- Global Voices ní-Yorùbá - https://yo.globalvoices.org -

Ní Kenya àti Ethiopia, àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ríran ‘àwòrán-ìtọ́nà’ àt'ọ̀run wá láti gbẹ́ ihò nísàlẹ̀ ilẹ̀

Sàwáwù : Ìlú Gúúsù Aṣálẹ̀ Sahara, Ethiopia, Kenya, Àṣà àti Iṣẹ́-ọnà, Ẹ̀sìn, Ìròyìn Ọmọ-ìlú, Ìṣẹ̀lẹ̀ àtijọ́, Iyè-inú

Ihò nísàlẹ̀ ilẹ̀ẹ Dunbar ní gúúsù Ethiopia tí Mohammed Yiso Banatah gbẹ́ jáde pẹ̀lú ọwọ́ọ rẹ̀ láì lo ohunkóhun. Allah l'ó pa á láṣẹ láti gbẹ́ ilé Ọlọ́run fún ètò ìgbéyàwó sísàlẹ̀ ilẹ̀. Àwòrán láti ọwọ́ọ Amanda Leigh Lichtenstein, a fi àṣẹ lò ó.

Lọ́jọ́ 26 oṣù Ọ̀pẹ, BBC Swahili gbé àwòrán-àtohùn kan tí ó ṣe àfihàn-an Francisco Ouma, ẹni àgbà kan láti Busia, ìlà-oòrùnun Kenya, ẹni tí ó gbọ́ ohùn Ọlọ́run láti gbẹ́ ihò nísàlẹ̀ ilẹ̀ jáde. Ìran náà wá nípasẹ̀ àwòrán ìtọ́nà tí ó rí lójú àwọn àláa rẹ̀. Láti inú oṣù kejì ọdún-un 1967, ni Ouma ti ń tọ ipasẹ̀ẹ ìtọ́nà látọ̀run wá náà tí ó gbà Iójú àláa rẹ̀. Lónìí, ihò nísàlẹ̀ ilẹ̀ẹ rẹ̀ ti ní yàrá 24 tí ó sì ń lé sí i.

Àgékù àwòrán-an Francis Ouma, tí ó gbọ́ ohùn Ọlọ́run láti gbẹ́ ihò sísàlẹ̀ ilẹ̀ tí ó ní 24 ìyàrá lóríi BBC Swahili / Instagram [1].

Láti ayébáyé, ọ̀pọ̀ ènìyàn ló ti ní kò sí ẹ̀rí tí ó dájú wípé ìran àt'ọ̀run wá ni àwọn irú àlá báwọ̀nyí, tí wọn ń dẹ́jàá ìlera ọpọlọ irú ẹni bẹ́ẹ̀ tí ó pé òún ríran lójú àlá. Àmọ́ àwọn òjíṣẹ́ ẹ̀sìn Ìmàle, Júù àti Onígbàgbọ́ gbogboó ti jẹ́rìí sí ìran láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run [2]ent tí ó wá lójú àlá fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún.

“Ọlọ́run fi nǹkankan bí àwòrán-ìtọ́nà hàn mí,” Ouma sọ fún BBC Swahili. “Nígbà yẹn, nígbà tí mò ń wa ilẹ̀, àwòrán-ìtọ́nà yìí ni mo tẹ̀lé. Kì í ṣe nígbà tí mò ń walẹ̀ nìkan, ó dára jù kí n máa walẹ̀ lọ, rárá.”

Ìtúlẹ̀ àti ọwọ́ọ rẹ̀ méjèèjì ni ó lò, Ouma kan àwọn òkúta abẹ́lẹ̀ tí kò mú ìwalẹ̀ náà rọrùn fún un. Àṣẹ̀yìnwá àṣẹ̀yìnbọ ó rí ibi tí yóò ti mú àwòrán-ìtọ́nà ihò nísàlẹ̀ ilẹ̀ẹ Ọlọ́run tí ó wà ní ọkàn-an rẹ̀ wá sí ìmúṣẹ.

