- Global Voices ní-Yorùbá - https://yo.globalvoices.org -

Ìwé àbádòfin ìlò ẹ̀rọ alátagbà yóò pa òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ lórí ayélujára ní Nàìjíríà

Sàwáwù : Ìlú Gúúsù Aṣálẹ̀ Sahara, Nàìjíríà, Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn, Ìjàfúnẹ̀tọ́ Ẹ̀rọ-ìgbàlódé, Ìròyìn Ọmọ-ìlú, Ìtẹríbọlẹ̀, Òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ, Ìgbàwí GV

Aṣojú Mohammed Sani Musa ni agbátẹrùu ìwé àbádòfin ìlò ẹ̀rọ alátagbà. Àwòrán àgékù láti ibùdó Channel Television You Tube . [1]

Lọ́jọ́ 20 oṣù Belu, Ìwé Àbádòfin tí ó fi Ààbò fún Irọ́ àti Màkàrúrù tí ó rọ̀ mọ́ ọn ti ọdún-un 2019, [2] tí a mọ̀ sí “ìwé àbádòfin ìlò ẹ̀rọ alátagbà,” tí Aṣojú kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mohammed Sani Musa ṣe agbátẹrùu rẹ̀, ti di kíkà nínú ìgbìmọ̀ fún ìgbà kejì. [3]

Èròńgbà ìwé àbádòfin ìlò ẹ̀rọ alátagbà náà ni láti dẹ́kun àwọn àhesọ àti gbólóhùn tí kì í ṣe òtítọ́ lórí ẹ̀rọ ayélukára bí ajere. Bí-ó-ti-lẹ̀-jẹ́-wípé, kì í ṣe láti fi òfin de ìlò ẹ̀rọ alátagbà ni ìwé àbádòfin náà dá lé lórí, àmọ́ ṣá, ó máa pa òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ lórí ayélujára, ìsọ alátakò ìjọba di ọ̀daràn àti fífi àtìpà ẹ̀rọ ayélujára fúngbà díẹ̀ sínú ìwé òfin.

Àtẹ̀pa bí erín bá tẹ koríko ni àwọn ọmọ Nàìjíríà tẹ irú ìwé àbádòfin báyìí [4] pa ní ọdún-un 2016.

Ẹ̀ṣẹ̀ ni bí o bá gbó ìjọba lẹ́nu (tako ìjọba)

Gẹ́gẹ́ bí Abala 1A ti ṣe ṣàlàyé, èròńgbà ìwé àbádòfin yìí ni láti “[máà jẹ́] kí ìgbéjáde ọ̀rọ̀ tí kò ní òtítọ́ kan nínú tàbí èyí tí ẹ̀ríi rẹ̀ kò f'ẹsẹ̀ rinlẹ̀ tó ó jáde ní Nàìjíríà.” Yóò yọ ọwọ́ kílàńkó àwọn àtẹ̀jáde irọ́ tí ó lè kó orílẹ̀ èdèe Nàìjíríà sí” ìyọnu,” láwo láì gbàgbée àwọn ọ̀ràn bíi ètò ìlera gbogboògbò, ààbòo gbogboògbò,”ìbalẹ̀-ọkàn-an gbogboògbò tàbí ìṣúná owóo gbogboògbò” àti” àwọn ìbáṣepọ̀ orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà pẹ̀lú àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn.”

Abala 1c sọ bí ìwé àbádòfin náà yóò ṣe “mú, ṣàkóso àti fi ààbò bo ìlònílòkulò àwọn ìṣàmúlò àti ẹ̀rọ adánìkanṣiṣẹ́ orí ẹ̀rọ ayélujára.” Ní àlàyé síwájú sí i, kò sí ohun tí ojú òfin tuntun náà kò leè tó bí ó bá ti jẹ́ lórí ayélujára — lábẹ́ àbùradà à ń gbógun ti àhesọ àti irọ́ pọ́nbẹ́lẹ́.

