- Global Voices ní-Yorùbá - https://yo.globalvoices.org -

Ààmì ìdánimọ̀ orílẹ̀ èdèe Jamaica tí Kanye West lò di awuyewuye tí ó dá fìrìgbagbòó lórí ‘ìsààmì’

Sàwáwù : Caribbean, Jamaica, Àṣà àti Iṣẹ́-ọnà, Ìròyìn Ọmọ-ìlú, Ìṣèlú, Orin
[1]

Kanye West ń kọrin níbi ayẹyẹ ọlọ́dọọdún Ilé-ọnà ti Ọnà Ìgbàlódé ní Garden benefit, New York City, ọjọ́ 10, oṣù karùn-ún, 2011. Àwòrán láti ọwọ́ọ Jason Persse, CC BY-SA 2.0.

Ọ̀kọrin tàkasúfèé tí ó jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdèe Amẹ́ríkà Kanye West gbé àríyá “Ìsìn Ọjọ́ Ọ̀sẹ̀” pop-up concert [2] wá sí Kingston,  Jamaica, ní kété tí ìsinmi ọjọ́ ọ̀sẹ̀ fún Àyájọ́ Ọjọ́ Àwọn Málegbàgbé Ọmọ Orílẹ̀-èdè [3] náà (19-21, oṣù Ọ̀wàrà ọdún-un 2019) yóò bẹ̀rẹ̀. Èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ tí ọ̀kọrin náà yóò kó ẹgbẹ́ akọrin ìyìnrere rẹ̀ kúrò ní Amẹ́ríkà, ní ìjẹ́pèe ti agbè fún ìjọba orílẹ̀ èdèe kan tí ó Ja kí ó gbé ètò náà wá sílùú òun. Síbẹ̀, àríyá náà tí rí ìtakò láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, tí ó Ho forí sọlẹ̀ pẹ̀lú àmì ìdánimọ̀ọ orílè-èdèe Jamaica tí West we lórí ọjà tí ó ń tà lóríi ibùdó ìtakùn àgbáyée rẹ̀ láì gba àṣẹ láti lò ó.

Láàárín ọjọ́ méjì ni ìkéde fi lọ síta, inúu gbàgede Emancipation Park [4] tó wà ní Kingston, olú ìlú orílẹ̀ èdè náà ni bẹbẹ́ ti wáyé — ojú ibi tí ó mú àwọn sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ kan wí tẹnu wọn látàrí àwọn ọ̀rọ̀ tó mú àríyànjiyàn dání [5] tí West sọ nípa òwò ẹrú nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan báyìí lóṣù karùn-ún ọdún-un 2018. Ọdún-un 2002 ni gbàgede náà di lílò [6] ní ìbọ̀wọ̀ fún “òmìnira dójú àmì” fún àwọn ẹrú 300,000 ní Jamaica lọ́jọ́ 1, oṣù kẹjọ ọdún-un 1838.

Ó lè jẹ́ èyí gan-an ni oun àkọ́kọ́ nípa àríyá orin náà, ṣùgbọ́n òun kọ́ ni ó gbẹ̀yìn. Pàápàá jù lọ bí Olóòtú Ètò Àṣà Olivia “Babsy” Grange ṣe bẹnu-àtẹ́ lu àwọn alátakò nígbà tí ó sọ wípé [7] orílẹ̀ èdè náà ṣe àbápín nínú èrè àríyá náà, ní èyí tí aṣagbátẹrù orin kan lérò wípé àríyá náà tí ó ṣe é wò lójú ẹsẹ̀ bí ó ṣe ń lọ lóríi ìtakùn àgbáyée Ìsìn Ọjọ́ Ọ̀sẹ̀ [8], “gba” [9] àwọn ètò tí ó rọ̀ mọ́ àṣà ìbílẹ̀ tí ó jẹ́ ti Ìsinmi àwọn Málegbàgbé Ọmọ orílẹ̀ èdè sẹ́gbẹ̀ẹ́.

