- Global Voices ní-Yorùbá - https://yo.globalvoices.org -

Àwọn ọmọ Bangladeshi lo ẹ̀rọ-alátagbà fi gbógun ti àjàkálẹ̀ àìsàn ibà-ẹ̀fọn

Sàwáwù : South Asia, Bangladesh, Ètò ìjọba, Ìjàmbá, Ìlera, Ìròyìn Ọmọ-ìlú, Iṣẹ́ ìkọ̀ròyìn àti Ìròyìn-kíkọ
[1]

Ẹ̀fọn Aedes albopictus, tí ó máa ń gbé kòkòrò ibà ká. Àwòrán láti oríi Wikipedia, James Gathany, CDC ni ó ni àwòrán. Àwòrán Òde.

Ní àárín ọdún, mélòó kan tí ó kọjá, pàápàá ní àsìkò ìjì ọdọọdún monsoon, iye àwọn tí àìsàn-an ibàa ẹ̀fọn ti kọlù ní Bangladeshì ti lékún síi. Ní ọdún yìí, àwọn tí àìsàn-an ibàá kọlù tó bíi 7,179, àwọn - [2] 2800 [3] ní sáà kínní osùu Agẹmọ nìkan.

Bí ètò ìjọba ò ṣe dántọ́ tó láti borí àjàkálẹ̀ àìsàn ibà tí ó gbòde yìí, àwọn ènìyàn ń gbẹ́kẹ̀le ẹ̀rọ-alátagbà láti fi sọ ẹ̀dùn-un ọkàn-an wọn, pín àlàyé nípa ìtànkálẹ̀ kòkòrò náà, àti ṣe ìkéde nípa bí àwọn ènìyán ṣe le dá ààbò bo ara wọn.

Ibà-ẹ̀fọn ní Bangladesh: ó tó bíi ẹni 2800 tí àìsàn-an nì tẹ̀ wò nínúu àwọn ọjọ́ mẹ́rìndínlógún àkọ́kọ́ osùu Agẹmọ – Outbreak News Today https://t.co/Ey7qUZ6HNR [4]

Àkọsílẹ̀ Àìsàn Pọ̀ Sí i Ní Osù Agẹmọ

Ilé ìwòsàn gba àwọn aláìsàn ibà ẹ̀fọn 403 [2] tí ó pọ̀ jù lọ ní ọjọ́ 22 osù Agẹmọ. Gẹ́gẹ́ bí àwọn onímọ̀ [6] kan ṣe rò, ipa ìyípadà ojú-ọjọ́, òjò àìdágbá kan, ojú-ọjọ́ tó ń ṣe ségesège, àti àìṣèmọ́tótó ni ọ̀dádá tí ó ń dá àtànkálẹ̀ ibà sílẹ̀. Àwọn mìíràn sọ wípé ibà ẹ̀fọn ti ọdún nìí ń ṣekú paon

ju ti ẹ̀yìn wá lọ. Ní ti òǹlò Twitter Md. Saif:

“Ibà-ẹ̀fọn àti àmìi rẹ̀ ní ọdún yìí ti yàtọ̀ nítorí ìdí èyí ni o fi ní láti tọ oníṣègùn rẹ̀ lọ ní kété tí o bá ti ní ibà náà” – gẹ́gẹ́ bí ògbólògbó onímọ̀ ìlera ti Ilé-ìwòsàn Bangabandhu ti sọ. Àwọn ẹ̀yà ara àwọn aláìsàn tí amodi tẹ̀ ti ń daṣẹ́ sílẹ̀ – a kò gbọ́ èyí rí.

Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú ìwé ìròyìn Bangla Tribune [8], Dókítà Gulzar sọ wípé kò sí bí a ṣe lè wo ibà ẹ̀fọn yìí nígbà àkọ́kọ́ tó, kí ó máà tún ṣeni lẹ́ẹ̀ẹkejì.

“এবার ডেঙ্গু ভাইরাস তার ধরন বদলেছে। আগের চেয়ে আরও বেশি দুর্ধর্ষ হয়েছে। ডেঙ্গু শক সিন্ড্রোম করছে বেশি। আরেকটা কারণ হতে পারে বিগত বছরগুলোতে ডেঙ্গুতে আক্রান্ত হয়েছেন অনেকেই। অনেকে হয়তো জানতেও পারেননি তিনি আগে আক্রান্ত হয়েছেন। দ্বিতীয়বার তারা যখন আক্রান্ত হচ্ছেন, তখন ব্যাপারটা ভয়াবহ হয়ে উঠছে।”

Ibà-ẹ̀fọn ti ọdún yìí jẹ́ tuntun, ó sì yára pa ènìyàn. Ó sì ń fa àmì ìfòyà. Ohun tí ó lè fà á lè pọ̀ – ọ̀pọ̀ ni ó kó àìsàn ní ọdún tí ó kọjá, tí wọn kò fura. Bí ó bá tún tẹ̀ wọ́n ní ẹ̀rìn kejì, sààárè ń sún mọ́ nìyẹn.