Ọ̀run ń ya bọ̀ ni ìwé àbádòfin ìlò ẹ̀rọ alátagbà náà, kò yọ ẹnìkan sílẹ̀, gbogbo ọmọ orílẹ̀ èdèe Nàìjíríà ni yóò bá, kò kan agbègbè tàbí ibi tí ènìyàn fi ṣe ibùgbé, máà ṣe é l'oògùn máà mọ́, ọwọ́ àwọn ológìnní ojú tólé ojú tóko ni “gbólóhùn irọ́ tí kò ní ẹ̀rí” tí ó bá gba òpópónà ẹ̀rọ ayélukára bí ajere Nàìjíríà yóò bọ́ sí. Abala 3a sí b(i) ti ìwé àbádòfin ìlò ẹ̀rọ alátagbà sọ wípé:

Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ wu ìwà kíwà kan nínú tàbí lẹ́yìn odi Nàìjíríà láti tari gbólóhùn tí kò ní òtítọ́ kan tí a kò leè fi ẹ̀ríi rẹ̀ múlẹ̀ síta; àti àgbésórí afẹ́fẹ́ ayélujára gbólóhùn t'ó lè kó orílẹ̀ èdèe Nàìjíríà síta bí ọmọ ọjọ́ mẹ́jọ nípa ti ààbò ìlú.

Ọ̀ràn-an ti “ààbò orílẹ̀-èdè” ni orí Èṣù tí òfin náà dúró lé láti pa ẹ̀tọ́ sí òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ mọ́. Àmọ́ kò tán síbẹ̀, kò sí ẹní tó lè tako ìjọba Nàìjíríà tàbí gbó o lẹ́nu nítorí kì í ṣ'àṣìṣe. Ní Abala 3b(vi), gbólóhùn tí ó bá yẹpẹrẹ “ojúṣe tàbí ìṣe, tí ó jẹ́ ti ìjọba lójú ará ìlú” kò leè la orí ayélujára kọjá.

Gẹ́gẹ́ bí Abala 3b(v) ti ṣe fi hàn, èyí ní í ṣe pẹ̀lú gbólóhùn tí ó: “fa ìmúnilọ́tàá, tí a sọ sí ẹnìkan tàbí ìtara láàárín àwọn ènìyàn.” Èyí léwu nítorí ó fi àyè gba àwọn onípò àṣẹ láti lo agbára nílòkulò.

Ta ní í sọ bóyá gbólóhùn kan lè fa rògbòdìyàn? Ìyẹn túmọ̀ sí wípé lílo inú kan tàbí mímú àwọn olóṣèlúu mú ìléríi wọn ṣe lè já sí ìkórìíra lójúu wọn.

Owó ìtanràn fún ẹni tí ilé ẹjọ́ bá dá lẹ́bi tó láàárín ẹgbẹ̀rún 200 àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún 10 owó naira [tí ó tó $556 sí $28,000 owó orílẹ̀ èdèe United States], ìtìmọ́lé fún ọdún mẹ́ta tàbí méjèèjì.

Àṣẹ fún Àjọ Agbófinró láti ṣán ẹ̀rọ ayélujára pa fúngbà díẹ̀

Ìwé àbádòfin ìlò ẹ̀rọ alátagbà náà fún ìjọba lágbára bí ó ṣe hù wọ́n láti ṣán ẹ̀rọ ayélukára bí ajere pa nígbàkúùgbà tí ó bá lérò wípé ó tọ́, nípasẹ̀ “Àṣẹ Ìdígàgá Ìráyè” láti lo ayélujára bí ó ti ṣe wà ní Abala 12, òǹkaye 3:

Ẹ̀ka Agbófinró leè fi àṣẹ fún Àjọ Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ Nàìjíríà NCC [Nigerian Communications Commission – tí ó ń ṣe bòńkárí ìtàkùrọ̀sọ orí ẹ̀rọ ayárabíàṣá] láti pa á láṣẹ fún apèsè àyè sí ìlò ẹ̀rọ ayélujára kí ó gbé ìgbésẹ̀ lójú ẹsẹ̀ tí ò ní mú àwọn òǹlò rí àyè lo ayélujára ní Nàìjíríà.

