- Global Voices ní-Yorùbá - https://yo.globalvoices.org -

Ìṣọdẹ-àjẹ́ ṣì ń gba ẹ̀mí àwọn ènìyàn ní ìgbèríko India

Sàwáwù : South Asia, India, Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn, Ìdàgbàsókè, Ìròyìn Ọmọ-ìlú, Obìrin àti Akọtàbábo

Ìletò kan ní ẹ̀báa Jamshedpur ní Jharkhand. Àwòrán láti ọwọ́ọ Anumeha Verma

Ní ọjọ́ 20 oṣù Agẹmọ, àgbájọ àwọn ènìyànkéènìà gba ẹ̀mí àwọn àgbàlagbà mẹ́rin kan láì dá wọn lẹ́jọ́ ní agbègbèe Gumla ní Jharkhand, India lẹ́yìn tí a fi ẹ̀sùn-un àjẹ́ kàn wọ́n. Gẹ̀gẹ̀ bí ìjábọ̀ ìròyìn [1], àwọn àgbàlagbà wọ̀nyí ṣe ikú pa ọkùnrin kan, ni ìgbìmọ̀ abúlée Panchayat [2] ṣe dá wọn lẹ́bi. Wọ́n wọ́ àwọn àgbàlagbà mẹ́rin wọ̀nyí jáde síta ilée wọn, àwọn ọkùnrin tí ó bòjú sì fi igi lù wọ́n títí tí ẹ̀mí fi bọ́ lára wọn. Mẹ́jọ nínú àwọn ènìyànkéènìà wọ̀nyí [3] ti wà ní akóló ọlọ́pàá.

Gẹ̀gẹ̀ bí àkọsílẹ̀ ọlọ́pàá tí Times of India tẹ̀jáde, ìṣọdẹ-àjẹ́ ní Jharkhand ti rán àwọn ènìyàn 123 [4]sọ́run àpàpàǹdodo ní àárín-in oṣù Èbìbí ọdún-un 2016 sí oṣù Èbìbí ọdún-un 2019. Jákèjádò, ènìyàn 134 di ẹni ẹbọra-ń-bá-jẹun látàrí èsùn-un lílo “ògùngùn” ní ọdún-un 2016, ìyẹn gẹ̀gẹ̀ bí Àjọ Aṣàkọsílẹ̀ Ẹ̀ṣẹ̀ Orílẹ̀-èdè náà ṣe kọ́ ọ sílẹ̀.

Àrùn T’ó Ń Peléke Sí i

“Ìṣọdẹ-àjẹ́ kò jẹ́ tuntun ní Jharkhand,” Prem Chand, Olúdásílẹ̀ àti Alága Free Legal Aid Committee (FLAC) [5]  Jharkhand, sọ nínúu ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò orí ẹ̀ro-ìbánisọ̀rọ̀ kan. FLAC ti ń e àtọ́nàa ìòfin tí ó tako ìṣọdẹ-àjẹ́ ní Jharkhand. Iléeẹ́ náà bẹ̀rẹ̀ iẹ́ ní agbègbè yìí ní ọdún-un 1991 nígbà tí àwọn aládùúgbò fi ẹ̀sùn kan obìnrin kan pé ó lọ́wọ́ nínú ikú ọmọdékùnrin kan. Àgbájọ àwọn ènìyànkéènìà kan dìgbò lù ú, wọ́n sì pa ọkọ àti ọmọ rẹ̀ ọkùnrin. Òún fi ara pa.

Nígbàtí Prem Chand àti àwọn ẹlẹgbẹ́ẹ rẹ̀ e ìbẹ̀wò sí àwọn ẹlẹ́ẹ̀ wọ̀nyí nínúu túbú, wọ́n bá ìpèníjà:

Wọ́n sọ fún wọn wípé àwọn dúró lé oríi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àwọn. Wọ́n sì tún gbàgbọ́ wípé bí ẹ̀jẹ̀ẹ ẹni tí a pè ní àjẹ́ bá kan ilẹ̀ ọ̀gẹ́rẹ́, yóò pàdánù agbára ẹlẹyẹ rẹ̀.

Prem Chand sọ wípé ó kan apá kan nínú àwọn ọmọ ìlú:

Nígbàgbogbo, àwọn obìnrin tí kò lárá tí ó tálákà ní í máa ń fi ara kááṣá. Àwọn tí ó f’ara kááṣá wọ̀nyìí ni àwọn Adivasis, Harijans àti Dalits. Ìfojú iyì àwọn obìnrin àti ìtasẹ̀ àgẹ̀rẹ̀ sí òfin ẹ̀tọ́ sí ayé iyì fún gbogbo ọmọ ènìyàn.