Nínú ìyẹ̀wù kan, ó ní òkúta kan tí a kọ ọ̀rọ̀ọ Jésù sí lára. “Jésù Kristì ni ẹni tí ó mú ìròyìn yìí wá fún mi,” Ouma sọ, “ó sì ṣàlàyée rẹ̀ fún mi gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ṣe fún Mósè.” Ouma gbàgbọ́ wípé òun ń mú májẹ̀mú mìíràn pẹ̀lú Ọlọ́run padà wá sílé ayé.

“Ìpele kejì ń bọ̀ lọ́nà. Èyí ni ìpele àkọ́kọ́ ti májẹ̀mú náà. Ìkejì ń bọ̀ lọ́nà. Mi ò leè sọ ní pàtó ohun tí yóò jẹ́ báyìí nítorí bí mo bá kédee rẹ̀, mo lè máa yan ìṣẹ̀dá ẹ̀dá ọmọ ènìyàn jẹ. Toríi bẹ́ẹ̀, mo máa dúró fún ìjábọ̀ náà bí ó bá tó àsìkò,” Ouma wí fún BBC Swahili.

View this post on Instagram

Ni pango lenye vyumba 24. [3]

A post shared by BBC News Swahili [4] (@bbcswahili) on

Àwòrán-àtohùn-un BBC Swahili ti di wíwò fún ìgbà 50,000 pẹ̀lú èsì tí ó tó 100 tí ó sì ń lé sí í. Níwọ̀n-ọn bí àwọn kan ti sọ nípa àìlera ọpọlọ àwọn t'ó ń sọ pé àwọn gbọ́hùn Ọlọ́run lójú àlá, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èsì àdásí gbè lẹ́yìn àwọn ẹni Ọlọ́run tí ó sọ sí ìran ojú àlá.

Òǹlòo Instagram kan kọ [1]:

Mimi watu kama hawa huwa nawaamini sana kuliko wanaotujaza Kwenye nyumba za Ibaada na Michango isiyoisha kwa Maneno ya Matumaini, Miaka 52 mtu anachimba tu kama angekuwa hana Akili ndugu zake na Serikali hawakumuona? Hajaomba hata msaada wa greda au pesa ya kuweka vibarua hupaswi kuihukukumu Nafsi yake.

Fún èmi, àwọn ènìyàn báyìí, mo máa ń gbà wọ́n gbọ́ gidi gan-an, ju àwọn tí ó máa ń fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run [rọ] wá nílé ìjọsìn, fún ọdún 52 èèyàn-án wa ilẹ̀ — bí kò bá tẹ̀lé ọkàn-an rẹ̀, ṣé kò yẹ kí àdúgbòo rẹ̀ àti ìjọba ó dá a mọ̀?  Kò tilẹ̀ béèrè fún ìrànwọ́ fún katakata tàbí owó fún làálàáa rẹ̀. A kò gbọdọ̀ dájọ́ ẹni yìí.

Mohammed Yiso Banatah lọ́dún-un 2012 ṣàlàyé àlá mẹ́wàá tí Allah yọ sí òun lójú àlá láti gbẹ́ ilé Ọlọ́run fún ìgbéyàwó sábẹ́ ilẹ̀. Àwòrán láti ọwọ́ọ Amanda Leigh Lichtenstein.

Ilé Ọlọ́run fún ètò ìgbéyàwó Ethiopia 

Ní gúúsù Ethiopia, ẹ̀rí tí ó jọra á wá láti àgbàlagbà kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mohammed Yiso Banatah, tí ó ní lọ́dún-un 2012 wípé Allah yọ sí òun ní ọdún 33 sẹ́yìn lójú àlá lẹ́ẹ̀mẹwàá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Lójú àwọn àlá náà, ó gbọ́ ohùn-un Allah láti gbẹ́ ihò ilé Ọlọ́run fún ètò ìgbéyàwó nísàlẹ̀ ilẹ̀.

Ihò nísàlẹ̀ ilẹ̀ẹ Dunbar ni a mọ̀ ọ́ sí, ilé Ọlọ́run fẹ̀nfẹ̀ wọ̀nyí wà ní ẹ̀bá ọ̀nàa Banatah tí í ṣe ìlàjì ọ̀nàa  Hawassa àti Shashamene.