Àwọn apèsè ayélujára gbọdọ̀ tẹ̀lé òfin ìdígàgá yìí tàbí kí wọ́n ó sanwó ìtanràn tí ó tó ẹgbẹẹgbẹ̀rún 5 sí 10 owó naira [$14,000-28,000 USD].

Ní àfikún, ìwé àbádòfin náà fi àrídájú ààbò bo àwọn apèsè iṣẹ́ ẹ̀rọ ayélujára tí kò ní mú wàhálà “ará ìlú tàbí bẹ́ẹ̀” tí kò bá à lè jáde láti ìdájọ́ kan tí ẹnikẹ́ni kò bá pè wọ́n fúnopé “wọ́n tẹ̀lé òfin ìdígàgá ìráyé” sí ayélujára, ìyẹn bí abala 12, òǹkaye 5 ṣe fi lélẹ̀.

Ìtẹ́rí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn náà ṣ'ókùnkùn sí i nítorí wípé òfin náà gba àwọn ọlọ́pàá láyè lábẹ́ òfin láti pa àṣẹ ìdígàgá-àyè bí ó ti ṣe hù wọ́n. Abala 15a sọ wípé “iṣẹ́ ọpọlọ” ọlọ́pàá ní àsìkò “ìṣèwádìí ẹ̀rí tó dájú” jẹ́ kókó láti fagilé ìṣánpá ẹ̀rọ ayélujára ní orílẹ̀ èdè náà.

Ní ìparí, “kò sí àyè fún ẹjọ́ọ kò tèmi lọ́rùn ní Ilé-ẹjọ́ Gíga” [Abala 13(2)] tí eẹnikẹ́ni lè fi yẹ ìdígàgá sílẹ̀ láì máà kọ́kọ́ tọ ọlọ́pàá lọ láti fagilé òfin ìdígàgá náà. Ipa èyí hàn gbàgàdà — ẹnikẹ́ni kò ní leè gba ilé ẹjọ́ lọ fún ìgbèjà ìfẹ̀tọ́ ẹni dunni yìí tí ìdígàgá náà ṣì wà.

Àwọn aṣojú-ṣòfin tí ó wà lẹ́yìn ìwé àbádòfin ẹ̀rọ alátagbà náà

Àwọn aṣojú-ṣòfin mẹ́ta kan ni ó gbé ìwé àbádòfin náà sórí nínú ìgbìmọ̀, ilé ìgbìmọ̀ àgbà: Mohammed Sani Musa (agbátẹrùu ìwé àbádòfin), Abba Moro àti Elisha Abbo.

Ilé-iṣẹ́ẹ Mohammed Sani Musa [8], Activate Technologies Limited, ni ó kó [9] ẹ̀rọ Ìwé-pélébé Ìdìbò Alálòpẹ́ (PVCs) tí a lò fún ìbò ọdún-un 2019, nígbà tí ó jẹ́ òǹdíjedupò lábẹ́ ẹgbẹ́ olóṣèlúu tí ó ń tukọ̀ ètò ìṣèlú lọ́wọ́ All Progressives Congress (APC) fún Aṣojú Ìlà-Oòrùn Niger, ìyẹn gẹ́gẹ́ bí ilé iṣẹ́ aṣèwádìí, Premium Times ṣe tẹ̀ ẹ́ jáde. Àjọ Elétò (INEC) gba ẹ̀sùn náà mọ́ra [10]. Ọ̀ràn yìí fi hàn pé àwọn alákòóso ìbò tí ó kọjá kò ṣiṣẹ́ láì lọ́wọ́ àwọn alágbára ń'nú.

Screenshot of Nigerian member of parliament, Senator Elisha Abbo.

