- Global Voices ní-Yorùbá - https://yo.globalvoices.org -

Sísọnù sínú ògbufọ̀: Ìdí tí Atúmọ̀ Google ṣe ń kùnà — nínú títúmọ̀ èdè Yorùbá — àti àwọn èdè mìíràn

Sàwáwù : Ìlú Gúúsù Aṣálẹ̀ Sahara, Nàìjíríà, Èdè, Ìdàgbàsókè, Ìmọ̀-ẹ̀rọ, Ìròyìn Ọmọ-ìlú, Iṣẹ́ ìkọ̀ròyìn àti Ìròyìn-kíkọ, Iyè-inú, Ohùn Tó-ń-dìde
[1]

Aṣàmúlò Ẹgbẹ́ Wikimedia Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, oṣù Ọ̀wàrà ọdún 2018 láti orí Wikimedia Commons CC.BY.2.0.

Èdè Gẹ̀ẹ́sì ti jẹ gàba lórí ìbánisọ̀rọ̀ tí ó ń wáyé ní orí ẹ̀rọ ayélukára-bí-ajere gẹ́gẹ́ bí èdè “gbogbo àgbáyé” fún ìtàkùrọ̀sọ láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ẹ̀rọ ayélujára. Nínú oṣù Èrèlé ọdún 2020, gẹ́gẹ́ bí WebTech3 ti ṣe fi hàn, ìdajì [2] ibùdó ìtakùn àgbáyé tó wà lórí ayélujára ni a kọ ní èdè Gẹ̀ẹ́sì.

Àmọ́ bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tí ó ń sọ oríṣìíríṣìí èdè àgbáyé ṣe ń bọ́ sórí ayélukára-bí-ajere, ó ṣẹ́ ẹtà ìjà fún èdè ẹni — ìráàyè sí ìṣògbufọ̀ sí onírúurú èdè tí yóò ṣẹ̀ ní mọnawáà.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iléeṣẹ́ onímọ̀ ẹ̀rọ ti ṣe iṣẹ́ ribiribi ní ti ìṣàkọsílẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ tí kì í ṣe èdè Gẹ̀ẹ́sì sórí ayélujára, tí ó ń ṣe olùlànà onírúurú èdè lórí ẹ̀rọ ayárabíàṣá lọ́nà ìgbàlódé. Google [3], Yoruba Names [4], Masakhane MT [5] àti ALC [6] jẹ́ àpẹẹrẹ àwọn iléeṣẹ́ ńlá àti àwọn iléeṣẹ́ kéréje tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ tí ó ti mú ìmọ̀-ẹ̀rọ ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn èdè tí kì í ṣe èdè Gẹ̀ẹ́sì.

Kí oṣù Èrèlé ọdún 2020 ó tó tẹnu bepo, Google filọ̀ [7] wípé òun yóò fi èdè tuntun márùn-ún kún iṣẹ́ Atúmọ̀ Google rẹ̀, àwọn èdè náà ni Kinyarwanda, Uighur, Tatar, Turkmen àti Odia, lẹ́yìn ìsinmi ọdún mẹ́rin tí wọ́n fi èdè tuntun kún un kẹ́yìn.

[8]

Ọkùnrin kan ń wò bí ẹni tí ó nídààmú nígbà tí ó ń ka gbólóhùn ọ̀rọ̀ lórí ayélujára. Àwòránlláti ọwọ́ Ọládiméjì Ajégbilẹ̀, àṣẹ-àtúnlò láti orí Pexels.

Àmọ́ ṣe o ti ṣíra tẹ àṣàyàn ìtumọ̀ rí tí ó ṣàkíyèsí wípé, bákan, ló dára jù lọ? Bákan náà, ló kù díẹ̀ káàtó, kò ṣe déédéé?

Orísìírísìí àríyànjiyàn àti ìṣòro [9] ló máa ń wáyé bí ó bá kan irú ìtumọ̀ èdè báyìí àti rírí i lò.

