Orílẹ̀-Èdè Nàìjíríà fi òfin de ìrìn-àjò lójúnà ìṣàmójútó àwọn tó ti kó kòkòrò àìfojúrí COVID 19

Image by Pete Linforth from Pixabay. Used under a Pixabay license (Free for commercial use/ No attribution required)

Àwòrán láti ọwọ́ Pete Linforth ní Pixabay. Ìlò àwòrán pẹ̀lú àṣẹ Pixabay, fún ìlò gbogboògbò.

Yẹ àkọsílẹ̀ àkànṣe Global Voices wò lórí ipa COVID-19 lágbàáyé.

Gẹ́gẹ́ bí àjò tí ó ń kápá ìtànkálẹ̀ àrùn ní Nàìjíríà ṣe sọ, àwọn èèyàn márùn-ún mìíràn ni wọ́n ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé wọ́n ti kó kòkòro àrùn COVID-19, àròpọ̀ iye àwọn tí wọ́n ní àrùn náà ní Nàìjíríà wá jẹ́ mẹ́jọ.

Iye àwọn ẹni tí ó ní kòkòrò àrùn náà di mẹ́jọ ní ọjọ́ méjì lẹ́yìn tí dókítà E. Osagie Ehanire fìdí i rẹ múlẹ̀ ní ọjọ́ 16, oṣù Ẹrẹ́na pé wọ́n ti rí ẹni kẹ́ta tí ó kó kòkòrò àìfojúrí COVID-19, ìyen “ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kan tí ó lé ní ẹni ọgbọ̀n tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé láti United Kingdom ní ọjọ́ 13, oṣù Ẹrẹ́na.”

Aláìsàn náà ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ fún ọjọ́ 14 ní ìlú Èkó, láàárín àsìkò yìí ni ó bẹ̀rẹ̀ sí i ní àmì àìsàn ibà àti ikọ̀. Aláìsàn náà wà ní ilé ìwòsàn tí wọ́n ti ń ṣètọ́jú Kòkòro àkóràn ní Yaba, ní Ìpínlẹ̀ Èkó. Ara rẹ̀ ti ń balẹ̀, ó sì ń dáhùn sí ìtọ́jú dáadáa.

Bí í iye àwọn ènìyàn tí ó kó kòkòrò àrùn COVID-19 ṣe ń pọ̀ sí i ni Nàìjíríà, ìjọba àpapọ̀ ti gbọ́ ohun tí àwọn aráàlú sọ ní ọjọ́ 18, oṣù Ẹrẹ́na nípa fífi òfin de àwọn tí ó ń rin ìrìn àjò láti orílẹ̀ èdè 13 bí i: China, Italy, Iran, South Korea, Spain, Japan, France, Germany, Norway, United States, United Kingdom, Netherlands àti Switzerland tí ó ní ju ènìyàn 1000 lọ tí ó ti kó kòkòrò àrùn Kòrónà láti má wọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Àwọn tí wọ́n ti wọ Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ láti àwọn orílẹ̀ èdè tí a dárúkọ yìí gbọ́dọ̀ ya ara wọn sọ́tọ̀ fún ọjọ́ 14.

Ọjọ́ 27 ni oṣù Èrèlé ní a fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ọmọ orílẹ̀ èdè Italy kan tí ó rìn ìrìnàjò wá sí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ tí ó ní kòkòrò àrùn COVID-19.

Ẹni kejì tí a fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ó ní kòkòrò àrùn yìí, gẹ́gẹ́ bí NCDC ṣe sọ jẹ́ ẹni tí ó rìnnà pàdé ẹni àkọ́kọ́ tí ó kó àrùn náà, tí ara rẹ̀ sì ti yá báyìí lẹ́yìn tí àyẹ̀wò méjì ti fi hàn pé àyẹ̀wò náà kò sí lára rẹ̀ mọ́. Ẹnìkejì yìí ò ní àrùn náà mọ́, wọ́n sì ti fi í sílẹ̀ kí ó máa lọ sílé ní ọjọ́ 13 oṣù Ẹrẹ́na, ọdún 2020,” gẹ́gẹ́ bíi àjọ NCDC ṣe sọ.