Láfikún, àwọn olùgbée Kingston, tí ó bá súnkẹrẹ fàkẹrẹ kòdìmú lọ́sẹ̀ yẹn, fọ àfọ̀tẹ́lẹ̀ [10] làásìgbò àti rọ̀tìrọti bí àwọn tó ṣíwọ́ iṣẹ́ bá ń darí lọ sílé nírọ̀lẹ́.  Láì sí àní-àní, àríyá náà lọ ní ìrọwọ́-ìrọsẹ̀, ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún àwọn Nev orílẹ̀-èdèe Jamaica gbádùn-un àríyá náà  [11] tí àwọn iléeṣẹ́ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ orílẹ̀ èdèe Jamaica náà gba ìgbóríyìn fún iṣẹ́ takuntakun tí wọ́n ṣe:

Mo jẹ́ ẹnìkan tí kò gba ti arákùnrin West àmọ́ mo máa ń ṣe ti ohunkóhun tó bá ní í ṣe pẹ̀lú ìtẹ̀síwájú orílẹ̀ èdè mi. Mo tẹ̀lé ètò náà bí ó ṣe ń lọ lórí ayélujára láì kúrò níbẹ̀… nítorí iṣẹ́ takuntakun #sundayserviceja…. Nítorí náà ó yẹ kí ènìyán ní ìwúrí dáadáa l'órí iṣẹ́ àgbékalẹ̀ ètò kan tí ta ẹlẹgbẹ́ẹ rẹ̀ yọ.

Denise Miller (@IrieDame) ọjọ́ 19, oṣù kẹwàá ọdún-un 2019 [13]

Àmọ́ ọ̀rọ́ tán lẹ́nu ó kù síkùn. Ẹgbẹ́ Ìsìn Ọjọ́ Ọ̀sẹ̀ gbogbo ló wọ aṣọ àti fìlàa bẹntigọ́ọ̀ tí a ya àwòrán àmì ìdánimọ̀ọ orílẹ̀ èdèe Jamaica sí. Ní kété tí àríyá náà kásẹ̀ ńlẹ̀, ọ̀kan-ò-jọ̀kan ọjàa tí àkórí rẹ̀ dá lóríi orílẹ̀ èdèe Jamaica ti wà fún títà lórí ibùdó ìtakùn Ìsìn Ọjọ́ Ọ̀sẹ̀ n — tí ó sì fa awuyewuye.

Àwọn ọmọ Jamaica b'ara jẹ́ gidi gan-an ni:

# [12]SundayServiceJa N kò lè dẹ́kun ẹ̀rín rínrín, bẹ́ẹ̀ni n ò le se láì má gbé túwíìtì àríyá Ọ̀fẹ́? Mélòó nínú ẹ̀yin òmùgọ̀ ni yóò ra aṣọ tó wọ́n tí kò dùn-ún rí pẹ̀lú ààmìi orílè èdèe yín lára rẹ̀ láì gba àṣẹ bí ẹni wípé kò jámọ́ nǹkankan? Ọlọ́run ṣeun tí kò yí olúkúlùkù padà nítorí pé àwọn ènìyàn ń ta ara wọn láì sí tàbí ṣùgbọ́n.

-Stalker Walkers (@stalker_walkers) ọjọ́ 20, oṣù kẹwàá ọdún-un 2019 [14]

Òmíràn túwíìtì àìṣedédé kan tí ó wọ́pọ̀ — wípé ó mọ́ Jamaica lára láti máa “tá ara rẹ̀ lọ́pọ̀” fún ara ìta:

Ṣé pé wọ́n ta àjogúnbá orílẹ̀ èdèe Jamaica fún àríyá orin ọ̀fẹ́. Àwọn aláṣẹ Jamaica ń fún àwọn ará ìta láǹfààní tí kò yẹ  #SundayServiceJa [12] #KanyeWestSundayService [15] #kanye [16] pic.twitter.com/QbA0ZygTmO [17]Detective Sasha ?? (@OneDonSasha1) ọjọ́ 19, oṣù kẹwàá ọdún-un 2019 [18]

Olóòtú Grange yára fèsì, ó pàṣẹ pé kí wọn ó mú àwọn ọjà náà wálẹ̀. Ó ṣàlàyé [19]:

We neither received a request for nor did we give permission for our national symbols and emblems to be used for a commercial manner or otherwise.

I have since requested that the items be withdrawn and the vendor has agreed to do so.

A kò béèrè fún un tàbí fún ẹnikẹ́ni láṣẹ láti lo àwọn ààmì ìdánimọ̀ àti àsíá orílẹ̀ èdèe wa fún ọjà títà tàbí ohun tí ó f'ara pẹ́ ẹ.

Mo ti pa á láṣẹ fún onísọ̀ náà láti kógbá wọlé, ó sì ti pinnu láti ṣe bẹ́ẹ̀.

Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn àlàfo kan ṣì wà. Gẹ́gẹ́ bí olóòtú náà ti ṣe sọ nínúu apá kejì ọ̀rọ̀ọ rẹ̀, ìjọba gbé àgbéyẹ̀wò sí ìlòo àsíá orílẹ̀ èdè tì ní ọdún-un 2011 nígbà tí ìjọba ṣíwọ́ padà  — àmọ́ ní báyìí, ó sọ wípé, òún ti “gbàṣẹ láti tún ìgbìmọ̀ gbé kalẹ̀ kí iṣẹ́ ó bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹwu”.

Iléeṣẹ́ Olóòtú Ìjọba Orílẹ̀ èdè tọ́ka [20] sí àsíá orílẹ̀ èdè mẹ́fà tí ẹnikẹ́ni kò leè lò láì jẹ́ wípé ó gba àṣẹ tí onítọ̀hún yóò sì sanwó.

Wàyí, olùdarí Kingston ní kò sí ohun tí ó jọ ọ́, gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ alátakò People's National Party tí ṣe polongo [21] a lo àsíá orílẹ̀ èdè náà lọ́nà tí kò tọ́:

Bí ibùdó ìtakùn @JISNews [22] ṣe ròyìn … Àwòrán àkọ́kọ́ ìsàlẹ̀ ni àsíá apata Jamaica… Èyí tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ẹ rẹ̀ (àṣẹ ìlò: @cevancoore [23]) wá láti Ìsìn Ọjọ́ Ọ̀sẹ̀ tí ó ń fi aṣọ náà tí Kanye West àti ẹgbẹ́ akọrin rẹ̀ wọ̀ hàn. Wọ́n yàtọ̀ọ̀tọ̀ síra. pic.twitter.com/tQrUdBqVcl [24]

— Delroy Williams (@MayorWilliamsJA) ọjọ́ 21, oṣù kẹwàá ọdún-un 2019 [25]

Ìtàkùrọ̀sọ orí ayélujára nípa agbára ààmì orílẹ̀ èdè ti gba ìlú kan:

Ǹjẹ́ o kò ní sọ wípé wọn kì í ṣe “ààmì-ìṣòwò” ní ti òfin àmọ́ pé ìgbésẹ̀ láti gbé ìdánimọ̀ọ wa lárugẹ? Ọ̀kan lára ìdí tí a fi ní wípé ó yẹ kí ààmìi Taíno ó wà lára Àsíá Apata náà. Mo lérò wípé yóò fún wa ní àlékún ìmọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ àtẹ̀yìnwá orílẹ̀ èdèe wa

— Peta-Anne Baker (@PA13Baker) ọjọ́ 21, oṣù kẹwàá ọdún-un 2019 [26]

Agbẹjọ́rò kan sọ wípé àwọn ààmì wọ̀nyí kì í ṣe “ààmì-ìṣòwò”:

Mo gbárùkù ti GOJ (fún iṣẹ́ tí wọ́n ṣe). A kò fi àyè gba wa láti lo ààmì orílẹ̀ èdèe wa fún ìṣòwò torí náà àwọn ènìyàn ní láti gba ìwé àṣẹ lọ́wọ́ọ OPM kí wọn ó tó ṣe bẹ́ẹ̀.

— Grace Lindo (@gracelindo_) ọjọ́ 20, oṣù kẹwàá ọdún-un 2019 [27]

Ó sọ síwájú sí i wípé àwọn ọjà kan tí ó ní ààmì wọ̀nyí lára kò tasẹ̀ àgẹ̀rẹ̀ sófin, nítorí kò sí àṣẹ kan tí ó fi ààbò fún wọn:

Ààbò bo àsíá apata àti ẹyẹ náà. Ẹyẹ tí ó wọ́n yà sóríi aṣọ ìlékè ara tí ó wà lóríi ibùdó ìtakùn KW kì í ṣe ti wa, torí náà wọ́n leè lò ó.