Òtítọ́ Àwùjọ àti Ìṣèlú 

Àwọn ajìjàngbara sọ wípé ìgbàgbọ́-asán tí ó rinlẹ̀ ní ìgbèríko [6] ni ó ń fa ìwà pálapalà náà. Àìgbẹ̀kọ́, ètò ìlera tí ò pójú òṣùwọ̀n àti kòlàkòṣagbe tí ó ń gb’àgbègbè tí ìwà pálapalà wọ̀nyí ti gbalẹ̀ bí i ìtàkùn ni ó fi wọ́pọ̀.

Ọ̀ràn wọ̀nyí ti fi hàn wípé àhesọ ni ó máa fi ń bẹ̀rẹ̀. Pẹ̀lú òfin àwọn ìpínlẹ̀ India tí ó ka ìṣọdẹ-àjẹ́ sí ohun tí ó lòdì sófin, àwọn akópa ọ̀ràn wọ̀nyí rí i gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ìdáààbò-ara-ẹni.

Bákan náà ni wọ́n ń wí àwáwí fún gbígba ohun ìní àwọn obìnrin, fi agbára gbẹ̀san tàbí fi ipá bá obìnrin lò pọ̀ [7].  Gẹ́gẹ́ bí Prem Chand ṣe ti sọ:

Àtètèròtẹ́lẹ̀ ni wípé ní kété tí o bá ti pe obìnrin ní àjẹ́, o lè tẹríi rẹ̀ ba fún ìlòkulò. Síbẹ̀síbẹ̀, ó ṣe kókó láti mọ̀ wípé wọn máa ń lo ìwà pálapàla yìí fi gba tara àwọn obìnrin, kò sì kìí ṣe ìdí tí ó ń fà á pàtó.

Ní ti ẹ̀fẹ̀, láì wí tó, panchayat [2] náà sábà máa ń lọ́wọ́ sí ìpènìyàn ní àjẹ́ pàápàá bí kò bá pàṣẹ ìjìyà t'ó tọ́.

Ní àfikùn sí panchayat tí ìbó yàn, àwọn kan ńbẹ tí wọ́n pe ara wọn ní panchayat ipò-ìsàlẹ̀ [8] láì ní àṣẹ kankan tí ó fún wọn lágbara níbikíbi ní orílẹ̀-èdè. Àwọn ẹgbẹ́ yìí máa ń dájọ́ àti fi ìyà jẹ ènìyàn tí kò sì sí ẹni tí ó ká wọn lápá kò. Ìṣẹ̀lẹ̀ kan ní agbègbèe Ajmer ní Rajasthan lọ́dún-un 2017 jábọ̀ ìlọ́wọ́sí panchayat ipò-ìsàlẹ̀ tí ó ṣ’okùnfa ikú obìnrin ogójì ọdún kan [9].

Gẹ́gẹ́ bí òfin, ilé ẹjọ́ lé gbé ìgbésẹ̀ tí ó tako irúu ìdájọ́ báwọ̀nyí yálà láti ọ̀dọ̀ àwọn panchayat tí ìbó yàn àti panchayat ipò-ìsàlẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn tí ó fara kááṣá ò tilẹ̀ ní àǹfààní sí ilé-ẹjọ́ òfin kí àgbájọ-àwọn-ènìyànkéènìà ó tó kojúu wọn.

Ìṣọdẹ-àjẹ́ jákèjádò India

Jharkhand ti ṣe àkọsílẹ̀ iye ẹṣẹ̀ àwọn ènìyán ṣẹ̀ tí ó pọ̀ jù lọ tí ó tan mọ́ ìṣọdẹ-àjẹ́ àmọ́ kì í ṣe ìpínlẹ̀ náà nìkan.