Àwọn Aráàlú lórí ayélujára béèrè fún Ìfòfin-de-Ìrìnàjò

Bí wọ́n ṣe ń bójú tó àrùn COVID-19 kò tẹ́ ọ̀pọ̀ aráàlú lórí ayélujára lọ́rùn, wón sì ti ń béèrè fún àwọn ìgbésẹ̀ tí ó lágbára láti dẹ́kun ìtànkálẹ̀ àrùn náà ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Ọmọ ìlú lórí ayélujára, Ayobami kéde pé ìgbésẹ̀ NCDC falẹ̀. Ó gbà wọ́n nímọ̀ràn pé “kí wọ́n dẹ́kun ṣíṣe àṣehàn lórí ayélujára kí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́!”

Gideon sọ pé “ó yẹ kí ó bà wá lẹ́rù” pé ṣíṣe àyẹ̀wò fún kòkòrò àrùn COVID-19 ń falẹ̀ ní Nàìjíríà.

“Ẹ fi òfin de àwọn arìnrìn-àjò tí ó fẹ́ wọlé láti àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn” pàápàá jù lọ àwọn tí ó wá láti àwọn orílẹ̀ èdè tí àrùn náà ti gbilẹ̀, akọ̀ròyìn Bayo Olupohunda náà tẹnumọ:

Dr. Whitewalker náà tẹnpẹlẹ mọ́ ọn pé kò sí ohun tí ó burú nínú fífi òfin de àwọn arìnrìn-àjò ní àkókò tí wọ́n ṣiṣẹ́ ìṣàdínkù ìtànkálẹ́ àrùn láti lè dẹ́kun àkóràn ní àsìkò ìtànkálẹ́ àrùn bí i irú èyí.

Dr. Chikwe Ihekweazu, olórí àjọ NCDC, bẹ̀bẹ̀ pé àwọn ń “gbìyànjú GIDI láti rí i pé àwọn ṣe gbogbo ohun tí ó yẹ kí àwọn ṣe:

Ní ọjọ́ 17 oṣù Ẹrẹ́na, ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà ti kọ́kọ́ sọ pé kí wọ́n fi òfin de àwọn ọkọ̀ òfurufú tí ó ń bọ̀ láti àwọn orílẹ̀ èdè tí àrùn náà ti gbilẹ̀  bí i United Kingdom àti China, kí wọ́n tó dúró di ọjọ́ kejì kí wọ́n tó fi òfin náà múlẹ̀.

Cable Nigeria jábọ̀ gbogbo àwọn tí wọ́n wá láti àwọn orílẹ̀-èdè tí àrùn náà ti gbilẹ̀ ni wọ́n máa yà sọ́tọ̀ pẹ̀lú àbójútó fún ọjọ́ mẹ́rìnlá. Ìjọba àpapọ̀ sì fi òfin de fífún àwọn ènìyàn ní visa Nàìjíríà.

Ìfòfindèrìnàjò náà bẹ̀rẹ̀ ní àbámẹ́ta ọjọ́ 21, oṣù Ẹrẹ́nà, ọdún 2020, yóò sì wà fún ọ̀sẹ̣̀ mẹ́rin tí ó ṣe é ṣe kí wọ́n sún un síwájú lẹ́yìn àpérò.

Ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè ní ilẹ̀ Adúláwọ̀ ti ń gbé ìgbésẹ̀ láti ṣe àdínkù ìtànkálẹ̀ kòkòrò àrùn COVID-19. Lára àwọn ìgbésẹ̀ yìí ni fífi òfin de ìrìn-àjò láti àwọn orílẹ̀ èdè tí kòkòrò àrùn COVID-19 náà ti gbilẹ̀ láti má ṣe wọ orílẹ̀ èdè wọn.

