- Global Voices ní-Yorùbá - https://yo.globalvoices.org -

Ọ̀nà wo ni àrùn COVID-19 ń gbà ṣe àtúnṣe sí ètò ìṣèlú àti ẹ̀yìn-ọ̀la Orílẹ̀-èdè China lágbàáyé?

Sàwáwù : Ìròyìn Ọmọ-ìlú, COVID-19

Àwòrán tó ń fi ààlà-ilẹ̀ orílẹ̀-èdè China hàn lórí ọmọ ọ̀rọ̀ mẹ́rin tí kíkà rẹ̀ jẹ́ 武汉肺炎 tí ó túmọ̀ sí “àrùn ẹ̀dọ̀fóró Wuhan” (tí ó ṣì jẹ́ lílo ní èdè Chinese), gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe mọ àjàkálẹ̀ náà ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, kí ó tó yí orúkọ padà sí COVID-19. A gba àṣẹ láti lo àwòrán.

Ohun tí ó bẹ̀rẹ̀ nínú ọjà oúnjẹ inú odò, gẹ́gẹ́ bí i ọ̀ràn àìlera ìbílẹ̀, ti wá di nǹkan tó rànká Orílẹ̀-èdè China. Lẹ́yìn ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ìjẹyọ kòkòrò àìfojúrí kòrónà ní Wuhan nínú Oṣù Kejìlá Ọdún 2019, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ ló ṣẹ̀ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé ló ṣú yọ tó sì fi àwùjọ ilẹ̀ Chinese làkàlàkà tí ó sì tún dojú ìpèníjà kọ ìdúróṣinṣin ètò ìṣèlú Beijing [1].

Kíkúndùn ìṣàkóso ìròyìn ti fún ìjọba lọ́rùn, àti ìjọba ìbílẹ̀ àti ìjọba àpapọ̀ ní àárín gbùngbùn, ló máa ń fa ìdádúró fún àgbéjáde ìròyìn tí yóò ṣe ará ìlú láǹfààní [2] fún ọ̀sẹ̀ pípẹ́. Nígbà tí wọ́n wá sọ jí láti ṣe ìkéde lórí àwọn ọ̀nà tí yóò dẹ́kun ìtànká àjàkálẹ̀ náà, ó ti bọ́ sórí, nítorí ayẹyẹ ọdún tuntun ìran Chinese [3] ọlọ́dọọdún ti gbérasọ.

Àwọn Dókítà àti àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sì ń ṣe ìwádìí àti ìfọ̀rọ̀jomitoro-ọ̀rọ̀ [4] lórí ohun tí ó lè jẹ́ orísun àrùn tí wọ́n mọ̀ nígbà náà lọ́hùn-ún gẹ́gẹ́ bí kòkòrò àìfojúrí kòrónà ti Wuhan, tí ó padà wá ṣe okùnfà COVID-19, kòkòrò àìfojúrí tó ń mú kí ènìyàn má leè mí sókèsódò tí ó sì ń fa àrùn ẹ̀dọ̀fóró. Ìdámọ̀ràn ohun tí ó lè fa sábàbí àrùn náà kan fi yé wí pé kòkòrò àìfojúrí kòrónà jẹ yọ látàrí ẹran ejò tàbí ẹran àdán tí àwọn ará China máa ń jẹ [5] l'óúnjẹ, tí wọ́n ń tà ní ọjà Huanan wet [6] ní agbègbè Wuhan níbi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní èrò wí pé ibẹ̀ ni orísun kòkòrò àìfojúrí yìí.    

Ìbéèrè kan tí ó nílò ìdáhùn ni ti ọ̀nà ìtànkálẹ̀ àrùn yìí: bóyá ó leè rànká láti ara èèyàn kan sí ìkejì, àti ìyè èèyàn mélòó ló leè kó àìsàn yìí látara ẹni tí ó bá ti ní i. Ẹ̀rí láti ìmọ̀ ìlera tó fẹsẹ̀múlẹ̀ ṣe ìṣípayá àrànkán láti ara ènìyàn kan sí ìkejì, tí ó fi jẹ́ wí pé kòkòrò náà yóò ti wà lágọ̀ọ́ ara fún ìgbà díẹ̀ kí ẹni tí ó kó o ó tó máa rí àwọn ààmì rẹ̀ lára, [7] tí èyí ò sì mú mímọ ẹni tí ó bá ti lu gúdẹ àrùn náà rọrùn.  