.

Ìròyìn nípa àjàkálẹ̀ àìsàn yìí ń gba gbogbo orí ẹrọ-alátagbà kan tí ó sì ń mú àìbalẹ̀ara àti ọkàn bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn òǹlo ẹ̀rọ-alátagbà. Shofiq Ahmed pín Túwíìtì kan nípa ìròyìn àìsàn tuntun:

Alákòóso Olùgbé Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé náà papàá ti ní àìsàn ibà-ẹ̀fọn.  .

Òǹlo Twitter Shorbo Bosonto wípé:

Àwọn dókítà méjì kan náà kú látàrí ibà-ẹ̀fọn, èyí sì ti ń mú kí àwọn ènìyàn ó máa bẹ̀rù. Ilé-ẹjọ́ Gíga Dhaka ti fi àṣẹ pe Ọ̀gá  [13]Àgbà Ètò Ìlera ti ìjọba. Àwọn tí ó ń kú nh pọ̀ ọ́ sí i.

Ǹjẹ́ ìjọbá ń ṣe tó?

Ojú-ìwé Facebook ti BBC Bangla rọ [14] àwọn òǹkàwée rẹ̀ láti jábọ̀ àwọn ìgbésẹ̀ akin tí àwọn òníṣẹ́ ìlú Dhaka ń gbé láti gbógun ti ẹ̀fọn. Òǹlò Mohammad Mynuddin jábọ̀ [15] ìfàsẹ́yìn láti ọwọ́ àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba láti kápá àjàkálẹ̀ náà:

A ò tíì rí nǹkan. Òṣìṣẹ́ Àjọ Ìlú kan ti sọ wípé yóò tó ọ̀sẹ̀ mélòó kan kí egbògi ìdáààbòbò tí yó sì dín ẹ̀fọn kù. Ó yà mí lẹ́nu ??

Àwọn kan lérò wípé ìjọba ò mú kiní ibà-ẹ̀fọn ọ̀hún ní kanpá, àwọn ọmọìlú ń lo ẹ̀rọ-alátagbà mú kí àwọn ènìyàn ó mọ̀ nípa kòkòrò náà. Health Barta gbé fídíò kan sí oríi YouTube [16] tí ó ń ṣe àlàyé lẹ́kùnúnrẹ́rẹ́ ohun tí ó pọn dandan láti ṣe bí èèyán bá ní ibà-ẹ̀fọn:

Ọ̀gọ̀rọ̀ l’ó ń d'orí kọ ẹ̀rọ-alátagbà lọ láti gba ẹ̀jẹ̀ fún àwọn aláìsàn. Òǹlo Sajid Islam Khan túwíìtì [17]pé òún nílò ẹ̀jẹ̀ fún àbúrò òun tí ibà-ẹ̀fọn ń bá fínra. Hannan Gazi náà se àgbéjáde tirẹ̀:

Ajagun ẹ̀jẹ̀ #Dhaka
Bọ́ Sí gbangba láti dóólà ẹ̀mí
A nílòo ẹ̀jẹ̀ ní kíákíá ? fún aláìsàn Ibà-ẹ̀fọn
?Ẹgbẹ́ ẹ̀jẹ̀: A- A òdì
?Ẹ̀jẹ̀ tí a nílò: àpò 2
?Nígbà wo: Òní
?Níbo: Shantinagar, Dhaka।
☎Ìkànsíni: 01758410473

Chittagong ṣe àgbéjáde túwíìtì:

Àmì ibà-ẹ̀fọn  àti àtiṣe..

Ní àárín-in àjàkálẹ̀ náà, Alákòóso-ìlú Àríwá Dhaka ti fagilé [24] ìsinmi ránpẹ́ àwọn ikọ̀ tí ó ń rí sí pàntí kíkó àti ìgbégidínà àpọ̀si ẹ̀fọn. Síbẹ̀síbẹ̀, fún ìdáààbò àwọn ènìyàn, ṣíṣe ṣì kú.