Ishaku Elisha Abbo [11] ti ẹgbẹ́ alátakò People’s Democratic Party (PDP) jẹ́ aṣojú tí ó ń ṣojú Ẹkùn-un Àríwá Adamawa ní Ìpínlẹ̀ Adamawa, ní ìlà-oòrùn àríwá orílẹ̀ èdèe Nàìjíríà. Nínú oṣù Agẹmọ 2019, ní ìṣojú ọlọ́pàá, Abbo ṣe àṣemáṣe pẹ̀lú òṣìṣẹ́bìnrin kan nínú ìsọ̀ ohun ìbálòpọ̀ [12] ní olú-ìlú Nàìjíríà ní Abuja. Lẹ́yìn tí àwòrán càṣemáṣe náà fọ́n ká sórí ẹ̀rọ alátagbà, Abbo offered mọ ìwàa rẹ̀ lẹ́bí, ó sì bẹ̀bẹ̀. [13]

Abba Moro, [14] tí í ṣe ọmọ ẹgbẹ́ẹ PDP, ni aṣojú fún ẹ̀ka Gúúsù Benue, àárín gbùngbùn àríwá Nàìjíríà. Ní ọjọ́ 15, oṣù Ẹrẹ́nà, ọdún-un 2014, Moro, tí í ṣe ọ̀gá pátápátá ètò abélé, ló wà nídìí ìṣẹ̀lẹ̀ abanilọ́kànjẹ́ Ìgbanisíṣẹ́ Ẹ̀ṣọ̀ aṣọ́bodè Nàìjíríà [15] tí àwọn ọ̀dọ́langba tí ó tó bíi ẹgbẹẹgbẹ̀rún 6 tó fẹ́ àyè iṣẹ́ ẹgbẹ̀rún 4 tí ó ṣí sílẹ̀ nínú iléeṣẹ́ Ẹ̀ṣọ̀ Aṣọ́bodè Nàìjíríà tí wọ́n kóra jọ níbi orísìírísìí jákèjádò orílẹ̀ èdè náà.

Ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó burúkú jáì náà tí ó ṣekú pa ogún ènìyàn àti ìpalára fún ọ̀pọ̀ èèyàn. Moro gbà nínú [16]of owó ìwáṣẹ̀ tí àwọn awáṣẹ́ san tí ó ń lọ bíi ẹgbẹẹgbẹ̀rún 675 owóo naira [ $1.8 USD]. Moro kó owó sápòo rẹ̀ bẹ́ẹ̀ náà ó fo òfin ìgbanǹkan [17] Aṣọ́bodè dá.

‘Kò nílò ìdákẹ́ jẹ́jẹ́, ìbẹ̀rù bojo tàbí ìkáàánú-araẹni’ – #SayNoToSocialMediaBill!

Nípa lílo àmì #SayNoToSocialMediaBill [18], àwọn ọmọ orí ayélujára orílẹ̀ èdèe Nàìjíríà bọ́ sóríi Twitter láti sọ èrò ọkàn-an wọn:

Èmi, Bukky Shonibare, #SayNoToSocialMediaBill [19].

Ìgbẹ́sẹ̀ lé ẹ̀tọ́ sí òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ lábẹ́ òfin ni èyí. Ó yẹ kí a lè sọ èrò ọkàn-an wa, kódà bí a bá ṣàṣìṣe tàbí bí wọ́n kò bá gbọ́ wa yé, láì fòyà ìfìyàjẹni, tàbí ìtímọ́lé.

Kí lo sọ? https://t.co/PRmif19Hk2 [20]

— HERmbassador (@BukkyShonibare) November ọjọ́ 22, Oṣù Belu ọdún-un 2019 [21]

Sikemi Okunrinboye kọ ìwé ìfisùn [22] tí ó takò Ìgbìmọ̀ Ìjọba àpapọ̀, ààrẹ Ìgbìmọ̀ Aṣojú-ṣòfin àti the  orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà.m. Ìwé ìfisùn ti ní ìfọwọ́sí ènìyàn tí ó tó 32,000.

Àwọn ọmọ Nàìjíríà mìíràn ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí àwọn aṣojú-ṣòfin láti dìbo tako ìwé àbádòfin náà.

mo kọ ìwé-orí ẹ̀rọ ayélujára ránṣẹ́ sí aṣojú ìpínlẹ̀ mi láti dìbò tako ìwé àbádòfin ìlò ẹ̀rọ alátagbà náà. Ìwọ náà ṣe bẹ́ẹ̀.

