- Global Voices ní-Yorùbá - https://yo.globalvoices.org -

Àyájọ́ Ọjọ́ Òmìnira ní Trinidad àti Tobago — àmọ́ ǹjẹ́ orílẹ̀-èdè náà ní òmìnira bí?

Sàwáwù : Caribbean, Trinidad & Tobago, Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn, Ẹ̀yà àti ìran, Ìròyìn Ọmọ-ìlú, Ìṣẹ̀lẹ̀ àtijọ́, Ìṣèlú, Ọ̀dọ́, Òfin

Ère Orin Ìràpadà, Ọgbà Òmìnira, Jamaica. Àwòrán láti ọwọ́ọ Mark Franco, a gba àṣẹ láti lò ó.

Ọjọ́ 1 oṣù Ògún ni ọ̀pọ̀ agbègbè tí ó wà ní [1]Caribbean [2] mọ̀ sí Àyájọ́ Ọjọ́ Òmìnira [3], tí í ṣe ọjọ́ tí a máa ń sààmi ìgbòmìnira àwọn ọmọ Adúláwọ̀ t'ó jìyà ní àsìkò okòwò ẹrú orí òkun atlantic [4].

Trinidad àti Tobago jẹ́ àkọ́kọ́ nínú àwọn orílẹ̀-èdè ní àgbáyé [5] tí yóò ya ọjọ́ sọ́tọ̀ láti fi sọríi ìfòpin sí òwò ẹrú, àmọ́ lẹ́yìn-in 34 ọdún tí ìsinmi àpapọ̀ náà fi ẹsẹ̀múlẹ̀ àti ọdún 185 lẹ́yìn-in tí Àbá òfin Ìfòpin sówò-ẹrú [6] kọ́kọ́ wáyé [7], awuyewuye ṣì ń lọ lóríi wípé bóyá erékùṣù-ìbejì olómìnira náà ní òmìnira tàbí kò ní.

Nínú ọ̀rọ̀ọ rẹ̀ nípa òmìnira ní ọjọ́ 27, ọdún-un, Alákòóso Ìlú Dókítà. Keith Rowley ṣàkíyèsí [8] wípé ní àárín àwọn ọmọ bíbíi Trinidad àti Tobago, àwọn tí ó jẹ́ ọmọ Adúláwọ̀ “kol ṣe dáadáa tó bí ó ṣe yẹ”. Rowley sọ wípé ìwà-ipá tí í ṣe ti ènìyàn dúdú, ìrírí ọ̀dọ̀, ní láti máa ṣe ìwúrí fún àwọn ọmọìlú láti “fiyèsí, ṣe àfihàn àti ṣe ìtàkùrọ̀sọ pàtàkì nípa ibi tí a wà gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè”.

Alága Ìgbìmọ̀ Àtìlẹ́yìn Òmìnira ti orílẹ̀-èdè náà, Khafra Khambon, gbà [9].

Àwọn ìwé àpilẹ̀kọ kan sí olóòtú fi àwọn àpẹẹrẹ [10] okòwò ẹrú ìgbàlódé láwùjọ hàn èyí tí ó fi hàn wípé òmìnira tòòtọ́ ṣì ku díẹ̀ káàtó, nígbà tí àwọn mìíràn gbìyànjú [11] láti sọ ọ́ di ọ̀rọ̀ òṣèlú, bí wọ́n ṣe ń tako àwọn iṣẹ́ ìlú àti àṣà.

Ìwé ìròyìn Trinidad Express yàn láti kọ èròo [12] rẹ̀ nípaÀyájọ́ Ọjọ́ Òmìnira tí ó dábàá wípé Rowley, Kambon, àti ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọ-ènìyàn Pearl Eintou Springer ṣì sọ nígbàtí wọ́n sọ ìdí tí àwọn ọmọìlú Trinidad àti Tobago tí ó jẹ́ ènìyàn dúdú ò fi ṣe dáadáa tó:

Ó rọrùn fún ẹgbẹ́ tí ó dúró ṣinṣin láti dá ètòo ẹlẹ́yàmẹyà àti ìtẹ̀bọlẹ̀. Àwọn tí kò bá ètò náà lọ yóò di aláìṣetó tí wọ́n á sì di ẹni àgbésẹ́yìn sí ipò kejì tàbí èyí tí ó burú ju bẹ́ẹ̀ lọ. […]