Ní ti bí àrùn náà ti ń ràn, èyí tí àwọn onímọ̀ nípa àjàkálẹ̀ àrùn ń pè ní “òǹkà ìpìlẹ̀ ìbísí [8]“, gbà pé ó wà láàárín 2 sí 3 ní ìparí Oṣù Kìn-ín-ní, ẹni tí ó ní i yóò kó o ran ẹni méjì sí mẹ́ta, ṣùgbọ́n ìfikùnlukùn àti ìwádìí kò dúró, ìyẹn bí àwọn ìwífún-alálàyè tí ó wúlò bá wà ní àrọ́wọ́tó. 

Bí òǹkà àwọn tí wọ́n ti ní kòkòrò yìí ṣe ń lọ sókè sí i lójoojúmó, àáríngbùngbùn Orílẹ̀-èdè China tí i ṣe Hubei [9] àti Olú-ìlú rẹ̀ tí í ṣe Wuhan ti ní ìdojúkọ tó gogò [10] lórí ètò ìlera, tí àpapọ̀ àwọn tí wọ́n ń gbé lágbègbè yìí sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún-lọ́nà-ẹgbẹ́rùn ní ìlọ́po 60. Bí iye àwọn tí ó ti kó àrùn yìí ṣe ń pọ̀ káàkiri Orílẹ̀-èdè China, àwọn òṣìṣẹ́ elétò ìlera ti wà digbí, tí wọ́n sì tún kóná mọ́ ètò ìlera tí kò sùwábọ̀ tó [11] fún ìtọ́jú àwọn ọ̀kẹ́ àìmọye arúgbó tó kún ìlú.  

Ṣùgbọ́n àrùn kòkòrò àìfojúrí kòrónà Wuhan náà kì í ṣe ìkọlù ètò ìlera lásán, ó jẹ́ àkókò òtítọ́ ètò ìṣèlú tí ó lákaakì. Ìgbẹ́kẹ̀lé ìjọba tí ó sọ fún àwọn ará ìlú wí pé kò s'éwu l'óko àfi gìrì àparò ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, títí tí ẹ̀pa ò fi bóró mọ́, tí àwọn ará ìlú kò sì ní ìfọkàntán nínú àwọn ìjọba wọn mọ́, àti pé, kì í ṣe ní agbègbè Hubei nìkan ni èyí ti ṣẹlẹ̀. Àwọn ará ìlú bu ẹnu àtẹ́ lu ìjọba Beijing fún ọwọ́ yẹpẹrẹ tí wọ́n fi mú ọ̀rọ̀ àjàkálẹ̀ àrùn èémí SARS [12] tó ṣú yọ ní ọdún 2002 sí 2003, bí ó ti ṣe fi ìròyìn tó péye lórí rẹ̀ pamọ́ fún [13] Àjọ Elétò Ìlara Lágbàáyé (WHO). Olórí Orílẹ̀-èdè China àgbà Xi Jinping dákẹ́ rọrọ lórí àjàkálẹ̀ àrùn yìí àyàfi ìgbà tí ó di ọjọ́ 20, Oṣù Kìn-ín-ní Ọdún, tí ó kéde fún ará ìlú [14] lẹ́yìn oṣù kan tí àrùn náà ti ń ṣọṣẹ́, pé ọ̀ràn náà ti kọjá àfẹnusọ. Agbára lórí ìṣàkóso àtẹ̀jáde ìròyìn fẹsẹ̀ múlẹ̀ rìnrìn ní orílẹ̀-èdè China, àti pé, ìwọ̀yáàjà ètò káràkátà pẹ̀lú Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, àti bí ọrọ̀-ajé wọn ṣe ń dẹnukọlẹ̀, bí wọ́n bá ṣe yanjú ìṣòro kòkòrò àìfojúrí kòrónà ti Wuhan náà ni yóò forí lé ní ọdún 2020.

Bí a ṣe ń tẹ̀síwájú láti fi àwọn àkànṣe ìròyìn kún ojú ìwé yìí, kà síwájú sí i pẹ̀lú àwọn ìròyìn wọ̀nyí:

Ìpolongo tó ń rọ àwọn olùgbé Wuhan pé kí wọ́n ṣe ìmọrírì olórí Ẹgbẹ́ Olóṣèlú Communist fún ìgbógunti COVID-19 tí ó lẹ́yìn [15]

Ọ̀nà tí àwọn gbàgede ẹ̀rọ agbọ́rọ̀káyé ti orílẹ̀-èdè Chinese ń gbà kó ara wọn níjàánu bí wọ́n bá ń gbé ìròyìn jáde lórí COVID-19. [16]