— Grace Lindo (@gracelindo_) Ọjọ́ 21, oṣù kẹwàá ọdún-un 2019 [28]

Ní ìparí àríyá náà, a pín àwọn aṣọ ìlékè ara fún àwọn èrò; alárìíyá kan rí aṣọ náà bí ohun tí ó jọjúńgbèsè:

Mo fẹ́ràn aṣọ òtútù mi, ó kàn jẹ́ wípé inú ṣì ń bí àwọn ènìyàn mi ẹ̀rín-kkkk #SundayServiceJa [12] pic.twitter.com/gUL3dxpBcx [29]

— Andrew Brown (@drewpuddy)  Ọjọ́ 19, oṣù kẹwàá ọdún-un 2019 [30]

Lóríi Facebook, “The Artful Blogger” ṣàkíyèsí [31]:

Word on the street is that there may be a move by [Sunday Service] to seek patent/ownership rights on the Kingston, Jamaica logos as well as […] the fabled streamer-tailed humming bird. I have done a fair amount of online searches for information to corroborate the claim without luck but have come across their online release of merchandise bearing these landmark symbols, which coincided with the concert…

Jamaica’s reality is that successive political administrations have never fully appreciated the economic value of the brand ‘Jamaica’ nor the symbols that [represent] that brand including its flag and its coat of arms […] The same is true for our music and its associated brand marks, Ska, Mento, Rock Steady, Reggae among others.

That Jamaica was blindsided by the release of clothing bearing the island’s important symbols is a classic case of guerilla marketing. Having a concert to promote the line at the historic Emancipation Park provides tacit assent of not only the line of garments by the government and people of Jamaica, but also of the use of the country’s national symbols in their creation.

I have noticed that there is now hurried pushback by the Ministry of Culture as well as from the Mayor of Kingston. Both should realize that this isn’t a bottle that will be easy to re-cork.

I hope that the government has good lawyers.

Ìròyìn etíìgbọ́ ìgboro ni wípé ó ṣeé ṣe kí ìgbésẹ̀ wà láti (Ìsìn Ọjọ́-àìkú) láti gba àsẹ èmi-ni-monií/ẹ̀tọ́ oníhun ààmì ìdánimọ̀ọ Kingston, orílẹ̀ èdè Jamaica àti […] ti ẹyẹ olùlànà onírù gígùn. Mo ti ṣe àwọn ìwádìí kan lórí ayélujára tí mo sì ṣe àwárí láti fi ti ẹ̀rí lẹ́yìn àmọ́ kádàrá kò ṣe mí lóore, mo ṣalábàápàdé ọjàa wọn tí wọ́n ń tà lórí ayélujára tó ní àwọn ààmi ìdánimọ̀ wọ̀nyí, tí ó sì ṣe dọ́gba-n-dọ́gba pẹ̀lú àríyá náà…

Òtítọ́ orílẹ̀ èdèe Jamaica ni wípé àwọn ìjọba àná kò fi ìgbàkan kọbiara sí ìgbéró èto ọrọ̀ Ajée ‘Jamaica’ tàbí àwọn ààmi ìdánimọ̀ tó jẹ́ ti wọn bíi àsíá àti àsíá apata  […] Bákannáà ni ó rí fún orin wa àti ohun tí ó rọ̀ mọ́, Ska, Mento, Rock Steady, Reggae àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ilẹ̀ Jamaica kò tètè lajú sí òwò aṣọ ṣíṣe tí ó ní ààmì pàtàkì erékùṣù tí yóò mú àwọn ènìyàn rà á wìtìwìtì. Bí a bá fi ètò àríyá ṣe ìgbélárugẹ àwọn ọjà wọ̀nyí nínúu gbàgede Emancipation Park tí ó mú ìlọsíwájú bá ohun tí ó ju aṣọ lọ láti ọ̀dọ̀ ìjọba àti àwọn ọmọ orílẹ̀ èdèe Jamaica náà, pẹ̀lú lílo àwọn ààmìi orílẹ̀ èdè náà ní ọ̀nà àrà.

Mo ti ṣe àkíyèsí wípé Iléeṣẹ́ Ètò Àṣà àti Olùdarí ìlúu Kingston ti ń gbé ìgbésẹ̀ẹ pàjáwìrì láti ra nǹkan padà. Kí àwọn méjèèjì mọ̀ pé àtúnṣe kì í ṣe nǹkan tó ma yá kíákíá.

Mo lérò wípé ìjọba ní àwọn agbẹjọ́rò tó ká ojú òṣùwọ̀n.

Lóòótọ́, àwọn agbẹjọ́rò ṣì níṣẹ́ láti ṣe láti tú kókó awuyewuye etí aṣọ ti lílo àsíá orílẹ̀ èdèe Jamaica.