#SexForGrades: Ètò Alálàyé-afẹ̀ríhàn tú àṣìírí ìwà ìyọlẹ́nu ìbálòpọ̀ ní àwọn Ifásitìi Ìwọ-oòrùn Ilẹ̀-Adúláwọ̀

Boniface Igbeneghu, ọ̀jọ̀gbọ́n Ifásitìi Èkó, Nàìjíríà ti bá ẹni tí ó wọ ìbòjú yìí ṣe erée gélé ní àìmọye ìgbà (Àwòrán láti BBC #SexForGrades)

#SexForGrades, ètò alálàyé afẹ̀ríhàn-an BBC kan tí ó dá fìrìgbagbòó lóríi àṣemáṣe eré ìfẹ́ tí àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ifásitì pẹ̀lú àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìrin ní Nàìjíríà àti Ghana ti ràn bíi pápá inú ọyẹ́ ní orí ayélujára tí ó sì ti fa àwọn ìbéèrè ọlọ́kanòjọ̀kan nípa ọ̀nà tí a leè gbà dẹ́kùn àṣemáṣe ọ̀hún láwùjọ:

Okùn:

Àgbà iṣẹ́ ìwádìí náà, tí ó di gbígbé jáde ní ọjọ́ kéje oṣù Ọ̀wàrà 2019, tí akọ̀ròyin Kiki Mordi tí kò parí ẹ̀kọ́ọ rẹ̀ látàríi wípé kò fẹ́ ṣe àṣemáṣe pẹ̀lú olùkọ́ní ifásitì rẹ̀ tí ó ń fi ìdíi rẹ̀ rẹmi nínú ìdánwò nítorí wípé kò fún un ṣe ṣe atọ́kùn-un rẹ̀:

Kòfẹ́sọ̀ t'ó ń pa wọ́n jẹ bí ẹ̀pà

Boniface Igbeneghu, Ifásitì Èkó, tí a ká ìwà àṣemáṣe pẹ̀lú àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìrin nínú ìwádìí abẹ́lẹ̀ tí BBC ṣe. Àwòrán láti BBC #SexForGrades.

Ìwádìí tí ó pé wákàtí kan tú àṣìírí ìwà àṣemáṣe ti “eré ìfẹ́ fún ojú-àmì ẹ̀kọ́” ní ifásitì Ìwọ̀-oòrùn Ilẹ̀ Adúláwọ̀ méjì: University of Lagos (UNILAG) ti Nàìjíríà àti University of Ghana.

Boniface Igbeneghu, tí í ṣe kòfẹ́sọ̀ ní ẹ̀ka iṣẹ́ ọnà ti UNILAG, tí ó sì tún jẹ́ àlùfáà Ìjọ Foursquare Gospel, ní Èkó, ń bẹ nínú àwọn olùkọ́ tí òkété bórù mọ́ lọ́wọ́.

A rí Igbeneghu nínúu ètòo BBC náà tí ó kọ ẹnu ìfẹ́ sí ọmọdébìnrin tí ó díbọ́n gẹ́gẹ́ bí ọmọ ọlọ́jọ́ orí mẹ́tàdínlógún tí ó ń wà ìgbanisílé ẹ̀kọ́ láì fura wípé ajábọ̀ ìròyìn tí ó ń ṣe iṣẹ́ ìwádìí abẹ́lẹ̀ fún BBC ni ó ń ṣe. Igbeneghu sọ báyìí wípé:

Ṣé o kò mọ̀ wípé ọmọbìnrin arẹwà ni ọ́? Ǹjẹ́ o mọ̀ wípé àlùfáà ìjọ ẹlẹ́sìn ìgbàgbọ́ ni mo jẹ́, àti pé mo tó ẹni àádọ́ta ọdún ṣùgbọ́n bí mo bá fẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún ọ̀rọ̀ dídùn àti owó ni ó máa jẹ…

Níbi ìpàdé kan láàárín àwọn méjèèjì, Igbeneghu ṣẹ́ iná pa, ó sì ní kí ọmọdébìnrin náà ó fẹ́nu ko òhun lẹ́nu, tí ó sì tún dì mọ́ ọn gbádígbádí nínúu iyàraa iṣẹ́ẹ rẹ̀ tí ó wà ní títì pa.

Ìjọ Ajíhìnrere Foursquare ti dá Igbeneghu dúró “lẹ́nu iṣẹ́ ìhìn rere”. Bákan náà, Ifásitì Èkó ti lé Igbeneghu kúrò ní ilé ìwé wọ́n sì ti sún ìpèré sí ẹ̀hìn ilẹ̀kùn ilé òṣìṣẹ́ tí wọ́n ń pè ní “yàrá tútù,” tí àwọn ọ̀gá olùkọ́ni ti máa ń ṣe àríyá níbi tí wọ́n ti máa ń gba àwọn ọ̀ṣọ́rọ̀ ọmọge lálejò.

Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìbànújẹ́ ọdún sẹ́yìn

Àkàrà tí ó tú sépo yìí ti fi gọ̀ngọ̀ fa kòmóòkùn ọ̀rọ̀ jáde lẹ́nu ọ̀gọ̀rọ̀ ọmọ orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà ní orí ayélujára pẹ̀lú àmìi #SexForGrades ní oríi Twitter. Púpọ̀ nínú àwọn òǹlò tí ó jẹ́ abo ní oríi Twitter fi ẹ̀dùn ọkàn-an wọn hàn nípa ìríríi wọn lóríi ìwà erée gélé ti ìbálòpọ̀:

Lọlá Ṣónẹ́yìn, alátinúdáa àjọ̀dún ìwé àti òǹkọ̀wé, ṣàlàyé “ìtìjú ńlá” tí òhún rí nígbà tí amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀gá pátápátá ifásitì kan (DVC) fọwọ́ kan ibi tí kò yẹ kí ó fọwọ́ kàn lára òun:

Ẹnìkan ní oríi Twitter sọ báyìí “ìlòkulò àṣẹ”:

Àwọn mìíràn ẹ̀wẹ̀wẹ̀ ń gbà á ládùúrà kí iṣẹ́ ìwádìí náà ó dé ilé ẹ̀kọ́ọ ti wọn náà, bíi Abia State University ní Nàìjíríà fún àpẹẹrẹ:

Àti University of Calabar ní Nàìjíríà náà:

Àwọn kan fẹ́ kí irúfẹ́ iṣẹ́ ìwádìí báyìí ó wádìí ilé ìjọsìn àti àwọn àwùjọ mìíràn tí ìwà àṣemáṣe ti ìbálòpọ̀ tí kò bá òfin mu ti ń wáyé:

Ilé ẹ̀kọ́ gíga nìkan kọ́ ni a ti ń rí ìwà pálapàla ìlù àpàlà yìí, kò yọ ilé ìfowópamọ̀ náà sílẹ̀:

Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n oníṣìná ilé ẹ̀kọ́ gíga Nàìjíríà ti ba ti àwọn obìnrin jẹ́. Síbẹ̀síbẹ̀, nítorí ìtìjú àwọn tí ó fi ara pa kì í leè sọ̀rọ̀ síta èyí kò sì jẹ́ kí ó rọrùn láti dá sẹ̀ríà fún àwọn awùwà ìbàjẹ́.

Ní ọdún-un 2016, Ìgbìmọ̀ Àṣòfin mú àbá ẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún wá fún olùkọ́ní tí ilé ẹjọ́ bá dá lẹ́bi àṣemáṣe pẹ̀lú akẹ́kọ̀ọ́ nínú “Ìwé àbádòfin Ìfòpin sí ìwà ìbàjẹ́ ìbálòpọ̀ ní Ilé Ìwé Gíga”.

Síbẹ̀, Àjọ Olùkọ́ni Ifásitìi Nàìjíríà kọ ẹ̀yìn sí ìwé àbá yìí, wọ́n ní ó kọ iyán àwọn kéré, nítorí ó kọjú ìjà sí àwọn olùkọ́ àti wípé ó yẹpẹrẹ àṣẹ àti agbára ilé ẹ̀kọ́ gíga.

Ìsọtasí ìwé àbá náà pa òfin náà ní àpakú finínfinfín — èyí kò sì jẹ́ kí ààrẹ ó bu ọwọ́ lù ú.

Ṣé Eré ìfẹ́ fún ojú-àmì Ẹ̀kọ́ #SexForGrades ni ìjìjàngbara ilé ìjọsìn #ChurchToo tuntun?

Nínú oṣù kéje ọdún yìí, gbajúgbajà ayàwòrán-an nì, Bùsọ́lá Dakolo, fi ẹ̀sùn kan Bíọ́dún Fátóyìnbó, àlùfáà àgbà ìjọ  Commonwealth of Zion Assembly (COZA), wípé ó fi ipá bá òun ní àjọṣepọ̀ nígbà tí òhún wà ní ọmọ ọdún mẹ́rindínlógún.

Fún ọdún mẹ́fà tí ó ré kọjá lọ, Fátóyìnbó aródẹ́dẹ́ ti rí ìfẹ̀sùnkàn ìfipábánilòpọ̀ ọ̀kan-ò-jọ̀kan. Síbẹ̀, ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tí Dakolo ti fẹ̀sùn kan Fátóyìnbó dá awuyewuye sílẹ̀ lórí ayélukára bí ajere. Fún ọjọ́ díẹ̀, ilé ìjọsìn náà; #ChurchToo — tí í ṣe àpẹẹrẹ èmi náà ní àgbáyé #MeToo — gba ayélujára kan ní Nàìjíríà.

Ẹ̀sùn yìí fò fẹ̀rẹ̀ láti orí ayélujára sí ìfẹ̀hónúhàn lóríi òpópónà ní àwọn ìlú ńlá ní Nàìjíríà bíi Èkó àti Abuja. Ìpèsí àkíyèsí ilé ìjọsìn náà #ChurchToo movement rọ ìjọba láti da “ọ̀ràn-an ìjìyà obìnrin àti ọmọdébìnrin dúrò.”

Ilé ìjọsìn náà #ChurchToo ṣípayá ìdákẹ́ rọ́rọ́ àmọ́ “ ìbàjẹ́ àṣà ìfipábánilòpọ̀ tí ó ń gbèrú, pàápàá jù lọ ní agbo ìjọsìn” ní Nàìjíríà. Ó fún àwọn obìnrin ní àǹfààní láti wí ti ẹnu wọn.

Bíi ti #ChurchToo, ìké tantan eré ìfẹ́ fún ojú-àmì ẹ̀kọ́ #SexForGrades ti fẹ ìdí ìlòkulò agbára tí ó bí ìwà àṣemáṣe ti ìbánilájọ̀ṣepọ̀ tí àwọn obìnrin kò fi tọkàntọkàn fẹ́ síta gbangba.

Ǹjẹ́ àmì orí ayélujára yìí yóò ṣe amọ̀nàa ìgbèjà ẹ̀tọ́ tí kì í ṣe ti orí ayélujára tí yóò béèrè fún àtúnṣe tí yóò sọ ilé ẹ̀kọ́ gíga ifásitì di ibi ààbò fún àwọn obìnrin bí? Ìgbà àti àkókò nìkan ni yóò sọ.

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.