Banatah sọ wípé nínú àláa rẹ̀ kẹ́ta ni ó ti rí àwòṣe [5] fún àwọn ilé Ọlọ́run wọ̀nyí.

O lè ka ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àkọsílẹ̀ àláa Banatah ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé àti ohun tí ó gùn ún kí ó tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwalẹ̀ ayée rẹ̀ níbí: [5]

Lójú àláa àsèkágbáa rẹ̀, èyí tí ó jẹ́ ìkẹwàá nínú àkọsílẹ̀ oníṣísẹ̀ntẹ̀lé ọdún-un 1979, ọkùnrin kan fara hàn tí ó mú Mohammed lọ sí ibi igi kékeré kan nínúu ọgbàa rẹ̀, ó sì tọ́ka sí egbòo rẹ̀. Ọkùnrin náà fi ojú ibi tí yóò ti bẹ̀rẹ̀ ìwalẹ̀, ó sì tún sọ fún un pé lórí iṣẹ́ ìwalẹ̀ náà ni yóò ti là. Ní ọ̀gànjọ́, ó ríran rí wúrà. Agbègbè tí ó sún mọ́ jìnà, àwọn ohun tí ó jìnà di fífà sún mọ́ ọ. A sọ ibi tí yóò ti bẹ̀rẹ̀ ìwalẹ̀, ìgbà tí yó bẹ̀rẹ̀ àti bí yóò ṣe bẹ̀rẹ̀. Lọ́jọ́ kejì, nígbà tí ó lajú sáyé, ó bẹ̀rẹ̀ síí gbẹ́lẹ̀ pẹ̀lú ọwọ́ọ rẹ̀ nìkan láì lo ìtúlẹ̀.

Ihò nísàlẹ̀ ilẹ̀ tí ìmọ́lẹ̀ oòrùn tán sínúu rẹ̀ wọ̀nyí ti di ibi ìgbafẹ́ olówó kékeré fún àwọn èèyàn láti ṣe ìrinsẹ̀ máìlì mẹ́rin lábẹ́ ilẹ̀ tí ó pa lọ́lọ́. Àwọn àfẹ́sọ́nà kan ti ṣe ètò ìgbéyàwó níbé.

Bí a ṣe kọ́ àwọn ìyẹ̀wù wọ̀nyí fi iṣẹ́ ọpọlọ àti itú ọwọ́ọ Mohammed hàn – ó ti fi ìfarabalẹ̀ lọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí fún gbígbẹ́, dídán, àti ṣíṣe iṣẹ́ ọnà sí gbogbo kọ́lọ́fín inú iyàrá àti ògiri, pẹ̀lú àwọn tìmùtìmù, àti pẹpẹ tí a fi iyẹ̀pẹ̀ mọ nínúu rẹ̀, tí àwọn yàrá mìíràn ní fèrèsé tí ìmọ́lẹ̀ oòrùn ń tàn gbà láti ibi tí ẹnìkan kò mọ̀.

Láti ayébáyé ni ihò nísàlẹ̀ ilẹ̀ ti jẹ́ ibi àpẹẹrẹ tí a kà sí gẹ́gẹ́ bí ibi ti ẹ̀mí.

Odindin ìwé kan gbáko tí a pè ní “Al Kahf” [6] tàbí “Ihò nísàlẹ̀ ilẹ̀” jẹyọ nínúu ìwé mímọ́ọ Kuran. Nínúu rẹ̀ ni a ti bá ìtàn Ẹ̀sìn ìgbàgbọ́ kan tí a mọ̀ sí “Àwọn ẹni Ihò-òkúta,”  [7] which nínú èyí tí àwọn ọ̀dọ́, jìyà àìṣẹ̀ nítorí ìgbàgbọ́ọ wọ́n sá kúrò nílùú, wọ́n sì wá ibi ihò-òkúta kan sùn sí.

Nígbà tí wọ́n jí, wọ́n padà sílé, wọ́n sì ṣàkíyèsí wípé gbogbo ọmọ ìlú ti di ònígbàgbọ́.