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ètòo wa, ẹ̀kọ́ tí í ṣe baba, ń gbé àwọn ènìyàn sí ipòo tálákà, kò sì fún wọn ní àǹfààní lẹ́ẹ̀kan sí i. Gbogbo ètò ni ó ní òṣùwọ̀n, tí ó ṣì jìnà gbégbérégbé sí òkè. Àwọn tó bá ara wọn ní ìsàlẹ̀ ní ìṣòro láti bá àwọn tí ó wà ní òkè ṣe. Iyì-ara-ẹni máa ń relẹ̀, tí èyí yóò sì mú wọn hu ìwà-ipá láti jà fún ẹ̀tọ́ọ wọn láwùjọ.

Ajábọ̀-ìròyín [13] Arthur Dash gbóríyìn fún “ìṣẹ̀lẹ̀-àtẹ̀yìnwá ìdàgbàsókè” orílẹ̀-èdè náà ní ti ọ̀ràn-an ẹ̀yà, àmọ́ ó tún dá àbá wípé ìṣòro náà ju bí àwọn ti ṣe rò lọ, ó sì mú u ní àbá pé ó yẹ kí ọ̀rọ̀ alákòóso ìlú jẹ́ ìwúrí fún ọmọìlú láti ṣe ìwádìí fínnífínní sí bí ẹlẹ́yàmẹyà nínú ilé-iṣẹ ṣe ń pín àwọn ènìyàn sọ́tọ̀ọ̀tọ̀.

Àwọn òǹlò ẹ̀rọ-alátagbà sọ ti wọn. Òǹlò Facebook Adrian Raymond sọ [14]:

Ní ọjọ́ òní a ṣe ìrántí àti ìsààmì òmìnira àwọn babańláa wa nínú ìgbèkùn ara ti òwò ẹrú.

Ní òní, lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, àwa ọmọ ẹrú tí à ń jà fitafita fún àjogúnbá ìjọba amúnisìn.

Àwọn àjogúnbá tí ó gbèèrú àti tí ó ní ìmúgbòrò ti di gbẹndẹ́kẹ: A ò kí ń ṣe òǹrorò, a ò kí ń ṣe oníjàgídíjàgan, a ò kí ń ṣe apanijẹ, a ò kàn kí ń ṣe ọ̀daràn àti ọmọ-ìta. Olórí ni wa, aronújinlẹ̀ ni wa, ọlọ́pọlọ pípé ni wa, onímọ̀ ni wa. Obama ni wá, Garvey ni wa, Marley ni wa, Angelou ni wa, Walcott ni wa. […]

Ẹ jẹ́ ká mọ̀ wípé ìyàsọ́tọ̀ọ̀tọ̀ nípa ti àwọ̀ ara ni ogún tí ó ń pín wa níyà […]

Ẹ jẹ́ kí á ṣe ìṣèlú tó kún fún ọ̀wọ̀; ẹ dẹ́kun à ń ba dúdú jẹ́ ní etí àwọn ènìyàn […]Ẹ jẹ́ ká ṣ’àjọyọ̀ àtúnrí àwọn ìgbàgbọ́ọ wa. Wọ́n gba ẹ̀sìn àwọn babańláa wa, wọ́n mú ìgbàgbọ́ àti ohun iyìi wa kúrò ní ọkàn-an wa. Ní ayé òde òní tí ẹ̀rọ ayélujára mú iṣẹ́ ìwádìí rọrùn, ó yẹ kí o ṣe àyẹ̀wò sí ìgbàgbọ́ àwọn babańláa wa, ìbọ̀wọ̀ àti ìmọrírì àgbà, gbígba ìwùsàsí ẹni […] ìtẹnumọ́ ẹwùn àti èrè ìwà ẹni, ìgbàgbọ́ ń bẹ nínú ẹbí, nínúu mọ̀lẹ́bí, nínú ìletò, nínúu àdúgbó.

Òmìnira yìí faramọ́ ẹni tí o jẹ́, ibi tí o ti ṣẹ̀ wá, ẹ̀jẹ̀ àti ìṣẹ̀lẹ̀-àtẹ̀yìwá tí ó wà nínú iṣan-ẹ̀jẹ̀. Gbá iyìi rẹ̀ mú, àṣàà rẹ, àti ìdánimọ̀ọ rẹ.