Túwíìtì nípa èdè Ilẹ̀-Adúláwọ̀ àti ẹ̀tọ́ sí ìlò ẹ̀rọ ayárabíàṣá

Ilẹ̀-Adúláwọ̀ láti ọwọ́ọ Georgia Osinga ti Noun Project.

Láti tẹ̀síwájú nínú àkànṣe iṣẹ́ tuntun kan tí a pè ní “Orísun Ìdánimọ̀: òfin gbàgede orí ẹ̀rọ-ayélujára bí ajere tí ń gbégi dínà ìdàgbàsókè ọ̀rọ̀ sísọ ní Ilẹ̀-Adúláwọ̀,” tí ó ń ṣe àgbéyẹ̀wò ọ̀rọ̀ ìkórìíra tẹ̀gbintẹ̀gbin tí ó dá fìrìgbagbòó lóríi ìdánimọ̀, ìṣìwífún àti ìyọlẹ́nu lórí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá ní àsìkò ètò ìṣèlú, Ohùn Tí-ó-ń-gbéra (Rising Voices) ń kó ọmọ lùbọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn akẹgbẹ́ẹ wa ní yàrá ìròyìn Ohùn Àgbáyé Ẹ̀ka Agbègbè Àṣálẹ́ Sahara Ilẹ̀-Adúláwọ̀ fún ìpolongo tuntun lórí ẹ̀rọ ìkẹ́gbẹ́ ayélujára láti ṣe àyẹ̀wò ìbáṣepọ̀ tí ó ń bẹ láàárín àwọn èdè Ilẹ̀-Adúláwọ̀ àti ẹ̀tọ́ sí ìlò ẹ̀rọ ayárabíàṣá. Ilé iṣẹ́ Collaboration on International ICT Policy in East and Southern Africa (CIPESA) ní ó kó owó sílẹ̀ fún iṣẹ́ àkànṣe yìí. Ka ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ nípa iṣẹ́ àkànṣe náà sí i níbí.

Ìpolongo lórí ẹ̀rọ alátagbà ọlọ́sẹ̀ márùn-ún yìí yóò fìwé pe àwọn ajìjàngbara èdè ní orí ẹ̀rọ ayárabíàṣá márùn-ún láti orígun mẹ́rin Ilẹ̀-Adúláwọ̀ tí yóò máa gbé ọ̀ràn ẹ̀tọ́ sí ìlò ẹ̀rọ náà wò lónírúurú ọ̀nà lójúnà àti ṣe àwòfin ìmọ̀ràn àti pàtàkì fún ìlò èdè Ilẹ̀-Adúláwọ̀ lórí ẹ̀rọ-ayélujára bí ajere. Lọ́sọ̀ọ̀ọ̀sẹ̀ ni wọn ó máa ‘tukọ̀’ ìṣàmúlò @GVSSAfrica lórí Twitter tí wọn yóò máa túwíìtì yálà ní èdè Gẹ̀ẹ́sì tàbí Faransé, àti ní èdè Ilẹ̀-Adúláwọ̀ tí wọ́n ń ṣe ìgbélárugẹ rẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn atukọ̀ náà ni ó kópa nínú ìpolongo orí @DigiAfricanLang in tí a fi sààmì Àyájọ́ Ọdún Èdè commem Lágbàáyé 2019.

Mọ̀ sí i nípa ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn atukọ̀ nípasẹ̀ ṣíṣíra tẹ orúkọ wọn níbi tí o ó ti ka àwọn Ìbéèrè àti ìdáhùn ráńpẹ́ tí ó ń ṣàlàyé iṣẹ́ kọntakọnta tí wọ́n ń ṣe. Rí i dájú wí pé o tẹ̀lé ìṣàmúlò @GVSSAfrica lórí Twitter àti àmì #IdentityMatrix bákan náà.

 

Àlàkalẹ̀ Ètò

 

Igbe 20-24:

Denver Toroxa Breda ( @ToroxaD) – àjàfẹ́tọ̀ọ́ èdè Khoe àti àṣà Kuwiri, òǹkọ̀wé tí ó ń jà fún dídá èdè Khoekhoe àti N|uu, àwọn èdè Gúúsù Ilẹ̀-Adúláwọ̀ àtijọ́ mọ́ gẹ́gẹ́ bí èdè ìlú. Khoekhoe jẹ́ èdè kan tí wọ́n ń sọ ní Namibia, tí ó jẹ́ kíkọ́ nílé, tí ó wà dunni yet in wí pé kò ju ẹni 2000 lọ tí ó ń fọ èdè náà ní Gúúsù Ilẹ̀-Adúláwọ̀ níbi tí ó ti ṣe, nítorí ìjọba kò dà á mọ̀, kò sí nílé ìwé. Èèyàn kan ṣoṣo ni ó ń sọ èdè N|uu yékéyéké, ìjọba kò fọwọ́ sí i gẹ́gẹ́ bí èdè ìlú, a kò kọ́ ọ nílé ìwé, ó sì ń ṣe wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ di èdè tí yóò re oko parun díẹ̀ díẹ̀.