Ìṣàmójútó tí kò péye tó

Àwọn ìjábọ̀ kan wà nípa bí ìṣàmójútó àwọn òṣìṣẹ́ elétò ìlera kò ṣe péye tó lórí àwọn tó ní kòkòrò àrùn COVID-19 ni orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Obìnrin kan tí ó jẹ́ ẹni ọdún 70 tí ó ti lo oṣù márùn-ún ní United Kingdom padà sí Nàìjíríà ní ọjọ́ 11 oṣù Ẹrẹ́na. Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀ tí ó dé, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní àmì àìsàn kòkòrò àrùn COVID-19 bí i òtútù àti ikun tí ó pọ̀ lápọ̀jù ní ọjọ́ 13, oṣù Ẹrẹ́na. Wọ́n sì sáré gbé lọ sí Teaching Hospital ti ìpínlẹ̀ Enugu (ESUTH) Colliery Parklane, ní gúúsù ìlà-oòrùn Nàìjíríà.

Wọ́n yà á sọ́tọ̀ ní ESUTH Colliery Parklane, wọ́n sì fi àyẹ̀wọ̀ tí wọ́n ṣe fun un ṣọwọ́ sí àjọ NCDC ní ọjọ́ 14, oṣù Ẹrẹ́na fún àyẹ̀wò. Ní ọjọ́ 15, oṣù Ẹrẹ́na, obìnrin náà kú lẹ́yìn tí àjọ NCDC jábọ̀ pé kò ní kòkòrò àrùn COVID-19.

Bẹ́ẹ̀, nínú lẹ́tà tí wọ́n kọ sí gómìnà ìpínlẹ̀ Enugu, ọmọ obìnrin náà fẹ̀sùn kan àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn náà pé “tàbùkù” ìyá òun, wọ́n gbé e sínú “ilé àkọ́kù” tí ó kún fún koríko.

Ọ̀rọ̀ ẹnìkan tí ó ní kòkòrò àrùn COVID-19 tí wọn kò ṣe àbójútó tó péye fún wáyé ní ìpínlẹ̀ Èkó tí ó jẹ́ olú-ìlú ìdókòòwò ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Ní ọjọ́ 17, oṣù Ẹrẹ́na, David Hundeyin tí ó jẹ́ akọ̀ròyìn pẹ̀lú News Wire, jábọ̀ nípa ìṣàmójútó tí kò gúnrégé tó lórí ọ̀rọ̀ ẹni tí wọ́n furasí pé ó ní kòkòrò àrùn COVID-19 ní ilé iṣẹ́ Dangote ní Ibeju-Lekki, ní Ìpínlẹ̀ Èkó, tí ó sì ti ń fa ìpayà láàárín àwọn òṣìṣẹ́ ibẹ̀.

Ní ọjọ́ kejìlá oṣù Ẹrẹ́nà, òṣìṣẹ́ iléeṣẹ́ Dangote kan tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ India tí ó ń tún ọ̀pá omi ṣe wá sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti Mumbai, lẹ́yìn tí ó dúró díẹ̀ ní Cairo, ní orílẹ̀-èdè Egypt. Ìwádìí Hudeyin fi hàn pé ọkùnrin náà tí ó ń tún ọ̀pá omi ṣe bẹ̀rẹ̀ sí i ní “ibà, ikọ́ gbígbẹ, ọ̀fun dídùn àti àìlè mí délẹ̀,” ní ọjọ́ kejì tí ó dé láti India. Síbẹ̀, “kò tí ì hàn bóyá ẹnikẹ́ni ní iléeṣẹ́ Dangote ti gbìyànjú láti kàn sí” àwọn elétò ìlera tí ọ̀rọ̀ náà kàn.

Hudeyin sọ̀rọ̀ síwájú pé ilé iṣẹ́ náà ń lo àǹfààní “àyíká òfin tí kò múnádóko tó” ní Nàìjíríà “láti fi èrè tirẹ̀ síwájú”, èyí sì ń fi ẹ̀mí àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ àti gbogbo àwùjọ sínú ewu.

Ìròyìn yìí mú kí iléeṣẹ́ náà gbé èrò wọn jáde pé àwọn ti gbé aláìsàn náà lọ sí ilé ìwòsàn tí wọ́n ti ń ṣètọ́jú kòkòrò Àkóràn ní Yaba, ní ìpínlẹ̀ Èkó.

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.