- Global Voices ní-Yorùbá - https://yo.globalvoices.org -

Ìrọ́lù ọlọ́pàá tí í mú ikú bá ‘ni ní Guinea bí Ààrẹ Alpha Condé ṣe kọ̀ láì gbé’ jọba sílẹ̀

Sàwáwù : Ìlú Gúúsù Aṣálẹ̀ Sahara, Guinea, Ètò ìjọba, Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn, Ìfẹ̀hónúhàn, Ìròyìn Ọmọ-ìlú, Ìṣèlú

Àgékù ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ ní Guinea láti ìròyìn ránpẹ́ [1] France 24 kan. 

Ìwà ipá bẹ́ sílẹ̀ ní Guinea lọ́jọ́ 14 oṣù Ọ̀wàrà, tí ó ti fa ikú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn [2]tí wọ́n sì ń kó àwọn ènìyàn kiri lẹ́yìn ìyíde ìféhónúhàn tí ó tako ìjọba ààrẹ tí ó wà lórí oyè ìyẹn Alpha Condé, ẹni tí ó ń gbèrò láti yí ìwé-òfin padà kí ó bá fi ààyè gba òun láti lọ fún ìgbà kẹta.

Ojúu pópó olú ìlú náà, Conakry, àti àwọn ìlú tó kù ti di ojú ogun láàárín àjọ agbófinró àti àwọn ọmọ ìlú tó ń fi èhónú hàn.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti lo àǹfààní tuntun tí ó fún wọn láṣẹ láti lo ohun ìjà aṣekúpani bí ó bá dé ojú ẹ̀. Àwọn afẹ̀hónúhàn ti rán ẹni mẹ́fà sí ọ̀run àjànto [2], ní èyí tí ó jẹ́ pé ọlọ́pàá kan wà nínúu àwọn tí ó jẹ́ Ògún nípè, ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì fi ara pa.

Àwọn afẹ̀hónúhàn kò lọ́wọ́ sí kílàńkó àyípadà sí ìwé-òfin tí wọ́n rí gẹ́gẹ́ bí ìgbésẹ̀ ààrẹ láti wà lórí ipò fún ẹlẹ́ẹ̀kẹ́ta. Ní tòótọ́, ìwé-òfin náà fi ààyè ọdún méjì gba ẹni tí ó bá wà ní ipò ààrẹ láti ṣèjọba. Condé, ẹni ọdún 81, yẹ kí sáà rẹ̀ ó parí ní oṣù Ọ̀wàrà ọdún-un 2020. [4]

Àwọn afẹ̀hónúhàn ni a lè ṣá lọ́gbẹ́ jù lọ nítorí wípé wọ́n tasẹ̀ àgẹ̀rẹ̀ sí òfin náà bí Human Rights Watch ṣe pè fún àkíyèsí [5]:

Depuis plus d’un an, le gouvernement de la Guinée [6] interdit de fait les manifestations de rue en invoquant les risques pour la sûreté publique. Les autorités locales ont interdit au moins 20 manifestations. Les forces de sécurité ont utilisé des gaz lacrymogènes contre les personnes qui défiaient l’interdiction, et ont arrêté des dizaines de manifestants.

Human Rights Watch sọ lónìí wípé, ìjọba orílẹ̀-èdèe Guinea [7] ti gbẹ́sẹ̀ lé ìfèhònúhàn l'ójúu pópó fún ọdún kan, ó tọ́ka sí ìdojú-ìjà-kọ ààbò ìlú. Àwọn aláṣẹ ìjọba ìbílẹ̀ ti fọ́n ó tó bíi ogún ìfèhònúhàn ẹgbẹ́ òṣèlú àti àwọn mìíràn ká yángá. Àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ti sọ tajútajú sí àárín àwọn tí kò gbọ́ràn láti tú wọn ká, wọ́n sì kó àìmọye ènìyàn.