— tòlú daniel (@iamToluDaniel)  ọjọ́ oṣù Belu 23, ọdún-un 2019 [25]

Síbẹ̀, díẹ̀ nínú àwọn aṣojú-ṣòfin, bíi Chimaroke Nnamani, ni kò lọ́wọ́ sí ìwé àbádòfin náà nígbà tí a gbé e sílẹ̀ fún kíkà lẹ́lẹ́ẹ̀kejì.

Mò ń tako ìwé àbádòfin ìlò ẹ̀rọ alátagbà ní àsìkòo kíkà fún ìgbà kejì lónìí -apá 1 pic.twitter.com/Xn6oh6vNeD [26]

— HE Chimaroke Nnamani MD. FACOG. D.Sc (@ChimarokeNamani) Ọjọ́ 20, oṣù Belu ọdún-un 2019 [27]

Nínú gbólóhùn [28]kan, Amnesty International fajúro sí lílo “àwọn òfin tí ó ń fìdìí ìfojú ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn gbolẹ̀ múlẹ̀” nítorí pé kò ní pa àwọn ọmọ Nàìjíríà lẹ́nu mọ́ “láti máà sọ èrò ọkàn-an wọn” tí yóò sì tún “rán wọn lọ s'ẹ́wọ̀n fún wípé wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀.”

Lábẹ́ àbùradà à ń dẹ́kun gbólóhùn irọ́ àti ọ̀rọ̀ àhesọ, ń gbèrò ìṣòfin tí kò ní ìfẹ́ ará ìlú lọ́kàn. Ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu, àwọn olóṣèlúu ló léwájú níbi ká gbé gbólóhùn irọ́ sórí ayélujára. [29]

Ẹgbẹ́ olóṣèlúu tí ó ń jẹ lọ́wọ́ àti ẹgbẹ́ alátakò gbòógì sọ Twitter di pápá ogun  [30]fa ọ̀rọ̀ ìkórìíra ẹlẹ́yàmẹ́lẹ́yá, ìròyìn tí kò pójú òṣùwọ̀n àti ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn lásìkò ìdìbò ààrẹ ọdún-un 2019.

Ní àkókò bíi ti òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ ní Nàìjíríà tí a wà yìí, ọ̀rọ̀ ọlọ́pọlọ láti ẹnu òǹkọ̀wé orílẹ̀-èdèe Amẹ́ríkà Toni Morrison tí ó mú ìrétí dání [31]:

This is precisely the time when artists go to work. There is no time for despair, no place for self-pity, no need for silence, no room for fear. We speak, we write, we do language.

‎Èyí ni ìgbà tí àwọn ayàwòrán ń ṣiṣẹ́. Kò sáyé fún ìsọ̀rètínù, kò sáyé fún ìkáàánú-ara, kò nílò ìdákẹ́ jẹ́jẹ́, kò sí àyè fún ìbẹ̀rù bojo.                  A sọ, a kọ, a p'èdè.

Ìwé àbádòfin ìlò ẹ̀rọ alátagbà náà ti jẹ́ kíkà ní ìgbà kejì nínú ìgbìmọ̀ Aṣojú-ṣòfin. Kí ó tó di òfin, ó gbọdọ̀ gba ìgbìmọ̀ kan tí àwọn aṣojú-ṣòfin yóò yẹ̀ ẹ́ wò. Ìgbìmọ̀ọtẹ̀ẹ́kótó náà yóò sì jábọ̀ àbájáde àyẹ̀wòo rẹ̀ fún Ìgbìmọ̀ àgbà, láti gbé e yẹ̀ wò, tí wọn yóò tẹ òmíràn jáde fún àyẹ̀wò tí ó kẹ́yìn, kí ààrẹ ó tó bu ọwọ́ lù ú.

A gbọdọ̀ fajú ro sí ìgbésẹ̀ Ìgbìmọ̀ kí wọ́n ba ju ìwé àbádòfin ìlò ẹ̀rọ alátagbà náà dànù sígbó. Nítorí orílẹ̀ èdèe tí ó gbajúmọ̀ jù lọ nílẹ̀ Adúláwọ̀ yóò yẹ̀ gẹ̀rẹ̀ sí ìjọba ìfipámúnisìn ní kété tí òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ bá di títẹ̀ bọlẹ̀.