Twitter máa ń ṣe ìtumọ̀ èdè Yorùbá sí èdè Gẹ̀ẹ́sì nípasẹ̀ lílo Atúmọ̀ Google bí ó ti ṣe fàyè gbà wọ́n, tí àbájáde rẹ̀ sì kù díẹ̀ káàtó nígbàgbogbo — tí àwọn ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan sì ṣe déédéé.

Ohun tí ó fa àwọn ìpeníjà wọ̀nyí ó ju pé orí ayélujára ni àwọn iléeṣẹ́ onímọ̀ ẹ̀rọ ti máa ń ṣe àkójọ èdè wọn [10] for tí wọ́n ń fi ṣe ògbufọ̀ gbólóhùn ọ̀rọ̀. Àwọn àkójọ gbólóhùn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí lè ṣiṣẹ́ fún àwọn èdè kan, àmọ́ èdè bí i Yorùbá àti Ìgbò, jẹ́ èdè méjì ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, tí ìpèníjà yìí bá, látàrí àìpọ̀tó gbólóhùn ọ̀rọ̀ àti gbólóhùn tí a ò yán lórílábẹ́ dáadáa tí yóò tọ́ka sí ìró ohùn.

Láti fèsì sí ohun tí ó fa sábàbí tí ó fi gba Google ní ọdún mẹ́rin kí ó tó ṣe àfikún èdè tuntun márùn-ún kún tilẹ̀, agbẹnusọ iléeṣẹ́ náà ṣe ìṣípayá [7]:

Orí ìtakùn àgbáyé ni Atúmọ̀ Google ti máa ń ṣa gbólóhùn tí a ti túmọ̀ jọ, àmọ́ bí èdè kò bá ní gbólóhùn ọ̀rọ̀ tí ó pọ̀ tó lórí ayélujára, ó nira fún ẹ̀rọ wa láti ṣe àtìlẹ́yìn tí ó lákaakì fún irú àwọn èdè bẹ́ẹ̀… Síbẹ̀, látàrí ìlọsíwájú àbùdá kíkọ́ ẹ̀rọ lẹ́kọ̀ọ́ wa, àti àwọn aṣiṣẹ́ Ìtumọ̀ Google lọ́fẹ̀ẹ́, ecent advances in our machine a ti fi àtìlẹ́yìn fún àwọn èdè wọ̀nyí.

Bákan náà, ọ̀pọ̀ ènìyàn ni kò mọ bí a ṣe ń kọ ọ̀rọ̀ dájúdánu — tàbí pípe ọmọ-ọ̀rọ̀ — inú àwọn èdè wọ̀nyí. Torí náà, ògbufọ̀ tí ó kúnjú òṣùwọ̀n kò jẹ́ àkópọ̀ nítorí kò sí bí a ṣe lè dá àwọn àṣìṣe wọ̀nyí mọ̀.

Púpọ̀ nínú ògbufọ̀ tí ẹ̀rọ ṣe ni kò ní ìtumọ̀, pàápàá jù lọ àwọn gbólóhùn tí ó rọ̀ mọ́ àṣà tí ó ní ju ìtúmọ̀ kan ṣoṣo lọ. Fún àpẹẹrẹ, gbólóhùn Yorùbá bí i ayaba àti ọbabìnrin ní ìtumọ̀ tó yàtọ̀.  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀rọ ní í máa tú ìmọ̀ gbólóhùn méjèèjì sí “queen.” Síbẹ̀, tí a bá ti ọ̀nà ìṣe-àti-àsà wò ó, ó ṣe kókó láti sọ wí pé ìtúmọ̀ ayaba and ọbabìnrin yàtọ̀ síra wọn: Ọbabìnrin túmọ̀ sí “queen” lédè Gẹ̀ẹ́sì nígbà tí ayaba jẹ́ “wife of the king.”