Ní ti ìṣẹ̀lẹ̀ òṣèlú náà, àjọ ọba náà ń kéde iṣẹ́-ìjẹ́ tí ó ń tako ara wọn: Ní ọjọ́ 13, oṣù Ọ̀wàrà Ààrẹ Condé fẹ́ ìsọ̀rọ̀-ní-tùnbí-ǹ-nùbí [8]:

Alpha Condé a réitéré son appel au dialogue responsable et à la concertation permanente pour aplanir toutes les divergences et relever tous les défis qui se posent au pays.

Alpha Condé ti pè fún ìsọ̀rọ̀ ní tùnbíǹnùbí ó sì fẹ́ kí ìjókòó gẹ́gẹ́ bí tọmọtìyá tí yóò fi pẹ̀lẹ́pùtù yanjú gbọ́nmi-síi-omi-ò-tóo tí ó ń ṣẹlẹ̀ àti ọ̀nà àbáyọ sí àwọn ìpèníjà tí ó ń kojú orílẹ̀-èdè náà.

Síbẹ̀, Ahmed Tidiane Traoré, olùdámọ̀ràn ipò ààrẹ, sọ lọ́jọ́ tí ó tẹ̀lé e [9], ìyẹn ní ọjọ́ 12 oṣù Ọ̀wàrà, — ọjọ́ méjì kí ìfẹ̀hònúhàn ó tó bẹ̀rẹ̀, — fún àwọn èrò tó jẹ́ ọ̀dọ́ langba RPG ẹgbẹ́ olóṣèlúu [ruling Reunion of the People of Guinea]:

Nous invitons la jeunesse du parti à la vigilance dans les quartiers. Ils [les militants de l'opposition] ont stocké des pneus usés dans les trous, nous invitons la jeunesse du parti à faire sortir ces pneus. Empêchez-les. Sortez ces pneus cachés, n’attaquent personne, ne détruisez rien, défendez-vous seulement. Tous les malfaiteurs seront dénichés et ils seront montrés au peuple

A rọ àwọn ọ̀dọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú náà láti kún fún ìṣọ́ra ní ojúu pópó. Àwọn [tí àwọn jẹ́ ajìjàngbara alátakò] ti fa ìṣòro, a pe àwọn ìpẹ́ẹ̀rẹ́ láti inú ẹgbẹ́ náà láti wá ọ̀nà àbáyọ sí ìṣòro tó wà nílẹ̀, àmọ́ kí ẹ máà dojú ìjà kọ ẹnikẹ́ni, kí ẹ máà ba dúkìá kankan jẹ́, ju ìdáàbò bo ara yín lọ. Gbogbo àwọn oníṣẹ́-ibi ni ó di àwárí tí a ó fi ojúu wọn hàn f'áráyé rí.

Ẹnu méjì àwọn tí ó ń tukọ̀ ìlú ti túbọ̀ mú inú bí ẹgbẹ́ alátakò àti àwọn àjàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn, ó ní bí ìtakùn globalguinee.info ṣe sọ [10]:

Ce 14 octobre 2019, sans doute un lundi sombre pour ne pas dire noir, à l’appel du FNDC, les Guinéens sont massivement sortis dans les rues pour s’opposer au projet de changement constitutionnel.

Des affrontement ont été signalés dans plusieurs quartiers de la Capitale guinéenne. Les activités au centre administratif de Kaloum ont été quasiment paralysées. Plusieurs Points d’appui (PA) des unités d’intervention de la police ont été aussi saccagés. A l’intérieur du pays, l’appel a été aussi observé dans les régions De Moyenne Guinée, Basse Guinée. En forêt et en Haute Guinée, l’appel n’a pas tellement prospéré. Mais tout de même, les villes sont restées paralysées.

Ọjọ́ 14 oṣù Ọ̀wàrà ọdún-un 2019 jẹ́ ọjọ́ Ajé burúkú Èṣù gbomi mu, ní ti ìfèsì sí ìpè àjọ FNDC [Àwọn tí ó ń lé wájú ń'nú Ìdáàbò bo Ìwé-òfin Orílẹ̀-èdè], àwọn ọmọ Guinea tú yáyá tú yàyà sí ojúu títì láti tako ìgbésẹ̀ àtúnṣe sí ìwé-òfin.