Orílẹ̀ Èdè China ṣe ìtẹ̀mọ́lẹ̀ ìròyìn tí ó jínyìn bí àwọn aláṣẹ ìjọba China ṣe fi ọ̀rọ̀ pamọ́ lórí àbájáde àyẹ̀wò ìtọ̀lẹ́yìn ẹ̀dá COVID-19 fún ọjọ́ Mẹ́rìnlá. [17]

Ìbú-ẹnu àtẹ́ lu àwọn aṣojú Àjọ Elétò Ìlara Lágbàáyé (WHO) látàrí ‘ìwà àìtètè bìkítà’ àti ‘ìwà ìkọ̀yìnsí ìtìlẹ́yìn China’ bí àrùn COVID-19 ṣe ń tàn ká gbogbo àgbáyé. [18]

Ìkáni-lọ́wọ́-kò lórílẹ̀-èdè China fihàn wí pé òun leè f'ara gba ìparun tí yóò bá ilé iṣẹ́ ìgbéròyìn jáde.  [19]

Ìfòfinde ìwọléjáde ní Orílẹ̀-èdè China túbọ̀ ń dúkokò mọ́ ẹ̀ka ètò ìrìnàjò ìgbafẹ́, ẹ̀kọ́ àti ìṣòwò orílẹ̀-èdè Australia. [20]

Agbára ọ̀tun gba orí ẹ̀rọ alátagbà Orílẹ̀-èdè China kan nígbà tí àwọn ènìyàn ó lé ní ẹgbẹ̀rún 60 kó àrùn COVID-19. [21]

Ǹjẹ́ àjàkálẹ̀ kòkòrò àìfojúrí kòrónà ni ‘ìgbà Chernobyl’ ti orílẹ̀-èdè China? [22]

Ìṣémọ́lé ìgbà péréte: Gbígbé pẹ̀lú àjàkálẹ̀ kòkòrò àìfojúrí ní Hong Kong [23]

Kíké gbàjarè síta látàrí àrùn kòkòrò àìfojúrí kòrónà ti Wuhan ti dá aáwọ̀ ìdánilẹ́bi sílẹ̀ ní Orílẹ̀-èdè China. [24]

Ikú kòkòrò àìfojúrí kòrónà tí ó pa Li Wenliang tí ó jẹ́ ẹni tí ó tú àṣírí nípa àrùn náà ti fa ìkérora ẹ̀dùn ọkàn lórí ẹ̀rọ agbọ́rọ̀káyé.  [25]

Ìlàkàkà lórí òǹkà ìtànkálẹ̀ kòkòrò àìfojúrí ti Wuhan. [26]

Chen Qiushi: Oníròyìn Ọmọ-ìlú tó ń léwájú ní ti àgbéjáde ìròyìn lórí àjàkálẹ̀ kòkòrò àìfojúrí kòrónà ti Wuhan [27]

Ìdí pàtàkì méje tí àwọn ará ìlú Hongkong se ń bínú sí àwọn ìjọba wọn látàrí àìbìkítà lórí ọ̀rọ̀ kòkòrò àìfojúrí kòrónà. [28]

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti Orílẹ̀ Èdè Pakistan tí wọ́n wà lábẹ́ òfin kó-nílé-gbélé pè fún ìrànwọ́. [29]

Àwọn olólùfẹ́ ìlú China ní tòótọ́ gbẹ̀san lórí ayélujára lẹ́yìn ìgbà tí gbàgede Danish fi ‘àsíá oníkòkòrò àìfojúrí Chinese’ ṣe yẹ̀yẹ́. [30]

Ní Taiwan, ìjà ọgbọ́n ìṣèlú ni àrùn kòkòrò àìfojúrí kòrónà ti Wuhan jẹ́. [31]

Àwọn onímọ̀ ìlera ti Hong Kong banújẹ́ lórí ìṣiyèméjì ìjọba nípa ti àtìpa ojú ilẹ̀ ìlú fún àìfàyè gba àlejò.  [32]

Ìpalára fún ọrọ̀-ajé ni àrùn kòkòrò àìfojúrí kòrónà ti Wuhan yìí tún jẹ́ fún Orílẹ̀-èdè China  [33]

Àwọn Ọmọ bíbí orílẹ̀-èdè China lábẹ́ òfin kó-nílé-gbélé kérora pé “Beijing ti pa Wuhan tì.” [10]

Ní ìpalẹ̀mọ́ ìṣíláti-ibìkan-lọ-sí-ibòmìíràn fún ayẹyẹ Ọdún Tuntun Òṣùpá àpapọ̀, Orílẹ̀ China ti wá jáwé sóbì ìgbìyànjú wọn lórí kòkòrò àìfojúrí kòrónà ti Wuhan. [34]