

Ìṣẹ̀lẹ̀ àtẹ̀yìnwá nípa ìjìyà akọ̀ròyìn

Lẹ́yìn ètò ìdìbò tí ó dá wàhálà sílẹ̀ ti ọdún-un After 2015 — èyí tí ó gbé Nkurunziza padà sípò fún ìgbà kẹta tí àwọn ènìyàn sọ wí pé ó tasẹ̀ àgbẹ̀rẹ̀ sófin — ìfipágbàjọba tí kò yọrí sí rẹ. Iṣẹ́ àwọn akọ̀ròyìn de polúkúmuṣu. [54]

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iléeṣẹ́ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ — tí àwọn ènìyàn fẹ́ràn fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìròyìn tí kò figbákanbọ̀kan ní Burundi — ni a ṣán pa [55]. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ akọ̀ròyìn lló júbà ehoro tí àwọn mìíràn bíi Esdras [56] Ndikumana [57] jẹ mo-yó-ìyà

Ọ̀gọ̀rọ àwọn akọ̀ròyìn ni ó ti ní ìrírí ìyà [58] lọ́wọ́ àwọn ẹ̀sọ́ agbófinró ìlú, pàápàá jù lọ bí wọ́n ń bá kó ìròyìn tí ó “pọn dandan” jọ. Ní ìparí ọdún 2015, ọlọ́pàá pa [59] òǹyàwòrán Christophe Nkezabahizi pẹ̀lú àwọn ọmọ-lẹ́bí mẹ́ta, ní àsìkò ìbò tí ìfẹ̀hónú wá sáyé.

Nínú oṣù Keje ọdún 2016, Jean Bigirimana di àwátì [60],  ó ṣe é ṣe kí ó jẹ́ wí pé iléeṣẹ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ (SNR) ló gbé e, láì jẹ́ kí àwọn ọlọ́pàá ó ṣe ìwádìí ìfínìdíikókò bó ṣe yẹ. 

Lọ́dún yìí, ní ọjọ́ 16 oṣù Kìn-ín-ní, akọ̀ròyìn Blaise-Pascal Kararumiye pẹ̀lú Radio Isanganiro (Meeting Point Radio) di èrò akánrán ọlọ́pàá [61] lẹ́yìn ìròyìn kan nípa owó ìjọba ìbílẹ̀ kan. Lọ́jọ́ 28, oṣù kẹrin, ọlọ́pàá kan na akọ̀ròyìn [62] Jackson Bahati níbi tí ó ti ń ṣiṣẹ́ ìkóròyìn jọ. 

Àwọn iléeṣẹ́ oníròyìn àgbáyé náà ò gbẹ́yìn, a gbẹ́sẹ̀ lé [63]iṣẹ́ BBC ati VOA ní 2019. RSF to [64] Burundi sí ipò 160 nínú orílẹ̀èdè 180 fún òmìnira oníròyìn — ó fi 15 láti 2015.