Ìkọlù wáyé ní àwọn agbègbè tí ó wà ní àárín olú ìlú orílẹ̀-èdè náà. Káràkátà dẹnu kọlẹ̀ ní àárín gbùngbùn ibi ìṣàkóso ìlú ní Kalou. Àwọn tí ó wà ní Àárín àti Odò orílẹ̀ èdè Guinea náà gbọ́ ìpè, wọ́n sì darapọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ìlú tó kù. Ènìyàn díẹ̀ ni ó jáde ní ìgbèríko àti Òkèe Guinea. Àmọ́ ṣá, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìlú ti kọ̀yìn síjọba lórí ìgbésẹ̀ yìí.

Ní oríi benbere.org, gbàgede ìtàkùrọ̀sọ fún àwọn ọ̀dọ́ ní Mali, akọ̀ròyin búlọ́ọ̀gù Adam Thiam kọ [11]:

Les choses sérieuses commencent en Guinée, avec ses surenchères incendiaires, ses morts presque banales de manifestants criblés de balles, les traînées de sang sur les pavés barricadés et carrefours fumant sous les pneus enflammés et les gaz lacrymogènes.

Nǹkan kàyèéfì ń lọ lọ́wọ́ lọ́wọ́ báyìí ní Guinea, pẹ̀lú ìrógbàmù tí ó ń wáyé, ọta ìbon ti fọ́ sí ara àwọn afẹ̀hónúhàn tí ó sì ti ṣekú pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ọ wọn, ẹ̀jẹ̀ ní ojúu pópó, ìdígàgá ní gbogbo, iná ẹsẹ̀ ọkọ̀ọ sísun àti tajútajú nínú afẹ́fẹ́.

Àwọn ọmọ ìlú orí ayélujára fajúro sí ìṣẹ̀lẹ̀ náà lórí ẹ̀rọ alátagbà:

Òǹlò Twitter Concerned Citizen®?? (@raia_husika) ṣe ìkìlọ̀ fún ààrẹ orílẹ̀-èdèe the Guinea:

Bíi ti Blaise Compaoré [olóṣèlúu Burkinabé] Alpha Condé ń forí lé ibi ìparun, ǹjẹ́ yó leè gbóhùn inúbíbí àwọn aráa rẹ̀ bí? Ó di ọjọ́ iwájú kí á tó mọ̀. Ní báyìí ṣá, ọkọ̀ ojú omi ti ń ré.

Lọ́jọ́ 15 oṣù Ọ̀wàrà, akọ̀ròyin Guinea  Bhiye Bary kọ:

Ilé ìtòògùn Hamdallaye (#Conakry [14]): àwọn ọlọ́pàá ló jí àwọn ọmọ ìlú kan lójú oorun ní òwúrọ̀ yìí. Gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan ti ṣe sọ, àwọn ọlọ́pàá ń jálẹ̀kùn tí wọ́n sì ń kó ẹrù nílé onílé. (Àwòrán ní ìpamọ́)#Amoulanfe [15] #Kibaro [16] #Guinee [17] pic.twitter.com/xk6xax8DT0 [18]

S. Nkola Matamba, òǹkọ̀wé àti ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyan tí ó jẹ́ ọmọ Ìlú Olómìnira Ìjọba ara wa ti Congo, fi ìbánújẹ́ ọkàn hàn:

Ọmọ ẹgbẹ́ alátakò ìgbàkan, tí ó wá fẹ́ yí òfin padà nítorí ìfẹ́ ara rẹ̀ kí ó ba ṣèjòba fún ìgbà kẹta, bóyá kí ó bá jẹ gàba títí tí Ọlọ́jọ́ yóò fi dé, Alpha Condé gan-an ni àpẹẹrẹ ibi tí ó ń fa ìfàsẹ́yìn fún Ilẹ̀-Adúláwọ̀! Ẹ̀yin aráa Guinea, ẹ mú ọkàn le!