Igbe 27- Èbìbí 1:

Kpénahi Traoré ( @kpenahiss) Èmi ni Kpénahi TRAORÉ, a bí mi ní orílẹ̀-èdèe Ivory Coast, àmọ́ ọmọ orílẹ̀-èdèe Burkina Faso ni mí. Mo jẹ́ olóòtú àgbà fún RFI mandenkan, yàrá ìròyìn ní èdè Bambara nílé iṣẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ Radio France Internationale (RFI). Ìrírí ńlá ni fún mi láti ṣiṣẹ́ nínú èdè yìí, nítorí pé tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ́ rí mo lérò wí pé kò ní ṣe é ṣe tàbí yóò ṣòro láti It iṣẹ́ akọ̀ròyìn ní èdè Bambara. vSamogo ni èdè abínibí mi, pàápàá bí mo bá gbọ́njú mọ èdè tí à ń pè ní Dioula ní Ivory Cost àti ní Burkina Faso. Àwọn aráa Mali máa ń pè ní Bambara, àwọn aráa Guinea ní Malinke, àwọn mìíràn pé Mandingo.

Èbìbí 5-8:

Blossom Ozurumba ( @blossomozurumba) Èmi ni Blossom Ozurumba tí àwọn èèyàn púpọ̀ máa ń pè ní Blossom nígbà tí àwọn mìíràn ń pè mí ní Asampete ní èyí tí a leè túmọ̀ láti inú èdè Igbo sí “ẹni tí ó rẹwà.” Bí ẹni tí a gẹṣin nínú rẹ̀ ni ọ̀rọ̀ èdè àti àṣà Igbo fún mi ni mo ṣe pakuru mọ́ ìgbélárugẹ kí an d cultu ènìyàn ó bá dántọ́ díẹ̀ nínú ìmọ̀ tàbí gbogbo sísọ, kíkọ àti kíkà. Mo jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùdásílẹ̀ Ẹgbẹ́ Òǹṣàmúlò Wikimedia nítorí náà ó ṣe é ṣe kí n gbẹ́nu  lé akitiyan iléeṣẹ́ Wikimedia Foundation láì ṣe àní-àní. Ìpínlẹ̀ Abuja, Nàìjíríà ni mo fi ṣelé, mo sì fẹ́ràn-an ìparọrọ àti àìkánjú ìlú náà.

Èbìbí 11-15:

Ọmọ Yoòbá ( @yobamoodua) -Adéṣínà Ayẹni tí àwọn ènìyàn mọ̀ sí Ọmọ Yoòbá jẹ́ oníròyìn àti alágbàwí àṣà ìbílẹ̀ tí ó gba ojúṣe ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ìṣe àti àṣà ìbílẹ̀ ṣe nípa ìpamọ́, ìfọ́nká àti ìtagbà àjogúnbá ilẹ̀ẹ Yorùbá lórí ẹ̀rọ ayélujára àti ní ojúkorojú. Gẹ́gẹ́ bí òṣèrè ohùn, ó ti ṣe àwọn àìlóǹkà ìpolówó ní èdèe Yorùbá fún ẹ̀rọ amohùnmáwòrán àti ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́. Òun ni olùdásílẹ̀ Yobamoodua Cultural Heritage, pẹpẹ tí ó ń ṣe ìpolongo èdè àti àṣà Yorùbá. Ọmọ Yoòbá náà ni alákòóso ibùdó Ohùn Àgbáyé ní èdèe Yorùbá. Olùkọ́ni èdèe Yorùbá ní tribalingua.com níbi tí ó ti ní akẹ́kọ̀ọ́ kárí ayé. Ó sì ti bá Localization Lab, àjọ àwọn aáyan ògbufọ̀, onímọ̀ ẹ̀rọ ayárabíàṣá àti àwọn ènìyàn tí ó ń lò ó ṣiṣẹ́ papọ̀ rí. Ọmọ Yoòbá ti kọ ìwé tí a pè ní: Ẹ̀yà Ara Ẹ̀dá Ọmọ Ènìyàn, àkójọpọ̀ ìpín ara nípa lílà á àti bí àwọn ẹ̀yà ará ṣe rí àti àwọn onírúurú ewé àtegbò tí ó ń ṣe iṣẹ́ ìyanu sí ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹ̀yà ara náà. Oníwàádìí fún Firebird Foundation for Anthropological Research ní í ṣe.

Èbìbí 18-22:

Bonface Witaba ( @bswitaba) Mo jẹ́ òǹkọ̀wé, ọlọ́gbọ́n àtinudá ìbílẹ̀ àti alágbàwí, olùkọ́ni, oníṣẹ́-ìwádìí àti ọ̀mọ̀ràn nípa ètò Òfin Ẹ̀rọ-ayélujára. Èmi ni asíwájú ICANNWiki Swahili, ibùdó ìkójọ àwọn àpilẹ̀kọ 10,000 lórí Òfin Ẹ̀rọ-ayélujára láti ṣe ògbufọ̀ rẹ sí èdè Swahili fún àwọn ẹgbẹẹgbẹ̀rún 150 ènìyàn tí ó ń sọ èdè Swahili kí ó tó di ọdún-un 2020. Ní àfikún, mo ṣe àgbékalẹ̀ ètò ìrónilágbára nípa Òfin Ẹ̀rọ-ayárabíàṣá fún àwọn Ọ̀dọ́ láti kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́, olùkọ́ àti àwọn ènìyàn tí ó ń ṣiṣẹ́ ìjọba àti; tàbí iṣẹ́ àdáni ní ẹ̀kọ́ ìmọ̀ òfin ayélujára, kí wọ́n ba ní òye tí ó kún nípa ìlànà rẹ̀.

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.