  • Ọ̀ràn-an ìṣọdẹ-àjẹ́ ti wà l’ákọsílẹ̀ ní Chattisgarh, Odisha, Gujarat, West Bengal Assam, Bihar, Maharashtra àti Rajasthan [10] pẹ̀lú.
  • Nígbà ìṣẹ̀lẹ̀ kan ní 2014, Debjani Bora [11], ẹlẹ́sẹ̀ ehoro ọmọ bíbíi orílẹ̀-èdèe India ti fi ara kááṣá rí. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ọ Debjani, a f’ẹ̀sùn-un ìgbẹ̀mí ènìyàn púpọ̀ kàn án ní abúlée Cherekali tí ó wà ní kìlómità 180 láti Guwahati, olú-ìlúu India ti apáa ìlà-oòrùn. Olóríi gbọ̀gán àdúrà abúlé l’ó dárúkọ rẹ̀ tí àwọn ará abúlé sí fi ìyà jẹ́ ẹ.
  • Ìṣẹ̀lẹ̀ 2017 ní ipínlẹ̀ Rajasthan. Lára èyí ni, ọmọbìnrin ogójì ọdún kan Kanya Devi [12] rí ìkọlù tí a sì lù ú pa lẹ́yìn tí mọ̀lẹ́bíi rẹ̀ fi ẹ̀sùn kàn án ní agbègbèe Ajmer.

Àwọn Ẹni-tó-fara-kááṣá àti Ẹni-tórí-kó-yọ

Àwọn ènìyàn ń f’ẹ̀sùn kan àwọn ẹlẹyẹ fún iṣẹ́-ibi ọwọ́ọ wọn: ikú ènìyàn tàbí ẹranko, ọ̀dá òjò, àìso jìngbìnnì irúgbìn, àti bẹ́èbẹ́è lọ. Ìkọlù tí ó kọ lu àwọn obìnrin wọ̀nyí (àti àwọn ọkùnrin kan) rorò bí ẹranko ẹhànnà [13]. Nígbà mìíràn, àwọn èsùn náà àti ìjìyà ẹṣé máa wá láti ọ̀dọ̀ mọ̀lébíi wọn.

Àwọn kan ń gbé tí wọ́n sì ń sọ ìtàn-an wọn tí wọ́n sì ń jà fún ẹ̀tọ́ọ wọn. Chutni Mahato ti Saraikela ní Jharkhand jẹ́ ọ̀kan lára wọn. Àwọn ènìyàn láti agbègbè náà máa ń pè é ní ‘tigress’. Wọ́n fi ẹ̀sùn-un àjẹ́ kàn-án ní ọdún-un 1995. Láti ìgbà náà, ó ti yírapadà di ajìjàǹgbara olùtako ìfìyàjẹ àwọn obìnrin pẹ̀lú àtìléyìn Ilé-iṣẹ́-tí-kìí-ṣe-tìjọba.

Chutni sọ bí àìsí àtìlẹ́yìn tó késejárí ṣe mú u nira láti jà tako ìwà pálapàla yìí. “Ìbájẹ́pé àtìlẹ́yìn tó tó wá láti ọwọ́ àwọn oníṣẹọba àti ìjọba fún iṣẹ́ tí à ń ṣe níbí. Síbẹ̀síbẹ̀, mo ti jìyà nítorí ìwà pálapàla yìí. Bí ènìyàn bá tọ̀ mí wá fún ìrànlọ́wọ́, mo máa dúró tì wọ́n gbágbágbá,” ó sọ nínúu ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò orí ẹ̀ro-ìbánisọ̀rọ̀ kan.

Dídá Ohùn Gbogboògbò Sí i 

Àwọn ẹni-tórí-kó-yọ àti ajàfẹ́tọ̀ọ́-ènìyàn rò wípé àwọn ènìyàn gbogbo kò ti ìfòpin sí ìṣọdẹ-àjẹ́ lẹ́yìn. Àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́-ènìyàn tí a fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò lórí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí jẹ́ kí á mọ̀ wípé àbùkù ìrànwọ́ ìjọba àti àwọn onímọ̀ ni kò mú ìwà àìbójúmu náà ṣíra kásẹ̀ ńlẹ̀.

Ohun tí ó dára jù lọ ni wípé àwọn tí ó ń tako ìwà burúkú yìí gbàgbọ́ wípé àyípadà lè dé. Ní ọ̀rọ̀ọ Prem Chand:

Akitiyan láti f’òpin sí ìṣọdẹ-àjẹ́ lè tẹ̀lé ìlànà tí ìjọba fi polongo ètò mímọ̀ọ-kọ-àti-mímọ̀ọ-kà. Bákan náà, àwọn onímọ̀ ní láti f’ọwọ́ sí i k’áwọn ènìyàn ó ba f’ohùn sí i.

B. Vijay Murty, akọ̀ròyìn àti olùgbé Jharkhand ni ó gbọ̀rọ̀ sílẹ̀ lẹ́nu àwọn tí ọ̀rọ́ kàn.