Pẹ̀lú àwọn àìṣedéédéé wọ̀nyí, ìmọ̀-ẹ̀rọ ti ṣe ìrànwọ́ fún ìdàgbàsókè àwọn èdè Ilẹ̀-Adúláwọ̀ lórí àwọn gbàgede orí ayélujára, tí ó ti mú ìṣẹ̀dá ọ̀rọ̀ tuntun wáyé. Èdè Ilẹ̀-Adúláwọ̀ ti gòkè àgbà látàrí àwọn lílo àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé tuntun bí i ẹ̀rọ-ìléwọ́ àti ẹ̀rọ ọpọ́n ayárabíàṣá, tí ó sì ń bí àwọn gbólóhùn tuntun tí a fi ń pe àwọn irinṣẹ́ ìmọ̀-ẹ̀rọ tuntun wọ̀nyí. Èyí sì ti fẹ bí a ti ṣe ń lo àwọn èdè wọ̀nyí lójú.

Látàrí àwọn ẹ̀rọ tuntun wọ̀nyí, ìpèdè ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdè Ilẹ̀-Adúláwọ̀ ti lé kún sí i. Fún àpẹẹrẹ, èdè Yorùbá ní àwọn gbólóhùn tí ó ní ṣe pẹ̀lú ìmọ̀-ẹ̀rọ bí i ẹ̀rọ-amúlétutù (“air conditioner”), erọ-ìbánisọ̀rọ̀ (“phone”) and ẹ̀rọ-ìlọta (“grinder”). Ẹ̀wẹ̀wẹ̀, èdè Igbo náà ní ọ̀rọ̀ bí i ekwè nti (“telephone”) àti ugbọ̀ àlà (“vehicle”). A ṣẹ̀dá àwọn orúkọ yìí ní ìbámu pẹ̀lú iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe.

Nínú ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ àti ètò ìpolówó ọjà lédè Yorùbá, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti kọ́ wí pé ẹ̀rọ-amóhùnmáwòrán ni oọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ń pe TV. Ìṣẹ̀dá ọ̀rọ̀ yìí fa àwọn onírúurú ìbéèrè àti èrò — àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan jiyàn wí pé a lè pe ẹ̀rọ-ayàwòrán náà ní ẹ̀rọ-amóhùnmáwòrán nítorí iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe.

Àwọn ìpèníjà t'ó tara ìmọ̀-ẹ̀rọ wá yìí ni yóò mú ìdàgbàsókè bá èdè — ó máa ń fa àròjìnlẹ̀ fún ìgbéga èdè àti ìmọ̀-ẹ̀rọ.

Lọ́dún 2019, gẹ́gẹ́ bí CNN ti ṣe ròyìn, Google ṣí [11] ibiṣẹ́ ìwádìí AI àkọ́kọ́ irú ẹ̀ sí Accra, Ghana, tí ó ń lépa láti mú kí “Atúmọ̀ Google ó gba àwọn èdè Ilẹ̀-Adúláwọ̀ jọ kí ó lọ geere”. Onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa iṣẹ́ ìwádìí Moustapha Cisse, tó jẹ́ olórí iṣẹ́ Google AI ní Ilẹ̀-Adúláwọ̀, nígbàgbọ́ wí pé ó tọ́ sí “ilẹ̀ tí ó ní ju ẹ̀ka-èdè 2,000 lọ láti jẹ́ àǹfààní iṣẹ́,” — CNN jábọ̀.

Mozilla àti BMZ [12] kéde àjùmọ̀ṣe wọn láti ṣe agbátẹrù iṣẹ́ àkànṣe tí ó dá fìrìgbagbòó lórí ìmọ̀-ẹ̀rọ alohùn fún thei èdè Ilẹ̀-Adúláwọ̀. Pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ àtinudá bí eléyìí, ọjọ́ iwájú ìwádìí èdè Ilẹ̀-Adúláwọ̀ dára.