https://t.co/K3DAaqaIYI [21]

— S. Nkola Matamba??? (@Simeon_5) ọjọ́ 12, oṣù Ọ̀wàrà 2019 [22]

Ní ti Cheikh Fall, ọmọ Senegal, ìṣòro ibẹ̀ ni àìfẹ́ gbéjọba sílẹ̀:

#GUINÉE [23] – ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu. Ìfẹ̀hònúhàn ìtako ìṣèjọba Condé fún ìgbà kẹta ọjọ́ kan ṣoṣo tí mú ẹ̀mí àwọn ènìyàn lọ. Sísíwín àwọn olóṣèlú tí ó fẹ́ kú sórí ipò ààrẹ yìí ti ń pọ̀ jù Amoulanfe [15]— Cheikh Fall™ (@cypher007) ọjọ́ 14, oṣù Ọ̀wàrà 2019 [24]

Ajìjàǹgbara Guinea Macky Darsalam sọ ti ìgbésẹ̀ láti tọwọ́ bọ èròńgbà àwọn ará ìlú lójú: 

#Guinée [20]
Láti máà jẹ́ kí Ìfẹ̀hònúhàn náà nípa, @GouvGN [25] [ìjọba Guinea] fi #Lundi14 [26] [ọjọ́ Ajé yìí, ọjọ́ọ 14] pín àpò ìrẹsì ní olú-ìlú orílẹ̀-èdè náà @Amoulanfe2020 [27] @AlphaCondePRG [28]@Cellou_UFDG [29]@diallousmane [30]@RFI [31]@afpfr [32] pic.twitter.com/T7qY6JOlzB [33]

— Macky Darsalam (@DarsalamMacky)  ọjọ́ 12, oṣù Ọ̀wàrà 2019 [34]

Ẹgbẹ́ alátakò Guinea náà kò ní ààbò tí ó lè fi bo araa rẹ̀ lásìkò ìkọlù: àwọn aṣojú aláṣẹ ẹgbẹ́ alátakò gbogbo kò dá sí [35] àríyànjiyàn ìgbìmọ̀ ìjọba mọ́ láti ọjọ́ 11, oṣù Ọ̀wàrà 2019. Ìwà ipá sí àwọn ẹgbẹ́ olóṣèlú wọ̀nyí ti gba ọ̀nà àrà, bẹ́ẹ̀ ni ibùdó ìtakùn mediaguinee.org [36] ṣe kọ:

…au siège de l’Union des forces républicaines (UFR) de Sidya Touré, des échauffourées ont éclaté entre certains éléments de l’opposition et des militants de la mouvance qui avaient pris des dispositions la veille pour boucler toute manifestation non autorisée dans le fief traditionnel du parti au pouvoir. Des affrontements qui se sont soldés par le saccage du siège de l’UFR et l’arrestation de 6 personnes dont les identités et leurs partis d’origine restent encore méconnus du grand public.

…ní olú iléeṣẹ́ Union of Republican Forces (URF) tí agbègbè Sidya Touré, ìjá wáyé láàárín àwọn ọmọ ẹgbẹ́ alátakò kan àti àwọn tí ó ń fẹ́ ti ìjọba tí ó ti ṣètò tí kò ní jẹ́ kí ìyíde ìfẹ̀hónúhàn náà ó wáyé lọ́jọ́ kan sí ọjọ́ ìfẹ̀hónúhàn ní àwọn agbègbè tí wọ́n ti lẹ́nu. Ìkọlù náà wá sí òpin lẹ́yìn-in ìkólọ iléeṣẹ́ URF náà tí àwọn ènìyàn mẹ́fà tí kò sí ẹni tó mọ orúkọ àti ẹgbẹ́ olóṣèlú tí wọ́n ń bá ṣe di èrò àtìmọ́lé.